gijn-logo

Ìdàpọ̀ Alápapọ̀

Owó-ìrànwọ́ àti Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ fún àwọn oníròyìn

Owó-ìrànwọ́ tó níṣe pẹ̀lú COVID-19

 • Àwọn Ìdàpọ̀ Lápapọ̀
 • Àwọn Ìdápọ̀ Kárí-ayé gbogbo
 • Àwọn Ìdàpọ̀ àrà ọ̀tọ̀
 • Jíjábọ̀ Owó-ìrànwọ́
 • Àkọsílẹ̀ Owó-ìrànwọ́
 • Àwọn Ówó-ìrànwọ́ yòókù

Ò ń wá ààyè láti ṣe àtúnṣe sí ìmọ̀ọ́ṣe rẹ àti láti fẹ ayé rẹ lójú? Iṣẹ́ ojoojúmọ́ ti sú ọ nínú yaàrá-ìròyìn rẹ? A máa ń ṣe ìmúdójú-ìwòn ìtọ́nisọ́nà wa lóòrèkóòrè sí owó-ìrànwọ́ àti àwọn ìdàpọ̀. Àwọn èyí ni ètò sí ìnífẹ̀sí tó ṣe pàtàkì sí àwọn oníròyìn aṣèwádìí káàkiri àgbáyé. Ọ̀pọ̀ àǹfàání ìgbà-kúkurú àti ìgbà-gígùn ló wà, fún àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn aládàáni oníròyìn. Tẹ̀lé líǹkì yìí fún àlàyé lórí ọjọ́-ìparí àti àgbétẹ́lẹ̀ oríṣìíríṣìí ètò. 

O tún le rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìwúlò 

Ojú-ewé ohun èlò GIJN

 • Àmì-ẹ̀yẹ
 • Déétà
 • Ìrànwọ́ Pàjáwìrì
 • Ìgbédìde-owó
 • Àwọn Ìtọ́nisọ́nà Aṣèwádìí
 • Ààbò Amòfin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ǹjẹ́ o mọ ti àǹfàání ńlàlà tí a kò tí ì ṣe àkójọ rẹ̀? Kọ sí wa ní GIJN. Fún àkójọ ní Spanish, wo ojú-ewé wa Becas y Subvenciones.

Àkójọ GIJN dojúkọ àwọn àǹfààní tí ó wà nílẹ̀ sí gbogbo àwọn oníròyìn jákè-jádò àgbáyé. Fún Àkójọ mìíràn, wo abala àǹfàání ti àwọn ọọ̀rẹ́ wa ní IJNet (àti pé wá “àwọn ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́”). Rory Peck Trust ṣètọ́jú àkójọ apákan-tópọ̀ pẹ̀lú abala àwọn ìgbèríko. Èyí tó ju ọgọ́rùn-ún orísun owó-ìrànwọ́ US ní wọ́n kójọ lórí lẹ́jà tí wọ́n dá sílẹ̀ láti ọwọ́ The News & Obserẹer (Raleigh, N.C.).

Pẹ̀lú, wo átíkù àmọ̀ràn GIJN lórí bí a ṣe ń b`wẹ̀ fún owó-ìrànwọ́. 

ÌDÀPỌ̀ ALÁPAPỌ̀

Ìdàpọ̀ Nieman ní Ilé-ìwé gíga Havard fún àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ ní Harvard fún ọdún ajẹmákadá; knight ṣe àbẹ̀wò sí Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ Nieman, èyí tí ó pẹ́ fún nǹkan bí ọ̀sẹ́ méjìlá tàbí kò má tò ó bẹ̀, ó tún wà ní iṣẹ́-àkànṣe tí yóò ṣe ìlọsíwájú iṣẹ́-ìròyìn ní àwọn ọ̀nà titun kan.

Ta ni: Ìdàpọ̀ Nieman bèèrè fún ó kéré tán ìrírí ọdún máàrún. Kò sí ìrírí tó kéré sí ìyẹn fún bíbẹ ìdàpọ̀ wò; ṣíṣe àbẹ̀wò sí àwọn ẹlẹgbẹ́ le jẹ́ àwọn oníròyìn tàbí àwọn alámọ̀dájú mìíràn ní ipò láti ran iṣẹ́-ìròyìn lọ́wọ́, bí i àwọn atẹ̀wésíta, àwọn elétò, tàbí àwọn oníṣe. Ní àfikún, Ìdàpọ̀ Nieman-Berkman  ní àrà-titun iṣẹ́-ìròyìn mú ẹnìkọ̀ọ̀kan wá sí ilé-ìwé gíga Harvard láti ṣiṣẹ́ lórí ìwádìí kọ́ọ̀sì kan ní pàtó tàbí iṣẹ́-àkànṣe kan ní pàtó tó níṣe pẹ̀lú àrà titun iṣẹ́-ìròyìn.

Iye:  US$65,000 owó-ìrànlọ́wọ́, pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da fún ìgbélé, ìtọ́jú-ọmọ, àti ìṣedúró ìlera tó dúrólórí iye ẹbí àti ọjọ́-orí wọn. Fún àbẹ̀wò ẹlẹgbẹ́, owó-ìrànlọ́wọ́ ti wọ́n pín fún gígùn ìdàpọ̀ (nǹkan bí US$1,600 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀) àti ìgbélé ọ̀fẹ́.

John S.Knight Journalism Fellowship ní Stanford fàyè gba àwọn oníròyìn láàyè láti ṣiṣẹ́ lórí iṣẹ́-àkànṣe alárà-titun lọ́dún ajẹmákadá.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn pẹ̀lú ó kéré tán ìrírí ọdún máàrún.

Iye: US$85,000 owó-ìrànlọ́wọ́, àwọn ìwé, owó ilé-ìwé, ìgbélé, ìtọ́jú ìlera, owọ́ ìrìnàjò àti ìtọ́jú-ọmọ. 

Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ Iṣẹ́-ìròyìn Germany lórí Ìgbìmọ̀ Àwọn Ará America pèsè àwọn àǹfààní fún pàṣípàrọ̀ iṣẹ́-ìròyìn ìyísíra-àṣà. Ohun tó ń lọ lọ́wọ́ ní Àgbáyé lórí Ìdàpọ̀ McCloy gba àwọn àgbà-ọ̀jẹ̀ ará America àti German láàyè láti iṣẹ́-ìròyìn, ẹ̀ka àwùjọ, táǹkí ìronú, aláìlérè, òfin, àti àjọ àṣà láti ṣe ìwádìí àti ìráàyè sí ọ̀pọ̀ àwọn àkọ́lé tó lọ lọ́wọ́ lórí ètò-àwòse ìṣípò Atlantic nígbà tí ó bá ń lọ́wọ́sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn lókè-òkun. Ìdàpọ̀ Anna-Maria àti Stephen M. Kellen pèsè àǹfààní fún àtẹ̀jáde ìtẹ̀dó-Berlin tó yàtọ̀, ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, àti àwọn oníròyìn ẹ̀rọ ilé-iṣẹ́ ìròyìn láti rin ìrìnàjò sí United States láti sàkóso àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú olùṣe-ìlànà àti Adarí èrò àti láti sàkóso ìwádìí fún àwọn ìjábọ̀ ìròyìn.

Ta ni: Àwọn Oníroyìn German tàbí America.

Iye: Máa ń yàtọ̀

Ìdàpọ̀ Hubert H.Humphrey jẹ́ ètò ọlọ́dún kan láti ọ̀dọ̀ ilé-ìwé gíga ti Maryland àti Ẹ̀ka Ìpínlẹ̀ U.S.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn tí kì í ṣe ti U.S. 

Iye: Owó ilé-ìwé, owó ìrìnàjò, ìwé àti ìyọ̀ọ̀da kọ̀ḿpútà àti yàrá àti bọ́ọ̀dù.

Ètò Fulbright fi àǹfààní ìwádìí àti ìkọ́ni fún àwọn tó ń bẹ ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ U.S. wò àti èyí tí kì í ṣe U.S. àti àwọn Alámọ̀dájú.

Ta ni: Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ àti àwọn alámọ̀dájú tó ní ìrírí ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà tó fẹjú ní ti ajẹmákadá àti alámọ̀dájú. Àwọn Oníròyìn láti àwọn orílẹ̀-èdè kan le tọ́ fún ìwádìí Fulbright ní U.S. Ìkọ́ni Fulbrights tún wà fún àwọn tó ti sìn lórí ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé-ìwé gíga tí kì í ṣe ti U.S.

Iye: Máa ń yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí gígùn owó-ìràwọ́ àti ibi.

Ìdàpọ̀ Knight-Wallace fi ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún kan tó jẹ́ ti ajẹmákadá sílẹ̀ ní ilé-ìwé gíga ti Michigan.

Ta ni: Ọmọ America méjìlá àti oníròyìn mẹ́fà ti jákè-jádò àgbáyé tó ní ìrírí ó kéré tán ọdún márùn-ún.

Iye: US$75,000 owó-ìrànlọ́wọ́, pẹ̀lú owó ilé-ìwé àti owó kọ́ọ̀sì, owó ìrìnàjò fún ìròyìn jákè-jàdò àgbáyé àti ìṣedúró ètò-ìléra

Ètò Ìdàpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ Reuters fún àwọn oníròyìn ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ kí ó sì hànde ní ilé-ìwé gíga ti Oxford ní UK.

Ta ni: Oní-ìrírí, iṣẹ́-àárín láti orílẹ̀-èdè kórílẹ̀. Àwọn ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ ní orílẹ̀-èdè ppàtó náà wà fún Australia, Austria, Ààrín gbùgbù ilà-oòrùn, Norway, South Korea, àti ibòmíràn.

Iye: Àmì-ẹ̀yẹ le pẹ̀lú ìnàwó ìrìnàjò (pẹ̀lúpẹ̀lú kílàsì ọrọ̀-ajé ìrìnàjò afẹ́fẹ́) àti ìyọ̀ọ̀da ìgbé-ayé níwọ̀nba.

Ìdàpọ̀ ní Iṣẹ́-ìròyìn ní Àgbáyé wà nípa University of Toronto’s Munk School of Global Affairs.

Ta ni: Ogún “Àwọn Alámọ̀dájú tó dá dúró, àwọn Onímọ̀, àti Àwọn Aládàáni Ọ̀tọ̀ ní gbogbo àgbáyé.”

Iye: C$10,000 (tó tó ìdajì owó ilé-ìwé). Àwọn ẹlẹgbẹ́ náà le gba ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ lẹ́yìn ètò láti ara àwọn ìpàdé orí-ìtàkùn ọ́fíìsì lóṣooṣù.

