gijn-logo

Ohun èlò: Ató̩nà láti rí orísun tí ó dáńtó̩Guides to Finding Expert Sources

Láti o̩wó̩ Kira Zalan | May 23, 2016

Ǹjé̩ e̩ ń wá àwo̩n orísun? Rírí onímò̩ ní apá ibì kan jé̩ ibi tí ó dára láti bè̩rè̩ fún ò̩pò̩ ìtàn. GIJN s̩e àyè̩wò ò̩pò̩ àwo̩n ató̩nà sí àwo̩n abé̩nà ìmò̩. Lé̩yìn tí a tig é àwo̩n tí kò bá ìgbà mu mó̩ dànù, tàbí àwo̩n tí ó jé̩ pé ibì kan ni wo̩n mo̩ sí, tàbí àwo̩n irins̩é̩ ìpolongo, a rí àwo̩n díè̩ tí wo̩n s̩e é bè̩wò. Èyí ni mé̩fà nínú àwo̩n is̩é̩ tí ó ń wúlò, àko̩sílè̩ tí àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn tó ń wá abé̩nà ìmò̩ lò. 

E̩ tún kàn sí àwo̩n onímò̩ obìnrin ní Women in Journalism Resource Center ti GIJN

SciLine, tí American Academy for the Advance of Science s̩e onígbò̩wó̩ rè̩, jé̩ “irins̩é̩ olómìnira ti ó wà nílè̩ ló̩fè̩é̩ tí ó sì máa ń s̩e àgbékalè̩ ààyè sí abé̩nà ìmò̩ tí ó s̩e é gbàgbó̩, tí ó sì dára fún àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn ati àwo̩n sò̩rò̩sò̩rò̩ mìíràn tí wo̩n ń s̩e àgbéjáde àtè̩jáde, ìgbóhùnsáfé̩fé̩ tàbí àko̩sílè̩ orí ayélujára tí ó je̩ mó̩ ò̩rò̩ sáyé̩ńsì ní àsìkò tí ó tó̩. E̩ ó s̩e àfikalè̩ ìbéèrè orí ayélujára, ìgbà tí yóò tán àti onímò̩ tí e̩ nílò.

Request a Woman Scientist tí ó jé̩ ìtàkùn tí è̩é̩dé̩gbè̩ta àwo̩n obìnrin onímò̩-sáyé̩ǹsì s̩e onígbò̩wó̩ “s̩e àsopò̩ àwo̩n ìtànká tí ó ga fún àwon obìnrin onímò̩-sáyé̩ǹsì tí a ti jé̩rìí pè̩lú e̩ni tí ó bá fé̩ s̩e àyè̩wò pè̩lú onímò̩-sáyé̩ǹsì fún ìtàn ìròyì, pípe olùbánisò̩rò̩ pàtàkì tàbí olùbánidásí fún ìdánilé̩kò̩ó̩ tàbí è̩kó̩sé̩, wá onímò̩-sáyé̩ǹsì obinrin láti bá dà pò̩ lórí àkàns̩e is̩é̩, tàbí jé̩ abé̩na ìmò̩ ní ò̩nà kankan”. 

Diverse Sources jé̩ àko̩sílè̩ tí a lè wá fú àwo̩n onímò̩ tí ojú wo̩n kò fi bé̩è̩ hànde ní igun sáyé̩ǹsì, ìlera àti àyíká.

Expertise Finder, tí ó jé̩ dídá sílè̩ láti o̩wó̩ e̩ni tí ó ti fi ìgbà kan rí jé̩ onís̩é̩-ìròyìn àti onímò̩ è̩ro̩, máa ń gbà àwo̩n oníròyìn láàyè láti rí onímò̩ ní ibi è̩ka ìmò̩ wo̩n. E̩ńjìnì ìwá-nǹkan náà máa ń s̩e àgbéjáde àko̩sílè̩ àwo̩n oŕsun tí wo̩n ti jé̩rìí láti àwo̩n ilé-è̩kó̩ fáfitì tí wo̩n lù lóǹtè̩ ní US  àti Canada pè̩lú àwo̩n agbo ìmò̩ àmò̩dájú mìíràn. Àwo̩n ojú ewe orísun s̩e àgbákalè̩ àwo̩n èka ìmò̩, àko̩sílè̩ tí ó dáńtó̩ àti bí a s̩e lè kàn sí wo̩n. Ètò yìí jé̩ ò̩fé̩, ilé-is̩é̩ náà sì ní ìròyìn sís̩e àgbéjáde owó nípa kíko̩ ató̩nà tí ó dáńtó̩ fún àwo̩n ilé-è̩kó̩ gíga.

SheSource, àkàns̩e is̩é̩ ti e̩gbé̩ aláìgbó̩kàn-lé-èrè Women’s Media Center, jé̩ àkó̩jo̩pò̩ ìmò̩ ti e̩gbè̩rún lé ní o̩gó̩rùn-ún obìnrin tí a ti jé̩rìí sí káàkiri àgbáyé, tí a lè fi orúko̩, kókó ò̩rò̩ àti è̩ka ìmò̩ wá jáde. Àwo̩n àkó̩sílè̩ nípa ènìyàn àti àwòrán láti orísun jé̩ fífisílè̩ tí àwo̩n onímò̩ sì s̩e é kàn sí láti orí ìtàkùn ayélujára.

