Ohun tó Yẹ kó o ṣe Lásìkò tí Wọ́n Tẹ̀lé Ọ tàbí Orísun Rẹ

Láti ọ̀dọ Rowan Philip | ọjọ́ kẹtà-dín-lógún oṣù karùn-ún, Ọdún 2021

Harvey Weinstein lẹ́yìn ìgbà tí ó fara hàn ní Ilé-Ẹjọ́ ní New York. Wọ́n padà sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì dá ẹjọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méta-lé-lógún fún un. Àwòrán: Shutterstock

Ní ọdún 2017, Ronan Farrow, oníròyìn Aṣèwádìí ní New Yorker, ṣàkíyèsí àwọn ohun àjèjì tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe ìwádìí  lórí ẹ̀sùn ìfipá báni lòpọ̀ tó lòdì sí Hollywood Mogul Harvey Weinstein. Lórí ètò pọ́díkásììtì rẹ̀ tó pè ní Catch and Kill, ó ṣe àpèjúwe wí pé ò ń kó fìrí ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ ní ìta ilé òun àti ìtanijí lórí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀, èyí tí ó mú ìfunrasí dání, tí òun sì ní láti kó gbogbo àwọn ohun-èlò ìwádìí rẹ tì mọ́ inú àpótí tópamọ́.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, arákùnrin Ukraini kan, Igor Ostrovskiy,  kàn sí Farrow láti jẹ́wọ́ pé òun jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn oníṣẹ́ tí ó ti ń ṣọ́ Farrow, bẹ́ẹ̀ sì ni òun tún ń ṣọ́ oníròyìn mìíràn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ẹjọ́ Weinstein – Jodi Kantor ti New York Times. Ó sọ fún Farrow wí pé ilé-iṣẹ́ aládàáni ti Israeli intelligence agency ló gba òun. Lórí Àkọsílẹ̀ tó lérè, Ostrovskiy ṣàlàyé pé wọ́n tì òun láti di olófòófó lórí ẹjọ́ yìí lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣàkíyèsí pé ìṣọ́ tí àwọn oníròyìn Aṣèwádìí ni le ṣe àkóbá fún irúfẹ́ oníròyìn olómìnira tí ó ń fẹ́ má a gbé inú rẹ̀. 

Weinstein ti wà ní ọgbà ẹ̀wọn láti ọjọ́ tó ti pẹ́ fún ẹ̀sùn ìfipá-báni-lòpọ̀, àti pé ìtàn aṣèwádìí tí ó ṣáájú ìpejọ́ ní ilé-ẹjọ́ ló ṣe ìrànwọ́ òkùnfa ípéjọ tó lòdì sí ìfipá-bání-lopọ #MeToo lágbàáyé.

Sí bẹ́ẹ̀, ìfihan Ostrovskiy tún tẹnumọ́ ìdàgbàsókè ìhalẹ̀mọ́ni ti ìṣọ́ ojú-ayé tí oníròyìn Aṣèwádìí àti àwọn orísun rẹ tí wọ́n dojú kọ, èyí tí Farrow padà ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀ “Catch and Kill.”

“A ní èrò pé tí Ronan [Farrow] bá lọ lòdì sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ orí-ẹsẹ̀, tí ó wá yin ọkọ̀-akérò, àwọn oníṣẹ́-ẹsẹ̀ máa tẹ́ ìjàm̀bá ẹlẹ́sẹ-ẹsẹ láti dá ọkọ̀-akérò dúró” – Olùwádìí Aládáani Igor Ostrovskiy

Farrow sọ wí pé ìfikọ́ra ti “oníròyìn tó ń dọdẹ” wá níṣe pẹ̀lú ohun tí ojú ri àti ìṣọ́ orí-ẹ̀rọ ayélujára, èyí tí o “ní àwọn àkóbá tó tóbi lágbàáyé.”

Ní oṣù kẹta, Àwọn Olóòtú àti Oníròyìn Aṣèwádìí, àwọn àtapọ̀ ti àwọn oníròyìn Aṣèwádìí tí ó tẹ̀dó sí US, pe Ostrovskiy láti ṣe ìyánrọ̀ fẹ́rẹ́ fún àwọn oníròyìn lórí bí wọ́n ṣe le mọ àti ṣe pẹ̀lú ìṣọ́ ojú-korojú ní Àpérò déétà Oníṣẹ́-ìròyìn NICAR21.