Àmì-ẹ̀yẹ Jíjábọ̀ Ìròyìn ṣe é ní ọdọọdún láti ọwọ́ ilé-ẹ̀kọ́ iṣẹ́-ìròyìn Arthur L.Carter ti ilé-ìwé gíga New York láti ran iṣẹ́ ìròyìn tó lápẹrẹ lọ́wọ́ ní ọ̀nàkọnà lóri àkọ́lé tí wọn kò tí ì jábọ̀ rẹ̀ sí gbangba.

Ta ni:  Àwọn oníròyìn tí wọ́n ní ara tó ń ṣiṣẹ́ àti iṣẹ́-àkànṣe tí wọn kò tí ì jábọ̀ rẹ sí ìfẹ́ gbangba ní ìtẹ̀síwájú. Kò ní ẹ̀tọ́ láti fi orúkọ sílẹ̀: Àwọn oníròyìn pẹ̀lú àwọn ipò òṣìṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ìròyìn tí wọ́n dá sílẹ̀ ní àǹfààní láti fi owó sílẹ̀ fún iṣẹ́-àkànṣe láàyè ara wọn. Ó ṣí sílẹ̀ sí oníròyìn láti orílẹ̀-èdè kó rílẹ̀.

Iye: Àmì-ẹ̀yẹ tó pọ̀ jù ni US$2,500 lórí ìfilọ̀ jíjẹ́ olúborí ìgbèrò tí ó tún tó àfikún US$10,000 lórí ìparí iṣẹ́-àkànṣe náà.

Ètò Ìjábọ̀ Aṣèwádìí UC Berkeley ní ti kàwé-gboyè ilé-ìwé iṣẹ́-ìròyìn fúnni ní ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ ọlọ́dún kan ní ìjábọ̀ aṣèwádìí.

Ta ni: Àwọn Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ náà ṣí sílẹ̀ sí gbogbo àwọn oníròyìn aṣèwádìí. Olùkẹ́ẹ̀kọ́-gboyè oyè ìjìnlẹ̀ láti UC Berkeley ní Iṣẹ́-ìròyìn ni wọ́n gbà níyànjú láti gbà á.

Iye: Àwọn Ẹlẹgbẹ́ yóò gba owó-oṣù lọ́dọọdún ti US$54,336 àti pé wọn yóò ní ẹ̀tọ́ láti ní àǹfàání kíkún UC. Wọn yóò pèsè ààyè ọ́físì fún àwọn ẹlẹgbẹ́, ìnáwó ìpìnlẹ̀ àti èyí tó tó US$10,000 ní ìfowósílẹ̀ tí wọ́n ti gbé òǹtẹ̀ lù.

Àwọn Ẹlẹgbẹ́ Ayé Yale jẹ́ ẹ̀tò fún àwọn alámọ̀dájú iṣẹ́-àárín láti lo oṣù mẹ́rin ní ilé-ìwé US Ivy League “láti ṣàwárí àwọn ìṣòrò àgbàyé tó lágbára àti ẹ̀kọ́ ìwọ́gilé-ìbáwí, pọ́n ìmọ̀ọ́ṣe adarí mú kí ó sì kọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn yòókù tí ó ń yọjú láti di adarí.

Ta ni: mẹ́rin-dín-lógún “àwọn ìràwọ̀ tó ń dide” ní ìmọ̀ ọọgbọ́n ìmọ̀ọ́ṣe, iṣẹ́ ọnà, Ìsúná, Òṣèlú, ìṣòwò àwùjọ, iṣẹ́-ìròyìn, Àgbàwí àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣí sílẹ̀ sí àwọn tí kì í ṣe ọmọ bíbí U.S.

Iye: Ètò náà pèsè àwọn ẹlẹgbẹ́ pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da ìrìnàjò, ìgbélé, ìtọ́jú-ìlera, àti owó ìrànlọ́wọ́ láti bo ìnáwó ìgbélé. Yale tún san gbogbo owó tó níṣe pẹ̀lú abala ètò ẹ̀kọ́ àti àwọn àfikún ìwé-ẹkọ́.

Banff Investigative Journalism Intensive jẹ́ ètò ọ̀sẹ̀ méjì ní Banff (Canada) Ìkànnì fún Iṣẹ́-ọnà àti Àtinúdá.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn àti Àwọn Òǹkọ̀wé tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí iṣẹ́-àkànṣe aṣèwádìí tàbí tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ìdàgbàsókè ìmọ̀ọ́ṣe aṣèwádìí wọn ni wọ́n pé láti fisi i.

Iye: Ìgbélé, oúnjẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìrànlọ́wọ́ Tìnáwó tó ṣe éṣe.

ÀWỌN ÌDÀPỌ̀ JÁKÈ-JÁDÒ ÀGBÁYÉ 

Àwọn Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ Iṣẹ́-ìròyìn ara Europe wà fún àwọn Oníròyìn láti Ilà-oòrùn s`ti Iwọ̀-oòrùn Europe àti United States tí ó fẹ́ lo sáà méjì nínú lílọ́wọ́ sí ìwádìí ní Berlin. Wọ́n yẹ̀ wọ́n wò ní International Center for Journalism of the Freie Universitaet Berlin.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn láti Ilà-oòrùn àti Iwọ̀-oòrùn Europe, United States.

Iye: Owó ilé-ìwé, pẹ̀lú owó ìrànlọ́wọ́ olóṣoòṣù fún ìnáwó ìgbélé tí o dúró lé ipele ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́.

Ètò Iṣẹ́-ìròyìn Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ará Europe ni àwọn ẹgbẹ́ gbàgede GIJN àti Àjọ Toepfer àti èròńgbà láti pèsè mọ-bí iṣẹ́-ìròyìn ìfagilé-ààlà ìfọwọ́sowọ́pọ̀, fún ilé nẹ́tìwọ̀kì ní okun àti pàṣípàrọ̀ láàárín àwọn Olùkópa, sọ ìtàn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti Ìṣàwárí, àti láti tan òjìjí ìfikọ́ra iṣẹ́. ECJP bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ láti gbogbo Europe ní gbogbo ile-iṣẹ́ Ìròyìn, Àwọn Aládàáni, àti àwọn Òṣìṣẹ́ tó jọra. Àwọn ẹgbẹ́ pàdé lẹ́ẹ̀mejì, ní ìkànnì sẹminá ní Òkun Baltic ni Germany àti nígbà Ìpàgọ́ ìkájọ-déétà ní Belgium. Gbogbo ìnáwó ni àjọ náà gbé. Ọjọ́-ìpari ti ọdún yìí ni ọjọ́ kejì-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 2021.

Ìdàpọ̀ láti bọ́sípò kíákíá pèsè ìdàpọ̀–ọrẹ́ lọ́dọọdún.

Ta ni: Ẹlẹgbẹ́ mẹ́wàá láti oríṣìíríṣìí ìṣe, pẹ̀lú iṣẹ́-ìròyìn. Òsùwọ̀n ìmúni pẹ̀lú kókó mẹ́fà, pẹ̀lú wíwá láti orílẹ̀-èdè tí kò ṣe dédé tí fi ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ́n ṣètò kàn, tí ó sì le sọ ó kéré tán ẹyọ̀kan nínú èdè mẹ́ta yìí: Spanish, English, àti French.

Iye: Owó-ìrànwọ́ ti US$15,000 fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ni wọ́n yóò fi ṣe àmì-ẹ̀yẹ fún ọdún kan. Àwọn Ẹlẹgbẹ́ yóò jọ wà fún ọjọ́ mẹ́wàá fún ìpàdé.

Knight International Journalism Fellowship wà fún olùkẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́-ìròyìn láti lo ohun èlò ẹ̀rọ “láti gbin àrà titun àṣà ìròyìn àti ìsèdánwò káàkiri-àgbáye.” Wọ́n bẹ̀ wọ́n wò láti ara Ìkànnì Àwọn Oníròyìn Jákè-jádò àgbáyé.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn pẹ̀lú ó kéré tán ìrírí ọdún mẹ́wàá.

Iye: Ìnàwó ìgbélé, owó ìrìnàjò, ìsedúró ìléra, ìsinmí tí wọ́n sanwó fún àti ìbuyì fún sí i.

Ilé-ẹ̀kọ́ Íròyìn Ìdàpọ̀ Lágbàáyé àwọn Oníròyìn láti gbogbo ayé ní àǹfààní láti rin ìrìnàjò fún oṣù mẹ́ta àti láti kẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́-ìròyìn ní United States.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn tí kì í ṣe ti U.S. tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn United States pẹ̀lú ó kéré tán ìgbánisíṣẹ́ ọdún márùn-ún kíkún ní àtẹ̀jáde, ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, tàbí iṣẹ́-ìròyìn ní orí-ìtàkùn ayélujára.

Iye: Owó ìrìnàjò, oúnjẹ àti ibùgbé fún ìgbà díẹ̀.

Ìdàpọ̀ Persephone Miel ni Ìkànnì Pultizer lórí Jíjábọ̀ Wàhálà fúnni tí ó sì pèsè àǹfààní fún àwọn oníròyìn láti ṣiṣẹ́ ní ní ìṣọdá-ààlà.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn tí kì í ṣe ti United States.

Iye: Ó tó US$5,000 fún owó ìjábọ̀ ìròyìn.

Ìdàpọ̀ Abe fún Àwọn Oníròyìn ran àwọn oníròyìn lọ́wọ́ lórí iṣẹ́-àkànṣe nípa ààbò, ìtajà àti ọ̀rọ̀ nípa àwùjọ tí ó níṣe pẹ̀lú Japan àti United States.

Ta ni: Ará a Japan tàbí Oníròyìn U.S. pẹ̀lú ó kéré tán ìrírí ọdún márùn-ún.

Iye: Ìrànlọ́wọ́ owó jẹ́ $23,500, èyí tí ó pẹ̀lú ìwé-ìwọlé ìrìnajò afẹ́fẹ́ lẹ́ẹ̀kan.

Ìdàpọ̀ Àwùjọ tó ṣí sílẹ̀ wá “èrò òǹtajà” káàkiri gbogbo àgbáyé. Kókó íṣẹ́-àkànṣe gbọ́dọ̀ gba ó kéré tán ibi ìnífẹ̀ẹ́sí méjì sí àwọn Àjọ Àwùjọ tó ṣí sílẹ̀: ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, Àkóyawọ́ ìjọba, ìráàyè sí àlàyé àti sí ìdàjọ́, àti ìgbéga àwùjọ tó mọ́gbọ́n dání àti àfikún àwùjọ.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn, Àwọn Ajìjàgbara, Ajẹmákadá, àti Àwọn Oníwòsàn ní oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́.

Iye: Owó ìrànlọ́wọ́ tó jẹ́ US$80,000 tàbí US$100,000, tó dálé ìrírí iṣẹ́, ìjọ́gàá, àti iye tó ń wọlé lọ́wọ́lọ́wọ́, pẹ̀lú ìsúná ìrìnàjò.