Women Plus  jé̩ àkójo̩pò̩ àwo̩n onímò̩ té̩è̩kì tí wo̩n lé ni è̩é̩dé̩gbè̩rin lé ní àádó̩ta tí a tò̩ nií ìpele ìpele.

Expertfile s̩e àgbékalè̩ àwo̩n onímò̩ lórí àkòrí tó lé ní e̩gbè̩rún márùndínló̩gbò̩n. ExpertFile ti s̩e àtè̩jáde àjo̩s̩epò̩ pè̩lú e̩gbé̩ ìròyìn tí ó tan mó̩. 

The China-Africa Project ní orísun fún sís̩e àko̩jo̩pò̩ àwo̩n àko̩sílè̩ àwo̩n akó̩s̩é̩mo̩s̩é̩ ní gbogbo abala àjo̩s̩epò̩ láàrin China àti Áfíríkà.

ProfNet jé̩ dídarí pè̩lú alukoro Newswire tí ó sì jé̩ ò̩fé̩ fún àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn tí wo̩n bá ti fi orúko̩ sílè̩. 

Finding Experts Using the Internet 2018 jé̩ àkó̩jo̩pò̩ ò̩pò̩ àwo̩n orísun ìmò̩ tí a fiyè sí tí Marcus P. Zillman kó jo̩ fún LLRX (Law and Technology Resources for Legal Professionals). LLRX.com jé̩ dídá sílè̩ ní o̩dún 1996 láti o̩wó̩ olùdásílè̩, as̩àtúnko̩ àti atè̩wéjáde Sabrina I. Pacifici.

The Conversation Research and Expert Database, s̩e àkójo̩pò̩ àwo̩n òǹkò̩wé tí wo̩n ti hànde rí nínú The Conversation, “orísun olómìnira fún ìròyìn àti ìwòran tí wo̩n ń gbé jáde tààrà fún àwo̩n ará-ìlú”. 

Help a Reporter Out (HARO) jé̩ ti Cision, ilé-is̩é̩ oníròyìn ò̩te̩lè̩múyè̩ tí ó wà ní Chicago, tí ó sì ní is̩é̩ ìforúko̩sílè̩ ò̩fé̩ tí ó ran àwo̩n oníròyìn láti ibùdó àìláforúko̩sílè̩ ló̩wó̩ láti s̩e ìbéèrè tí ó ń so̩ ìhun ìtàn wo̩n, ìrètí àti o̩jó̩ tí yóò parí.  Ìbéèrè máa ń jé̩ gbígbéyè̩wò ló̩wó̩ àwo̩n as̩àtúnko̩ HARO tí wo̩n yóò sì fi ráns̩é̩ nípasè̩ ímeèlì sí orísun tí wo̩n ti fi sílè̩ àti, tàbi oníròyin as̩ojú wo̩n. Gé̩gé̩ bí èrò ilé-is̩é̩, e̩gbè̩rún ló̩nà márùndínló̩gó̩ta onís̩é̩ ìròyìn àti e̩gbé̩rún ló̩nà e̩gbè̩rin orísun ni ó wà ní ìforúko̩sílè̩ pè̩lú wo̩n. Wo̩n s̩e àfihàn ímeèlì ìbánisò̩rò̩ wo̩n.

Google Scholar àti Microsoft Academic  jé̩ ibùdó ìmò̩ tí ó máa ń fún àwo̩n olùwádìí ní àko̩sílè̩ kíkún lórí àwo̩n is̩é̩ akadá tí wo̩n ti jé̩ títè̩jáde pè̩lú àwo̩n òǹkò̩wé nípa wíwá olóríjorí. Èsì lè jé̩ sís̩e ní pàtàkì nípa ìlò déètì àti iye ìtó̩ka láti jé̩ kí a mo̩ àwo̩n abé̩nà ìmò̩ tí wo̩n s̩e pàtàkì jùlo̩. Ojú-ewé àwo̩n abé̩nà-ìmò̩ mìíràn ni àko̩sílè̩ nípa wo̩n, àtè̩jáde, ìbátan, e̩ka è̩kó̩, àwo̩n olùbákò̩wépò̩ àti ató̩nà sí ìtàkùn oǹkò̩wé, bí ó s̩e wà. Àwo̩n is̩é̩ kan s̩e é rí nípa ìtó̩nà tàbí àfikún PDF. Google Scholar tún ní is̩é̩ ìtanijí ímeèlì, tí ó lè s̩e alamí fún onís̩é̩ ìròyìn nípa àte̩jáde tuntun ní è̩ka wo̩n.

Shoeleather, ibùdó ìmò̩ US tí ó bè̩rè̩ ní o̩dún 2018 láti s̩e ìdánimò̩ àwo̩n òǹkò̩wé láti àwo̩n ìlú tí kò gbajúmò̩ fún ìròyìn (NYC, L.A., D.C., SF) tí wo̩n jé̩ ìbílè̩, ní ìmò̩, tí wo̩n sì s̩etán láti so̩ ìtàn fún àwo̩n ará agbègbè wo̩n.

Ìtó̩jú tí ó dára lórí bí a s̩e lè rí kí á sì s̩̩e ìtó̩jú àwo̩n orísun, àti dáàbò bò wó̩n ni Orí Ke̩fà ní inú The Investigative Journalism Manual, àkàns̩e is̩é̩ ti Global Media Programmes of the Konrad Adenauer Stiftung (KAS) ní o̩dún 2010.

Ǹjé̩ e̩ ní is̩é̩ mìíràn láti fi kún un? E̩ kò̩wé sí wa ní GIJN.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *