Òmìnira oníròyìn

GIJN dẹ́ku ìjálé láti ọ̀dọ̀ Aṣojú Russian lórí ilé olóòtú IStories Roman Anin.  

Láti ọ̀dọ̀ òṣìṣẹ́ GIJN | ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, ọdún 2021

Òṣìṣẹ́ IStories, dídá sí àwọn oníròyìn ajáfitafita ní Russia. Roman Anin ni ó jókòó ṣìkejì ní apá ọ̀tún.

Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí Ayélujára lágbàáyé dẹ́ku ìjálé òní lórí ilé Moscow ti Roman Anin, ọ̀kan nínú òṣìṣẹ́ tó ń  gbégbá-orókè ti oníròyìn olómìnira ti Russia, nípasẹ̀ aṣojúti ọ́fíìsì ìjọba-àpapọ̀ aláàbò. Ọgbẹ́ni Anin, olóòtú IStories, ni wọ́n mọ̀ ní jákèjádò gẹ́gẹ́ bí òlótéńté lágbàáyé nínú àwọn oníròyìn aṣèwádìí, àti pé ìgbésẹ̀ àwọn ọ̀gá Agbófinró yìí ni a lè túmọ̀ sí wí pé wọ́n fẹ́ pa iṣẹ́-ìròyìn rẹ̀ lẹ́nu mọ́. Pẹ̀lú àwọn àmì-ẹ̀yẹ Anin, ó jẹ́ akẹgbẹ́ iṣẹ́-ìròyìn John S. Knight ní ọdún 2019 àti pé wọ́n bu ọlá fún un ní Ayẹyẹ Àmì-ẹ̀yẹ Trailblazer ní ọdún tó kọjá láti Àáríngbùngbùn àwọn oníròyìn nì gbogboogbò.

GIJN dúró fún mọ́kànlá-lé-nígba àjọ ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde ní eéjì-lé-lọ́gọ́rin orílẹ̀-èdè. A ó máa wò ó ní pẹ́kípẹ́kí láti rí i dájú pé wọn kò fi igbákan bọ̀ kan nínú lórí ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ̀ni Anin lábẹ́ òfin Russian àti òfin gbogboogbò.

Fún Àfikún Àlàyé:

OCCRP

Istories

Àlàyé EU lóri ìjále Anin, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò