Mímúlò ìtàkùn ayélujára tó níwọ̀n lò ní Yàrá-ìròyìn rẹ: Ewé-ìtalólobó lórí Ìfọ́ńká àti lílọ́wọ́sí àwọn olùwòran
Láti ọwọ́ Rossalyn Warren | March 18, 2021
Bí o bá ń ka èyí, àwọn àǹfààní ni pé o ti ní òye pàtàkì àwọn olùwòran rẹ tẹ́lẹ̀. dájúdájú o kò nílò kí n sọ fún ọ pé mímọ ẹni tí olùwòran rẹ jẹ́, ibi tí wọ́n lọ lórí ìtàkùn-ayárabíàṣá, àti àwọn àkóónú tí wọ́n lò jẹ́ lámèyítọ́ sí àjọ kájọ tó yè. Síbẹ̀, bí o bá tilẹ̀ mọ àwọn nǹkan wọ̀nyìí nípa àwọn olùwòran àti àwọn oǹkàwé rẹ, àwọn ohun látí kọ́ si àti láti ṣiṣẹ́ lé máa ń wà. Èyí ni ìtọ́sọ́nà fún àjọ tó bá ń gbìyànjú láti ní òye sí i nípa ìtàkùn-ayárabíàṣá àwọn olùwòran wọn, àti àwọn tí wọ́n ń wá olùwòran tuntun láti débi àwọn àkóónú wọn.
Tí o bá ti dé ibi ìkànnì tí ó ṣiṣẹ́ dára jù, kò sí ìdáhùn tó tọ́ tàbí tí ò tọ́ tó hàn kedere. Ó máa ń jẹ́ ibi tí o wà gangan ní àgbáyé, agbára òṣìṣẹ́, àti ohun tí o mọ̀ nípa olùwòran rẹ.
Nígbà ti o bà ń ka àwọn ìsedúró wọ̀nyí, ohun à mú lọ́wọ́ lọ ni: láti ṣàṣeyege, o gbọ́dọ̀ máa fi akitiyan sí ríro bí o ó ṣe fọ́n àwọn iṣẹ́ rẹ ká bí o bá ṣe ń lo àkókò láti ṣẹ̀dá àkóónú fúnra rẹ̀. O le kọ ìtàn aláràgbàyídá, tàbi ṣe iṣẹ́-àkànṣe tárà rẹ̀ yàtọ̀ – ṣùgbọ́n bí o bá kàn jókòó tó fẹ̀yìn tì tí o nírètí pe àwọn olùwòran yóò ya lu ìkànnì rẹ, nígbà náà ìfàkókò ṣòfò ni. Láti fọ́ ariwó orí-ìtàkùn àgbáyé lẹ́nu, o nílò láti fi iṣẹ́ láti ṣàgbékalẹ̀ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn oǹkàwé rẹ kó jẹ́ ọlọ́jọ́-pípẹ́, kí wọ́n le rántí orúkọ rẹ àti kí wọ́n le má a padà wá.
Ta ni Olùwòran Rẹ? Ìkànnì Wo Ni A Lè Lò?
Kí o tó ṣètò láti ṣe ohunkóhun, o nílò láti pinnu ẹni tí ò ń gbìyànjú láti kàn sí pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ. Ǹjẹ o ń gbìyànjú láti sopọ̀ pẹ̀lú àwọn olùwòran tí kò ní iṣẹ́ tó tó? Ǹjẹ́ ò ń kàn sí àwọn ènìyàn tó ti dàgbà tàbi àwọn tó ṣì kéré?
Nígbà tí mo bi Àjọ pé ta ni wọ́n ńgbìyànjú láti kàn ṣí, ìdáhùn tí mo máa ń sábà gbọ́ ni pé: Ọ́hù, a ń gbìyànjú láti kàn sí gbogbo ènìyàn! A fẹ́ ọ̀pọ̀ oǹkàwé. Ṣùgbọ́n ìgbéjáde nílò láti ṣètò ìretí ohun tó bójú ayé mu.
Níwọ̀n ìgbà tí o ti dá àwọn ọ̀rínkínníwín àlàyé sílẹ̀ nípa àwọn olùwòran rọ, o lè pinnu ibi tí o fẹ́ fọn ká sí. Ọ̀pọ̀ ìkànnì ló wà tí wọ́n le gbé iṣẹ́ rẹ sí. Ṣùgbọ́n o kò le wà ní orí gbogbo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ kò ní mú ọpọlọ dání. Yíyan èyí tí ó tọ́ fún gbígbé jáde, ẹni tí olùwòran rẹ jẹ́, àti ibi tí o ti ń ṣiṣẹ́ lágbàáyé, jẹ́ kókó.
Nǹkan tí mo máa ń sábà gbọ́ tí àwọn Àjọ béèrè ni: “ṣé kí á ṣètò àwòrán-orí lórí *insert new trending app* Kí inú rẹ tó dùn àti kí o tó ṣètò àkáùǹtì ìtàkùn ayélujár lórí oríṣìíríṣìí ìkànnì àádọ́ta, rò nípa èyí: Ìkànnì tí àwọn ènìyàn ń lò yóò má a yí padà ni, ṣùgbọ́n àkóónú tí o pín kò ní yí padà. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé kò tó a ń sáré tẹ̀lé gbogbo ápùù tuntun tó bá ń tàn àyàfi tí ó bá mú ọpọlọ dáni fún ohun tí o mọ̀ nípa olùwòran rẹ. Fún àpẹẹrẹ, ìgbà ṣókí kan wà tí gbogbo ènìyàn rò pé “Snapchat” ni ọjọ́-iwájú, àti “Facebook Live” gba gbogbo àjọ ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde káàkiri ọkọ̀, ṣùgbọ́n ipa méjèèjì ti dínkù.