Àwọn ètò Ìdàpọ̀ Netherlands ní wọ́n fúnni ní oríṣìíríṣìí orí ọ̀rọ̀ láti Ìkànnì Ìkọ́ni Rédìò Ntherland (RNTC), Ilé-ẹ̀kọ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Netherlands. Àwọn kọ́ọ̀sì ni Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí, Iṣẹ́-ìròyìn Asọ̀tàn, àti Lílo ilé-iṣẹ́ ìròyìn fún Ìdàgbàsókè.

Ta ni: “Oníròyìn tó kéré àti pẹ̀lú iṣẹ́-àárín, olùṣètò, àtẹ̀jáde àti àwọn alámọ̀dájú ilé-iṣẹ́ ìròyìn orí-ìtàkùn ayélujára bẹ́ẹ̀ náà ni Olùkọ́ní Ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti Alákòóso àgbà.”

Iye: Máa ń yàtọ̀.

Owó-ìrànwọ́ àti Ìdàpọ̀ àwọn ará Europe fún àwọn orílẹ̀-èdè kan pàtó àti ìgbèríko ní Journalismfund.eu tò jọ. Wo ìtónisọ́nà sí Àǹfààní Ìfowósílẹ̀ fún Àwọn Oníròyìn Àṣà ní Europe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ó dojúkọ àwọn oníròyìn to ń kó ìròyìn jọ lórí iṣẹ́ ọnà àti àṣà, àwọn ìtalólobó tó wúlò wà lórí orísun ìfowósílẹ̀.

Ìdàpọ̀ Asia-Pacific ni ìkànnì ilà-oòrùn-iwọ̀-oòrùn fún àwọn oníròyìn láti Asia àti orílẹ̀-èdè Pacific Rim fúnni. Pẹ̀lú ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ Jefferson, ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ ìlera àti ètò pàṣípàrọ̀ fún àwọn ará China, ará Japan, ará Korea, Pakistani, àti àwọn oníròyìn U.S.

Ìdàpọ̀ Dáńfó Reagan-Fascell ni àwọn ìpéjọ U.S. gbówó sílẹ̀ fún láti ran àwọn ajìjàgbara tó dáńfó lọ́wọ́, àwọn onímọ̀, àti àwọn oníròyìn láti gbogbo àgbáyé kí wọ́n le gba ìwádìí òmìnira lórí àwọn ìpèníjà ìjọba tí ara ẹni. Àwọn ẹlẹgbẹ́ lo oṣù márùn-ún ni ibi tí wọ́n ńgbé ní National Endowment for Democarcy ní ìsàlẹ̀ Washington, D.C.

Ta ni: “Ajìjàgbara Ìjọba ara ẹni, Adarí ọmọ-ìlú láwùjọ, olùgbèjà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwọn oníròyìn àti mìíràn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí ìṣàájú ìjọba ara ẹni.”

Iye: Owó-ìrànlọ́wọ́ lóṣooṣù, ìsedúró ìlera, ààyè  ọ́fìsì, ìràwọ́ ìwádìí, àti ìrìnàjò ẹ̀ẹ̀kan sí Washington, D.C. Ìrànwọ́ Ìnáwó kò sí fún àwọn ẹbí tàbí àwọn olùgbáralé yòókù.

Ìdàpọ̀ Ìròyìn Ọlọ́rẹ̀ẹ́ Alfred jẹ́ ètò ọgbọ̀n ọdún tí ó ń gbé àwọn oníròyì tó lẹ́bùn jákè-jádò àgbáyé sí yàrá-ìròyìn U.S.

Ta ni: ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn oníròyìn láti àwọn orílẹ̀-èdè tó ń dàgbà sokè àti àwọn ọjà pàjáwìrì.

Iye: Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ gbé gbogbo ìnáwó tó níṣe pẹ̀lú ètò náà ní jákè-jádò àgbáyé àti ìrìnàjò abẹ́lé U.S., ìsedúró ìlera àti pé ó pèsè owó ìrànlọ́wọ́ oṣoòṣù láti gbé gbogbo ìnáwó ìpìlẹ̀ ilé gbígbé.

Ìdàpọ̀ Ìjábọ̀ Aṣèwádìí TRACE. Àjọ TRACE ni wọ́n dá sílẹ̀ láti gbé ìwádìí ga, ran ìwádìí lọ́wọ́ àti láti fi owó sílẹ̀ fún Iwàdìí, Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí, Ìtẹ̀wéjáde, àwọn Fídíò àti àwọn iṣẹ́-àkànṣe tó níṣe tí ó sì ń gba àkóyawọ́ ìsòwò tó lágbára níyànjú àti láti mú ìlọsíwájú bá ẹ̀kọ́ ìtako rìbá. Ètò Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ olóṣù mẹ́fà níṣe pẹ̀lú Alfred Friendly Press Partners Fellowship (wò ó lókè), ṣùgbọ́n àwọn oníròyìn méjì tí wọ́n mú má a gba àfikún ẹ̀kọ́ lórí íṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn láti ibikíbi.

Iye: Ìnáwó ilé gbígbé fún ètò olóṣù mẹ́fà.

Ìdàpọ̀ Daniel Pearl ètò ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ olóṣù mẹ́fà níṣe pẹ̀lú Alfred Friendly Press Partners Fellowship (wò ó lókè). Ní àfikún, Àwọn ẹlẹgbẹ́ Daniel Pearl lo ọ̀sẹ̀ kan ní Jewish Journal of Greater Los Angeles, níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ ara Jew.

Ta ni: Oníròyìn tó ní ìrírí ọdún mẹ́ta tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Mùsùlìmí- ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè (wo àwọn òsùwọ̀n síwájú si lórí ojú-ewé ìbẹ̀wẹ̀).

Iye: Ìnáwó ilé gbígbé fún ètò olóṣù mẹ́fà.

Ìdàpọ̀ Arthur F. Burns fi àwọn àǹfààní fún àwọn ọmọ America, Canada, àti German láti jábọ̀ àti láti rìn ìrìnàjò ní orílẹ̀-èdè mìíràn kọ̀ọ̀kan. Ìkànnì jákè-jádò Àgbáyé fún àwọn Oníròyìn ni ó ṣàkóso ètò yìí tí wọ́n sì tún ṣe agbátẹrù pàṣípàrọ̀ iṣẹ́-ìròyìn U.S.-Austrian.

Ìdàpọ̀ Alámì-ẹ̀yẹ ti Òmìnira láti sọ̀rọ̀ sí ni Index lórí ìpalẹ́numọ́ ṣe agbátẹrù rẹ, Àjọ Aláìjèrè tó polongo fún àti tó gbèjà fún isọ̀rọ̀-sí ọ̀fẹ́ lágbàáyé.

Ta ni: Ṣí sílẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àjọ tó níṣe pẹ̀lú kíkojú ìhalẹ̀mọ́ni isọ̀rọ̀-sí ọ̀fẹ́, pẹ̀lú àwọn oníròyìn.

Iye: Àwọn Ẹlẹgbẹ́ gba ìrànlọ́wọ́ oṣù méjìlá tààrà, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀sẹ́ ìkọ́ni gbogbo ìnáwó ti di sísan ní London ní oṣù kẹrin ọdún 2018.

Ìdàpọ̀ yàrá-ìjìnlẹ̀ Ìròyìn Google fún àwọn akẹ̀kọ̀ọ́ tí ó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́-ìròyìn àti Ìmọ̀ Ọgbọ́n Àmọ̀ọse ní àǹfààní láti lò nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ nígbà ooru ní àwọn àjọ tó yẹ káàkiri àgbáyé.

Ta ni: Ó wà ní U.S., U.K., South Korea, Germany, Australia, Denmark, Finland, Sweden, Norway àti Ireland.

Iye: Àwọn ẹlẹ́gbẹ́ gba owó ìrànlọ́wọ́ àti ìsúná ìrìnàjò nígbà ètò ọlọ́sẹ̀ mẹ́wàá, tí ó wà láti oṣù kẹfà – oṣù kẹjọ. Ọjọ́ ìparí àti àwọn ìbéèrè tó yẹ máa ń yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn.

Water Integrity Network Water Integrity Journalism Fund “ní èròǹgbà láti fi okun kún ìwádìí, ìjábọ̀, àti ìtànkálẹ̀ àwọn ìjábọ̀ ìwádìí ní gbùngbùn jẹgúdújẹrá ní ẹ̀ka omi.”

Ta ni: owó náà wà fún ìwádìí àti àwọn oníròyìn déétà jákè-jádò àgbáyé, ṣùgbọ́n àwọn ààyò ni wọn yóò fún àwọn tó ń jábọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ń dàgbàsókè. Àwọn Aládàáni tàbi àwọn oníròyìn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n gbà tó jẹ́ òṣìṣẹ́ títí láí, tàbí ẹgbẹ́ kékeré oníròyìn le gbà á. Àwọn Olùbẹ̀wẹ̀ gbọ́dọ̀ gbẹ̀tọ́ àti àwọn oníròyìn tí wọ́ tẹ̀ jáde pẹ̀lú ó kéré tán ìrírí ọdún márùn-ún àti àwò ìṣáájú ti àtẹ̀jáde.

Iye: Iye ìfowósílẹ̀ máa bẹ̀rẹ̀ láti E2,000 sí E12,000, wọ́n sì tún le lò ó láti fi gbé ìnàwó ìrìnàjò àti ìmọ ẹ̀rọ, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún láti ra àwọn ohun èlò.

Ètò iṣẹ́-òótọ́ Logan wá láti kó oríṣìíríṣìí àti pẹ̀lú agbègbè àwọn ẹlẹgbẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ lórí òṣèlú àwùjọ tó jọjú, ìléra, àyíká, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àkórí ìdájọ́.

Ta ni: Olùṣe-fíìmù Adálérí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi àti àwọn oníròyìn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ lórí iṣẹ́-àkànṣe fọ́ọ̀mù-gígùn.

Iye: Àwọn ẹlẹ́gbẹ́ gba ìbúgbé, oúnjẹ, ìtọ́nisọ́nà alámọ̀dájú, àti àgbègbè fún ọ̀sẹ̀ márùn-ún sí ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá lórí Carey Institute for Global Good’s historic Campus ní upstate New York. Ìbẹ̀wẹ̀ fún kílààsì Fall 2020 (osù kẹwàá sí oṣù kejìlá) ni wọn yóò gbà di ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà. Gbogbo àwọn olùdásílẹ̀ fọ́ọ̀mù-gígùn ni wọ́n gbà níyànjú láti gbà á.

