Abraji’s Security Manual fún kíkó ìròyìn lópòópónà jọ lórí ìfẹ̀hónú hànKíkó Ìròyìn Lópòópónà Jọ Lórí Àwọn Tó Ń Fẹ̀họ́nú Hàn.
Kíkó ìròyìn jọ lórí ìfẹ̀hónú hàn lóri pópó níṣe pẹ̀lú ewu tí ó yẹ kí gbogbo oníròyìn máa gbáradì fún. Ìmọ̀, ìrírí àti èrò-gbígbà le ṣe ìrànwọ́ láti dín àwọn ewu yìí kù. Àwọn akẹgbẹ́ wa ní Abraji (Ẹgbẹ́ Àwọn ọmọ Brazil ti iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí) ní ìrírí kan pàtó lórí èyí pẹ̀lú – láàárín oṣù kaàrún ọdún 2013 àti oṣù kaàrún ọdún 2014, nibẹ̀ ni ó kéré tán ókan-lé-láàádọ́sàn-án ẹjọ́ ìrúfin tó lòdì sí àwọn òṣìṣẹ́ ti ilé-iṣẹ́ tó gbé ìròyìn jádelórí kíkó ìròyìn jọ lórí ìfẹ̀hónú hàn lóri pópó ní Brazil.
Fún àfikún àlàyé, láti oríṣìíríṣìí orísun, mo ṣàbẹ̀wò sí ilé-iṣẹ́ ohun-àmúlò ààbò àti àìléwu ti GIJN.
Ìtọ́nisọ́nà Abraji kún fún ìtàn-ìròyìn àti àwọn ìtalólobó láti ọwọ́ àwọn alámọ̀dájú tí wọ́n ti ní ìrírí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ eléewu yìí nígbà tí wọ́n kó ìròyìn jọ lórí ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn. Èyí ni àyọọlò kan, èyí tí Abraji ti finnú-fíndọ̀ gba GIJN láàyè láti tẹ̀ ẹ́ jade. Ẹ lè yẹ ìwé-àfọwọ́ṣe ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì wò níbí, ní Èdè Pọ́túgà níbí, àti Èdè Sípènì níbí.
Kí o tó kúrò – ìtúpalẹ̀ ewu
– Gbèrò lórí kíkó ìròyìn rẹ jọ ṣáájú àkókò. Ǹjẹ́ ọ̀nà tí kò léwu wà láti gba àwọn ìtalólobó ìròyìn tàbí àwọn àwòrán tó ṣe kókó? Gbèrò lórí ohun tí o ó ṣe bí wọ́n bá dojú ìjà kọ ọ́, tì ọ́ mọ́lé tàbí jà ọ́ lólè. Bí o bá mọ ipa-ọ̀nà fún ìfẹ̀hónú hàn, wá ọ̀nà tí o ó gbà sálọ, kí o sì kẹ́ páńpẹ́ sílẹ̀ fún wọn pẹlú àwọn akẹgbẹ́ rẹ ṣáájú.
– Mọ ọ̀gangan-ipò ti òṣèlú àti ajẹmáwùjọ tó ń ṣe ìmóríyá fún àwọn akópa: nígbà tí òdodo ọ̀rọ̀ ṣáájú ìfẹ̀hónú hàn, ohun tí ó jẹ́ ìwùwásí gbogbogbò sí ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jade ni, ohun tí wọ́n rò nípa iṣẹ́ tó ń ṣe; ṣe o ní àbùdà Kankan tí ó le pèsè àfikún ewu (bi i kí ènìyàn jẹ́ obìnrin níbi tí ewu ìwa-ipá ìbánilòpọ̀); ǹjẹ́ àwọn ẹgbẹ́ tó níṣe pẹ̀lú ìtàn ìwà-ipá tí ó tako àwọn oníròyìn wà?
