Ìpàdé Àpérò Àgbáyé lórí iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn yóò wà lórí ẹ̀rọ ayélujára ní oṣù kọkànlá, ọdún 2021; Òmíràn yóò wáyé ní ìlú Sydney lọ́dún 2022.
Láti Ìkànnì GIJN | ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀ń, Oṣù Èrẹ́nà, Ọdún 2021
Ìpàdé Àpérò Àgbáyé lórí iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn tó yẹ kó wáyé ní ìlú Sydney, Orílẹ̀ èdè Australia tẹ́lẹ̀ ni yóò wáyé báyìí lórí ẹ̀rọ ayélujára láàárín ọjọ́ kẹta sí ọjọ́ karùn-ún Oṣù Kọkànlá.
Àwọn tí yóò jìjọ gba àlejò náà ni àjọ tó ń rí sí iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn lágbàáyé àti ilé ẹ̀kọ́ Judith tó ń rí sí iṣẹ́ akọ̀ròyìn àti iṣẹ́ ọpọlọ yóò wáyé ní ìlú Sydney láàárín ọjọ́ kẹrìnlá sí ọjọ́ kejìdínlógún, Oṣù Kẹ̀wá, Ọdún 2022.