Ìdàpọ̀ Àrà-ọ̀tọ̀

Ìdàpọ̀ GIJN wà fún Ìpàgọ́ Nẹ́tíwọ̀kì Iṣẹ́-ìròyìn fún Aṣèwádìí Lágbàáyé. Àwọn Ìdàpọ̀ tó ju ọgọ́rùn-ún lọ ni wọ́n fúnni ní 2019 fún ìpàgọ́ lágbàáyé, tí wọ́n ṣe ni ọjọ́ kẹrin-dín-lọ́gbọ̀n sí kọka-n-dín-lọ́gbọ̀n oṣù keje ní Hamburg, Germany. Ìpè fún GIJC21 ni wọn yóò kéde lórí lẹ́tà-ìròyìn GIJN.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn Aṣèwádìí pẹ̀lú àwo rẹ́kọ̀dù tí wọ́n fi ń wá déétà àti ìtàn síta, àti pé wọ́n tẹ́dó sí àwọn orílẹ̀-èdè tó ń dà gbà sókè tàbí tó ń yí padà.

Iye: owó ọkọ̀-ofúrufú àti ibùgbé ní ilé-ìtura sí àwọn GIJC, tí wọ́n ṣe ni ìlú ọ̀tọ̀tọ ní gbogbo ọdún méjì. Àwọn Olùgbà ni yóò san owó oúnjẹ wọn àti ìṣípòpadà abẹ́lé.

Àwọn Oníròyìn Aṣèwádìí àti Owó-ìrànwọ́ Ìkọní Àwọn Olóòtú ni ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ àti owó-ìrànwọ́ fún ìwé kíkà láti gba àwọn oníròyìn alámọ̀dájú láàyè tàbì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni àǹfààní láti wá sí ibi ayẹyẹ ìkọ́ni.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn àti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn kò lọ ayẹyẹ ìkọ́ni IRE ní ìdà kejì.

Iye: Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó níṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ IRE ọdún kan, ìpàgọ́ tàbí owó ìwọlé sẹminá, àti àgbàpadà fún ilé-ìtura àti ìnàwó ìrìnàjò.

Ètò Iṣẹ́-ìròyìn Sáyẹ̀ǹsì Knight ní MIT fúnni ní ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ ajẹmákadá ọlọ́dún kan fún àwọn Oníròyìn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí níní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nínú sáyẹ̀nsì àti ìmọ̀ ọgbọ́n àmọ̀ọṣe.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn fún àkókò pípẹ́ pẹ̀lú ìrírí ọdún mẹ́ta. Ipa èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Iye: US$70,000, ìsedúró ìlera àti ìnáwó ìrìnàjò fún ìwádìí.

Ìpàdé àkànṣe-iṣẹ́ Ìtẹ̀bọmi Sáyẹ̀nsì fún àwọn Oníròyìn jẹ́ ìkọni ṣ`sẹ̀ kan lórí àyíká àti ìjábọ̀ sáyẹ̀nsì tí wọ́n fúnni láti ilé-ẹ̀kọ́ Metcalf ní Rhode Island.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn kùtùkùtù sí iṣẹ́ àárín.

Iye: Yàrá, bọ́ọ̀dù, owó ilé-ìwé, àti èyí tó tó US$500 ní ìrànlọ́wọ́ ìrínàjò (tó tó US$1000 fún àwọn oníròyìn jákè-jádò àgbáyé tó ń rin ìrìnàjò láti ìta US),

Ìdàpọ̀ Iṣẹ́-ìròyìn Sáyẹ̀nsì EGU ni European Geosciences Union (EGU) fúnni fún “àbá àrà titun láti jábọ̀ ìròyìn lórí ìwádìí sáyẹ̀ǹsì-ayé tí kò tí ì sí ní gbangba ayé.” Èróńgbà èyí ni láti mú ìlọsíwájú bá ìjábọ̀ sáyẹ̀ǹsì-ayé.

Ta ni: Alámọ̀dájú, Àwọn Oníròyìn aláápọn.

Iye: Tí ó tó E5000 láti kájú àwọn ìnáwó tó níṣe pẹ̀lú iṣẹ́-àkànṣe wọn.

Ìdàgbàsókè Ètò Ìjábọ̀ Owó-ìrànwọ́ ní Àrà-titun ni Ìkànnì Iṣẹ́-ìròyìn ará Europe fúnni pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Bill & Melinda Gates Foundation. Àwọn Àkòrí yípadà.

Ta ni: Ìjáde Ilé-iṣẹ́ Ìròyìn àti àwọn aláfaramọ́ wọn tí o wà ní Denmark, France, Germany, Italy, àwọn Netherlands, Norway, Spain, Sweden, àti United Kingdom.

Iye: Agbede Owó-ìrànwọ́ ni E20,000.

Ìdàpọ̀ Ilé-iṣẹ́ Ìròyìn Ìdájọ́ Soros gbé owó sílẹ̀ fún iṣẹ́-àkànṣe lórí ètò ìdájọ́ ọ̀daràn. 

Ta ni: Àwọn Oníròyìn alákòkó kíkún.

Iye: Owóìrànlọ́wọ́ US$50,000 tàbí 70,000 pẹ̀lú ìnàwó ìjábọ̀ àti àǹfààní ìlera.

Ìdàpọ̀ Knight-Bagehot ní Ilé-ìwé Iṣẹ́-ìròyìn Akẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Ilé-ìwé Gíga Columba fi kọ́ọ̀sì ọlọ́dún kan ajẹmákadá sílẹ̀ ní iṣẹ́-ìròyìn ìṣòwò àti ọrọ̀-ajé.

Ta ni: Ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ olóòtú ti ìwé-ìròyìn àkókò-pípé, magasìnìì, iṣẹ́ wáyà, ilé-iṣẹ́ ìròyìn ẹ̀rọ àti àjọ ìròyìn ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí sí àwọn oníròyìn aládàáni, pẹ̀lu ó kéré tán ìrírí ọdún mẹ́rin.

Iye: US$55,000 àti ilé gbígbé.

Ètò Ìdàpọ̀ Dart ni wọ́n fúnni láti ara Unifasitì Columbia ní New York City, pẹ̀lú Ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ Ochberg lórí ìbàlọ́kànjẹ́ àti rògbòdìyàn.

Ta ni: Ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn tó ní ìrírí fún ó kéré tán ọdún márùn-ún.

Ìdàpọ̀ Iṣẹ́-ìròyìn Ètò Kiplinger ní àlámọrí gbangba ni wọ́n fúnni láti ara Ohio State ni ó gbé ìkọ́ni to le koko ọlọ́sẹ̀ kan sílẹ̀ lóri lílo àwo gbangba, déétà àti ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn àwùjọ síta.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn pẹ̀lú ó kéré tán ìrírí ọdún márùn-ún. Ìlesọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Iye: Owó-ìrànlọ́wọ́ ìrìnàjò, yàrá àti bọ́ọ̀dù.

Ìdàpọ̀ Iṣẹ́-ìròyìn iṣẹ́ àgbẹ̀ àti Wákàtí Kọkànlá oúnjẹ-UC Berkeley ni Akẹ́kọ̀ọ́gboyè Ilé-ìwé UCB ti Iṣẹ́-ìròyìn fi sílẹ̀. Wọ́n ń wá àwọn ìtàn onífọ́ọ̀mù gígùn aláápọn lórí ètò oúnjẹ, láti ìlànà ohun ọ̀gbìn àti oúnjẹ aṣaralóore àti ilé-iṣẹ́ oúnjẹ fún ìlera àwùjọ tí wọ́n so mọ́ oúnjẹ àti iṣẹ́ àgbẹ̀. Ètò náà fún ààyò ní U.S., gbájúmọ́ ìtàn, ṣùgbọ́n wọn yóò tún ro ìtan jákè-jádo àgbáyé pẹ̀lú igun U.S. tó lágbára tàbí àsopọ̀.

Ta ni: Ìdàpọ̀ mẹ́jọ. Pẹ̀lú agbede, ẹlẹgbẹ́ ètò tó nǹkan bí ọdún méjì tàbí ọdún méje sí iṣẹ́ gẹgẹ́ bí oníròyìn; wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ jáde tàbí gbé àwọn ìtàn lé ìtẹ̀wéjáde orílẹ̀-èdè tàbí ìgbéjáde ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́; wọ́n ṣàfihàn ìlérí ńlá àti ẹ̀bùn ṣùgbọ́n wọn kò tí ì mọ̀ wọ́n dáadáa sí àwọn olóòtú orílẹ̀-èdè.

Iye: US$10,000 fún Ìdàpọ̀ kọ̀ọ̀kan.

Owó-ìrànwọ́ fún Òfófó Ẹ̀rọ ran Iṣẹ́-àkànṣe European lọ́wọ́ tí ó ń jábọ̀ lórí ìwà-ipá jẹ́ńdà, ẹ̀tọ́ àwọn tó kéré, aṣíkiri àti Asásàlá. Owó yìí jẹ́ kí ẹgbẹ́ iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí àti àjọ ìpìlẹ̀sẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn láti gba ìrànlọ́wọ́ nínu bíbẹ̀rẹ̀ ààbò àrà titun òfófó ẹ̀rọ. 

Ta ni: Àwọn àjọ nílò láti jẹ́ ara, ìfọwọ́si kedere/tọ́kasí, pẹ̀lú títẹ̀lé ọ̀kan lára ìsọ̀kan tàbí ọmọ ẹgbẹ́ nẹ́tíwọ̀kì: Ìdábòbò Olófòfó lórí ìdarapọ̀ ilà-oòrùn gúsù Europe, Nẹ́tíwọ̀kì Olófòfó Jákè-jádò Agbàyé, Àkóyawọ́ Jákè-jádò Àgbáyè, Àjọ jákè-jádò Àgbáyé ti Oníròyìn Aṣèwádìí, tàbí Iṣẹ́-àkànṣe tó ń jábọ̀ Ìrúfin àti Jẹgúdújẹrá tí wọ́n ṣètò.

Iye: Ó tó 3.000 euro pẹ̀lú “IT àti ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀ràn.”

Iṣẹ́-ìròyìn Òwò fún Ìdàpọ̀ McGraw ní City University of New York’s Graduate School of Journalism ṣe ìrànlọ́wọ́ fún kíkó ìròyìn òwò jọ níjìnlẹ̀ àti ọrọ̀-ajé lágbàáyé. Ìdàpọ̀ yìí pèsè olóòtú àti ìrànwọ́ owó sí àwọn oníròyìn tí ó nílò àkókò àti ohun èlò láti kojú oníbọ̀, àwọn ìtàn tó ń gba àkókò. Ètò yìí ń gba ìbẹ̀wẹ̀ fún àtẹ̀rànṣẹ́ tó jinlẹ̀, fídíò tàbí ọ̀nà ohùn, àti àǹfààní lílo fọ́ọ̀mù ìtàn-sísọ tó ju ẹyọ̀kan lọ láti pèsè páàtì ilé-iṣẹ́-ìròyìn alápapọ̀ ni wọ́n gbà níyànjú.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn Aládàáni, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Oníròyìn àti àwọn Olóòtú tí ó ń ṣiṣẹ́ ní àjọ ìròyìn pẹ̀lu ó kéré tán ìrírí ọdún márùn-ún, le gbà á. Àwọn Oníròyìn Jákè-jádò Àgbáyé náà ní ẹ̀tọ́ níwọ̀n ìgbà tí ìjábọ̀ wọn bá ti wà ní títẹ̀jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìgbéjáde ilé-iṣẹ́ ìròyìn tó tẹ̀dó sí U.S.