– Kí o tó kúrò ní ibẹ̀, ṣe àwòfín, pẹ̀lu ìtàkùn àgbáyé GPS tàbí ìtàkùn àgbáyé ayárabíàṣá, ní ojú-ilẹ̀ níbi tí wọn yóò ti ṣe ìfẹ̀hónú náà hàn, mọ àwọn àgọ́ ọlọ́pàá, àwọn ibi tí o ti lè wọ aṣọ, ibi tí o lè gbà sálọ, ọ̀nà tí òpópónà gbà, àwọn ibi tó ga fún àwòrán tó dára, òpin pátápátá àdúgbò, ọ̀nà-tódí, ilé-ìwòsàn àti ààyè ìtọ́kasí fún ìpè-àjọ padà bí ó bá ṣẹlẹ́ pé o yapa kúrò nínú àwọn akẹgbẹ́ rẹ.
– Ṣe ìṣirò bí o ó ṣe pẹ́tó ìwọ àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ nílò láti wà ní ọ̀gangan ipò láti le rí ohun tí ẹ nílò gbà.
– Gba ìjábọ̀ ojú-ọjọ́ fún àsìkò ìkóròyìn jọ. Bí ó bá ṣe kókó, mú aṣọ-kóòtù-kékeré mábòmirẹ́. Ní àwọn ibòmíràn, ìwọ̀n ìgbónà tàbi ooru máa ń wálẹ̀ ní alẹ́. Gbáradì. Ẹ lè lo ọ̀rá-ìdáàbòbò láti fi pa àwọn káàdì ìrántí fún kámẹ́rà pamọ́ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé omi tó ń ṣàn tó pọ̀ tàbí tí àwọn ọlọ́pàá bá lo àwọn ìbọn-ńlá olómi.
– Ní ìbáraẹnisọ̀rọ̀ déédé pẹ̀lú yàrá-ìròyìn. Ṣètò fífí àwọn ohun tó o ní lọ́kàn ránṣẹ́ lóòrèkóòrè, bí ó bá sì ṣe pàtàkì, kóòdù àwọn àtẹránṣẹ́ rẹ, bí i “táyà jó ò” tí ó túmọ̀ sí pé “wọ́n ti tì wá mọ́lé.” Àtẹ̀ránṣẹ́ tó ju méjìlá lọ ni a lè ṣẹ̀dá fún oríṣìíríṣìí ipò àwọn àbá ìpìlẹ̀ tí ó wáyé nígbà tí a ń gbèrò, fi papọọ̀ sí orí tábìlì pẹ̀lú ẹ̀daà rẹ nínú yàrá-ìròyìn.
– Ṣe àgbàsílẹ̀ àwọn nọ́ḿbà tí wọ́n le pè ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lórí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ fún ìpè-pàjáwìrì. Ṣe àfibọ̀ lẹ́tà “A” ní ibẹ̀rẹ̀ àwọn nọ́ḿbà ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kí wọ́n le hàn ní òkè àwọn ààtò nọ́ḿbà náà. Mú bátìrì mìíràn dání fún ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ láti kín ẹ̀rọ rẹ lẹ́yìn. Dín ìmọ́lẹ̀ àtẹ agbàwòrán-tàn kí o sì ri wí pé o kò jẹ́ ki gbogbo àwọn ápùù(app) tí kò nídìí ṣiṣẹ́. Bèèrè fún ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ tí ó le lo ṣípù méjì. Lo ṣípù láti ibi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ti ń gbé ẹrọ-ìbánisọ̀rọ̀.
– Oníròyìn tábí Olùrànlọ́wọ́ yẹ kí ó ran oníròyìn-ayàwòrán tàbí oníṣẹ́-kámẹ́rà lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí wọn yóò ṣe gbájúmó gbígba àwọn àwòrán. Ọ̀kan nínú akẹgbẹ́ ẹ yín gbọ́dọ̀ ranjú kànnàbọ̀n sí gbogbo ìran ní gbogbo ìgbà. Kí àìléwu àwọn aẹgbẹ́ rẹ̀ sì kàn án. ṣètò àwọn ipa yìí sílẹ̀ ṣáájú ọjọ́ náà.
– Bí o bá ní awakọ̀, yẹ̀ẹ́wò bóyá ó mọ agbègbè náà, á ní àǹfààní láti gbèrò ọ̀nà àti sálọ, ó ń ba yín sọ̀rọ̀ nígbàkuùgbà tí kò si kúrò nínú ọkọ̀ tí ẹ gbé sí ibi tí ẹnikẹ́ni kò le yẹ̀wò.ọ
– Bí o bá ní ikọ́-èfe, tàbí ààrùn inú tàbí ìṣòro, tí o lóyún, ní àjẹsára kékeré, ààrùn ojú, tàbí lo ẹyinjú tí wọ́n ń tìbọ́ àti pé o ò ní ìgò-ojú, ṣọ́ra láti kó irú ìròyìn yìí jọ. Rí i pé o pé ní ara láti ṣe iṣẹ́ yìí: Ǹjẹ́ o lè sáré?
– Yẹ̀ ẹ́ wò, bí nǹkan bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ìwọ àti àwọn ẹbí rẹ yóò ní ìṣedúró ìkóròyìn-jọ àti ti iṣòògùn.
– Lo ohun Ìdánimọ̀ tó ṣe é rí láti ọ̀nà to jìn bí o bá gbàgbọ́ pé eléyìí yóò pèsè ààbò tó dájú. Fi káàdì ìdánimọ̀ rẹ pamọ́ kí o sì gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn tó wà ní àyíká rẹ tí o bá ri wí pé ó jọ pé ó tọ́. Mọ bí o ó ṣe ka àkóónú àti ìṣesí àwọn tó kópa nínú ìfẹ̀hónú hàn tó ní iyì fún àwọn oníròyìn. Ṣètò àwọn ìgbésẹ̀ yìí pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ ṣáájú.
– Pín owó rẹ sí ọ̀nà kékèké kí o sì fi pamọ́ sí oríṣìíríṣṣìí àyè mábómirẹ́ ní ara rẹ tàbí inú àfikún àpamọ́wọ́.
Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́
– Ṣe àtúnyẹ̀wò ipò tí ọkọ̀ rẹ wà: máa yẹ̀ ẹ́ wò ní gbogbo ìgbà, kí ẹ tó pínyà, wí pé ẹ ní ẹ̀rọ panápaná tí ó ń ṣiṣẹ́, àti ní pàtàkì jùlọ, wí pé ẹ ní àǹfààní si, ẹ sì tún mọ bí wọ́n ṣe ń lò ó.
– Awakọ̀ gbọ́dọ̀ ní ìtanijí ní gbogbo ìgbà. Àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn tí ara ń kan máa ń ṣọ ọkọ̀ àwọn oníròyìn. O gbọ́dọ̀ fi òfin àwọn ile-iṣẹ́ rẹ sínú èrò kí o sì tún sọ ọ́ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ bóyá ó dára kí awakọ̀ dúró sí ìta ọkọ̀, láàárín wíwò ó tàbí kí ó dúró sínú ọkọ̀ pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ níbi tí yóò ti tàn án, múra láti kúrò ní kíákíá bí ó bá ṣe pàtàkì.
– Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti gbé ọkọ̀ sí ààyè ìdákọ̀ dúró, awakọ̀ gbọ́dọ̀ fetísílẹ̀ àti ojú-la-láńkàn-fi-ń-ṣọ́rí sí àyípadà ìṣesí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ àti àyípadà ipò ààbò àwọn tó yí i ká. Bí ó bá ṣe pàtàkì, o le pinnu láti yí ipò ọkọ̀ náà pada, láti yẹra fún sísùrùbò, kí o sì ní ìjẹ́rìí-sí pé ẹ fi tó àwọn ẹgbẹ́ ìròyìn létí nípa ipò titun rẹ̀.
–Ìyókù ọmọ-kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ gbọdọ̀ wa, kí wọ́n sì fi sọ́wọ́ akẹgbẹ́ mìíràn, yàtọ̀ sí awakọ̀, tí òun náà le wa ọkọ̀.
– Ṣíṣe ju ojúṣe kan lọ, bí i àwakọ̀/olùyàwòrán, máa ń jẹ́ kí ewu pọ̀ si fún àwọn Alámọ̀dájú.
