Verification Handbook

Ìwé Ìléwọ́ Ìṣàmúdájú jẹ́ ìwé àmúlò fún àwọn oníròyìn àti àwọn tó ń ṣe ìrànwọ́ lásìkò pájáwì láti ilé iṣẹ́ Ìròyìn ilẹ̀ Yúróòpù, ìyẹn European Journalism Centre. Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ohun èlò àti àwọn ohun amúṣẹ́yá àti àwọn ìtọ́sọ́nà lẹ́sẹẹsẹ lórí bí wọ́n yóò ṣe kojú àwọn ohun èlò wọ̀nyí tí a mọ̀ sí European Journalism User-Generated Contents (UGC) lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ pájáwì. Àwọn Èdè tí Wọ́n fi kọ́ọ́

Ta ló ń ṣe Àkóso ilé iṣẹ́: Ìtọ́ni sọ́nà lórí Ìròyìn tó jọ mọ́ Àwọn Ilé Ìṣèjọba tó jíire: Àfihàn lórí Ìròyìn tó jọ mọ́ ilé iṣẹ́ ìjọba tó jíire, pẹ̀lú abala lórí Ìgbìmọ̀ ìṣàkóso, and ìjábọ̀ lórí ètò ìṣúná, àti láti mójú tó bí àwọn ilé iṣẹ́ ṣe ń gbèrú síi. Ẹ̀ka ètò ìṣúná ti ilé ìfowó pamọ́ àgbáyé àti ilé iṣẹ́ tó ń rí sí iṣẹ́ akọ̀ròyìn lágbàáyé ló gbé ìwé ọ̀hún jáde.

Ètò ààbò àti kíkọ Ìròyìn lórí Ááwọ̀:

Àjọ IJNet ti ṣe àkójọpọ̀ ìwé atọ́nà fún oníròyìn tó ń ko ìròyìn jọ lórí ètò ààbò àti làásìgbò láti onírúurú àwọn ilé iṣẹ́. Dìẹ̀ lára wọn wà ní onírúurú èdè bíi Lárúbáwá, Chinese, Russian àti Spanish.

Spanish Nìkan 

Àwọn atọ́ni ṣọ́nà wọ̀nyí wá ní Spanish nìkan. Wo àwọn ìwé ìjábọ̀ tó wà lókè – ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ wà ní Spanish àti pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ wà ní ojú ewé  en Español.