Iye: Àwọn ẹlẹgbẹ́ máa gba US$5,000 lóṣù fún oṣù mẹ́ta.

Ìdàpọ̀ Ilé-ìwé Iṣẹ́-ìròyìn Donald W. Reynolds fìwépe àwọn àbá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn àti ilé-ìwé gíga láti dòwòpọ̀ “lórí iṣẹ́-àkànṣe àrà titun tí ó fún ìjọba tiwantiwa lókun láti ara iṣẹ́-ìròyìn.” Oríṣìí ìdàpọ̀ RJI mẹ́ta ló wà: residential, nonresidential and institutional.” Iṣẹ́-àkànṣe tó yọrí máa níse pẹ̀lú múmú ète titun lò lóòrèkóòrè láti mú àǹfààní tàbí láti yanjú ìṣoro, kíkọ́ ohun èlò titun fún àwọn àjọ ìròyìn, yíyí òye dà sí àfọwọ́kọ́ ìdánrawò-ọjà tàbí ìlọsíwájú àfọwọ́kọ́ nítorí èyí ó ti ṣetán fún ìdókò-òwò tàbí fún ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ́-àgbéṣe kíkún.”

Ta ni: Ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọmọ-ìlú U.S. àti àwọn Oníròyìn ilẹ̀-òkèrè.

Iye:  Àwọn ẹlẹgbẹ́ olùgbé gba $80,000 owó ìrànlọ́wọ́ àti $10,000 owó-ilé ìgbà-kan tàbí ìṣílọbòmíràn. Àwọn ẹlẹgbẹ́ tí kò gbé ibẹ̀ gba $20,000 owó ìrànlọ́wọ́, pẹ̀lú ìwádìí àti ìrànwọ́ ìrìnàjò. Owó-ìrànlọ́wọ́ ilé-ìwé gíga ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ – $20,000 – ni wọ́n san sí ilé-iṣẹ́ tàbí ilé-ìwé gíga àti pé wọ́n le lò ó fún ìtura owó-oṣù tàbí fún nǹkan mìíràn láti rí i dájú pé iṣẹ́-àkànṣe ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ yọrí sí rere.

Ìdàpọ Ilé-iṣẹ́ ìròyìn Jákè-jádò òkun àgbáyé tí Heinrich Boil Stiftung ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀, ṣagbátẹrù àwọn oníròyìn mélòó kan tí ó yàn láti US àti Europe ní ọdọọdún fún ẹnìkọ̀ọ̀kan, Ìrìnàjò jákè-jádò òkun àgbáyé fún ọjọ́-márùn-ún fún ìwádìí ìtàn tó níṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àjọ lórí afẹ́fẹ́ àti ìlànà agbára, ìjọba tiwantiwa & ìlànà àwùjọ, tábí ìlànà òkè-òkun & ààbò.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn tó wà ní US tí wọ́n ṣàfihàn ìwúrí tó lágbára fún kíkópa nínú ìwádìí àti ìjábọ̀ ìròyìn ní Ìsọ̀kan Ará Europe àti/ tàbí Turkey. Àwọn Oníròyìn tó wà ní ipò ọmọ ẹgbẹ́ EU àti tí ó ṣàfihàn ìwúrí tó lágbára nínú ìwádìí àti ìjábọ̀ ìròyìn ní US.

Àwọn Oníròyìn-ní-Ibùgbé ni Ìkànnì Stigler fún Ẹ̀kọ́ ti Ọrọ̀-ajé àti Ipò ní Unifásítì Ilé-ìwé ti Okòwò ní Chicago Booth fúnni. 

Ta ni: Àwọn Oníròyìn-tó-ń-bọ̀ láti gbogbo àgbáyé, tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní gbogbo ẹ̀dá ti ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde… àwọn oníròyìn tí ó ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n ní ìrírí nídìí iṣẹ́ ìròyìn àti ẹni tí ó le sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa ni wọ́n gbàníyànjú láti gbà á.”

Iye: Owó-ìrànlọ́wọ́ tó tó $12,000 láti fi san gbogbo ìnáwó fún ilé gbígbe fún ètò tó kọjá ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá.

Ètò Owó-ìrànlọ́wọ́ Ìwé-kíkà Ìsinmi àti Ìsádi tí àwọn Oníròyìn Aláìlálà ti Germany àti Àjọ taz Panter ṣe, àjọ aláìjèrè tí wọ́n so pọ̀ mọ́ tageszeitung, ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ láti Berlin.

Ta ni: Fi owó sílẹ̀ fún àwọn Oníròyìn méjì láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú wàhálà tàbí ogun “àkókò ìsádi àti ìsinmi tí ó tó oṣù mẹ́ta.” 

Ìdàpọ̀ Ìdàgbàsókè Ìjábọ̀ Ìgbà-kékeré ní kíá ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ ọlọ́dún kan tí Ìkànnì Jákè-jádò fún àwọn Oníròyìn àti Àjọ Ìfowósílẹ̀ Ìdókòwò àwọn ọmọdé ṣe onígbòwọ́ rẹ̀.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn láti gbogbo ibi tí wọ́n ń kó ìròyìn jọ lórí ìlera àwọn ọmọdé àti ìdàgbàsókè wọn ní Bangladesh, Brazil, India, Kenya, Nigeria, àti Tanzania.

Iye: Àwọn ẹlẹgbẹ́ mẹ́wàá yóò gba ìkọ́ni, ìbádámọ̀ràn àti ìrànwọ́ owó láti gbé àwọn ìtàn síta lóri oúnjẹ aṣaralóore àti ìdàgbàsókè àwọn ọmọdé ní kíákíá.

Ìpèníjà Bertha tí Àjọ Bertha ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ, èyí tí ó “ran àwọn ajìjàgbara lọ́wọ́, àwọn asọ̀tàn àti àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí ìdájọ́ ọrọ̀-ajé àti àwùjọ àti fún gbogbo ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn.” Ọdún àkọ́kọ́ fún ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ ọlọ́jọ́-pípẹ́ ni ó dojúkọ lórí: “Báwo ni ìbáṣepọ̀ láàárín ohun-ìní, èrè àti òṣèlú ṣe ń dásí ilẹ̀ àti àìṣòdodo ilé, àti pé kí la lè ṣe láti ṣe àtúnṣe sí èyí?”

Ta ni: Àwọn Oníròyìn àti àwọn Ajìjàgbara (márùn-ún fún ìkọ̀ọ̀kan). Bertha ń wá “àwọn Oníròyìn iṣẹ́-àárín fún ó kéré tán ìrírí ọdún márùn-ún àti àwo rẹ́kọ̀dù àti ìfẹ́ fún ṣiṣe iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí.”

Iye: Owó tó wọlé fún ẹlẹgbẹ́ Bertha kọ̀ọ̀kan fún ọdún kan, kò kọjá US$60,000. Ìfowosílẹ̀ fún Iṣẹ́-àkànṣe tó US$10,000 fún ẹlẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan láti le gbé ọjà tó gara síta. Ó jẹ́ ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ tí kò gbé bẹ̀ nítorí èyí àwọn ẹlẹgbẹ́ yóò máa dúró sí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé àti tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́.

ÀWỌN OWÓ-ÌRÀNWỌ̀ ÌJÁBỌ̀-ÌRÒYÌN

Owó-ìrànwọ́ fún Iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí fí owó-ìrànwọ́ sílẹ̀ fún ìwádìí ìtàn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ìjábọ̀. FIJ ni ó jẹ́ ọ̀nà ìfowósílẹ̀ tó dàgbà jù ti irú  rẹ̀, tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1969. Ó kọjá ọdún mẹ́wàá lọ́nà mẹ́rin, owó yìí ti fúnni ní àmì-ẹ̀yẹ tó jú $1.5 mílíọ̀nù lọ ní owó-ìrànwọ́ fún àwọn oníròyìn aládàáni, àwọn oǹkọ̀wé àti àwọn atẹ̀wésíta kékèké, gbà á láàyè láti tẹ ìtàn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin lọ àti àwọn ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti àádọ́ta ìwé síta.

Ta ni: Ìfowósílẹ̀ gba lẹ́tà-ìbẹ̀wẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aládááni, oǹkọ̀wé, àti àwọn alámọ̀dájú oníròyìn fún iṣẹ́-àkànṣe lóri U.S. àti àwọn ìṣòro jákè-jádò àgbáyé. Àwọn adájọ́ wo àwọn ìtàn tí ó fi ààyè titun sílẹ̀ tí ó sì tú àṣírí gbogbo àṣìṣe – bí i jẹgúdújẹra, àìṣedédé, tàbí àṣìlò agbára. Gbogbo àbáwọlé gbọ́dọ̀ jẹ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Bọ́ọ̀dù Ìfowósílẹ̀ pàdé lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún láti ro àwọn àbá wò. Àwọn Ìtàn gbọ́dọ̀ ní igun U.S. kí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Iye: Owó-ìrànwọ́ agbede FIJ tó US$5,000 fún ẹnìkọ̀ọ̀kan, lọ́pọ̀ ìgbà fún ìnàwó láti àpò ẹni bí àpẹẹrẹ ìrìnàjò, gbígba ìwé jọ, àti yíyá àwọn ohun èlò. Ìfowósílẹ̀ tún máa ń ro àwọn ìbéèrè fún àwọn owó-ìrànlọ́wọ́ kékeré.

Ìtàn Owó-Ìrànwọ́ The Society of Environmental Journalists lórí Ìpínsíyẹ́lẹyẹ̀lẹ. SEJ wá láti kọ ọ́ lábẹ́lẹ̀ lórí ìkóròyìn jọ lórí ọ̀rọ̀ ìpínsíyẹ́lẹyẹ̀lẹ àti àwọn ìpèníjà tó ń kojú àwùjọ ní gbogbo àgbáyé ní ìsáájú ìpàgọ́ 2020 ti Àjọgbà ẹgbẹ́ lórí Onírúurú Ìṣẹ̀dálẹ̀.

