Ìjẹ́-aládàáni:  Ìkànnì tó rí owó àpawọlé fún àwọn Oǹkọ̀wé

Ìdàgbàsókè àwọn ìkànnì wà tí ó ran àwọn òǹkọ̀wé lọ́wọ́ láti pa owó nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àtẹ̀jáde-ara-ẹni. Bóya eléyìí tọ́ fún ọ yóò nílò ìwádìí. 

Ní abala yìí, a kò ṣe àwárí ibi tó pọ̀ tí ó ṣe ìrànwọ́ láti dá ìtàkùn ayélujára, lẹ́tà-ìròyìn àti búlọ̀ọ̀gì, tàbí wíwá inú àwọn ìgbéwọlé tí gba ìtajà àti ìkọsódò. Bẹ́ẹ̀ ni a kò wọ inú ìkànni ẹ̀rọ ayélujára bíi Telegram, Facebook, Reddit, àti WhatsApp.

Ìdàgbàsókè Ìlúmọ̀ọ́ká ṣíṣẹ̀dá Ìtẹ̀wésíta Ímeèlì tó dáńfó wọ́n ṣàpèjúwe nínú átíkù New York ti oṣù kẹsàn-án ọdún 2020, òmíràn ní Axios, àti ìkẹta ní Medium láti ọwọ́ alámọ̀ràn ilé-iṣẹ́ ìròyìn Mark Glaser.

Ní abala mìíràn ni a ti sọ̀rọ̀ ìtẹ̀jáde ìtàn kan náà sínú ọ̀pọ̀ ìwé-ìròyìnláti ara àwọn ilé-iṣẹ́ ìtàkùn ayélujára tó ṣe kókó bíi Apple News+ àti SmartNews, èyí tí kò sí fún àwọn aládàáni kọ̀ọ̀kan.

Fún Ìfọ́nká, Ìgbéga, àti Ìjẹ́-Aládàáni sí i, wọ Ìtọ́nisọ́nà GIJN wa.

Fífọ́n pódíkáàstì ká jẹ́ ọ̀rọ̀ mìíràn. Dídá àbá náà kún un ní gbígbé sórí ìkànnì, 22 Top Networks to Submit Your Podcast ní ọdún 2020, láti ọwọ́ àgbà ọ̀jẹ̀ ọjàtítà Robert Katai.

Àwọn wọ̀fún àtẹ̀jáde titun ń peléke sí i. Èyí jẹ́ agbègbè ìmúdàgbà, nítorí bẹ́ẹ̀, ó mú ọpọlọ dáni láti ṣe ìwádìí òkòdoro nípa ìpinnu rẹ. Ibi kan láti fi máa mu dáju ni ìtọ́nisọ́nà Blogging láti ọwọ́ Casey Botticello. 

Àwọn Ìkànnì láti yí àwọn Ìtàn rẹ padà

Medium

Ìkànnì yìí, bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2012, nísìnyìí wọ́n sọ pé ó ti ni olùbẹ̀wò mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́fà lóṣooṣù àti pé ó jẹ́ ibi tí “gbogbo ènìyàn ní ìtàn láti pín àti èyí tó dára jù ni wọn yóò fijíṣẹ́ sí ọ nígbà tó yẹ.” “Nípa ṣíṣẹ̀dá àkáùntì rẹ ọ̀fẹ́, o lè tẹ̀lé àwọn òǹkọ̀wé tó nífẹ̀ẹ́ sí àti olùtẹ̀wésíta, ìsọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtàn wọn, fààmì sí ìwé wọn sílẹ̀ fún ìgbàmìíràn, tẹ ìfìwéránṣẹ́ tìrẹ jáde, àti jù bẹ́ẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí abala Medium’s Getting Started. “Títẹ̀wésíta lórí Medium jẹ́ ọ̀fẹ́ àti àwọn ìtàn tí o tẹ̀ jáde le jẹ́ fífọ́nká sí àwọn tó ń tẹ̀lé ọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mílíọ̀nù oǹkàwé tí wọ́n tẹ̀lé àkọlé tó yẹ.”

Medium rí owó tó wọlé gbà láti ara ìkọsódò. Fún $5/osù tàbí $50/ọdún, o lè di ọmọ ẹgbẹ́ Medium láti rí ìráàyè aláìlópin sí gbogbo ìtàn lóri Medium àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn olùkọsódò Medium le tẹ̀lé àwọn òǹkọ̀wé àti “ìtẹ̀wésíta” tí wọ́n ṣe láti ọwọ́ olùṣẹ̀dá wọn. (àwo Smedian àti ipò tó ju 11,000 ìtẹ̀wéjáde.)  Sí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, Medium ṣe ìfìwéránṣe àti gbé wọn ga láti ara “Àkórí.” Àkòónú “Olùṣẹ̀dá” le gba ìsanwó fún iṣẹ́ wọn. Fún ìfáàrà Medium, bẹ̀rẹ̀ níbí. Wọ́n rí owó látara Medium Partner Program. Níbí ni Ìfìwèránsẹ́ búlọ̀ọ̀gì alálàyé ti Medium. Àti èyí: Pàdé  Medium “Àtẹ̀gùn,” ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu wò pẹ̀lú olóòtú Medium méjì.

“Nígbà ètò Alábàáṣepọ̀ jẹ́ ìmóríyá ńlá fún àwọn ènìyàn láti tẹ ìwé jáde lórí Medium, aládàáni kò gbọdọ̀ retí láti lówó,” Aládàáni Tallie Gabriel kọ ọ́ ní tòròtòrò ọdún 2018, ń ṣàlàyé bí “àtẹ́wọ́” ṣe di owó. Ó gbà wọ́n nímọ̀ràn:

“Láti darí Ìjẹ́-onínǹkan iṣẹ́ tirẹ̀, àwọn aládàáni gbọ́dọ̀ ro lílo Mwdium gẹ́gẹ́ bí ìkànnì àátẹ̀lé tí ó tọ́ àwọn oǹkàwé sọ́nà sí orí ìtàkùn ayélujára tara-ẹni. Tẹ ìfíwéránṣẹ́ sí orí búlọ̀ọ̀gì rẹ nígbà náà kí o wá tún gbé sorí ìtàkùn ayélujára sórí Medium láti rí àfikún olùwò, pẹ̀lú ìsopọ̀ tó ṣe é mú dání sí ìkànnì rẹ àti lẹ́tà-ìròyìn tí wọ́n so mọ́ ọ ní ìparí.”

Ní oṣù kìn-ín-ní ọdún 2020, Medium jábọ̀ pé 68% àwọn òǹkọ̀wé tàbí olùtẹ̀wésíta tí ó kọ ó kéré tán ìtàn kan fún ọmọ ẹgbẹ́ tó rí owó. Ó sọ pé 8% òǹkọ̀wé tó lápọn rí owó tó ju $100 gbà, àti pé $21,650.88 ni owó tó pọ̀ jù tí òǹkọ̀wé rí gbà, àti pé $8,855.73 ni owó tó jù tí ìtàn kan rí.

Fún ìmọ̀ràn síwájú si lórí ìtẹ̀wéjáde lórí Medium, wo:

Medium sí WordPress – Bí a ṣe le yan ìkànnì tó tọ́? Ìjíròrò ọ̀rínkínníwín àti ìfijọra láti ọ̀dọ̀ 2020 lórí búlọ̀ọ̀gì WinningWP.

Ìtẹ̀wèsíta mẹ́wàá Medium tó dára jù láti kọ fún ní ọdùn 2020, ní èyí tí akópa Medium déédé Tom Kueglar sọ̀rọ̀ lórí bí a ṣe le wọ “Ìtẹ̀wésíta” láàárín Medium.

Ṣé mo lè rí owó lórí Medium? Átíkù ọdún 2019 láti ọwọ́ Aládàáni J.J.Pryor tó ń dáhùn sí àrídájú.

Bí wọ́n ṣe ń rówó lórí Medium – Bí mo ṣe rí $1,000+  ìkọ lórí Medium, átíkù ọdún 2020 ẹ̀rọ ayélujára àgbáyé.

Bí o ṣe le rówó lórí Medium: ìtọ́nisọ́nà tó jinlẹ̀ fún alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, átíkù ọdún 2020 láti ọwọ́ Shane Dayton ní NichePursuits.

Ìṣàpéye Ìtalólobo Medium méje láti rí átíkù rẹ le dí ìlúmọ̀ọ́ká, átíkù ọdúnn 2018 láti ọwọ́ Larry Kim ní Búlọ̀ọ̀gì Wordstream, àti átíkù 2019 rẹ̀, 4 Super-Effective Content Syndication Strategies fún àwọn oníbúlọ̀ọ̀gì èyí tí ó pẹ̀lú ìdí mẹ́wàá láti lò Medium. 