Wo Ìkànnì-ayélujára GIJN: Àwọn Olùwòran tó pọ̀, Ìlọ́wọ́sì sí i, àti ipa tó tóbi sí i: Bí àwọn Oníròyìn ṣe le ta ọjà tó dára sí i lórí ìtàn ajẹmọ́-ìwádìí
Ìyẹn kò sọ pé kí o má dán àwọn ìkànnì tuntun wọ̀nyìí wò. Ṣùgbọ́n ìlò àkókó rẹ tó dára jù ni láti fi okun sí ìlọsíwájú àwọn ohun-èèlò tí o ti lò tẹ́lẹ̀ – àti èyí o mọ̀ pé ó ṣiṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, kíkọ́ ìpìlẹ̀ ikọsódì lẹ́tà-ìròyìn le dára fún kíkọ́ òótọ́ àwọn oǹkàwé ọlọ́jọ́-pípẹ́ ju ṣíṣẹ̀dá àkáùntì titun “Instagram”.
Ohun gbogbo tí èyí sọ ni pé kí o wá ìkànnì tí wọ́n lò ní orílẹ̀-èdè rẹ láti ọwọ́ àwọn ènìyàn tí ò ń gbìyànjú láti kàn sí. Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún Àjọ ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jádé ní ilẹ̀ Australia kọ ni yóò ṣiṣẹ́ fún àjọ tó wà ní Senegal. Bí olùwòran rẹ bá wà ní Vietnam tí kò sì sí ẹni tó ń sábà lo àkáùntì “Twitter”, o kò nílò àkáùntì “Twitter”. Tí o bá ń gbìyànjú láti kàn sí àwọn ọ̀dọ́ tí ó wà ní ilẹ̀ “Italy” ṣùgbọ́n àwọn ọmọ kékèké kò sí ní lórí ẹ̀rọ “Facebook”, o kò nílò láti wà lórí “Facebook”. Bí o bá jẹ́ Àjọ pẹ̀lú ohun èèlò tó lódìwọ̀n, èyí pàápàá jẹ́ òótọ́.
O gbọ́dọ̀ máa fi akitiyan tó pọ̀ sí ríro bí o ó ṣe fọ́n iṣẹ́ rẹ ká bí o bá ṣe ń ṣẹ̀dá àkóónú fúnra rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìkànnì ni yóò má a wá lóṣooṣù, lọ́dọọdún; o nílò láti wádìí wọn àti sọ́ ìdàgbàsókè wọn – tàbí àìdàgbàsókè – ní agbègbè ìfojúsí rẹ àti ìráàyè sí létòlétò. Bí o bá ṣàkíyèsí pé àwọn ènìyàn tí ó ń wọlé sí orí ápùù pọ́ ọ̀ si ní àwọn orílẹ̀-èdè kan pàtó tí o ń fojú sọ, ó le mú ọpọlọ dání láti fojú sí i lára.
Pẹ̀lú, má ṣe wo orí ìkànnì nípa irúfẹ́ àkóónú tí wọ́n gbà ọ́ láàyè láti gbé sórí ìtàkùn. Dí pò, fọ́ wọn sí irúfẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fúnni. Mo fẹ́ láti ṣe èyí ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí:
- Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Ọlọ́nà-kan
O ń gbóhùnsáfẹ́fẹ́ sí àwọn ènìyàn, èyí tí ó túmọ̀ pé ó jẹ́ àsọgbà ọlọ́nà-kan tó pọ̀; o kò retí èsì tàbí ìpín. Lórí ìkànnì yìí o ṣì gbọ́dọ̀ fún àwọn oǹkàwé rẹ ní ìwọ̀fún láti fi ìdásí tàbi èsì ránṣẹ́, àti kí o sì ṣì tún bá olùwòran rẹ sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí yóò jẹ́ kó túra ká. Ṣùgbọ́n àwọn ìkànnì kì í fúnni ni ìdáhùnsí ojú-ẹsẹ̀, tàbí àfojúrí. Àwọn ápùù tàbí ọ̀nà kan tí ó fúnni ní irúfẹ́ ìlọ́wọ́sí yìí ni:
- Telegram: ìfiyèsí láti kọ́ olùwòran tó tóbi, ṣùgbọ́n láìsí èsì.
- Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ WhatsApp: fúnni ní òdìwọ̀n ṣùgbọ́n ìkànsí aláfojúsùn.
- Lẹ́tà-ìròyìn: le fi jẹ́ ti ìṣàájú.