OHUN-ÈLÒ ÌPÌLẸ̀ FÚN ÀPÒ-Ẹ̀YÌN
– Lo Àpò-ẹ̀yìn tó fúyẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí ó rọrùn láti ṣí àti tì àti tí ó gba ẹ̀yìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn, tí ó rọrùn láti ní àǹfààní sí àti ìrìnsẹ̀.
– Mú omi tó mọ ní kólóbó àti ìpápánu afúni-lókun nítorí bí kíkó ìròyìn jọ bá gba àkókò ju bí ó ṣe yẹ lọ. Pín oúnjẹ sí ọ̀nà kéèké. O lè nílò láti gbé e dání nígbà tí ẹ bá ń rin ọ̀nà tó jìn
– Mọ bí o ó ṣe lo iná orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ. Bí o kò bá ní irú èyí lórí ẹ̀rọ rẹ, gbà ápùù yìí sí orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ, kí o sì mú iná-ìlèwọ́ kan dání pẹ̀lú rẹ.
– Tí o kò bá mọ agbègbè yẹn, àwòrán-ayé máa ràn ọ́ lọ́wọ́. GPS – bóyá fún ọkọ̀-ayọkẹ́lẹ́ tàbí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀, le ranni lọ́wọ́ pẹ̀lú. Mọ bí wọ́n ṣe ń lò ó, yẹ̀ ẹ́ wò kí o sì fa ara rẹ mọ́ ìwúlò rẹ̀. O lè sàmì sí mápùù pẹ̀lú àwọn ibi tí ó wù ọ́, bí i àwọn ibi tí ó ga tó dára fún yíya àwòrán, ilé-ìwòsàn, àwọn àgọ́ ọlọ́pàá, àti àwọn ibi tí ènìyàn lè gbà sálọ síwájú.
– Atukọ̀ ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán gbọ́dọ̀ bèèrè fún àwọn ohun èlò tó fúyẹ́, tó rọrùn lati gbé. Gbaradì láti fi sílẹ̀ bí ẹ bá nílò láti kúrò níbẹ̀ kíákíá.
– Lo ohun ẹ̀sọ́ ọrùn-ọwọ́ tàbí báàjì ìtanijì ti ìṣòògùn tí ó máa ń ṣàfihàn irú ẹ̀jẹ̀ rẹ tàbí ipò ìṣòògùn tó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tàbí ẹhun.
Àwòrán: Carlos Varela ní Flickr (CC lincense)
Lásìkò Ìfẹ̀hónú hàn
IPÒ ÀTI ÌṢE
Àwọn ìgbìmọ̀ láti dá ààbò bo àwọn oníròyìn dá àbá pé ó yẹ kí wọ́n máa rí àwọn oníròyìn gẹ́gẹ́ bí àwọn onídàájọ́ lórí pápá ìṣeré: “Ó yẹ kí wọ́n súnmọ́ ọ tó láti le ṣàkíyèsí eré náà láìtàsé, ṣùgbọ́n o nílò láti ṣọ́ra láti yàgò fún dída núrú pọ̀ ìṣápá ìṣe.” Yàgò fún ìyíniká tàbí ìdọdẹ láàárín àwọn ẹgbẹ́ tó dojú kọni, tàbí láàárín àwọn èrò tó pọ̀. Gbìyànjú láti dúró sí ibi yóò ti ṣe é ṣe láti rí ìran ìròyìn náà yà. Ní ibi tí o lè gbà sálọ lọ́kàn ní gbogbo ìgbà. Bí o bá ti dé ojú ìran, ṣáájú ohunkóhun mìíràn, ro èrò bí o ṣe lè jade ní pàjáwìrì.
– Nígbà tí o bá dé agbègbè, fí orí ya màpùù, ṣàwárí ibi tí àwọn ọlọ́pàá tó ń rí sí rògbòdìyàn àti Káfárì. Àwọn ẹgbẹ́ tó yàtọ̀ yìí le dúró sí búlọ̀kù kan tàbí òmíràn tó jìnà sí ibi tí àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn. Ó ṣe kókó láti máa fọkànsí ibi tí wọ́n ti lè jade wá àti ọ̀nà tí o lè sá sí bí wọ́n bá lọ pàṣẹ pé kí wọ́n túká.
