Ìmò̩ràn lóri kókó ìs̩èwádìí máa ń wáyé ní orís̩irís̩I ò̩nà – kìí s̩e fún onís̩é̩-ìròyìn o̩ló̩fintótó nìkan, s̩ùgbó̩n fún o̩ló̩pàá, agbanisís̩é̩, agbe̩jó̩rò, onís̩é̩ ìlú, àti àwo̩n yòókù. Nǹkan tó fojú hàn ni pé ìwádìí jé̩ ò̩kan nínú àwo̩n ohun èlò tí ó s̩e é gbó̩kàn lé tí ó sì sis̩é̩ nínú àpótí-ohun-èlò olùwádìí.
GIJN ti s̩e àgbékalè̩ àwo̩n àyè̩wò, pàápàá láti o̩wó̩ àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn, s̩ùgbó̩n pè̩lú ìmò̩ràn láti ò̩dò̩ àwo̩n yòókù náà.
Ohun èlò tí ó wúlò pò̩. Ò̩rò̩ náà ‘is̩é̩ o̩nà’ je̩ yo̩ púpò̩, gé̩gé̩ bí ò̩rò̩ ‘ìmúrasílè̩’ àti ‘gbígbó̩’. Àti àwo̩n mìíràn. A rí àko̩sílè̩ tí ó ní ìtanilólobó tí ó tó mé̩rin, ogún, o̩gbò̩n àti ogójì.
Ìmò̩ràn láti ò̩dò̩ àwo̩n onís̩é̩-ìroyìn
María Emilia Martin, ò̩kan lára àwo̩n oníròyìn àkó̩kó̩ ní rédíò gbogbogbò, ko̩ orí tí ó dá lé ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò ní inú Reporter’s Guide to the Millennium Development Goals: Covering Development Commitments for 2015 and Beyond tí ó ti jé̩ ò̩kan lára àwo̩n àko̩sílè̩ tí wo̩n kà jù lórí ìtàkùn GIJN láti ìgbà pípé̩.
Àwo̩n àbá lórí sís̩e ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò lórí ìtàkùn Zoom jé̩ èyí tí Marie Naudascher ní Multimedia Journalism mú wá.
Ìlànà ìtàkurò̩so̩ àti ìbéèrè ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò tí ó wo̩ inú títakókó jé̩ èyí tí wo̩n júwe nínú àko̩sílè̩ o̩dún 2019 yìí láti o̩wó̩ Solutions Journalism léyìí tí ó wá láti ara àròko̩ kan láti o̩wó̩ oǹkò̩wé àti oníròyìn Amanda Ripley nípa ohun tí onís̩é̩-ìròyìn lè kó̩ láti ò̩dò̩ àpè̩tù-sí-aáwò̩, agbe̩jó̩rò, olórí è̩sì àti àwo̩n yòókù “tí wo̩n mo̩ bí wo̩n s̩e ń da e̩jó̩ tí kò dára rú tí wo̩n yóò sì jé̩ kí àwo̩n ènìyàn so̩ òtító̩”.
Top Tips on Investigative Television Interviews, láti o̩wó̩ Oriana Zill, olóòtú ìròyìn ní CBS, tí ó sò̩rò̩ níGIJC19.
Mark Schoofs, as̩àtúnko̩ ìwádìí àti àkàns̩e is̩é̩ fún Buzzfeed News, s̩e àgbékalè̩ The Art of Interviewing ní GIJC17 ní Johannesburg ní November 2017.
“Investigative Interviewing” jé̩ orí ko̩kànlá nínú Modern Investigative Journalism láti o̩wó̩ Mark Lee Hunter àti Luuk Sengers, pè̩lú Marcus Lindemann.
Asking the Right(!) Questions, Orí keje, The Investigative Journalism Manual, àkàns̩e is̩é̩ o̩dún 2010 fún Global Media Programmes ti Konrad Adenauer Stiftung (KAS).
“Learn the rules, then break them,” bè̩rè̩ a guide to mastering the investigative interview tí ó dá lórí ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò kan pè̩lú Julian Sher, olóòtú The Fifth Estate ti CBC, tí àwo̩n Investigative Reporters & Editors sì s̩e àtè̩jáde rè̩.
The craft (and art) of the interview, from thoughtful homework to whatever happens, àròko̩ o̩dún 2018 láti o̩wó̩́ Sally James lórí Nieman Storyboard, pè̩lú ìtumò̩, “Four field reporters share their best tips for effective interviews”.
No surprises: Transparency and the art of the investigative interview, jé̩ àko̩sílè̩ atanilólobó láti o̩wó̩ Karen de Sá, oníròyìn as̩ò̩fintótó fún San Francisco Chronicle, ati T. Christian Miller, àgbà oníròyìn fún ProPublica. Ó jé̩ gbígbéjáde ní 2018 Investigative Reporters & Editors conference ní o̩dún 2018.
Interviewing Techniques, ìwé ìléwó̩ láti o̩wó̩ Centre for Investigative Journalism ní UK, nínú èyí tí a ti rí abala kan lórí “adversarial interviewing.”
“Asking the Hard Questions About Asking the Hard Questions,” jé̩ ìtumò̩ àròkò̩ ajé̩mó̩-ìroyìn ti Columbia láti o̩wó̩ Ann Friedman.
5 interview tips every journalist needs, láti owó̩ Dana Liebelson fún IJNet, pè̩lú abala kàn lórí ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò orí ímeèlì.
Àko̩sílè̩ Knight Center yìí s̩e ìs̩enísókí ìmò̩ràn látí orísirísi orísun.
The BBC Academy ní àkójo̩pò̩ àwo̩n ohun èlò nípa ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò ìgbóhùnsáfé̩fé̩ láti ò̩dò̩ orís̩irís̩I onís̩é̩-ìròyìn BBC.
30 Tips on How to Interview Like a Journalist kún fún o̩gbó̩ láti ò̩dò̩ David Spark, onís̩é̩ ìròyìn àti olóòtú.
Ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò sís̩e jé̩ ò̩kan lára àwo̩n ìmò̩ tí ó gbo̩n-n-gbó̩n jù fún is̩é̩ ìròyìn o̩ló̩fintótó tí àròko̩ tí Gordana Igric, olùdárí agbègbè fún Balkan Investigative Reporting Network ko̩.
How Journalists Can Become Better Interviewers, àròko̩ Poynter Institute láti o̩wó̩ Chip Scanlan, s̩e è̩kúnré̩ré̩ àlàyé lórí àwo̩n orí ò̩rò̩ yìí: jáfáfá, s̩e àko̩sílè̩ ìbéèrè rè̩, fi etí sílè̩, s̩e àánú, wo àyíká, wo bí àwo̩n ènìyàn s̩e ń sò̩, s̩e òfìn tí ó ye̩ kí o sì jé̩ àpe̩e̩re̩.
Ní inú Essential Tips for Interviewing Children, akò̩ròyìn Washinton post John Woodrow Cox gba ìmò̩ràn: “Kó̩kó̩ jé̩ ènìyàn. S̩e is̩é̩ àkó̩kó̩ s̩aájú ìròyìn tó bí ó bá s̩e s̩eés̩e. Mo̩ àwo̩n ìbéèrè tí o̩mo̩ náà ti ń bèèrè. Nígbà tí ó bá s̩eés̩e, fi ara re̩ jìn. Jé̩ kí ara wo̩n balè̩. Fi wó̩n sí ibi gidi. Wá àrídájú ohun tí wo̩n ti so̩ fún e̩. Má sì fi ojú di wó̩n”.
GWo̩n s̩e ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò fún gbajúgbajà olùfò̩rò̩wánilé̩nuwò ti US National Public Radio Terry Gross nípa ìlànà rè̩ ní o̩dún 2018.
Ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò fún Olùfaragbá
E̩ nílò ìtó̩jú tí ó yàtò̩ láti s̩e ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò fún olùfaragbá. Ìmò̩ràn lórí èyí wà ní ojú-ewé GIJN lírí gbígbé o̩mo̩nìyàn kiri ló̩nà àìtó̩. Ó pè̩lú ìtó̩nisó̩na láti ò̩dò̩ oníròyìn Martha Mendoza àti Malia Politzer, àwo̩n méjèèjì tí wo̩n jé̩ oníròyì tó ti gba àmì è̩ye̩ lórí ìgbé-o̩mo̩nìyàn ló̩nà àìtó̩.
Ìmò̩ràn fún àwon oníròyìn tí wo̩n bá ń sis̩é̩ pè̩lú àwo̩n tí wo̩n ja àjàbó̩ nínú ìlòkulò o̩mo̩dé ni ó jé̩ àko̩lé fún ìs̩enísókí ìgbìmò̩ tí wo̩n gbé kalè̩ ní ìdánilé̩kò̩ó̩ GIJN ní o̩dún 2019 ní Hamburg. Kókó gbòógì mé̩ta:
- E̩ jé̩ kí àwo̩n alájàbó̩ ní ìgbàgbó̩ nínú yín
- E dáàbò bo àlàáfíà àwo̩n orísun yín.