Ohun tí o lè ṣe àti èyí tí o kò le ṣe lórí Medium.com láti ọwọ́ The Manifest.com ní ọdún 2018.

Èsì Ìdánrawò: Ìtẹ̀wéjáde lórí Medium vs Linkedln vs Bùlọ̀ọ̀gì ara-ẹni, átíkù ọdún 2018 láti ọwọ́ Rich Tucker.

Substack

Substack dààmú ìsọ-ayédẹ̀rọ̀ bíbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà-ìròyìn titun àti rírí owó. “Kò sí ìmọ̀ọ́ṣe ọgbọ́n-àmúṣe tí wọ́n bèrè; kàn sopọ̀ mọ́ àkáùntì ilé-ifowópamọ́ kí o sì ṣètò ìdíyelé,” orí-ìtàkùn ayélujára ló sọ èyí.

Substack mú 10% ìkọsódò tí wọ́n sanwó fún pẹ̀lú owó káàdì ìgbowó ti 2.9% pẹ̀lú sẹ́ǹtì ọgbọ̀n fún ìdúnàádúnràá kọ̀ọ̀kan. Àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n yàn láti má yí àkóónú wọn padà le lo substack lọ́fẹ̀ẹ́. Àwọn ìkànnì gbà pé mílíọ̀nù oǹkàwé alápọn káàkiri Substack àti àwọn Olukọsódi tó ń sanwó tó ju 250,000 lọ.

Láti oṣù keje ọdún 2020, Substack ti ń ṣagbátẹrù ètò ìrannilọ́wọ́ tó bófin mu nípa lílo àwọn agbẹjọ́rò ilé-iṣẹ́ ìròyìn láti pèsè ìmọ̀ràn ọ̀fẹ́ àti ìtọ́sọ́nà sí àwọn òǹkọ̀wé, gẹ́gẹ́ bí ìgbésí-ìtàkùn búlọ̀ọ̀gì Substack. Ó tún bẹ̀rẹ̀ ètò ìdàpọ̀. Substack tún fọwọ́kún ìkọsódì Pọ́díkààsìtì.

Ní oṣù karùn-ún yìí ọdún 2020, átíkù What’s Next for Journalists?,Olùdásílẹ̀ Substack Hamish McKenzie kọ̀wé lórí kìkọ oríire ìsúná ti Iṣẹ́-ìròyìn, ó sì sọ pé, “A ń gbìyànjú láti kọ́ ìdàkejì ètò ọrọ̀-ajé ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde tí ó fún àwọn oníròyìn ní ìjọba-ara-ẹni.

Patreon

Tẹ̀dó si San Francisco, Patreon bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2014 láti ṣẹ̀dá ìkànnì fún “Ìbánirajà ní àkókò ẹ̀rọ.” Patreon “olùṣẹ̀dá” lo ètò ìsanwó sítàì ìkọsódì. Àwọn ìwúrí bíi Àkóónú tó lé tàbí ìráàyè sí àrà ọ̀tọ̀ le fúnni.

Ní ìgbẹ̀yìn ọdún 2019, Àwọn olùdásílẹ̀ tó ju 100,000 ló lo Patreon, àwọn tó ju mílíọ̀nù mẹ́ta lọ ní ó ràn án lọ́wọ́. Ó ń retí láti sanwó $1 bílíọ̀nù fún àwọn olùṣẹ̀dá ní ọdún 2019. Kọ́ si lórí bí o ṣe ṣiṣẹ́ níbi àti níbí.

Fún àwọn Àtúnyẹ̀wò kan, èyí tó jẹ́ rere jù, yẹ àwọn ṣe olóòtú Oǹkọ̀wé wò, Merchant Maverick, àti VentureBeat. Àwọn òté-ìjẹyọpọ̀-àbùdá àkòónú kan wà, ṣùgbọ́n kò sí èyí tó pa iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí tó bá òfin mu lára. Iye tí wọ́n rí máa ń yàtọ̀ gidi. Graphtreon tọ ojú-ipa gbogbo olùrówó Patreon.