Ògbólóògbó Aṣèwádìí Aládàáni – tí ó ṣì ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ẹ̀ – sọ fún àwọn tó wá pé wí pé wọ́m máa ń pàṣẹ ìṣọ́ni ní gbogbo oníròyìn Aṣèwádìí láti dá àwọn orísun mọ̀, láti dín ipa ìtàn tó ń bọ̀ kù, pa átíkù, kó “àtìlẹ́yìn ìfẹ̀sùnkan-ènìyàn” jọ – tàbí àpapọ̀ àwọn èyí. Ostrovskiy sọ pé ìhalẹ̀mọ́ni tàbí ìwà-ipá ṣọ̀wọ́n – àti pé ó kọ ọgbọ́n tí kò bá òfin mu nínú iṣẹ́ rẹ̀ – ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ìjayà kan wà tí àwọn òṣìṣẹ́ lò tí ó lòdì sí àwọn oníròyìn lórí ẹjọ́ Weinstein.

“Ni lọ́kàn pé òfin de àwọn oníròyìn Aládàáni bí wọ́n bá ń wá ẹ̀rí tí illé-ẹjọ́ gbà wọlé,” àwọn ìwé e Ostrovskiy. Iṣẹ́ ìṣọ́ le wà níbi tí àfojúsùn wọn yóò jẹ́ àtìlẹyìn ìfẹ̀sùnkan-ènìyàn, ṣùgbọ́n níbi tí àfojúsùn wọn mìíràn ti jẹ́ láti fòpin sí ìtàn. Gẹ́gẹ́ bí oníròyìn, ó ní láti ṣe àgbéyẹ̀wò lórí ẹní tí ọ̀tá rẹ jẹ́, ohun tí ó jẹ́ ọ̀nà ìrówó wọn jẹ́, àti ojun tí wọ̀n ti ṣe sẹ́yìn.”

Ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí wọ́n mú kúrò nínú ìgbékalẹ̀ ni pé àwọn aṣèwádìí aládàáni kò ní àǹfààní sí téèpù pupa àti pé èyí máa ń fa orí-fífọ́ – àti pé àfojúsùn àwọn oníròyìn le lo akitiyan ìṣọ́ni tán nipá mímú wọn wọ́n si. Ostrovskiy ní pé oníròyìn tí wọ́n fojú sí lára tó ń sun ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀, fún àpẹẹrẹ, ó le jẹ́ kí ẹgbẹ́ tó ń ṣọ́ni má sùn títí tí ilẹ̀ yóò fi mọ́ ní òpópónà tí wọn kò mọ̀, kí ó dá iye owó tó lágbára fún òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ wọn, tàbí àkòrí ìwádìí oníròyìn náà.

“Ohun tí a ṣe sínú nǹkan ‘success fee,’” Ostrovskiy ṣàlàyé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà níbi tí wọ́n ti dá àwọn olùwádìí dúró láti kọ ìtàn. “Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀gá mi kò le rárá tó fi jẹ́ wí pé bí wọ́n bá rán mi lọ sí ilé-olóúnjẹ, wọ́n máa ń bi mi lèèrè iye owó mi. Ọ̀nà ìkọnusí-èèyàn lọ́nà tí ò le yìí ni ó sún déọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ méjì tí wọ́n jóòkó sínú ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ kan náà, nítòsí irin panápaná kan tó wà níbi ojúde ilẹ̀kùn Ronan. A wà níbẹ̀ ní àìmọ̀ iye ìgbà tí alámòójútó ilé Ronan fi mọ irú sìgá tí a ń mu.”

Àwọn olùwádìí náà máa ń ṣe àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ̀pẹ́.