- Àsọgbà Ọlọ́nà-kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú Ìdásí
O ń pín iṣẹ́ rẹ lórí ìkànnì pẹ̀lú olùwòran rẹ, ṣùgbọ́n èsì kan ṣoṣo tí o ó rì í wà ní ìwọ̀fún ìdásí ( tí wọ́n bá ṣí ìwọ̀fún ìdásí sílẹ̀). Ìdásí le ṣe ìrànwọ́ láti tún ojú-àmúwò àwọn ènìyàn rọ lórí ohun tí o gbé sórí ìkànnì, ní èyí tí o kò nílò láti lọ́wọ́sí i tàbí fèsì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó ṣe pàtàkì láti bójútó àti láti ka ohun tí wọ́n sọ. Àwọn àpẹẹre kan ni:
- Gírìdì Instagram
- Fídíò/YouTube
- Àsọgbà Ọlọ́nà-Méjì
O ń gbé nǹkan sí orí-ìtàkùn ayárabíàṣá àti pé o lè retí ìlọ́wọ́sí ẹsẹ̀kẹsẹ̀. Lórí áwọn ìkànnì yìí, iyè-ara tó pọ̀ sí ti àsọgbà kannáà ń ṣẹlẹ̀, àti pé wọ́n ń sábà ń retí èsì ní ọ̀nà tó yára jù sí àwọn olùwòran rẹ, pẹ̀lú.
- Instagram Live
- Àwọn ẹgbẹ́ WhatsApp
Ìmọ̀ràn temi ni láti ráàyè sí bóyá àjọ rẹ ní agbára láti bójútó àsọgbà náà; fún ápẹẹrẹ, ṣé o ní owó láti gba olóòtú orí-ìtàkùn ayárabíàṣá, tàbí olóòtú olùwòran? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o le mú ọpọlọ wá láti wà ní gbogbo agbègbè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta káàkiri, láti ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ọlọ́nà-kan sí àsọgbà ọlọ́nà-méjì, bíi níní àkáùntì Twitter tó ń ṣiṣẹ́, àti ojú-ewé Instagram tó bójútó àti ìfèsì sí ìdásí. Ṣùgbọ́n tí o bá ní òdìwọ̀n ohun-èèlò àti owó-ìrànwọ́, ó le mú ọpọlọ díẹ̀ dání láti dín ìdojúkọ, sí bẹ́ẹ̀ lórí ìkànnì àsọgbà ọlọ́nà-kan bíi lẹ́tà-ìròyìn tó lágbára, tàbí ìkànnì Telegram.
Ìkànnì kọ̀ọ̀kan ní oríṣìíríṣìí ibi-afẹ́dé èyí tí kò wúlò fún ẹnikẹ́ni tí wọn kò bá lò ó bí ó ti yẹ. Fún àpẹẹrẹ, o gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti lo “Twitter” fún ohun tí wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ fún: dídá olùwòran rẹ lóhùn àti níníṣe nínú àsọgbà. O kò gbọdọ̀ lo “Twitter” gẹ́gẹ́ bí Àsọgbà Ọlọ́nà-kan nítorí kì í ṣe “RSS feed” àti pé lílò ó lọ́nà yẹn kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí àwọn olùwòran rẹ lọ́wọ́ si.
Kíkọ́ ìpìlẹ̀ ìkọsódì lẹ́tà-ìròyìn le dára jù ní kíkọ́ ìsòtítọ́ oǹkàwé ọlọ́jọ́-pípẹ́ ju ṣíṣẹ̀dá àkáùntì “Instagram” tuntun.
Pẹ̀lú eléyìí lọ́kàn, má rò pé ìkànnì àsọgbà ọlọ́nà-méjì ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí èèyàn fi le rí òye àwọn olùwòran gbà. O lè rí ìmọ̀lára gidi bí o ṣe ń lọ́wọ́sí àwọn olùwòran rẹ ní ìkànnì àsọgbà ọlọ́nà-kan, pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, Lẹ́tà-ìròyìn ti fúnni ni ìwọ̀fún láti rí òṣùwọ̀n tẹ̀ẹ́-láti-ibí láti rí àwọn wúnrẹ̀n gbajúmọ̀, àti níbi lágbègbè tí wọ́n ti ṣí i. ( Díẹ̀ sí i lórí ìyẹn wà ní apá ìwọ̀n níwájú.)
Kókó ìṣoro mìíràn láti rò nígbà tí o bá ń yan irúfẹ́ ìkànnì láti lo ìràáyè sí. Fún àpẹẹrẹ, tí “Facebook” bá jẹ́ gbajúmọ́ ní agbègbè rẹ ṣùgbọ́n ìpanilẹ́numọ́ ojú tàbí àkóónú ni wọ́n ń dí sí i lójoojúmọ́, ṣé ó tó yíyọ àkóónú rẹ kúrò ní ìkànnì-gbangba kí o wá gbájúmọ́ Lẹ́tà-ìròyìn tàbí ìkànnì “Telegram”? Ìyẹn kò sọ wí pé ìpanilẹnumọ́ tán síbẹ̀ ṣùgbọ́n ó le ranni lọ́wọ́ tí o bá ro àwọn ìwọ̀fún tuntun láti fi ìfọ̀kànbalẹ̀ kàn sí àwọn olùwòraan rẹ.
