Ìtọ́ni sọ́nà fún Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Lórí Ìròyìn

  • Ìwádìí ìjìnlè lórí ìròyìn
  • Àwọn ohun èlò Ìkọ́ròyìn jọ
  • Ètò  ẹ̀kọ́ áti Ìdanilẹ́kọ̀ọ́
  • Ìtọ̀nisọ̀nà fún àwọn ohun èlò  mìíràn 
  • Èdè Spain Nìkan

Ǹ jẹ́ ẹ́ ń wá àmọ̀ràn ní ṣókí, àwọn ohun èlò tàbí ìtọ́ni sónà? Yẹ ìsàlẹ̀ wò fún àwọn ìtọ́sọ́nà tó ní í se pẹ̀lú ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí Ìròyìn pẹ̀lú àmúlò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀  to jọra won àti àpẹẹrẹ jákèjádò  àgbáyé gbogbo. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Iroyin wón yí ni e lè se àmúlò won lọ́ fẹ́ ẹ́, àyàfi tí ọ́rọ́ bá tún yẹ̀ lórí àdéhùn.

E tún lè ṣe àbápàdé ìtọ́ni sọ́nà ní èdè China àti Spanish.

Ń jé e ní ohun mìíràn tí e fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀? Fi Ímeelì rán sí e lórí rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀.

Ìwádìí Ìjìnlè Lórí Ìròyìn

Ṣèwádìí – Ìtọ́ni sọ́nà: Èrò ǹ gbà Ìwé ìtọ́ni sọ́nà yìí ni láti se àfihàn gbogbo ohun tó mọ mú lóókan àyà CiFAR èyí tó wà láti fi ṣíṣe ìwádìí lórí ìròyìn tó jo mọ́ ìwà àjebànu, síse owó ilu kúmo kùmo, gbígba ohun ìní tí a fi ọ̀nà èrú kó joo. Àwọn ọ̀nà  tí ìròyìn lórí ìwádìí ìjìnlẹ̀ ti se wúlò ni àkòrí àti ìwádìí, isẹ́ ìwádìí tó múná dóko lórí ẹ̀ro ayélujára, ibi ìpamó àwọn ohun eelo àti nínú anfaani sí ìròyìn, tí  kò sì yọ ààbò tó gbópon lórí ọ̀nà àmúlò ẹ̀rọ ìgbàlódé sílẹ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jora won mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti wà ní sẹpẹ́ láti fi se àpèjúwe àmúlò àwọn ohun èlò àti ọgbọ́n àti nú dá wọ̀n yìí, èyí tó dá lé awon Ìròyìn mérìyírí mẹ́ta tí a ń dá lẹ́kọ̀ọ́ gbé jáde. A tún gbé e jáde ní i èdè Faransé.

Ìwádìí Ìjìnlè Lòrí Ìròyìn ti Ìgbàlódé: Láti ọwọ́ Mark Lee, Hunter ati Luuk Sengers pẹ̀lú Marcus Lindemann. Wọ́n ṣe àpèjúwe rè gẹ́gẹ́ bí  ìlànà ìkọ́ni  “tó kọjá èyí tó ṣeé fi enu so: ó ń ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ́ olùkọ́ láti mo bí wọ́n se ń kó ẹ̀kọ́ nípa ṣíṣe àpéjúwe irú ìbéèrè tó ṣeé ṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bèèrè  (pẹ̀lú ìdáhùn), pẹ̀lú àwọn  ìdánra wò ráń pé nínú kíláàsì àti isẹ́ àmúrelé tó ní í se pẹ̀lú ọgbọ́n  àtinú dá àti ìrírí”. Láti ọwọ́ òǹkọ̀wé Ìròyìn tó níí se pẹ̀lú ìwádìí ṣíṣe (wo ìsàlè). Síwájú síi, wo Ìfàwòràńhàn láti inú ìgbé kalẹ̀ GIJC19.

Ìtọ́ni sọ́nà fún ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí Ìròyìn: Ìwé ìtọ́ni sọ́na yìí bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn a kọ ìròyìn ilẹ̀ Áfríkà, pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jora won àti ìṣe ìdárayá èyi tí àjọ Konrad Adenuer Stifun, tí Orílẹ̀ Èdè Germany se ìgbé láruge rẹ̀. Èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde, wá káàkiri Àgbáyé, tó jẹ́ àkànṣe fún àwọn akàròyìn tó ń kojú ìdíwọ́ òfin òní kùmọ́, à ì se òdodo lẹ́nu ìṣe won, tí ohun èlò tí wọ́n fi ń sisẹ́ ṣì ń dá lágara. Ó tún wà ní Bahasa àti Mongolian èyí tó wà fún fífi ọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Kúlẹ̀ -Kúlẹ̀ e : Ìtọ́ni sọ́nà Ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí Ìròyìn ní Balkans: Ìtọ́ni sọ́nà yìí jé èyí tí BIRN ṣe agbáterù rẹ̀, tó sì tún wà fún títà, jẹ́ èyí tí  àjọ tó ń rí  sí ìwádìí ìjìnlẹ̀  àwọn akọ̀ròyìn ń ṣe  àmúlò rẹ̀, tí àfojúsùn rẹ̀ wà fún fífi imú fín lẹ lórí èròjà Ìròyìn ní ẹkún  ọ̀hún. 

Òǹkọ̀wé kan, tó tún jẹ́  Ọ̀gá Àgbà ní ẹ̀ka tí wón ti ń kọ́ni ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìwádìí lórí Ìròyìn, tí a mọ̀ sí Stabile  Centre  Investigative Journalism, nílé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Columbia, Sheila Coronel ṣe àtúpalẹ̀ lórí àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ní ṣiṣẹ́  ìwádìí lórí Ìròyìn . Gba ìpín kìn ín ní lọ́fẹ̀ẹ́ lórí ẹ̀ro ayélujára. Àwọn èdè tí  wọ́n tẹ̀ẹ́: Gẹ̀ẹ́sì, Marcedonian.

Ìwé Ìléwọ́ fún ìwádìí  ìjìnlè lórí Ìròyìn  (2020) láti ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa  ìgbé ìròyìn jáde ti Al-Jazera.

Drehbuch der Recherche (Àkọsílẹ̀ fún  iṣẹ́ Ìwádìí). Láti owó Mark Lee Hunter àti Luuk Sengers, èyí tí wọ́n tẹ̀ nílé iṣẹ́ Netzwerk Rechrche ní Orílè-èdè Germany. Èdè tí wọ́n tẹ̀ẹ́: German

Fífi ìdí Òdodo Hàn: Ìtọ́ni sónà fún ìwádìí ìjìnlè Lórí Ìròyìn ní èdè Albania: Ìwé ìtọ́ni sónà ní ojú ewé mẹ́tàléláádọ́rin yìí ṣe  àmúlò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá  pẹ̀lú àwọn  ohun èlò lóníran ń ran. Ilé iṣẹ́ OSCE àti àjọ Balkan tó ń  rí sí iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn ló tẹ̀ẹ́ jáde. Àwọn Èdè tí wọ́n fi tẹ̀ẹ́: Albanian àti Geesi.

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀  tí kò  Fi ara Hàn, ìwé kan tí Luuk Sengers àti Mark Lee Hunter gbé jáde lọ́dún 2019 “ tí àfojúsùn rẹ̀ dá lórí bí  ìṣẹ̀lẹ̀ tó rújú se lè ṣe  ìrànwọ́m fún isẹ́ ìwádìí.” Ó wà  fún títà ní ilé isẹ́ tó ń rí sí isẹ́ ìwádìí lórí  Ìròyìn.