– Ṣọ́ra fún àwọn àyípadà ìṣesí àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn àti àyípadà ipò àwọn ọlọ́pàá. Mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe ògbufọ̀ fún àwọn àkóónú àmì àti kí o sì múra fún ewu. Ní déédé, Ọlọ́pàá tó níṣe pẹ̀lú rògbòdìyàn láti túká ẹgbẹ́ yẹn. Wo àwọn ìtọ́nisọ́nà síwájú pé ìṣípòpadà ṣeé ṣe láti gbèrò àti ṣe é lọ́nà tóyẹ.
– Yàgò fún rínrìn ká láàárín àwọn èrò; bèèrè fún ìṣípòpadà pàtó tí ó lójúùtú lórí gbígba-ọ̀rọ̀-sílẹ̀ ohun tó ṣe pàtàkì.
– Ro yíya-àwòrán láti ọ̀nà tó jìn gidi-gan, láti ẹ̀gbẹ́ tàbí láti òkè. Gbígbèrò yìí le ṣée ṣe pẹ̀lú mápùù, pẹ̀lú ìrànwọ́ àwòrán láti afẹ́fẹ́ tàbí láti ìtalólobó ìròyìn tí ó gbà láti nọ́ḿbà àgbègbè.
– Má ṣe mú ohunkóhun tí wọ́n jù lásìkò ìfẹ̀hónú-hàn. Ó ṣe é ṣe kó jẹ́ ìbúgbàmù tí wọ́n ṣe láti ilé tàbí ẹ̀rọ tó le jóná, sí bẹ́ẹ̀ si ó le mú ìfunra dání láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá pé olùfẹ̀hónú hàn ni ọ́. Ṣọ́ra fún ohun èlò kan kan tí wọ́n patì.
– Má ṣe fọwọ́kan ọta láti ara bọ́m̀bù tí àwọn ọlọ́pàá ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ. Ó ṣe é ṣe kó gbóná.
– Má gbè ṣẹ́yìn ẹgbẹ́ Kankan tí ó bá kópa.
– Nígbà tí o bá ń ya ìlọsíwájú àwọn ọlọ́pàá, yàgò fún ìyíniká láti ẹ̀yìn láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá tó níṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Dúró sí orí-ìlà rẹ. Má ṣe fọwọ́kan ọ̀gá ọlọ́pàá tí ó yọ ohun-ìjà dání – èyí ṣe pàtàkì fún àwọn ayàwòrán, tí ó ti mọ́ wọn lára láti máa bèèrè àyè láti rí àwòrán gidi yà. Rántí wí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó wà ní ipò yìí, ara le kan án kí ó sì ṣe ohun tí ẹ kò lérò nígbà tí ó bá rò ó wí pé ẹ ń halẹ̀ mọ́ òun.
– Oníròyìn-ayàwòrán àti oníṣẹ́-kámẹ́rà gbọ́dọ̀ mú Awòye-Àwòrán-láti-ọ̀nà tó-jìn pẹ̀lú wọn, èyí tí ó máa ń gbà wọ́n láàyè láti rí i ní ọ̀nà tó súnmọ́ ìṣe tó ń lọ lọ́wọ́ láìsí ìgbésáyé aláìnídìí sí ewu.
– Gbìyànjú láti yàgò fún yíya àwòrán tó pọ̀, tàbí yíya fíìmù fún àsìkò tó gùn, ẹnìkan tàbí ẹgbẹ́ kékeré. Èyí lè fún ọ ní ìwúrí pé ẹni yìí tàbí ẹgbẹ́ yìí wà nínú ewu.
– Bí o bá pinnu láti yí apá-ibìkan padà, bèèrè fún ìtalólobó àti àmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń dé sí ojú ìran láti apá-ibìkan tí o gbèrò láti lọ.
