Ìwé ìléwọ́ fún àwọn oníròyìn ilẹ̀ Lárúbáwá nípa òmìnira à ti kó ìròyìn jọ pẹ̀lú iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn: e yóò rí ìwé olójú ewé mọ́kànlélógún ọ̀hún gbà lọ́fẹẹ̀ẹ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára, ìpín ọ̀rọ̀ mọ́kàndínlógún, èyí tí àjọ UNDP ṣe a gbá tẹrù rẹ̀. Èdè tí Wọ́n fi kọ́ọ́: Gèésì àti Lárúbáwá.
Ìròyìn ọlọ́gbọ́n àti ú dá: láti ọwọ Google pẹ̀lú bí wọ́n ṣe pèsè ètò ìdáni lẹ́ẹ̀kọ́ o ní ìpele mẹ́sáń án èyí tó dá lórí iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn àti bí wọ́n ṣe àwọn ohun èlò Google.
Ìwé ìléwọ́ fún àwọn oníròyìn tó ń ṣiṣẹ́ ìwádìí lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì: Èyí tí Liz Gross gbé jáde lọ́dún 2008 tó dá lórí bí a ṣe lè mú ìròyìn jáde nínú ìròyìn, ṣe àfihàn à í ṣe déédéé nínú ìròyìn àti láti fi ìdí ìròyìn tó pamọ́ hàn sí gbangba.