“Nígbà tí à ń wá Ronan, lérèfé a tẹ̀lé alábágbé rẹ̀ ní òpópónà, èyí tí ó fọgbọ́n jọ Ronan,”Ostrovskiy rẹ́rìn-ín. “Mo mọ nọ́ḿbà ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ Ronan, nítorí bẹ́ẹ̀ [mo pè é láti fi yẹ̀ ẹ́ wò] àti pé nígbà tó gbé e, mo mọ̀ wí pé ó wà nínú ilé, báyìí ni a ṣe mọ̀ wí pé ọ̀tọ̀ ni arákùnrin tí à ń tẹ̀lé.”

“Dídúró sí ibòmíràn, bí i sísùn sí ilé ọ̀rẹ, máa ń jẹ́ kí àwọn tó ń ṣọ́ni má sùn títí ilẹ̀ fi má a mọ́ nínú ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ ní tipátipá. ṣọ̀wọ́n láti tẹ̀lé.” – Igor Ostrovskiy

Gẹ́gẹ́ bí oníwọ̀ntunwọ̀nsì ní ìpàdé àkanṣe-iṣẹ́ NICAR21, Sean Sposito –  ẹni tí ó jẹ́ atúnǹkanká nínú ẹ̀ka fún ìròyìn lórí àìléwu ti ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde lórí ẹ̀rọ-ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ ní Verizon – àwọn oníròyìn ọgbọ́n inú tí wọ́n ṣètò láti dojúkọ ìṣọ́ ti ara ẹni.

“Ṣá à jẹ́ ẹní tí ó ń wá àwáfin ní ọ̀rọ̀ ara ẹni gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ ní ìgbé-ayé iṣẹ́ rẹ̀,” Sposito dá àbá. “tẹ̀síwájú láti jẹ́ oníròyìn gidilẹ́yìn àwọn wákàtí kan, kí o sì jẹ́ ẹni tó ń ṣọ́ra sí àwọn nǹkan tí ó wà ní ìta.”

Ostrovskiy ṣe àlàyé àwọn ọgbọ́n tí àwọn gbọ́dọ̀ wò láti dènà àwọn akitiyan àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣọ́ni tí wọ́n dàbí òun.

Bí A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Amí Le Sí I.  

 • Bá èrò àwọn amí jẹ́ nípa ṣíṣàròyé lórí ìmọ́tótó ẹ̀rọ-ayélujára. Láti rí i dájú pé àwọn òṣìsẹ́ kò le gbèrò lórí àwọn ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣọ́ ènìyàn ṣáájú àkókò, fi àtẹ́ àkókò-iṣẹ́ rẹ̀ pamọ́, nípa lílo ìkànnì tí ìbára-ẹni-rẹ̀ sọ̀rọ̀ ń pàrokò bi Signal àti ProtonMail àti ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé ìfaṣẹsí ìfọ́síwẹ́wẹ́-méjì lórí ẹ̀rọ-ayélujára rẹ. “Bí o bá wá ní òkè àìléwu ẹ̀ro-ayélujára rẹ, a kò ní ní àlàyé lórí ìbánisọ̀rọ̀ rẹ tàbí àtẹ àkókò-iṣẹ́ rẹ, nítorí bẹ́ẹ̀, a fi ipá mú wa láti gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ìrìn ojú-ayé,” Ostrovskiy ló sọ bẹ́ẹ̀.
 • Lo oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìrinsẹ̀ – lòdì sí ọ̀rọ̀ súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ní òpópónà ọlọ́nà-kan. “fi tipátipá mú mi láti yí ọ̀nà ìṣíni-nípòpadà, wọ ọkọ̀, wọ ọkọ̀-ojú-irin, ṣe ìfowó-ránṣẹ́ tó lé. Ó gbà wọ́n ní ìyànjú. “ A ní èrò wí pé tí Ronan bá lòdì sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ tẹsẹ, tí ó wá gbóríyìn fún ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn òṣìṣẹ́ ẹsẹ̀ máa jẹ́ kí ìjàmbá aláfẹsẹ̀rìn wáyé láti dá àwọn ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ dúró, nítorí náà awakọ tí ìjàm̀bá náà ṣẹlẹ̀ sí yóò ní àyè láti dí ọ̀nà. Mo ti gbáradì láti bẹ́ sí ìbòrí ọkọ̀.”
 • Jẹ àbá àwọn tó ń ṣọ́ ọ run. “Gbígbé ní ibòmíràn, bí sísùn ní ilé ọ̀rẹ́ rẹ, máa ń jẹ́ kí àwọn tó ń ṣọ́ ọ  má sùn nínú ọkọ̀ wọn lálẹ́ pẹ̀lú tipátipá.” Ni ó sọ. Níkẹyìn, rí i wí pé o sọ̀wọ́n láti tẹ̀lé, ṣe àpò wọn léṣe.
 • Lo ọ̀nà mìíràn láti jáde, pàápàá jùlọ, ní àwọn ilé ìtajà. “Nígbà tí o bá ní ìpàdé tó ṣe pàtàkì láti lọ, ní èrò láti gbẹ́ kòtò fún àwọn tó ń ṣọ́ ẹ kí wọ́n má mọ̀ wí pé o mọ̀ mọ́ ṣé ni.” Ostrovskiy ló ṣọ bẹ́ẹ̀. “Àwọn ilé ńlá pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àwọn ọ̀nà àbájáde bójú mu. Lo oríṣìíríṣìí ọ̀nà àbájáde ní ilé ìtajà kí o sì tún lo ọkọ̀ alájọwọ̀pọ̀ – bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n á bá ọ nílé rẹ níkẹyìn ọjọ́ náà, ṣùgbọ́n o ti rí wákàtí díẹ̀ láti dá wà.”
 • Pa àwọn ìtanilólobó ìròyìn tó jẹ ti ara rẹ kúrò nínú àtẹ àwọn oníbàárà àti ìkànnì ayélujára Adúnàádúrà. “Bí mo bá jẹ́ oníròyìn tó ń ṣiṣẹ́ lórí irúfẹ́ ìtàn yìí, mà á ṣe àkọsílẹ̀ ara mi,” ni ó sọ. “Nítorí bẹ́ẹ̀, [ẹ lọ sí]  wá ohun gbogbo lórí ara rẹ ní Yandex lórí ìtàkùn àgbáyé Google, palẹ̀ ohun gbogbo tí ó jẹ́ kí ó rọrùn fún wọn láti rí ọ níta, kí o sì kúrò ní gbogbo ìkànnì tí ààtò détà rẹ wà. Ìkànnì ayélujára tí ó da ni FamilyTreeNow – ó fẹ́rẹ̀ jọ èsì tí mo gbà ní iṣẹ́ tí wọ́n san owó rẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ọ̀fẹ́ àti pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yọ kúrò nínú àwọn ààtò náà.
 • Jẹ́ ẹni tí wọn kò sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ sí. “ jẹ́ kí àwọn ìlànà-iṣẹ́ tinú ọkàn rẹ wá – kì í ṣe láti lé ọ, ṣùgbọ́n láti jẹ́ kó nira fún wa láti tẹ̀lé ọ, nípa fífogun mú wa láti lo àwọn ohun èlò sí i.”
 • Má ṣe dárúkọ àwọn ètò rẹ lórí ìtàkùn ayélujára. “Ronan dáa – àfojúsùn tó le,” ló sọ. “Mà á wo ìkànnì ẹ̀rọ ayélujára rẹ̀ àti ìtàkùn àgbáyé Instagram, kò sí ohunkóhun lórí àwọn ètò rẹ tàbí ibi tí ó wà. Kò fi bẹ́ẹ̀ wá sí ilé; Los Angeles ló ń dúró sí.”
 • Bí ṣíṣọ́ bá ti ń di lemọ́lemọ́, fúrúgbìn sí orí ìkànnì ẹ̀rọ ayélujára àti ìbẹ̀wẹ̀ fún káàdi ìsanwó pẹ̀lú ‘Ásíà èké’ “fi àwọn àwòrán láti ibi tí o jáde lọ ní ọ̀sẹ̀ pamọ́, lẹ́yìn ìgbà náà ni kí o wá kó wọn sí orí ìtàkùn ayélujára lẹ́yìn ìgbà tí o bá dé, àwọn ènìyàn á fi rò wí pé o ṣì wà ní Paris,” Ostrovskiy mú àbá wá. “ju àwọn ènìyàn sílẹ̀. Bu ọwọ́ lu ìwé fún àwọn onítàkùn ayélujára kí o sì ṣe ààtò oríṣìíríṣìí àdírẹ̀sì. Ṣe àfikún orúkọ ilé-iṣẹ́ kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pinrọrọ pé o wà níbi tí o kò sí. Lo Àpótí ìfìwé-ránṣẹ́ sí lẹ́yìn ìgbésẹ̀ rẹ tó tẹ̀le.

Bí O Ó Ṣe Mọ̀ Wí Pé Wọ́n Tẹ̀lé O.  

 • Ṣàkíyèsí àwọn tí ẹ jọ san owo ọkọ̀ kan náà aláfiránṣẹ́ tí ìwọ náà ṣe. ṣùgbọ́n má kọbi ara si,” Ostrovskiy ṣàfikún.
 • Wo àwọn tí ó kúrò ní orí ìlà ààbò tí o wà. Eléyìí níṣe pẹ̀lú àwọn orí-ìlà tí ó wà ṣáájú àwọn olùwá irin rí àti ibi àyẹ̀wò ní ilé-ẹjọ́ àti pápá ọkọ̀-òfúrufú.
 • Pinrọrọ láti máa ka àwọn àkójọ àṣàyàn ní ojú-fèrèsé ilé-olóúnjẹ kí o sì dọ́gbọ́n fojú wo àwọn tó ń ṣe ohun tó yàtọ̀ – bí ẹni tí ó ń ka àwọn àkójọ àṣàyàn. “ Bí o bá ń ṣe é rìn, kí o máa yà – má rìn ní ọ̀nà tí wọn yóò fi mú ọ, ṣùgbọ́n kọ́lọkọ̀lọ kí o sì kọbi ara sí àwọn tó wà lẹ́yìn rẹ,” Ló sọ.
 • Kọ bi ara sí bàtà àwọn ènìyàn.  “Bàtà máa ń ṣòro láti pàrọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ – wọ́n máa ń jẹ́ ohun aṣàmìsí ètò ohun tí ẹni yẹn fẹ́ ṣe lọ́jọ́ yẹn; wá àwọn [bàtà ẹsẹ̀ tí kò bójú mu], ló sọ. “Ní ibi tí wọ́n ti ń ṣọ́ni, mo fẹ́ràn láti wọ bàtà dúdú tí ìtẹ̀lẹ̀ rẹ̀ rọ̀ nígbà ooru fún ìtura àti bàtá dúdú tí ó bo gbogbo ẹsẹ̀ nígbà òtútù.”
 • Ní kí ọ̀rẹ́ rẹ máa ṣọ́ àwọn ọkọ̀ tí ó wà lẹ́yìn rẹ – pàápàá jùlọ àwọn tó wà ní ìdáàbú. “Nígbà mìíràn, nítorí owó níná, a máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọkọ̀ kan níbi tí ó yẹ kí á ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀, èyí tí ó jẹ́ àǹfààní fún ọ láti rí wa,” ni ó sọ. “Ìwọ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ le wá àwọn àmì bí àwọn ọkọ̀ tí ó wà lẹ́yìn rẹ tí o lọ tààrà lẹ́yìn ìgbà tí o yà, láti wa dí ọ lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fara hàn. Tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì, wọ́n ń tẹ̀lé ọ.”
 • Fi ipá mú àwọn tó ń ṣọ́ ọ láti súnmọ́ ọ ní wákàtí tó ń kánjú. “Tí o bá wà ninú ọkọ̀-alájà-ilé tí ó kún fún èrò, a ó nílò láti wà ní tòòsí ní èyí tó jẹ́ àrọ́wọ́tó láti le sọ ìrìn rẹ fún àwọn akẹgbẹ́ wa tí a ń jọ ṣiṣẹ́,” ni ó sọ. O le kíyèsí wa – a kò le rí i nínú èrò.
 •  Ka ìwé lórí ìṣọ́ni àti kíkó àwọn ipa-ọ̀nà ẹ̀rọ ayélujára jọ. Èyí níṣe pẹ̀lú àwọn ìwé “Open Sourse Intelligence” láti ọwọ́ Michael Bazzel, tàbí “Extreme Privacy: What it takes to Disappear in America”  láti ọwọ́ òǹkọ̀wé kan náà. “Èyí ni àwọn ìtalólobó tó lágbára níbẹ̀,” Ostrovskiy ló ṣàkíyèsí èyí. 

Ohun Tó Yẹn Kí O Ṣe Lẹ́yìn Ìgbà Tí O Bá Tí Ká A Pé Wọ́n Ń Ṣọ́ Ẹ. 

 • Pe ọlọ́pàá tí o bá lérò wí pé o wà nínú ewu tó le pani lára. “Tí o bá lérò wí pé o wà nínú ewu, o níló láti kìlọ̀ fún àwọn orísun rẹ àti àwọn olóòtú rẹ,” ló sọ. “Tí o bá rí i wí pé o wà nínú ewu ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀, lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá. Àmọ́ bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀,o máa nílò láti dáhùn àwọn ìbéèrè lórí àpèjúwe – àwọ̀ rẹ̀, ilé-iṣẹ́ tó ṣe é àti irúfẹ́ ọkọ̀ náà àti nọ́ḿbà ìwé-àṣẹ ọkọ̀ wọn;bóyá àwọn ìwà tó yàtọ̀ wà, níbi tí ó ti ṣàkíyèsí àwọn òṣìṣẹ́ náà àti ìgbà náà.
 • Má súnmọ́ àwọn tó ń tẹ̀lé ẹ – má sì ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ̀ wí pé o ti rí wọn. “Má ṣe jẹ́ kí irú ènìyàn bí èèmi bínú!” ni Ostrovskiy sọ. “Ó ṣe pàtàkì láti má jẹ́ kí àwọn tó ń ṣọ́ ọ mọ̀ wí pé o ti rí àwọn, nítorí ó le jẹ́ kí ìhalẹmọni tàbí ìwaà-ipá pọ̀ si,” ni ó sọ. “Má ṣe juwọ́ sí mi tàbí fún mi ní ìka. Ṣùgbọ́n o lè rìn láti ibìkan sí ibòmíràn – jẹ́ kí ó rẹ àwọn ẹgbẹ́ pẹ̀lú bí o ṣe ń yí ọkàn padà, nítorí bẹ́ẹ̀ wọn kò le lọ sí balùwẹ̀ tàbí kí wọ́n sinmi.”
 • Sètò àwọn ìpàdé tí ó le ní ilé-ẹjọ́ ìjọba, tàbí ní agbègbè pápá ọkọ̀-òfúrufú tí ó kọjá ibi àyẹ̀wò ààbò. “Pàdé nínú ilé-ẹjọ́ ìjọba  níbi tí àwọn ẹgbẹ́ náà kò ti le gbé àwọn ẹ̀rọ oníná wọlé, wọ́n á fi ipá mú wọn láti gba ọ̀dọ̀ àwọn aláàbò,” ni ó sọ.
 • Bí o bá wà ní abẹ́ ìṣọ́ ti òṣìṣẹ́ ìjọba, gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ agbẹjọ́rò àti àwọn ààbò ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí kò jèrè. “Citizen Lab àti Electronic Frontier Foundation jẹ́ àwọn ibi tí ó dára láti lọ bí o bá lérò wí pé ipò orílẹ̀-èdè ń fojú sí ọ lára,” ni ó sọ. “Bí ọlọ́pàá bá tẹ̀lé ọ ni orílẹ-èdè àjòjì, o nílò láti kúrò ní orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀, tàbí kí o lọ sí ilé-iṣẹ́ tí ó rọ́pò orílẹ̀-èdè kan ní orílẹ̀-èdè mìí, nìtorí o lè dojúkọ àwọn ewu sí ẹ̀mí rẹ.”
 • Lo ẹ̀rọ-ìbáraẹni-sọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lú àwọn orísun rẹ – ẹ pàdé lẹ́ẹ̀kan bí ẹ bá nílò láti pàdé. “Tí ìwọ àti orísun rẹ bá nílò láti pàdé lójúkorojú, ẹ gbìyànjú láti ní ìpàdé kan ní ìbẹ̀rẹ̀, níbi tí ẹ ti le ṣe àgbékalẹ̀ èrò yìí lórí ìtako àwọn tó ń ṣọ́ ọ yín,” ni ó sọ. “O nílò láti rò ó láti má dẹ́rúba àwọn orísun rẹ. O le wá àwọọn ibi tí ẹ ti lè paàdé tó le fún àwọn àjèjì láti wọ̀.”
 • Ṣètò kóòdù tó ṣeé se pé ó rọrùn jù láti ta àwọn orísun rẹ jí sí ìhalẹ̀mọ́ni àwọn alamí. “Àwọn ìlànà tó wọ́pọ̀ ni láti ṣètò láti pe ẹnìkọ̀ọ̀kan tí orúkọ wọn jọ́ orúkọ rẹ – dípò orúkọ rẹ àkọ́kọ́, mo le pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ́ bàbá rẹ, àwọn orísun rẹ yóò sì mọ̀ wí pé nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀ tí kò tọ́,” Ostrovskiy ló ṣo ọ. “Wọ́n á mọ̀ wí pé àwọn kò gbọ́dọ bá ẹnikẹ́ni sọ ohun tó ń gbèrò láti sọ.” Nígbà tí Ostrovskiy kọ́kọ́ kàn sí Farrow, ó rán ohun tí ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́, ọ̀rọ̀ tí kò lámì lórí I “ìkòkò ìdí-nǹkan tó ha alátakò,” tí ó jẹ́ àpólà tí Farrow lò ọ̀rọ̀ àtẹ̀ránṣẹ́ tó gbé sí ìtàkùn ayélujára. Lórí ètò pódíkásìtì rẹ̀, Farrow sọ pé èdè alámì yìí ti tó láti fi ṣe ìtanijí fún òun láti fi mọ̀ pé àtẹ̀ránṣẹ́ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni tó ń tẹ̀lé òun. 
 • Ṣọ́ ara nítorí àwọn òṣìṣẹ́ yìí le ṣe bí oníròyìn láti fi ọ̀rọ̀ wá àwọn orísun rẹ lẹ́nu wò. “Àwọn ilé-ìṣẹ́ ti gba àwọn oníròyìn tẹ́lẹ̀ rí láti ṣe bí oníròyìn tó jẹ́ ojúlówóláti mọ ohun tí orísun ti ń fún àwọn oníròyìn tó kùn, tàbí kí ẹnikan pinrọrọ láti fi fọ̀rọ̀ wá oníròyìn lẹ́nu wò fún iṣẹ́,” lo sọ. “Wọ́n ní kí n gba ẹni-tó-ń-wáṣẹ́ láti ṣètò ayédèrú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu-wò [fún oníròyìn].”