Tẹ̀lé  Owó Yen: Ìtọ́ni sọ́nà lọ́nà tí Ayélujára láti Dẹ́kun  Ìwà Àjebánu: Ọ̀fẹ́ ni Ilé Iṣẹ́ tó wà  fún àwọn  Akọ̀ròyìn, tí a mọ̀ sí International Centre for Journalists tẹ ìwé yìí jáde. Àwọn Èdè tí  wọ́n tẹ̀ẹ́: Gẹ̀ẹ́sì, Russian, Georgian.

Ìwé Àpamọ́wọ́ gbo gbo gbò tó wá  fún Ìwádìí ìjìnlè lórí Ìròyìn: Ìwé àpamọ́wọ́ yìí tẹ̀lé Ìròyìn  tó jo mọ́ iṣẹ́ iwadii (Wo ìsàlè). Iṣẹ́ ìwádìí lórí àwọn àròkọ tó se ategun fún àwọn akọ̀rọ̀yìn lórí bí wọ́n ṣe  ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí  sí, àti bí wọ́n ṣe ń  ko I ròyìn wọn. Èdè tí  wọ́n fi kọ́ọ́: Gèésì.

Iṣẹ́ Ìwádìí ìjìnlè gbo gbo gbò lórí Ìròyìn: Àtìlẹ́yìn fún ọgbọ́n àti nú dá: Iṣẹ́ ìwádìí àti ìjíròrò fún bí iṣẹ́ ìwádìí ìjìnlè lórí i Ìròyìn tàn kále káko láti ọwọ́ David E. Kaplan ti ilé iṣẹ́ GIJN pẹ̀lú àwọn àmọ̀ràn lórí àgbékalè síse iṣẹ́ ìwádìí. 

Lórí à ti kówó jọ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà fún àwọn lẹ́gbẹ́ lẹ́gbẹ́, lọ́gbà lọ́gbà, èyí tí ilé iṣẹ́ tó ń rí sí àtìlẹ́yìn fún ilé iṣẹ́ Ìròyìn ṣe agbáterù rẹ́. Èdè tí  wón fi kọ́ọ́: Gẹ̀ẹ́sì.

Ìtọ́ni sónà Lórí Iṣẹ́ Ìwádìí fún Àwọn Ará Ìlú: Ìwé pẹlẹbẹ yìí tí ilé iṣẹ́ tó ní rí sí Ìgbòhùn sí afẹ́fẹ́ ní ìlú Amẹ́ríkà gbé jáde lọ́dú 2007 ṣe ìdanílẹ̀kọ́ rá ń pẹ́ fún àwọn akọ̀ròyìn lórí bí wọ́n ṣe lè dá Ìròyìn mọ̀, láti mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀, ṣiṣẹ́ ìwádìí lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀, bí wọ́n ṣe lè ṣe àwárí àti gba àwọn ìwé ìpamọ́ tí yóò ṣe ìránwọ́ fún wọn, kó Ìròyìn wọn jọ, kí wọ́n sì fi síta fún àwọn ará ìlú. Èdè tí  wọ́n fi kọ́ọ́: Gẹ̀ẹ́sì.

Ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi ara pamọ́ láti ọwọ́ Luuk Sengers àti Mark Lee Hunter [Ó wà fún títà ni ilé iṣẹ́e tó ń rí sí ilé ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí Ìròyìn, ìyẹn Centre for Investigative Journalism] Ó ṣe àfihàn ìlànà  tó yẹ láti tẹ́lẹ̀ tí a bá ń  ṣe iṣẹ́ ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí Ìròyìn. Èdè tí Wọ́n  fi kọ́ọ́: Gèésì .

Ìfihàn sí  Ìwádìí ìjìnlè lórí Ìròyìn , láti ọwọ́ Brant Houston (Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Fáṣítì Poynter). Èyí jẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ atọ́ni sónà lórí ẹ́ro ayélujára tí owó rẹ̀ kò dín ní US$29.95.