Ìwé atọ́nà fún ààbò SEEMO

Ìwé atọ́nà fún ààbò SEEMO: Ìwé atọ́ni sónà fún àwọn oníròyìn tí Wọ́n ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ tàbí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ pájáwì: Ìwé ìléwọ́ yìí jáde láti ilé iṣẹ́ Ìròyìn Gúúsù Ìlà Òòrùn Europe –  ó wà lára ètò itaniji làti dáàbò tó péye bo àwọn oníròyìn ní Ẹkùn ọ̀hún. Èdè tí Wọ́n fi kọ́ọ́: Gẹ̀ẹ́sì àti Serbian, Italian, Romanian, Greek, Turkish, Bulgarian, Croatian àti Slovenian.

Àjálù àti àwọn Akọ̀ròyìn: Ìwé atọ́ni sọ́nà olójú ewé ogójì pẹ̀lú àwọn ìlànà tí yóò ṣe ìrànwọ́ fún àwọn akọ̀ròyìn, àwọn akọ̀ròyìn o ní fọ́tò, àti àwọn olóoòótú ìròyìn bákannáà lórí kíkó ìròyìn jọ lórí làásìgbò àti láti dáàbò bo ara wọn àti àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí. Ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé Dart lórí Ìròyìn àti ẹ̀dùn ọkàn ló tẹ ìwé náà jáde. Joe Hight àti Frank Smyth lọ kọ́ọ́. Èdè tí Wọ́n fi kọ́ọ́: Gẹ̀ẹ́sì, Spanish, 中文 (Chinese).