Kín ni Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí?
Fún wíwo ohun tí ó ǹ lọ lọ́wọ́, wo Ọjọ́-iwájú Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí pẹ̀lú.
Nígbà tí oríkì ìjábọ̀ ìròyìn aṣèwádìí máa ń yàtọ̀, láàárín àwọn ẹgbẹ́ alámọ̀dájú iṣẹ́-ìròyìn, àdéhùn tó gbòòrò wà ti ẹ̀yà tó jẹ́ kókó: sísẹ̀ntẹ̀lé, níjìnlẹ̀, àti ojúlówó ìwádìí àti ìjábọ̀, tí ó sábà máa ń níṣe pèlú tú àṣírí. Àwọn nóòtì mìíràn tí ìfikọ́ra rẹ̀ máa ń sábà níṣe pẹ̀lú àkọsílẹ̀ àwùjọ tó wúwo àti déétà, pẹ̀lú ìdojúkọ lórí ìdájọ́ àwùjọ àti ìṣirò.
Ìtàn-dálé ìbéèrè ìwé-ìléwọ́ iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí tí UNESCO tẹ̀ jáde, kì í báyìí pé: Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí níṣe pẹ̀lú títú àṣírí fún àwùjọ àwọn ọ̀rọ̀ tó bò – bóyà ẹnìkan tó wà ní ipò agbára ló dìídì ṣé ni, tàbí ò ṣèèṣì, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdàrú ti òtítọ́ àti àwọn àyídàyídà tó dí òye lójú. Ó bèrè fún àṣírí àti orísun tó ṣí gbangba àti ìwé-àṣẹ.” Ìjábọ̀ Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí Dutch-Flemish gẹ́gẹ́ bí “iṣẹ́-ìròyìn lámèyíyọ́ àti tójinlẹ̀.”
Fún Fídíò àwọn ẹlẹgbẹ́, kín ni iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí,” wo ìkànnì GIJN’s YouTube.
Àwọn oníròyìn kan, ní tòótọ́, gbà pé gbogbo ìjábọ̀ jẹ́ ìjábọ̀ aṣèwádìí. Àwọn òtítọ kan wà sí èyí – ìlànà ìwádìí ni àwọn oníròyìn tí wọ́n nà máa ń lò lọ́pọ̀lọpọ̀ ní àkókò-iparí bẹ́ẹ̀ náà láti ọwọ́ “ẹgbẹ́-I” ọmọ ẹgbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀sẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí ìtàn. Ṣùgbọ́n iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí gbòòrò ju eléyìí lọ- ó jẹ́ ìpàtẹ àwọn ọgbọ́n-ìkọ́ni tí ó jẹ́ iṣẹ́-ọwọ́, àti ó lè gba ọdún láti mọ̀. Àwòfín sí àwọn ìtàn láti jáwé olúborí àmì-ẹ̀yẹ tó ga jù fún iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí jẹ́rìí sí Ìpéwọ̀n tó ga ti ìwádìí àti ìjábọ̀ pé iṣẹ́-àmọ̀dájú lépa sí: àwọn ìbéèrè tó jinlẹ̀ tí owó-ìrànwọ́ àwùjọ ipa-ọ̀nà ìkógun ní láìyára àti ìṣọ́ra, àṣìlò agbára, ìbájẹ́ àyíká, ìtànjẹ ìlera, àti síwájú sí i.
Ní ọkàn rẹ̀: Ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé, Ìjìnlẹ̀, àti ojúlówó ìwádìí àti ìjábọ̀ tí ó máa ń sábaà tú àṣírí síta…
Nígbà mìíràn pè é ní ilé-iṣẹ́, ìjìnlẹ̀, tàbí ìjábọ̀ iṣẹ́-àkànṣe, iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí kò gbọdọ̀ dàpọ̀ pẹ̀lú ohun tí wọ́n ti gbàsílẹ̀ “iṣẹ́-ìròyìn di mímọ̀ nígbangba” –àwọn òfófó kíákíá tí wọ́n rí láti ara àwọn ìwé-àṣẹ tàbí ìbalólobó tí ó tú síta, ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti ọwọ́ àwọn tó wà nídìí agbára òṣèlú. Ní tòótọ́, ní ìyọjú ìjọba tiwantiwa, oríkì rẹ máa ń jẹ́ pọ́nna nígbà mìíràn, àti àwọn ìtàn máa ń sábà ní ààmì ìjábọ̀ ìròyìn aṣèwádìí nìkan tí wọ́n bá jẹ́ lámèyítọ́ tàbí níṣe pẹ̀lú àkọsílẹ̀ tó tú síta. Àwọn ìtàn tó dojúkọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí jẹjúdújẹra, ìtúpalẹ̀, tàbí yálà ẹyọ èrò pátápátá le jọra kí wọ́n wá ṣi ààmì fi sí i bí ìjábọ̀ aṣèwádìí.
Olùkọ́ni oní-ìrírí tó pẹ́ sọ pé iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí tó dára jù gba ọgbọ́n-ìkọ́ni ìṣọ́ra, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé lórí orísun alákọ̀ọ́kọ́, ṣíṣààtò àti ìdánrawò àbá ìpìlẹ̀, àti àyẹ̀wò-kíákíá tó le. Oríkì atúmọ̀-èdè tí “ìwádìí” jẹ́ “ìbèèrè síṣẹ̀ntẹ̀lé”, èyí tí wọn kò le ṣe ní ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì; ìbéèrè pípé bèèrè fún àkókò. Àwọn kókó mìíràn sí ipa kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ní ṣíṣáájú ìlànà tuntun, gẹ́gẹ́ bí ìfàmọ́ra kọ̀m̀pútà ní ọdún 1990 fún ìtúpalẹ̀ déétà àti àwòrán. “Ìjábọ̀ ìwádìí ṣe pàtàkì nítorí ó kọ́ni ní ìlànà tuntun, Brant Houston ṣàkíyèsí rẹ̀, àga Knight ti Iṣẹ́-ìròyìn ní Unifásítì Illinois, ẹni tí ó ṣe olóòtú àgbà ti Oníròyìn Aṣèwádìí àti àwọn Olóòtú. “ Àwọn ìlànà náà darapọ̀ mọ́ ìjábọ̀ ìròyìn ojoojúmọ́. Nítorí náà ẹ ń ṣe ìgbéga ìdálẹ́kun fún gbogbo iṣẹ́-àmọ̀dájú.”
Ṣà yọkúrò láti Global Investigative Journalism: ète fún ìrànwọ́, Da ẹid E. Kaplan, Center for International Media for Assistance, ọdún 2013. Kaplan jẹ́ olùdarí àgbà ti Global Investigative Journalism Network, àjọ ti ẹgbẹ́ aláìjèrè 211 ní orílẹ̀-èdè méjì-lé lọ́gọ́rin tí ó ṣiṣẹ́ láti ran ìjábọ̀ ìròyìn aṣèwádìí lọ́wọ́.