Bí ayé bá ṣì ń kojú ipele ìpenilẹ́numọ́, àfikún ìwọ̀n bíi VPN (Nẹ́tíwọ̀kì Àdáni Orí-afẹ́fẹ́, èyí tí ó lè dá ààbò bo ìdánimọ̀ olùmúlò àti ìṣe lílọ-kiri-ayélujára kúrò lọ́wọ́ ìtọpa) àti pé wọ́n le nílò àwọn nẹ́tíwọ̀kì tuntun. Ní ọ̀nà-mìíràn, bí o bá kojú ìpanilẹ́numọ́ tó le, àjọ rẹ le fẹ́ fi nǹkan sí orí-ìtàkùn láìlórúkọ; tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ro ìkànnì tó mú ọpọlọ dání jù ní orílẹ̀-èdè rẹ láti ṣe èyí láìléwu bó ti ṣeé ṣe. (A gbọ́dọ̀ ṣàkíyèsí pé ìtọ́sọ́nà yìí kò sọ sí ìkànnì ilẹ̀ China tàbí àwọn ìpèníjà àrà-ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ìpalẹ́numọ́.)
Ibòmìíràn láti rò nígbà tí ó bá di ìrààyè sí jẹ́ èyí tó ṣeé faradà. Fún àpẹẹrẹ, tí o bá ń gbìyànjú láti kàn sí àwọn agbègbè tí owó-tó-ń-wọlé kéré, tí wọn kò sì ráàyè sí ẹgbẹ́-tó-gbòòrò kíákíá, dípò ṣíṣètò ìkànnì YouTube pẹ̀lú àwọn Fídíò tí ó máa ń pẹ́ kó tó ṣe, bóyá àtúnṣe àtẹ̀ránṣẹ́ onílẹ́tà ni ó dára jù fún un, bí o ṣe jẹ́ pé òhun ni wọ́n ráàyè sí jù. Ro àwọn ápùù àti àwọn ìkànnì tí ìráàyè sí wọn lódìwọ̀n pẹ̀lú àwọn ìhámọ́. Fún àpẹẹrẹ, “Paywalls” jẹ́ ìṣòro kan nígbà tí ó bá di ìhámọ́ ìfaradà, ṣùgbọ́n tí ápùù kan bá sọ pé kí olùmúlò san owó nígbà tí ó bá fẹ́ wọlé, ṣé èyí yóò mú ọpọlọ wá fún àfẹ́jáde olùwòran rẹ?
Títẹ̀lé jẹ́ ìparun ọ̀pọ̀ àwọn ìkànnì ẹrọ ayárabíàṣá tí ó wọ́pọ̀ jù àti ọ̀nà ìfọ́nká tí àwọn àjọ lò, pẹ̀lú àsopọ̀ sí àwọn átíkù lórí ìlò wọn, àti ibi tí wọ́n ti le rí wọn. Gbogbo èyí jẹ́ ọ̀fẹ́ láti lò àyàfi àwọn mìíràn tí wọ́n fi ààmì $ sọ ọ́.
Ìkànnì | Àkíyèsí / Àwọn Ìtalólobó |
WhatsApp-Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ / àwọn ẹgbẹ́ / Ìṣòwò ($) | Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Whatsapp: Bí Wọ́n Ṣe Lè Tọ́nisọ́nà Bí O Ṣe Lè Ṣètò Àjo Ìròyìn Lórí Whatsapp Bí O Ṣe Lè Lo Whatsapp Fún Ìkóròyìn-Jọ Bí Àwọn Orúkọ-Ilé-Iṣẹ́ Ṣe Ń Lo Whatsapp Fún Okòwò láti Gbajúgbajà sí Àṣírí: Àǹfààní àti Aláìláǹfààní ìlò Okòwò WhatsApp |
Twitter fún Aláìjèrè: Ìtọ́nisọ́nà tó gbòòrò Ìtalólobó Mẹ́rìn-dín-lọ́gbọ̀n Twitter fún àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ O ó fẹ̀ ẹ́ kí o tì tètè Mọ̀ Ìtajà Twitter: Ìtọ́sọ́nà tó pé fún Okòwò Ọ̀nà Àtinúdá Márùn-ún Orúkọ-ilé-iṣẹ́ le lo okùn Tweet Ọ̀nà tó dára jù fún Àjọ Ìròyìn láti lọ́wọ́sí pẹ̀lú Olùwòran wọn Àwọn èrò Mẹ́tà-dín-lógún Ìlọ́wọ́sí fún Ohun tí ó yẹ ká gbé sórí Twitter | |
Ojú-ewé Facebook / Ẹgbẹ́ / Boṣe-ńlọ-lọ́wọ́lọ́wọ́ | Bí o ṣe le Ṣẹ̀dá Fídíò Boṣe-ńlọ-lọ́wọ́wọ́ ti Facebook tí Àwọn Ènìyàn Fẹ́ Wo Ohun gbogbo tí o Nílò Láti Mọ̀ Nípa Ẹgbẹ́ Ìtajà Facebook Bí àwọn Olùtẹ̀wésíta Ìròyìn Ìbílẹ̀ ṣe ń Lo Ẹgbẹ́ Facebook láti Sopọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Oǹkàwé Ìtọ́sọ́nà tó pé sí Ẹgbẹ́ Facebook: Bí o ṣe lè ṣẹ̀dá Ẹgbẹ́, kọ́ Agbègbè àti jẹ́ kí Ìkànsí ọ̀gáníkì rẹ Gbé nǹkan sórí ìtàkùn díẹ̀, jẹ́ kí àwọn pósìtì rẹ tó wà lókè rú gágá si, àti jù bẹ́ẹ̀: Ọ̀nà mẹ́rìnlá láti jẹ́ kí Ìlọ́wọ́sí ojú-ewé Facebook rẹ pọ̀ si Ọ̀nà Mẹ́wàá láti jẹ́ kí Ìlọ́wọ́sí Facebook rẹ pọ̀ si tó ṣiṣẹ́ |