- Àkójo̩pò̩ àwo̩n ajàjàbó̩ lè ran è̩yin àti ara wo̩n ló̩wó̩.
Trauma Reporting: A Journalist’s Guide to Covering Sensitive Stories Ìwé o̩dún 2019 láti o̩wó̩ Jo Healey jé̩ èyí tí a s̩e àlàyé nípa rè̩ nínú aròkò̩ yìí láti o̩wó̩ òǹkò̩wé.
Ató̩nà láti ò̩dò̩ àwo̩n aláìgbáralé-ìjo̩ba Project Reach pè̩lú àwo̩n ìkìlò̩ bí: “Mò̩ pé, ìyàtò̩ nínú ohun tí ènìyàn mò̩ kò fi dandan so̩ pé iró̩ ló ń pa, ó lè jé̩ àrídájú ìfìyàjé̩”.
Suggestions geared for journalists tí ó jé̩ àgbékalè̩ Minh Dang, as̩àyè̩wò lórí ò̩rò̩ ìgbénikiri-ló̩nà-àìtó̩ ní California, tí ó s̩e àko̩sílè̩ àwo̩n ìlànà márùn-ún. Ajàjàbó̩ nínú ìgbé-o̩mo̩-kiri-s̩e-as̩é̩wó, Holly Smith, ko̩ nípa the importance of building rapport and trust.
Ìmò̩ràn pàtó lórí sís̩e ìfò̩rò̩wánilè̩nuwò fún àwo̩n obìnrin àti o̩mo̩dé wà nínú The Toolkit to Combat Trafficking in Persons láti United Nations Office of Drugs and Crime (UNODC). Léyìí tí ó tún wúlò lórí ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò àti àwo̩n àkòrí mìíràn ni Anti-Human Trafficking Manual for Criminal Justice Practitioners ti UNODC. Àjo̩ elétò ìlera àgbáyé, World Health Organization ti dá sí Ethical and Safe Interviewing Conduct.
10 rules for reporting on war trauma survivors wá láti inú The War Horse, ìròyìn aláìgbáralé-èrè tí ó mójú tó ríròyìn ogun, ìpalára àti ò̩rò̩ àwo̩n ajagun-fè̩yìntì lé̩yìn 9-11.
Àwo̩n ìtanijí láti àwo̩n è̩ka tí ó súnmó̩
Láti ò̩dò̩ àwo̩n onísùúnà ìwádìí
Investigative Interviewing Techniques jé̩ dídojúko̩ sí orís̩irís̩i ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò s̩ùgbó̩n è̩kó̩ wà níbí fún àwo̩n onís̩é̩ ìròyìn, ó sì jé̩ àgbékalè̩ Christopher Haney àti Andrea Roller ti Duff & Phelps, ilé-is̩é̩ ní US tí o ń s̩e is̩é̩ fífúnni ní ìmò̩ràn àti ìfowopamó̩ ló̩nà ìdókòwò.
Láti ò̩dò̩ aláyè̩wò jìbìtì
Checklist láti o̩wó̩ Dawn Lomer, olùdárí àgbà ní i-Sight Software, pè̩lú àmójútó fún ò̩rò̩ jìbìtì.
Láti ò̩dò̩ àwo̩n agbófinró
Investigative Interviewing pè̩lú àwo̩n ohun èlò tí ó pò̩ láti College of Policing, ìgbìmò̩ akó̩sé̩mo̩s̩é̩ fún àwo̩n o̩ló̩pàá ní England àti Wales.
Interviewing the FBI Way jé̩ àko̩sílè̩ tí ó gbó̩kàn lé ò̩rò̩ láti e̩nu òsìs̩é̩-fè̩yìntì ní FBI Joseph Stuart.
Láti o̩wó̩ ò̩jò̩gbó̩n ilé-è̩kó̩ òwò-síse
Interviewing white-collar criminals: ìtanijí mé̩fà láti o̩wó̩ Eugene Soltes ní Harvard Business School
Àti padà sí ò̩dò̩ onís̩é̩ ìròyìn
How to Interview Like a Journalist (No Matter What Your Job Is), àkòrí tí ó mú o̩gbó̩ dání fún ìs̩enísókí láti o̩wó̩ as̩àtúnko̩ e̩gbé̩ Jory MacKay.