Ìdáṣe: Ìfúnnilówó Iṣẹ́-àkànṣe Oníwàádìí Tìrẹ

Ìfúnnilówó Owó-ìrànwọ́ fún àwọn iṣẹ́-àkànṣe ìjábọ̀ wà láti onírúurú orísun. Àwọn Olùfúnnilówó kan gba gbogbo irúfẹ́ àbá wọlé, nígbà tí àwọn mìíràn wá láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn àkórí kan pàtó.

Níbí yìí ní Nẹ́tíwọ̀kì Iṣẹ́-ìròyìn Oníwàádìí Lágbàáyé a bójútó àtẹ owó-ìrànwọ́ àti ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ fún àwọn oníròyìn jákè-jàdò àgbáyé.

Fún Àfikún lóri Ìfọ́nká, Ìgbéga, àti Ìdáṣe, wo Ìtọ́sọ́nà GIJN wa

Àtẹ GIJN dojúkọ àwọn àǹfààní sí àwọn oníròyìn jákè-jádò àgbáyé. Nígbà tí àwọn ètò owó-ìrànwọ́ fúnni ní ìrànlọ́wọ́ tààrà fún àwọn iṣẹ́-àkànṣe ìjábọ̀, yẹ àwọn àǹfàání ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ wò, pẹ̀lú. Nígbà tí ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́ wà fún ẹ̀kọ́ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, díẹ̀ nínú wọn da àkóónú ìkọ́ni pọ̀ mọ́ ìjábọ̀ iṣẹ́-àkànṣe, tàbí wọ́n gba àwọn olùkópa ní ààyè nígbà tí wọ́n wà ní ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́.

Fún ọ̀pọ̀ ìṣééṣe sí ní ipele orílẹ̀-èdè àti agbègbè wo àwọn abala àǹfààní lórí ìkànnì ayélujára IJNet. Rory Peck Trust bójútó àtẹ apá-tópọ̀ pẹ̀lú abala ti agbègbè. Orísun owó-ìrànwọ́ ti US tó ju ẹgbẹ̀rún kan lọ ní wọ́n tò sí orí ìṣé-ráàyè-sí spreadsheet sí orí-ìtàkùn Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ìròyìn Ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde.

Àmọ̀ràn lórí Ìkọ̀wésí

Nígbà tí o bá rí Olùrànlọ́wọ́ Onípá, farabalẹ̀ ka àwọn ìwé náà. Ọ̀pọ̀ àwọn olùgbówósílẹ̀ pèsè àwọn ìlànà ìtọ́sọ́nà ọlọ́rìnínkínníwín àlàyé ti irúfẹ́ iṣẹ́-àkànṣe tí wọ́n ń wá láti ràn lọ́wọ́, pẹ̀lú onírúurú àwọn ìbéèrè tó pọn dandan àti ìwúlò. Àwọn kan ti ṣètò àkókò ìparí. Àwọn òfin le wà lórí èdè, àkóónú, àti ìtẹ̀wéjáde.

Kọ́ ohun tí wọ́n ń retí àti bóyá o kún ojú òṣùwọ̀n. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ àmọ̀ràn kan náà lóri bí wọ́n ṣe ró-ohùn àwọn òye ìtàn sí àwọn olóòtú pẹ̀lú sí ìfisílẹ̀ kíkọ owó-ìrànwọ́ tó lágbára.

Wo ojú-ewé ohun-èèlò GIJN pẹ̀lú lórí àwọn Ìtàn Ríró-ohùn.

“News Media Alliance” ṣàtẹ̀jáde ìwé-ìtọ́sọ́nà olójú-ewé mọ́kànlá lóri gbígba owó-ìrànwọ́. Ó kojú bi o ṣe lè rí owó-ìrànwọ́, bí o ṣe lè gbà á, bí o ṣe lè ṣe ìsúná, ohun tí ó yẹ ní ṣiṣe nígbà tí o bá gbà á, ohun tí o ó yẹ̀wò fún nínú àdéhùn, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Láàárín àwọn àbá onígbáradì:

 • Tẹ̀ẹ́ wọlé fún Lẹ́tà-ìròyìn tí àwọn olùfúnnilówó onípa àti àjọ ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde lórílẹ̀-èdè tẹ̀ jáde láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí ó ṣe ń lọ lórí ètò tuntun owó-ìrànwọ́, àwọn ohun tó ṣe kókó àti àkókò ìparí.
 • Yẹ ìkànnì-ayélujára àjọ ìfúnnilówó fún ọ̀pọ̀ àpèjúwe ìmúdójú-ìwọ̀n ti àwọn àkórí àti àwọn iṣẹ́-àkànṣe tí wọ́n ràn lọ́wọ́.
 • Ní Olójú-ìwé kan sílẹ̀. Bí o kò bá tilẹ̀ ní olùfúnnilówó kankan lọ́kàn, ìwé àkọsílẹ̀ dáadáa, ojú-ewé kan tí ó ṣàlàyé iṣẹ́-àkànṣe rẹ, èròngbà rẹ, àti àwọn ohun tí o nílò tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọjúsí àwọn akitiyan rẹ.
 • Ṣe Ìpè Ẹ̀rọ-ìbáraẹnisọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ètò ni ó ń wù láti sọ fún ọ, ó kéré tán lápapọ̀, ìdí tí lẹ́tà-ìgbaṣẹ́ rẹ kò fi jẹ́ àṣeyorí.

Ní àkótán, yẹ Bí o kò ṣe le jẹOwó-ìrànwọ́ Iṣẹ́-ìròyìn. Átíkù yìí ti ọdún 2018 láti ọwọ́ Eric Karstens, ẹni tó ti lọ́wọ́ nínú owó-ìrànwọ́ iṣẹ́-ìròyìn nígbà kan rí gẹ́gẹ́ bí olùgbówósílẹ̀ àti olugbowó-ìrànwọ́. Karstens dá àwọn oníròyìn lẹ́kun nípa:

 • Wọn kò kà á àti kò ní òye kání àti ọ̀rọ̀-ìperí
 • Sísọ àwọn àkórí tó ṣe pàtó nù
 • Kò ṣe pàtó tó
 • O ò ṣàlàyé ara rẹ dáadáa
 • O ò tún un sọ fún olùgbówósílẹ̀ pé o lè ṣe é
 • Dídábàá pé olùjẹ-owó-ìrànwọ́ ni ẹ, nígbà tí kò sí ìjọra láàárín ẹnì yẹn tàbí ẹgbẹ́ tó ń gbà á, àti àkórí
 • Ríro ìfúnlákọ̀ọ́lé
 • Fífi ìsúná sílẹ̀ tí kò ní ìgbóríyìn-fún àti / tàbí ìdí
 • Rírújú lórí èdè (ẹ̀ka-èdè) olùgbówósílẹ̀ àti àwòṣe.

Tún wo àwọn ìtalólobó lóri “the mechanics and art” ti kíkọ-ìwé àbá tó dára tí ó wà nínu átíkù láti ọwọ́ Iṣẹ́-ìròyìn àti Yàrá-ìmọ̀-ìjìnllẹ̀ Ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde (Jamlab).