Telegram | Telegram: Ohun tí ó jẹ́ àti Bí wọ́n ṣe ń lò ó Bí Ìròyìn “Bloomberg” ṣe ń lo Telegram Bí o ṣe lè lo Telegram fún Okòwò – Gbogbo ète fún Ìgbéga Ohun tí Ile-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn jáde Nìlò láti Mọ̀ Láti Bẹ̀rẹ̀ Lórí Telegram |
Mailchimp | Ìtọ́sọ́nà Dídánrawò Mailchimp A/B: Bí wọ́n ṣe ń ṣe é àti ohun tí o yẹ kó dánwò Ìtọ́sọ́nà Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Bí wọ́n ṣe ń lo Mailchimp ( Kọ́ àtẹ Ímeèlì rẹ) Bí o ṣe le ṣe Ímeèlì Lẹ́tà-Ìròyìn tó péye ní Mailchimp |
Instagram – Àwọn Ìtàn / Bó-ṣe-ńlọ-lọ́wọ́lọ́wọ́ | Ìtọ́sọ́nà tó lágbára sí àwọn ìtàn Instagram fún okòwò Bí o ṣe lè lo Bó-ṣe-ńlọ-lọ́wọ́lọ́wọ́ Instagram láti dàgbà àti láti jẹ́ kí àwọn tó ń tẹ̀lé ọ lọ́wọ́sí i. Bí ìròyìn BBC ṣe jẹ́ kí àwọn olùwòran ní ìlọ́wọ́sí sí i lórí Instsgram |
YouTube | Ọ̀nà Mẹ́rìn-dín-lógún láti gbé ìkànnì YouTube rẹ ga fún wíwò tó pọ̀ si Bí o ṣe le ní àwọn tó ń wo ohun tí o gbé sí orí YouTube sí i: ọgbọ́n méjìlà tí ó Ṣiṣẹ́ Mú Ète fún Kíkàn sí àwọn Olùwòran Lágbàáyé Àwọn Ọ̀nà Méjì-dín-lógún Láti ní Olùwò sí í Lórí YouTube |
Ìtẹ Àtẹ̀rànṣẹ́ | Pépà Tuntun Fúnni ni Ìròyìn ‘Fact-First’ láti kà ní Ààtò àtẹ̀ránṣẹ́ Nípa títẹ-àtẹ̀ránṣẹ́ tó pọ̀ sí àwọn ṣí àwọn Olùgbé, Ilé-Iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde so Olùlò Ìròyìn Owó-tó-wọlé tó kéré pọ̀ láti Wúlò, Àkójọpọ̀-ìmọ̀ Ara-ẹni |
TikTok | Pàdé TikTok: Bí àwọn Washington ṣe máa ń gbé nǹkan sí orí ìtàkùn, Ìròyìn NBC, àti Ìròyìn Àárọ̀ Dallas ń lo Ìkànnì the-of-the-Moment Bí Ìròyìn Yahoo ṣe tó Olùtẹ̀lé Mílíọ̀nù kan lórí TikTok láàárín ọdún kan |
Ọ̀pọ̀ Oríṣìíríṣìí Ọ̀nà láti Gbé Àkóónú Rẹ Kalẹ̀
Tí ó bá di wí pé ìkànnì wo ló ṣiṣẹ́ dára jù fún Àjọ rẹ, kò sí ìdáhùn tó tọ́ tàbí èyí tí kò tọ́ tó hàn kedere. Ó wà níbi tí o wà ní ayè, agbára òṣìṣẹ́ tí o ní, àti ohun tí o mọ̀ nípa olùwòran rẹ. Ṣáà rántí: O kò nílò láti tan ara rẹ ká tíńrín. Rò ó pẹ̀lú ètè lórí ohun tí ó tọ́ fún àkókò rẹ àti èyí tí kò tọ́.
Jẹ́ kí á gbà pé o ní èrò nípa ẹni tí olùwòran rẹ jẹ́ àti ìkànnì tí yóò ṣiṣẹ́ dáadáa láti kàn sí wọn ní apá ayé rẹ. Níbàyìí o wá sí apá ibi tí a ti dín bí o ṣe lè báraẹnisọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ rẹ kù.
Ìkànnì kọ̀ọ̀kan ni ó fúnni ni oríṣìíríṣìí nǹkan, àti nígbà tí ìkànnì kọ̀ọ̀kan gbèrò láti di ìlúmọ̀ọ́ká fún ààtò kan pàtó, ọ̀pọ̀ ní àbùdá tó yàtọ̀. Fún àpẹẹrẹ, Instagram dára fún àkóónú ìwòran ṣùgbọ́n ó tún le dára fún àwọn ohun alárìígbọ́. Lórí Twitter, o kò nílò láti kàn “Tweet” àkòrí àti Àsopọ̀; o lè lò ó fún Sísọ-ìtàn, fún àpẹẹrẹ, nípa gbígbé “Tweet” mẹ́wàá ní ìtàn tó gbayé kan. “Telegram” dára fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìmúdójú-ìwọ̀n ojoojúmọ́, ṣùgbọ́n ó tún dára fún títẹ́ fídíò sílẹ̀.