Ó wù ọ́ láti mọ̀ sí láti ọ̀dọ̀ NICAR21? Ẹ lè rí àtẹ àkókò-iṣẹ́ tó kún níbí. Wọn kò ṣe àkọsílẹ̀ ìgbà ìṣọ́ni-orítábìlì, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ni a ní ẹ̀tọ́ sí tí a sì le yẹ̀wò di oṣù kẹta ọdún 2022 láti ìkànnì yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé o máa nílò láti forúkọ kalẹ̀. 

Àfikún Àwọn Ohun-Èlò

Ìlọsókè ìṣọ́ni-ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ní kíákíá.

Dídáàbò bò ara ẹni lórí ẹ̀rọ-ayélujára fún àwọn oníròyìn: Ìfáàrà

Ìkànnì ohun-èlò GIJN: Ààbò ẹ̀rọ ayélujára.

Rowan Philip jẹ́ oníròyìn fún GIJN. Ó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ọ̀gbá-àgbá oníròyìn fún Sunday Times ní South Africa. Gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé-ìròyìn ní ilẹ̀ àjẹ̀jì, ó ti jábọ̀ lórí ìròyìn, òṣèlú, jẹgúdújẹrá, àti aáwọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó ju mẹ́rin-lé-lógún lọ káàkiri àgbáyé.