ILÉ IṢẸ́ FRANK

Ilé Ẹ̀kọ́ Fáṣítì Illinois ń ṣe Ìgbanisíṣẹ́ sí Ipò Ọ̀gá Àgbà èyí tí yóò jẹ́ Alárinà Láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ fún Ìmọ̀ Ìròyìn àti Àwọn Akọ́ṣẹ́mọsẹ́ 

Láti ọwọ́ Jelter Meers | Ogúnjọ́, Oṣù Ọwẹ́wẹ̀, Ọdún 2021 

Kọ́lẹ́ẹ̀jì tó ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fún Ìmọ̀ Ìròyìn ní Fáṣítì Illinois, tó wà ní Urbana-Champaign, ti gbé orúkọ Ọ̀gá Àgbà àkọ́kọ́ fún ilé iṣẹ́ Frank jáde, èyí tí yóò máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fún ipò aṣíwájú lẹ́nu ẹ̀kọ́ṣẹ́ wọn, láti jẹ́ kí wọ́n ṣe àbápàdé àwọn akọ́ṣẹ́mọsẹ́ àti àwọn olùdanilẹ́kọ̀ọ́.