Nígbà tí mo gbà ọ́ níyànjú láti ronú pẹ̀lú àtinúdá lórí bí o ṣe fọ́n iṣẹ́ rẹ ká, èyí kì í ṣe láti sọ pé, bí o bá ní iṣẹ́-ìwádìí tó gbẹ́ja ńlá hánu, pé o nílò láti kàn dédé jù ú sí orí TikTok. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ rẹ kọ̀ọ̀kan, o nílò láti máa rò ó oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó di síṣọ lórí ìtàkùn ayárabíàṣá. Fún àwọn ènìyàn ní ìwọ̀fún láti ka àwọn átíkù ọlọ́jọ́-pípẹ́ lórí ìkànnì rẹ, ṣùgbọ́n kí o tún ro bí o ṣe lè fa àlàyé tó ṣe pàtàkì yọ láti inú átíkù àti kí o tàn án ká síwájú láti dé ọ̀dọ̀ àwọn oǹkàwé tuntun.
Níbí ni àgbékalẹ̀ oríṣìíríṣìí fọ́nrán tí o lè rò nígbà tí o bá ń pinnu bí o ó ṣe tẹ ojúlówó ìtàn jáde:
- Àtẹ̀ránṣẹ́: Bí o ṣe ṣe olóòtú gígùn, ṣe àfikún bí o ṣe ṣé rí sí, ṣe ìrísí ohun àti “ìkùn” àkóónú rẹ ọwọ́ rẹ lówà.
- Alárìígbọ́: Alárìígbọ́ kò kàn túmọ̀ sí pódíkààsìtì. O lè yọ kílìpù-alárìígbọ́ kúrò lórí-ìtàkùn ayélujára kí o sì fi sí “Twitter”; o lè gbé kílípù-alárìígbọ́ léra wọn pẹ̀lú àtẹ̀ránṣẹ́ kí o wá sọ ọ́ di fídíò-olójú-alárìígbọ́ lórí “Facebook”.
- Àwòrán: Ro fọ́tò, àrà gíráfìkì, gíràfù, àpẹẹrẹ – àwọn ènìyàn le wà láàárín àwọn olùwòran rẹ tí ó máa ń fèsì dáadáa sí póòsìtì-aláfojúrí.
- Fídíò: ìwé tó kúrú; aṣàlàyé ààtò fídíò kúkurú.
Nígbà tí o bá ń wá ìṣítí lórí bi o ṣe máa pín iṣẹ́ rẹ, má kàn wá àwọn ẹgbẹ́ ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde mìíràn. Ọ̀pọ̀ ìṣítí ló wà níta lórí bí o ṣe lè pín àlàyé tó múnádóko, àwọn ìtàn, àti ìròyìn ní ọ̀nà àtinúdá káàkiri gbogbo ilé-iṣẹ́, láti ìnífẹ̀ẹ́sí sí àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni.
Bí Wọ́n Ṣe ń Lo Mẹ́tíríkì láti Wọn Ipa Iṣẹ́ Rẹ
Wíwọn àtúpalẹ̀ wúlò, ọ̀nà pàtàkì láti ni òye nípa olùwòran rẹ si i. Sí bẹ́ẹ̀, ò sì tún túmọ̀ sí ohun nǹkan bí o kò bá ṣètò ibi-afẹ́dé. Kí o tó lo nọ́ḿbà láti wọn àwọn ènìyàn tó wo ohun tí o gbé sórí ìtàkùn ayárabíàṣá, fẹ́ẹ, tàbí fèsì sí iṣẹ́ rẹ, o nílò láti pinnu ohun tí aṣeyọrí jọ fún àjọ rẹ. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá jẹ́ àjọ kékeré, jẹ́ àníyàn láti kàn sí iye x ti orí-ìtàkùn ayélujára tí o lọ lóṣooṣù, tàbí ṣé ó jẹ́ lári rí olùkọsódì lẹ́tà-ìròyìn tuntun tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta? Bí o bá jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó tóbi jù, ṣé o fẹ́ kí àwọn oǹkàwé máa tún n kà lórí ìkànnì rẹ, tàbí ṣé ó dára láti ṣètò iye olùtẹ̀lé tí o fojú sọ? Kò sí ilé-iṣẹ́ tí yóò ní èrò kan náà ti àṣeyọrí, nítorí bẹ́ẹ̀ ó tó rírò ohun tí ó jọ fún ọ.
Àkíyèsí nípa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ: nígbà tí ó bá di àtúpalẹ̀ ìtàkùn-ayélujára, àwọn ọ̀nà mìíràn wà láti ní òye díẹ̀ si lórí olùwòran. Fún àpẹẹrẹ, o lè rí bí àwọn oǹkàwé ṣe pẹ́ tó lórí ojú-ewé rẹ, èyí tí ó le dá àbá bóyá àwọn oǹkàwé lọ́wọ́sí í dáadáa (tàbí bẹ́ẹ̀ kọ̀ọ́). Àti pé nígbà tí o ní súnkẹrẹ-fàkẹrẹ tó pọ̀ lórí ìkànnì rẹ le dára, èyí kò túmọ̀ sí ipa, tàbí olùwòran tó lọ́wọ́sí i. Ohun tó pọ̀ láti ṣe ló wà láti kọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn oǹkàwé láti máa padà wá lóòrèkóòrè, àti pé kí orúkọ àjọ rẹ le di rírẹ́ mọ́ ọkàn wọn bí olùfọkàntán, orísun àti-lọ. (Fún àfikún mẹ́tírìkì pàtàkì láti wò fín, wo Beyond Metrics: A Beginners Guide to Metrics that Matter.)
Tí o bá ni àwọn èèlò àti owó-ìrànwọ́ tí ó gba èèlò mẹ́tírìkì láàyè láti kọ́ -ọ-sínú-ilé, iyẹn jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu! Ṣùgbọ́n ó ná ni lówó, àti pé, bí o kò bá ní, olùgbàlejò èèlò tó pọ̀ wà níta tí ó le ranni lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ jẹ́ ọ̀fẹ́, ọ̀pọ̀ máa ń fúnni ní àyọkúrò owó fún aláìlérè, nígbà tí àwọn mìíràn ní oríṣìí-ẹ̀dá tó jẹ́ ọ̀fẹ́ pẹ̀lú iṣẹ́ tó lódìwọ̀n. Níbí ni àwọn ìléwọ́ ti ìwọ̀fún:
Èèlò | Ohun tó ṣe / Àkíyèsí | Ìnáwó? |
Buffer | Buffer jẹ́ èèlò tí ó le ṣe é lò láti bójútó àkáùntì lórí nẹ́tíwọ̀kì ìtàkùn ayárabíàṣá, nípa pípèsè ohun-èlò fún olùmúlò láti ṣètò ohun tí wọn yóò gbé sórí ẹrọ̀ ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ sí Twitter, Facebook, Instagram, àwọn ìtàn Instagram, Pinterest, àti LinkedIn, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtúpalẹ̀ àwọn èsì rẹ àti ìlọ́wọ́sí pẹ̀lú àwọn agbègbè rẹ̀. | Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n fúnni ní àyọkúrò sí aláìlérè |
Later | Èèlò tí ó gbà ọ́ láàyè láti fètòsí, ṣètò, tẹ̀ jáde, àti wọn èsì ohun tí o gbé sí orí ẹ̀rọ ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Instagram | Bẹ́ẹ̀ni |
Sprout Social | Sprout Social jẹ́ ìsàkóso orí ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ àti ìkànnì ìṣàpéye. Ó fún ọ ní họ́ọ̀bù kan fún ìtẹ̀wéjáde ẹ̀rọ ayárabíàṣá, ìṣàtúpalẹ̀, àti ìlọ́wọ́sí káàkiri gbogbo púrófàìlì ẹ̀rọ ayárabíàṣá. | Bẹ́ẹ̀ni |
Mailchimp | Mailchimp fúnni ní onírúurú èèlò tí o lè lò láti ṣàtúpalẹ̀ ìṣèré rẹ, kọ́ nípa olùwòran rẹ sí i, àti mú ìtajà rẹ dára sí i, àti pẹ̀lú ìdánrawò A/B èyí tí ó gbà ọ́ láàyè láti fi oríṣìí-ẹ̀dá ojú-ewé ayélujára méjì wé ara tàbí ápùù tako ara wọn láti ṣe ìpinnu èyí tí ó ṣeré jù | Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́ ọ̀fẹ́ kan |
Ọ̀nà-àtúpalẹ̀ Twitter | Twitter fúnni ni iṣẹ́ ọ̀nà-àtúpalẹ̀ tirẹ̀, ṣùgbọ́n fún oṣù kan ni | Bẹ́ẹ̀kọ́ |
Ọ̀nà-àtúpalẹ̀ Facebook | Facebook fúnni ní èèlò ọ̀nà-àtúpalẹ̀ ọ̀fẹ́ tirẹ̀ nígbà tí o bá ṣí ojú-ewé | Bẹ́ẹ̀kọ́ |
Ọ̀nà-àtúpalẹ̀ Google | Ọ̀nà-àtúpalẹ̀ Google fúnni ní ọ̀yẹ̀là tó fẹjú (gbìyànjú Ọ̀nà-àtúpalẹ̀ Google fún àwọn Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.) | Bẹ́ẹ̀kọ́ |
Chartbeat | Chartbeat jẹ́ ọ̀nà-àtúpalẹ̀ àkókò-tyòótọ́ mìíràn, tó ń fúnni ní ọ̀yẹ̀là láti mú ìlọ́wọ́sí olùwòran dára sí, bun àwọn ìpinnu àwọn òṣìṣẹ́ síṣe olóòtú gbọ́, àti jẹ́ kí ọ̀nà-ìkàwé peléke sí i. | Bẹ́ẹ̀ni |
BuzzSumo | BuzzSumo jẹ́ èèlò orí-ẹ̀rọ ayárabíàṣá tó gbà àwọn aṣàmúlò ní ààyè láti ṣàwárí àkóónú tó jẹ́ gbajúgbajà nípa àkòrí tàbí lórí ìtàkùn ayélujára yòówù. | Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n àwọn iṣẹ́ ọ̀fẹ́ kan |
Láti ìṣèṣirò ìkànsí àwọn “Tweet”, láti rí ibi tí àwọn oǹkàwé rẹ ti ń bọ̀ nínú ayé, àwọn ohun-èèlò yìí gbogbo máa ń fúnni ní onírúurú ọ̀nà sí ìwọ̀n mẹ́tírìkì tí kì í ṣe ìkànnì tìrẹ nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń yẹ irúfẹ́ àkóónú tó jẹ́ gbajúmọ̀ káàkiri ìkànnì ilé-iṣẹ́ tó-n-´gbé-ìròyin ẹ̀rọ ayélujára jáde.
Síbẹ̀, nígbà tí àwọn ohun-èèlò le ka iye nọ́ḿbà, ó kù sí ọwọ́ rẹ láti yé wọn, kí o sì ro bí wọn ṣe dára tó fún èròńgbà àjọ rẹ. Fún àpẹẹrẹ, tí o bá ṣàkíyèsí nọ́ḿbà tó ga láti orílẹ̀-èdè x pé ó ń ṣàbẹ̀wò sí àwọn ìtàn lórí àkòrí x, ó le dá àbá ìdàgbàsókè ìnífẹ̀ẹ́sí ní agbègbè bẹ́ẹ̀, ó sì le ṣe ìrànwọ́ ìtọ́sọ́nà apá-ibìkan àkóónú àjọ rẹ. Tàbí tí o bá ní pàtó, olùwòran kékeré tí o ń gbìyànjú láti kànsí, fífojú sí lílo èèlò láti ṣe ìrànwọ́ kànsí olúkọsódì ímeèlì ẹgbẹ̀rún kan jẹ́ oríiré ńlá.
Ó dálé ipò rẹ, ó le wúlò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Facebook láti jíròrò àwọn àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ sí ìkànnì ẹ̀rọ ayárabíàṣá, pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, Ẹgbẹ́ Orí Ìtàkùn Ayárabíàṣá níbí jẹ́ ìwúlò.
Àwọn Ohun Ìkẹyìn láti Rántí
Níbi ni àwọn ohun àmúlọ mẹ́ta tó gbẹ̀yìn.
- Má ṣe lọ bá olóòtú ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn orí-ìtàkùn ayárabíàṣá jáde lẹ́yìn ìgbà tí o ti tẹ ìwé jáde kí o wá sọ pé “Èyí jẹ́ ohun tó lágbára, ṣé a lè rí ìfojúsọ sí i lórí èyí.” Bí èyí bá kjẹ́ ẹyọ iṣẹ́ kan tí o sì fẹ́ kàn sí ọ̀pọ̀ òǹkàwé bí ó ba ṣe éṣe sí, o ní láti bẹ̀rẹ̀ àsọgbà pẹ̀lú ẹgbẹ́ olùwòran tàbí àwùjọ kí wọ́n tó tẹ iṣẹ́ náà jáde, kí o sì má mù ú ìgbéga tàbí ìkànsíni bí ohun tí o ṣe lẹ́yìn ìrònú. Ẹgbẹ́ olùwòran tàbí ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ kò ní láǹfààní láti idán já wọ iṣe-kàwé lórí ẹ̀ṣin; wọ́n nílò àkókò láti ronú pẹ̀lú ète lórí láti ti ìgbéga àti ìpín káàkiri ìkànnì wọn.
- Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, má bèèrè lọ́wọ́ ẹgbẹ́ olùwòran tàbí ìbánidọ̀rẹ̀ẹ́ tí wọ́n bá le ṣe nǹkan láti jẹ́ kó lọ káàkiri. Gbogbo ìdí pé “lílọ káàkiri” kò ṣe é fojú di; kì í ṣe ohun tí o lè fipá mú. Dájúdájú, àwọn ìwà kan wà sí ìlọ káàkiri àkóónú tí ó jẹ́ kó ṣe é pín àti ìlọ̀wọ́sí. Ṣùgbọ́n má retí ìlọ káàkiri láti jẹ́ nǹkan tí o lè fojú yàwòrán rẹ síta.
- Ní ìkádìí, àwọn àkórí, àwọn àwòrán kékeré, àti ìpín àtẹ̀ránsẹ́ ọ̀rọ̀ átíkù. Tí o bá ń wo oríṣìíríṣìí àkóónú ọgọ́rùn-ún lórí “Twitter feed” rẹ, kí ló dá yàtọ̀? Kín ni Ìlọ́wọ́sí Àfojúrí? Àkórí wo ni kò bá a nítorí òdìwọ̀n ìwà? Ọ̀pọ̀ ohun ló wà tí wọ́n le sọ lórí èyí, ṣùgbọ́n, ní kúkúrú: Bá wo ni o ṣe má a rí i dájú pé iṣẹ́ rẹ dá àwọn ènìyàn dúró láti máa kọjá rẹ̀?
Àfikún Kíkà
Ó ju ẹyinjú lọ: Bí OIṣẹ́-ìròyìn ṣe le ráǹfààní láti Ìlọ́wọ́sí Olùwòran
Ẹjọ́ ìkówólé ní Ìlọ́wọ́sí Olùwòran: Ohun-èèlò GIJN tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé
Àwọn èèlò àti Ìtalólobó Jíjábọ̀: Ìfọ́nká àti Ìgbéga