Ta ni: Lẹtà-ìbẹ̀wẹ̀ jẹ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ SEJ. Àwọn tí kì í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ tí iṣẹ́ wọ́n jẹ́ ti alámọ̀dájú pàdé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ SEJ tí wọ́n ní àwọn ohun tí wọ́n bèèrè tó yẹ le gbà á pẹ̀lú $40 tí wọn yóò san. Wo ìlànà ìtọ́nisọ́nà tó pé kí o tó gbà á. Àwọn àbá gbọ́dọ̀ fi ilé-iṣẹ́ ìròyìn aṣòtàn ìtànkálẹ̀ ètò, àwọn afijẹ́ẹ̀rí , lẹ́tà ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olóòtú, àti àwọn ètò-ìsúná tí wọ́n tì mọ́lé.

Iye: Owó-ìrànwọ́ tó tó $5,000 fún owó-ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti ìnáwó bí i ìrìnàjò, ìgbéjáde ilé-iṣẹ́ ìròyìn onírúurú, ìtúmọ̀-èdè, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ètò Owó-ìrànwọ́ Asọdá-ààlà ará Europe tí Journalismfund.eu. ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn Alámọ̀dájú tí wọ́n ní èrò gidi fún ìwádìí ìsọdá-ààlà àti fún ìwádìí lórí àlámọrí ará Europe. Àwọn ìtàn yìí gbọ́dọ̀ níṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ àfojúsùn ará Europe.

Iye: Ó le pẹ̀lú ìrìnàjò, ìtúmọ̀-èdè, ìráàyè láti san owó àpótí-ìsura-déétà tàbí àkókò láti ṣe ìwádìí. Kò fi ọwọ́ kún iye owó kann pàtó bí i iye-owó ọ́fíìsì, ìkówólé bí i kámẹ́rà tàbí kọ̀m̀pútà tàbí iye-owó ìṣelọ́pọ̀.

The International Women’s Media Foundation fi ọwọ́ kún ìjábọ̀ iṣẹ́-àkànṣe, pàápàá jùlọ àwọn ìtàn tí wọn kò tí ì jábọ̀ fún kókó àgbáyé, àti wíwá sí àǹfààní ìdàgbàsókè alámọ̀dájú láti ara Ìfowósílẹ̀ Howard G. Fún àwọn Oníròyìn Obìnrin.

Ta ni: Olùbẹ̀wẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ oníròyìn obìnrin tó ní ìrírí. Tí ó bá ṣe ń gbà, ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn le gbà á, ṣùgbọ́n olórí ẹgbẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ oníròyìn obìnrin àti pé ẹgbẹ́ náà gbọ́dọ̀ fi ó kéré tán àádọ́ta nínú ọgọ́rùn sílẹ̀ kó jẹ́ obìnrin.

Iye: IWMF máa ṣe àpapọ̀ ọdọọdún tí ó jẹ́ $230,000 lápapọ̀ tí ó tó owó-ìrànwọ́ tí yóò lọ ìpele mẹ́rin fún ìfowósílẹ̀ títí di ọdún 2025. Owó yìí kò lópin sí bóyá owó-ìrànwọ́ ní dọ́là tàbí iye owó-ìrànwọ́ tí wọ́n fúnni láàárín ọdọọdún lápapọ.

IrúÌwádìí fi owó-ìrànwọ́ fún àwọn iṣẹ́-àkànṣe aṣèwádìí. Ọ̀pọ̀ Àjọ ní ó fọwọ́ kún akitiyan yìí, tí wọ́n máa ń pè ní Owó Aṣèwádìí. Àjọ Òbí jẹ́ Ìkànnì Irú Ilé-iṣẹ́ Ìròyìn. Irúìwádìí “gbin ipa ìjábọ̀ ìwádìí tí ó mú ìṣirò tó lágbára dání.”

Ta ni: “A ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn Oníròyìn Aṣèwádìí tó dáńfó láti pèsè ìjábọ̀ iṣẹ́-ìròyìn tó jinlẹ̀ tí a lè tẹ̀ jáde pẹ̀lú ìbádòwòpọ̀ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìtẹ̀jáde tó fẹjú, ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ìgbéjáde ẹ̀rọ ilé-iṣẹ́ ìròyìn.”

Iye: Àwọn Olóòtú wa pèsè àwọn oníròyìn tó yàtọ̀ pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà alámọ̀dájú olóòtú, ẹgbẹ́ aṣèwádìí, àti owó tó bo ìrìnàjò wọn, àkókò, àti àwọn ìnáwò ìjábọ̀ ìròyìn mìíràn.”

Leonard C.Goodman Institute for Investigative Reporting fi owó-ìrànwọ́ sílẹ̀ láti  lò ó fún iṣẹ́-àkànṣe ìjábọ̀ ìròyìn tí wọn yóò tẹ̀ síta ní In These Times, ìwé-ìròyin U.S. tó ń tẹ̀síwájú.

Ta ni: Ó ṣí sílẹ̀ fún gbogbo oníròyìn lágbàáyé, ṣùgbọ́n “ààyò ni wọn yóò fún àwọn ìtàn pẹ̀lú igun U.S.”

Iye: Òsùwọ̀n ìfigagbága ọ̀rọ̀-kọ̀ọ̀kan àti ìsanpadà owó fún ìrìnàjò àti àwọn ìnáwó mìíràn.

Pulitzer Center on Crisis Reporting Travel Grants fi owó sílẹ̀ fún ìrìnàjò jákè-jádò àgbáyé tí ó tapọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́-àkànṣe ajábọ̀ lórí àkòrí, àti pàtàkì agbègbè lágbàáyé, pẹ̀lú ìtẹnumọ́ lórí àwọn ìṣòro tí ó ti lọ láìjábọ̀ rẹ̀ tàbí tí wọn kò tí ì jábọ̀ rẹ̀ ní ilé-iṣẹ́ iròyin odò-ikùn ti America.

Ta ni: Ó ṣí sílẹ̀ fún gbogbo oníròyìn, àwọn òǹkọ̀wé, àwọn ayàwòrán, Atọ́kùn Rédíò tàbí olùṣefíìmù ní orílẹ̀-èdè kórílẹ̀.

Iye: Gbáralé iṣẹ́-àkànṣe ní pàtó “ọ̀pọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bẹ̀rẹ̀ láti US$5,000 sí US$15,000 ṣùgbọ́n iṣẹ́-àkànṣe ní pàtó tó gbáralé le ga sí i.”

Rainforest Journalism Fund, ìkànnì àrà-titun Pulitzer, ran ìjábọ̀ ìròyìn lọ́wọ́ lórí ipa ọ̀nà òòrùn igbó òjò ní Amazon Basin, Congo Basin, àti Ìlà-oòrùn gúsù Asia.

Ta ni: Àwọn oníròyìn tó ń jábọ̀ lórí igbó-òjò.

Iye: Máa ń yàtọ̀ nípa agbègbè. Àmì-ẹ̀yẹ Iṣẹ́-àkànṣe jákè-jádò wà látí $5,000 sí $15,000 ṣùgbọ́n ó gbáralé iṣẹ́-àkànṣe pàtó le ga sí i.

Owó-ìrànwọ́ Iṣẹ́-ìròyìn fún ìfowósílẹ̀ Àyíká fi I sílẹ̀ láti ara àwùjọ iṣẹ́-ìròyìn Àyíká tí wọn kò tí ì kọ lórí ìjábọ̀ iṣẹ́-àkànṣe àti afowópawó ìsòwò lórí ìṣòro káàkiri àyíká.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn tó ń ṣiṣẹ́ àdánìkanṣe tàbí lórí àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ àjọ fún-elérè tàbí aláìlérè ìròyìn lágbàáyé.

Iye: Owó-ìrànwọ́ tó tó US$5,000.

Daniel Pearl Investigative Journalism Initiative ni Moment fowó sílẹ̀, ìwé-ìròyìn ọmọ Jew tó tẹ̀dó sí U.S., “láti gba àwọn oníròyìn kékèké níyànjú láti kọ àwọn ìtàn tó jinlẹ̀ lórí ìfarahàn ayé-òde òní ti ó tako èdè Júù tàbí ẹ̀tanú tó jinlẹ̀ tó wà títí.”

Ta ni: Àwọn oníròyìn láàárín ọdún méjì-lé-lógún sí ọdún méjì-dín-lógójì.

Iye: US$5,000.

Arab Reporter for Investigative Journalism (ARIJ) fúnni ní owó-ìrànwọ́ sí àwọn oníròyìn tí ó wà ní àárín gbùgbù Ilà-oòrùn àti Àríwá Áfíríkà pẹ̀lú èrò ìtàn aṣèwádìí.

Ta ni: Àwọn oníròyìn láti Jordan, Syria, Lebnon, Egypt, Yemen, Iraq, Palestine, Tunisia, tàbí Bahrain.

Iye: Máa ń yàtọ̀.

Owó-ìrànwọ́ Ìtàn China-Africa wà láti iṣẹ́-àkànṣe Ìjábọ̀ Ìròyìn China-Africa ní Ẹ̀ka Iṣẹ́-ìròyìn ti Witwatersrand, South Africa.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn Alámọ̀dájú pẹ̀lú èrò tó jinlẹ̀ fún iṣẹ́-àkànṣe aṣèwádìí ní àwọn kókó kan pàtó pẹ̀lú: Amáyédẹrùn /Ìwakùsà  / Ìdókòwò / Arìnrìnàjò / ICT àti ilé-iṣẹ́ ìròyìn / Sáyẹ̀nsì àti Ìmọ̀ ọgbọ́n ìmọ̀ọṣe / Àyíká, Ìtọ́jú àti Ẹgàn.

Iye: Owó-ìrànwọ́ láàárín $300 àti $2000.

Àwọn Oníròyìn lójú Iṣẹ́ fi owó-ìrànwọ́ ìjábọ̀ ìròyìn sílẹ̀ fún iṣẹ́-àkànṣe ìsọdá-ààlà lábẹ́ẹ ètò tí Germany’s n-ost ṣe.

Ta ni: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ àti ìtàn rẹ gbọ́dọ̀ dálé ó kéré tán méjì lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí – Albania, Andorra, Armenia, Austria, Azerbaijan, Belarus, Belgium, Bosnia àti Herzegovina, Bulgaria, Croatia, Cyprus, CzechRepublic, Denmark, Estonia, Finland, France, Georgia, Germany, Greece, Hungary, Iceland, Ireland, Italy, Kosovo, Latvia, Liechtenstein, Lithuania, Luxembourg, Macedonia, Malta, Moldova, Monaco, Montenegro, Netherlands, Norway, Poland, Portugal, Romania, Russia, San Marino, Serbia, Slovenia, Spain, Sweden, Switzerland, Turkey, Ukraine àti United Kingdom.

Iye: Ó tó E8,000 láti fi kojú ìnáwó ìrìnàjò bẹ́ẹ̀ náà ni ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti àwọn ìnáwó mìíràn tí ó wà lára ìwádìí wọn.

