ÌRÒYÌN TUNTUN 

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ti ilẹ̀ Òkèèrè, tí wọ́n ń dé padà láti Àwọn Orílẹ̀ Èdè tí Àjàkálẹ̀ Àrùn kò fi bẹ́ẹ̀ bá fínra gbé Òṣùwọ̀n COVID-19 ju ti Amẹ́ríkà lọ 

Láti ọwọ́ Samantha Boyle/Fún Àjọ CU Citizen Access | Ọjọ́ Kẹsàn-án, Oṣù Ògún, Ọdún 2020 

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ti ilẹ̀ Òkèèrè tí ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Illinois tó wà ní Urbana-Champaign láàárín ọdún ìkọ́kọ̀ọ́ 2019 sí 2020 wá láti àwọn orílẹ̀ èdè tí Àjàkálẹ̀ Àrùn COVID-19 wọn kò fi bẹ́ẹ̀ tó ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bíi àjọ CU Citizen Access ṣe yànàná. 

Lásìkò òjò tó kọjá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá, ó dín mẹ́rìndínlógún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n kàwé ni ile ẹ̀kọ́ ọ̀hún láti àwọn orílẹ̀ èdè tí kò dín ní ọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe sọ. 

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ti ilẹ̀ Òkèèrè tí ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Illinois tó wà ní Urbana-Champaign ni wọ́n yóò kàn ń pá fún láti wà ní ìgbélé ọlọ́jọ́ mẹ́rìnlá tí wọ́n bá ti ń dé.