TinyLetter

TinyLetter jẹ́ “iṣẹ́ lẹ́tà-ìròyìn ara-ẹni tí wọ́n mú wá fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lẹ́yìn Mailchimp.” Ó jẹ́ ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n lódìwọ̀n sí àwọn olùkọsódì ẹgbẹ̀rún márùn-ún.

Ko-fi 

Ko-fi ran àwọn olùṣẹ̀dá oríṣìíríṣìí ìtọrẹ tí wọ́n gbà lọ́wọ́, fi ọgbọ́n sítàì rẹ̀ bi  “buy me a cup of coffee.” Ko-fi kì í bèrè iye kan. Owó sísan lọ sí inú Paypal tàbi àkáùntì Stripe rẹ. Fún $6 lóṣù, ipele “Gold” fi àwọn àbùdá mìíràn, bíi wọ̀fún ìkọsódì.

Kindle Direct Publishing

Kindle Direct Publishing ṣe ìsọdẹ̀rọ̀ ìyára, ìtẹ̀wésíta ọ̀fẹ́ fún ìwé-orí ìtàkùn ayélujára méjèèjì àti ẹ̀yìn-pépà. Ó gba àwọn òǹkọ̀wé láàyè láti mú ẹ̀tọ́ wọn dúró àti rí ipò àṣẹ gbà. Ìtẹ̀jáde jẹ́ láti ara Amazon. Wo ojú-ewé Getting Started. Ó wà, síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ láti rò. Àtúnyẹ̀wò ọdún 2019 láti ọwọ́ Doris Booth ni Oǹkọ̀wé àti Oǹkàwé ọ̀pọ̀ ìfàmìsí, pẹ̀lú òdìwọ̀n lórí wọ̀fún ààtò àti àwọn kókó tó dára ti wọ̀fún ipò àṣẹ. Wo átíkù ọdún 2020 yìí náà pẹ̀lú ní Ìmọ̀ràn Ìtẹ̀wésíta lórí Ètò Yíyàn KDP, nínú èyí tí o ní ẹ̀tọ́ tó peléke sí Amazon. Ọ̀pọ̀ ìdásí mìíràn àti ọ̀rínkínníwín àlàyé lórí bí o ṣe lè níta, pẹ̀lú.

Àwọn Èrò mìíràn

Gbígbe sí ibòmìíràn le fẹ ìdọ́dọ̀ rẹ lójú àti kí o mú àwọn òǹkàwé titun. Àwọn ìkànnì bíi Authory, BuzzFeed Community, Linkedin, àti Muckrack wà tí ó le ṣe ìrànwọ́ láti fọ́n iṣẹ́ rẹ ká.

Ṣùgbọ́n èyí kò pé, àti pé àwọn ewu ìtajà kan le wà, pẹ̀lú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ tí ó dínkùn sí ìkànnì ìtẹ̀wésíta ti ara-ẹni. Àwọn ìwádìí Google le mú àwọn oǹkàwé sí orí ìkànnì ìgbé-ìtàn síta sórí ọ̀pọ̀ ìwé-ìròyìn ju tìrẹ lọ. Sí bẹ́ẹ̀, Àwọn àgbà-ọ̀jẹ̀ gba ni nímọ̀ràn pé ipa yìí le dínkù.

Fún Ìjíròrò àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ka Do’s &Dont’s of Re-publishing Content on Medium or Linkedin, átíkù Carolyn Edgecomb ti Ipa. Edgecomb pẹ̀lú àwọn àbá, bíi bí a ṣe lè pẹ̀lú apá kan kóòdù láti sọ fún Google láti fi gbogbo ògo fún ọ àti má ṣe ṣe àfikún átíkù lórí ìtàkùn ayélkujára ti ìta.

Wò ó pẹ̀lú:

  • Medium Article Canonical Links láti ọwọ́ Cassey Botticello
  • What Is Content Syndication & How Does It Impact SEO? Láti ọwọ́ Maddy Osman ní Pathfinder SEO

Káàkiri Àgbáyé

Ọ̀pọ̀ ìkànnì káàkiri àgbáyé ló wà tí ó le ṣàgbékalẹ̀ àwọn àǹfààní. Ran GIJN lọ́wọ́ láti to àwọn àtẹ ti ohun èlò ìtẹ̀wéjáde-ara-ẹni mìíràn nípa fífi àwọn ìtalólobo ránṣẹ́ sí wa níbí.