Mongabay pèsè àwọn àǹfààní fún àwọn oníròyìn káàkiri àgbáyé láti jábọ̀ lórí àwọn àyíká tó ṣe kókó àti ìtọ́jú àwọn ìtàn. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀nà-ìgbàjáde ìròyìn lágbàáyé,wọ́n ṣètò Mongabay sí ẹgbẹ́ olóòtú agbègbè tí yóò ṣe ìfúnni àti yíyan àwọn ìtàn tó níṣe pẹ̀lú àwọn Iṣẹ́-àkànṣe Ìjábọ̀ ìròyìn tó ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí ìtàn àyíká.

Iye: Máa ń yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́-àkànṣe.

Owó-ìrànwọ́ Sáyẹ̀nsì fún Ìjábọ̀ ìròyìn Aṣèwádìí ni ìwé ìròyìn sáyẹ̀nsì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀ “ iṣẹ́-àkànṣe tó láapọn ní ìjábọ̀ aṣèwádìí àti iṣẹ́-ìròyìn déétà… a ní ìtara láti sọ ìtàn lórí agbègbè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì àti àwọn ìfikọ́ra rẹ̀, ipa owó àti òṣèlú ní sáyẹ̀nsì, àti ìlànà-àwùjọ tó níṣe pẹ̀lú sáyẹ̀nsì tí ó lè tan ìmọ́lẹ̀ nìkan sí ìjábọ̀ yàtọ̀, àwọn ìwé àṣẹ, àti dééta.”

Ta ni: “Àwọn oníròyìn pẹ̀lú àwo rẹ́kọ̀dù tó ní ipa tó ga ní ìjábọ̀ ìròyìn.” Le wá láti ibikíbi.

Iye: Owó-ìrànwọ́ ọdún mẹ́rin sí márùn-ún láàárín $10,000 sí $15,000. Ó kéré (tàbí ó tóbi) owó-ìrànwọ́ ṣe é ṣe, ó dáléiṣẹ́-àkànṣe.

Owó-ìrànwọ́ Ìjábọ̀ Ọlọ́jọ́-pípẹ́ àwọn Olùtẹ̀wésíwa ti aráa Europe jẹ́ iṣẹ́-àkànṣe ìfowósílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìròyìn tí Ìkànnì Iṣẹ́-ìròyìn aráa Europe tí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀. Èróńgbà wọn ni láti jẹ́ kí wọ́n mọ United Nation’s Sustainable Development Goals (SDGs) tí wọ́n mú.

Ta ni: Ìgbéjáde Ilé-iṣẹ́ Ìròyìn tí ó ń lọ fún àwọn olùwòran tó ṣe pàtàkì ní France, Germany, Netherlands, Sweden tàbí United Kingdom.

Iye: Gbèdéke Owó-ìrànwọ́ tí wọ́n fún wọn wà láàárín E130,000.

Thomson Reuters Foundation, ní oríṣìíríṣìí àǹfààní fún àwọn oníròyìn lọ́dọọdún. Ní ọdún yìí Thomson Reuters Foundation ọjọ́ márùn-ún lórí ìtàkùn ‘Jíjábọ̀ lórí Ìṣíkiri’ kọ́ọ̀sì yìí jẹ́ àǹfààní tó yàtọ̀ fún àwọn oníròyìn láti Bagladesh láti rí àwọn ìfikọ́ra ìmọ̀ọṣe gbà àti ìmọ̀ àti ṣiṣẹ́ lórí èrò ìtàn rẹ pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà láti ọ̀dọ̀ àwọn oníròyìn Thomson Reuters tó ní ìrírí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Laudes Foundation, Ìpàdé Àkànṣe-Iṣẹ́ fúnni ní àkójọpọ̀ àwọn àgbà-ọ̀jẹ́ tó ṣe pàtàkì àti àwọn ọwọ́ tó wà ní ìkọ́ni, pẹ̀lú ìtẹnumọ́ lórí ṣíṣe àwọn ìtàn tó ní ipa tó ga fún ìtànkálẹ̀ tó gbòòrò.

Ta ni: Fún 2021, olùbẹ̀wẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ oníròyìn àkókò-kíkún tàbí olùkópa déédé sí àjọ ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jade ní Bangladesh. Olùbẹ̀wẹ̀ gbọ́dọ̀ le ṣàfihàn ìfaramọ́ sí iṣẹ́-ẹni ní iṣẹ́-ìròyìn ní orílẹ̀-èdè wọn, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ oníròyìn àgbà pẹ̀lú ó kéré tán ìrírí ọdún mẹ́ta kí ó sì ní ipele tó dára ní kíkọ àti sísọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Iye: Thomson Reuters Foundation le kojú ìnáwó déétà àti àwọn olùkópa. Ìlànà-ètò yìí dálé ìyàtọ̀.

Owó-ìrànwọ́ Ilé-iṣẹ́ ìròyìn fún Ìsáádi Wàhálà tí Mary Raftery Journalism Fund (MRJF) ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ ni wọ́n dá sílẹ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn oníròyìn àti àwọn alámọ̀dájú ilé-iṣẹ́ ìròyìn tí ó wù wọ́n láti ṣe ìwádìí wàhálà ìsádi ní Europe àti ipa dídé àti ìṣìrọ̀ àsádi ní Ireland.

Ta ni: Ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn oníròyìn, àwọn alámọ̀dájú ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti àjọ ilé-iṣẹ́ ìròyìn ti wọ́n fẹ́ láti fi lẹ́tà ìgbaṣẹ́ sílẹ̀ fún àtẹ̀jáde, ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti/tàbí iṣẹ́-àkànṣe orí-ìtàkùn ayélujára. Àwọn tí wọ́n wá láti agbègbè níbi tí ìsádi ti ṣí kúrò láti ibi tí wọ́n ti gbà wọ́n níyànjú ní pàtó láti gbà, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn tó ń gba á dípò ilé-iṣẹ́ ìròyìn-tópọ̀, àwọn ẹgbẹ́ tó dúró lé ìfọwọ́sowọ́pọ̀.

Iye: Ó tó E40,000 tí wọn yóò fún lẹ́tà-ìgbaṣẹ́ tó bá yọrí sí rere àti pé owó tí wọn yóò san tó pọ̀ jù fún olùbẹ̀wẹ̀ ni E20,000.

Iṣẹ́-àkànṣe GroundTruth fúnni ní onírúurú ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ sí àwọn oníròyìn tí wọ́n fẹ́ jábọ̀ ìtàn ní àárín gbùgbù Ilà-oòrùn tí wọn kò tí ì kójọ ní ilé-iṣẹ́ ìròyìn agbéesáfẹ́fẹ́.

Ta ni: Fún àwọn Oníròyìn tó tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, túmọ̀ sí ìrírí ọdún kan sí márùn-ún. Olùdíje le jẹ ọmọ orílẹ̀-èdè tó wù ú, ṣùgbọ́n ó gbọdọ̀ faramọ́ àwọn àṣà ààrín gbùgbù Ilà-oòrùn àti kí ó ní ipa láti ṣàfihàn àwọn àbọ̀ ìròyìn rẹ fún olùwòran tó ń sọ ède Gẹ̀ẹ́sì.

Iye: Gẹ́gẹ́ bí ara owó ìrànwọ́ US$10,000, oníròyìn máa gba owó ìrànlọ́wọ́ àti ètò ìsúná tí yóò níṣe pẹ̀lú ìgbéléwọ̀n tó léwu àti àyíká kanra àti ìkọ́ni ìrànlọ́wọ́ àkọ́kọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ìsedúró iṣẹ́-òògùn àti ìnáwó ìjábọ̀ iṣẹ́. Àwọn ẹlẹgbẹ́ tí wọ́n mú máa gba ìmọ̀ràn àti ìrànlọ́wọ́ olóòtú láti ọ̀dọ̀ gbogbo ẹgbẹ́ olóòtú pátá ní GroundTruth.

Earth Journalism Network (EJN) fúnni ní ìkọ́ni, Sẹ́mínà-lágbàáyé àti owó-ìrànwọ́ kékeré fún àwọn oníròyìn àti àjọ tó níṣe pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìròyìn. Àwọn àǹfààní ran àwọn oníròyìn lọ́wọ́ láti kó ìròyìn jọ dáadáa lórí àwọn ìṣòro tí àwọn àyíká ń kojú.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn (orí-ìtàkùn, àtẹ̀jáde, tẹlifísàn) àti àwọn olùkópa ilé-iṣẹ́-ìròyìn tó jẹ́ àgbà-ọ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwo rẹ́kọ̀dù ìjábọ̀ ìròyìn lórí ọ̀rọ̀ àyíká. Àwọn Aládàáni àti òṣìṣẹ́ láti gbogbo oríṣìí àgbéjáde ilẹ́-iṣẹ́ ìròyìn – àti èyí tó tóbi àti kékeré – le fi lẹ́tà-ìgbaṣẹ́ sílẹ̀.

Iye: Owó-ìrànwọ́ tí ó ń bẹ̀rẹ̀ láti US$1,000 sí US$2,000 ló dálé àbá àti ọ̀nà ìkóròyìn jọ, pẹ̀lú àwọn ìrọ̀rùn tó jinlẹ̀, ìtàn aṣèwádìí tí ó lo àrà titun tó ń súnmọ́ ìtànsísọ.

Reporting Grants for Women’s Stories, tí International Women’s Media Foundation àti The Secular Society ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ, ran iṣẹ́-ìròyìn lọ́wọ́ tí àwọn obìnrin ṣe àti nípa wọn.

Ta ni: Àwọn Oníròyìn Obìnrin, láti lé àwọn ìtàn tó jẹ́ jákè-jádò àgbáyé ti ó ṣe kókó láti ara ìkóròyìn jọ kókó-jẹ́ńdà ti àkòrí tí wọn kò tí jábọ̀ rẹ̀.

Iye: Àwọn Owó-ìrànwọ́ máa jẹ́ gbèdéke US$5,000. Wọn yóò ṣe ìfúnni owó-ìrànwọ́ láti kó ìjábọ̀ ìròyìn tó níṣe pẹ̀lú ìnáwó pẹ̀lú ìrìnàjò (ọkọ̀ òfúrufú, ìṣípòpadà orí-ilẹ̀, àwọn awakọ̀), èèkaderi, owó ìwé-ìwọ̀lú, àti owó fún àwọn olùṣètò/ atúmọ̀-èdè.

IJ4EU Ìfowósílẹ tó tó E450,000 ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2018 láti ọwọ́ Ìgbìmọ̀ Aráa Europe láti ara European Centre for Press and Media Freedom (ECPMF), tí Internertional Press Institute (IPI) ṣàkóso rẹ̀, láti ran àwọn ìwádìí aṣọdá-ààlà aṣèwádìí lọ́wọ́ ní EU.