BÍ ÌFINRÀN TÀBÍ ÀTÌMỌ́LÉ BÁ WÁYÉ
– Bí wọ́n bá gba ohun ìní rẹ kúrò ní ọwọ́ rẹ, pẹ̀lú àwo-fídíò tàbí àwọn àkíyèsí, ṣàfihàn àìfọwọ́sí rẹ. Sọ pé èyí jẹ́ ọ̀nà ìpanilẹ́numọ́, tí ó jẹ́ èèwọ̀ lọ́dọ̀ òfin-ìpìlẹ̀, ṣùgbọ́n má ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìjíròrò tó móoru., má ṣe fọwọ́kan ẹnikẹ́ni.
– Ó dá lórí àyè, ó ṣe é ṣe kó má ṣe é gbani nímọ̀ràn láti sọ ohunkóhun lásìkò náà. Má kojú èèyàn pẹ̀lú ìbínú kí o sì bọ̀wọ̀ fún àyè ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ṣàkíyèsí àmì ìfara-sọ̀rọ̀. Àwọn tí wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ gidi gan nílò àyè tó pọ̀ káàkiri wọn. Èyí náà jẹ́ òótọ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé ohun-ìjà dání. Faramọ́ àbùkù àti kí o sì ní sùúrù.
– Ṣètọ́jú ìbánisọ̀rọ̀ ojúkorojú nígbà tí wọ́n bá ń bi ọ ní ìbèèrè. Bí ó bá wọ ìgò-ojú dúdú, yọ wọ́n kúrò. Wo ojú ẹni tó ń bi ọ́ ní ìbéèrè, mí kanlẹ̀, kí o sì gbìyànjú láti fi ara balẹ̀ àti pé kí o fi òsùnwọ̀n sí ohun rẹ nínú ọ̀rọ̀. Yàgò fún ṣíṣe ìfẹ̀sùn-kànyàn tàbí sísáré nínú ìjíròrò. Ṣe àfihàn pé o kò ṣe ìhalẹ̀mọ́ni.
–Bí wọ́n bá gbé ọ, ṣakitiyan gbogbo agbàra láti ṣètọ́jú ìwà allámọ̀dájú nígbà tí o bá ń ṣàlàyé fún wọn pé oníròyìn ni ọ́ àti wí pé iṣẹ́ rẹ ní láti máa bun àwọn ènìyàn gbọ́; bí ó tilẹ̀ jé pé, wọ́n fi ọ sínú àtìmọ́lé wọn, tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà kí o sì dúró fún ìgbà tí àǹfààní yóò wà láti tẹ́ ẹjọ́ rẹ síwájú ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá.
– Má a sọ òtítọ́ nígbà gbogbo kí o sì yàgò fún yíyí ìtàn rẹ padà. Fara rẹ balẹ̀ kí o sì dúrò ní ìdúró ẹni tó tẹríba. Rántí, àfojúsùn rẹ kan ṣoṣo ní àkókò yí ni láti yè àti láti jáde kúrò níbẹ̀ láìfarapa.
– Bí o bá jẹ́ olùfaragbà ẹni-tí wọ́n-gbé láìbófin mu láti ọwọ́ ọ̀gá òṣìsẹ́ fún ìmúṣẹ òfin, sọ fún Abánirojọ́ tàbí Aláṣẹ ìdálẹ́nu-ìlú àti gbogbo oníròyìn pátá ní kíákíá, kí o sì bèèrè fún wíwá agbẹjọ́rò.
– Bí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn ọ́ tàbí wọ́n bú ọ, ṣàkíyèsí nọ́ḿbà ìdánimọ̀ tàbí orúkọ olùfínràn náà, kí o sì fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn àwọn aláṣẹ (olóṣèlú, Abánirojọ́ láwùjọ-ẹ̀dá, Amòfin) ile-iṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ọ̀gá olùfínràn.
– Bí wọ́n bá gbé ọ sínú ọkọ ọlọ́pàá, pariwo orúkọ rẹ àti orúkọ ilé-iṣẹ́ ìròyìn tí o ti ń ṣiṣẹ́ kí ìtalólobó ìròyìn pé wọ́n gbé ọ le rìn káàkiri.
Ṣe àyọlò láti Security Manual for Protest Coverage ní Brazil láti ọwọ́ Abraji (Ẹgbẹ́ Àwọn ọmọ Brazil ti iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí), ọdún 2014.