Ta ni: Wọ́n gbọdọ̀ fi Lẹ́tà-ìgbaṣẹ́ ránṣẹ́ láti àwọn ẹgbẹ́ tó kéré tán ìgbéjáde ilé-iṣẹ́ ìròyìn méjì àti/ tàbí àwọn oníròyìn àti tí tẹ̀dó sí ó kéré tán ọmọ ẹgbẹ́ ipò EU méjì lórí ìbáramu àkórí ìsọdá-ààlà. Iṣẹ́-àkànṣe tí wọ́n dábàá gbọ́dọ̀ ṣàfihàn èróńgbà ìròyìn titun.

Iye: Owo-ìrànwọ́ tó tó E50,000 ló pọ̀ jù. Ọjọ́-ìpari, ọjọ́ kẹta oṣù kaàrún, ọdún 2018.

Owó-ìrànwọ́ Ipa-ọ̀nà Owó ni Journalismfund.eu ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀, àjọ Aláìlérè Belgian tí wọ́n ti forúkọ rẹ sílẹ̀ pẹ̀lú àfojúsùn láti ran àwọn ìwádìì ti owó ìrúfin ìsọdá-ààlà lọ́wọ́, ìlòkulò owó-orí àti jẹgúdújẹrá ní Áfíríkà, Asia àti Europe. Owó náà wá láti Dutch Nationale Postcode Loteriji.

Ta ni: Ẹgbẹ́ Oníròyìn jákè-jádò kọ́ńtínẹ̀tì tí ó ní ó kéré tán ọmọ Áfíríkà kan, ọmọm Asia kan àti/ tàbí ọmọ Europe kan, oníròyìn ní ẹ̀tọ́ láti gbà á. Ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ní ó kéré tán àwọn oníròyìn láti kọ́ńtínẹ̀tì méjì.

Iye: Kò sí gbèdéke kan pàtó. Lẹ́tà-ìgbaṣẹ́ mẹ́wàá ni yóò wà fún bí ọdún mẹ́ta. Gbogbo iye owó fún ìpè kọ̀ọ̀kan tó E50,000. Ọjọ́-ìparí fún ọdún 2019 ni: ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n osù kẹta, ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹfà, ọjọ́ kẹrìn-lé-lógún oṣù keje àti ọjọ́ kẹrìn-dín-lógún oṣù kejìlá.

Investigative environmental journalism grants GRID-Arendal, àjọ Norwegian tí ó ń ran ìdàgbàsókè tó gbé àyíká ró lọ́wọ́, ran ìjábọ̀ ìròyìn lórí ẹ̀sẹ̀ àyíká lọ́wọ́.

Ta ni: Àwọn àbá gbọ́dọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn oníròyìn tó jẹ́ alámọ̀dájú pẹ̀lú ìrirí nídìí iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí. Wo àwọn kání yòókù pẹ̀lú.

Iye: Olùgbà owó-ìrànwọ́ mẹ́rin máa gba 25,000 Norwegian Kronor kọ̀ọ̀kan (tó súnmọ́ E2,300). Lẹ́tà-ìgbaṣẹ́ máa ń sábà parí ní oṣù kìn-ín-ní.

Ìdàpọ̀ Bruno owó-ìrànwọ́ oṣù mẹ́sàn-án láti fi owó sílẹ̀ fún iṣẹ́-àkànṣe aṣèwádìí tó láápọn tí wọ́n parí sí inú ìtàn kan tàbí ọ̀wọ́ àwọn ìtàn tóní ipa, “àwọn ìròyìn tí wọ́n ṣàwárí àwọn àwọn ipá tó lágbára kò fẹ́ rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.” Tí Coda Story ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ, tí ó bo kókó ọ̀rọ̀ mẹ́ta: ìròyìn-irọ́, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àṣẹ ati ogun lórí sáyẹ̀nsì. Ìpolówó gbọ́dọ̀ bá ìkan tàbí méjì mu nínú àwọn ìsọ̀rí yìí.

Ta ni: Fún Oníròyìn tó tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láàárín níbikíbi.

Iye: US$16,000

OWÓ-ÌRÀNWỌ́ ADÁLERÍ-ÌṢẸ̀LẸ̀ GIDI

IDFA Bertha Fund fi owó sílẹ̀ fún iṣẹ́-àkànṣe adálérí-ìṣẹ̀lẹ̀ gidi ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ń dàgbàsókè. Fún bí ọdún méjì-dín-lógún kọjá ní àwọn tó tẹ̀dó sí Netherlands ti fowó sílẹ̀ láti ran iṣẹ́-àkànṣe tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ. Ìsọ̀rí IBF Classic àti IBF Europe fund náà fi àwọn olùṣefíìmù sílẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìdàgbàsókè tàbí ṣíṣe olóòtú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀-gidi àti ìmọ̀ràn lórí ìfọ́nká jákè-jádò àgbáyé.

Ta ni: Àwọn Olùṣe ìṣẹ̀lẹ̀-gidi ní Áfíríkà, Asia, Latin America, Àárín gbùgbù Ìlà-oòrùn, àti apá kan ti ìlà-oòrùn Europe.

Iye: Láàárín E50,000 àti E40,000 ó ń dá lérí ìsọ̀rí.

Filmmakers Without Borders ran àwọn olùṣefíìmù tó dáńfó lọ́wọ́ ní gbogbo àgbáyé nípaṣẹ̀ owó-ìrànwọ́ àti ìfowósílẹ̀ àwọn àrà titun yòókù. Àwọn Iṣẹ́-àkànṣe tí wọ́n ràn lọ́w´ọ níṣe pẹ̀lú fíìmù asọ̀tàn, fíìmù Adálérí-ìṣẹ̀lẹ̀ gidi, àti iṣẹ́-àkanṣe ìròyìn ilé-iṣẹ́ ìròyìn tí ó dàpọ̀ mọ́ àwọn kókó ìdájọ́ àwùjọ, ìfúnilágbára, pàṣípàrọ̀ àṣà.

Ta ni: FWB gba àwọn aláìmọ̀-nǹkan àti àwọn olùṣefíìmù tó ní ìrírí láti orílẹ̀-èdè kórílẹ̀-èdè le gbà á. Lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dọọdún.

Iye: Ó máa ń yàtọ̀ nípa ipele, fún “Gbòógi” owó-ìrànlọ́wọ́ láàárín US$250 àti US$5,000.

BRITDOC fúnni  ń ọ̀pọ̀ oríṣìí owó-ìrànwọ́ fún àwọn olùṣe adálérí-ìṣẹ̀lẹ̀ gidi, pẹ̀lú BRITDOC Circle Fund (fùn àwọn fíìmù aráa Europe) Bertha BRITDOC Connect Fund (fún àwọn olùṣe-ìṣẹ̀lẹ̀ gidi lágbàáyé), Pulse BRITDOC Genesis Fund (fún àbùdá ààtò ìwé-ìtàn adálérí ìṣẹ̀lẹ̀-gidi tó gùn) àti Bertha Doc Society Journalism Fund.

Iye: Láti E5,000 sí E50,000

Tribeca Film Institute pèsè ìfowósílẹ̀, ìgbaninímọ̀ràn, àti àǹfààní nẹ́tíwọ̀kì fún ìwọlé-sí-ipele-àárín olùṣefíìmù.

Ta ni: Fún àwọn olùṣefíìmù asọ̀tàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ lórí fíìmù tí ó gùn tàbí aláátò kúkurú tàbí ọ̀wọ́, fún àwọn olùṣefíìmù adálérí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí fíìmù aláátọ̀ gígùn tàbí kúkurú, àti fún àwọn òṣèré tí ó ń lo àpapọ̀ ìmọ̀-ọgbọ́n ìmọ̀ọṣe bíi VR tàbí AR láti yí ìtànsísọ padà.

ÀWỌN OWÓ-ÌRÀNWỌ́ YÒÓKÙ

Àwọn Ìlú pèsè àwọn owó-ìrànlọ́wọ́ tó ṣe kókó láti fún iṣẹ́-ìròyìn ìnífẹ̀ẹ́sí àwùjọ lágbára jákè-jádò Europe. “Owó yìí yóò pèsè ìfaramọ́ ọdún tó pọ̀ fún ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣiṣẹ́ lápapọ̀ àti ìfokunfún tí ilé-ìwé gíga ti olùbádòwòpọ̀ owó-ìrànwọ́ rẹ̀ láti kọ́ èyí tó ṣe ń gbé jù, tó lágbára jù, tí ó ní nẹ́tíwọ̀kì jù, àti tí ó ní ipa fún àjọ Iṣẹ́-ìròyìn Ìnífẹ̀ẹ́sí Láwùjọ ní Europe.” Ọjọ́ ìparí ni ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹfà, ọdún 2020.

National Endowment for Democracy (NED) ṣe owó-ìrànwọ́ tààrà sí ẹgbẹ́rùn-ún àjọ tí kì í ṣe ti ìjọba lágbàáyé tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sí àfojúsùn ìjọba tiwantiwa lọ́jọ́ iwájú, mú ìlọsíwájú bá ìjíyìn àti àkóyawọ́ àti fífún ilé-ìwé gíga ìjọba tiwantiwa ní okun.

Ta ni: Àwọn àjọ tí kì í ṣe ti ìjọba, tí ó le pẹ̀lú àjọ tó níṣe pẹ̀lú ìlú, àwọn ẹgbẹ́, ilé-iṣẹ́-ìròyìn tó dáńfó, àti àwọn àjọ yòókù tó farajọ ọ́.

Iye: Iye owó owó-ìrànwọ́ máa ń yàtọ̀ èyí tó gbáralé bí ó ṣe tó àti ọ̀nà iṣẹ́-àkànṣe, ṣùgbọ́n owó-ìrànwọ́ tó wà láàárín gbẹ́yìn fún oṣù méjìlá àti ó tó US$50,000. Ọjọ́-ìparí: déètì mẹ̀rin ní ọdún kan.

ÀKÍYÈSÍ: A ti fojú sọ ìtọ́ka àwọn oníròyìn Aṣèwádìí. Fún Ìtọ́ka tó kún fún ti ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ àwọn oníròyìn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́-ìròyìn lápapọ̀, wo ìpín àwọn àǹfààní IJNet (kí o sì wá “ìdàpọ̀”). Fún ìtọ́ka ti àwọn owó-ìrànwọ́ àti ìpè fún àwọn àbá ní ìdàgbàsókè ilé-iṣẹ́ ìròyìn, yẹ ojú-ewé ti Global Forum For Media Development wò fún Àwọn Àǹfààní Owó-ìrànwọ́.

Ìmùdójú-ìwọ̀n ní oṣù kẹrin, ọdún 2021.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *