gijn-logo

Ìdáṣe: Àwọn Ibi láti Ró-ohùn Àwọn Òye Ìtàn

Kò sí àwọn ìkànnì kan tí wọ́n ṣe fún àwọn oníròyìn ní pàtó láti ta àwọn òye ìtàn oníwàádìí, ṣùgbọ́n àwọn ìkànnì orí-ìtàkùn ayélujára díẹ̀ le fihàn pé wọ́n wúlò.

Láti rí atẹ̀wéjáde fún òye oníwàádìí, ọ̀pọ̀ àwọn olùjábọ̀ dábàá àwọn ọ̀nà àbáyọ kan, bí i ṣíṣe ìwádìí lórí àwọn ìgbéjáde tó ṣeé ṣe àti ṣíṣe ìkànṣí ara-ẹni (wo púpọ̀ sí i lórí ìṣe-nẹ́tíwọ̀kì ní abala lórí àwọn ìtàn ìṣe-róhùn.) 

Sí bẹ́ẹ̀, àwọn ìkànnì-orí-ìtàkùn-ayélujára kan wà tí ó pèsè àwọn àǹfààní láti ró-ohùn àwọn òye ìtàn sí olùworan tó gbòòrò àti láti wo àwọn ìpè atẹ̀wéjáde fún ìdáwójọpọ̀ ( bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í sábà rí i lóri àwọn àkòrí oníwàádìí).

Fún àwọn olùjábọ̀ Oníwàádìí Àdáṣe, ìwúlò àkọ́kọ́ ti àwọn ìkànnì iṣẹ́ ni lati wá àwọn akinẹ́gbẹ́ tó sanwó nígbà tí wọ́n ń lé ohun tó wuni tó tóbi jù.  

Méjìlá ìkànnì iṣẹ́ ló wà, dájúdájú àtẹ wa kò tí ì pé. A ti ṣe àfikún àwọn tó tóbi jù àti àwọn tó yẹ jù, ṣùgbọ́n ìwádìí tìrẹ láìṣe-iyèméjì yóò mú àwọn ìkànnì rú gágá bí ó ti yẹ sí àwọn àgbà ọ̀jẹ̀, èdè, tàbí ibi.

Àwọn Ohun-èèlò Journo, Aláìfi-tèrè-ṣe ní ilẹ̀ United Kingdom, ní àwọn àtẹ ọlọ́gbọ́n ti àpólà láti wá pẹ̀lú lórí ìkànnì ìbánidọ̀rẹ̀ẹ́ ayélujára.

Ìlò ìfikọ́ra kan fún àwọn ìkànnì ìró-ohùn  ni láti ṣàwárí àwọn akẹgbẹ́ láti gbà tàbí bá dòwòpọ̀ pẹ̀lú. Wọ́n le wá àwọn ìkànnì kan nípa ibi, èyí tí ó wúlò láti rí ẹgbẹ́ ní orílẹ̀-èdè mìíràn.

Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, níbí ni àwọn ohun-èèlò orí-ìtàkùn ayélujára”

HackPack ni wọ́n ṣe láti so àwọn aládàáṣe pọ̀, olùtúnṣe, àwọn àgbà ọ̀jẹ̀, àti àwọn agbéròyìn-jáde tuntun káàkiri àgbáyé. Ó tó ọmọ-ẹgbẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní àwọn orílẹ̀-èdè mọ́kàn-dín-láàdọ́sàn-án san owó tó gbúpọn láti ṣẹ̀dá púrófàìlì láti ṣàfihàn àwọn agbègbè ìdojúkọ, èdè, àwọn ìmọ̀ọ́ṣe, àti ìwàláàye.Pẹ̀lú ìṣẹ̀dá ìró-hùn ìtàn, HackPack ṣèlérí láti “mú èyí tó dàra jù ní gbogbo ọ̀ṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kí ó sì gbé wọn ga nínú Lẹ́tà-ìròyìn ÀTI fi wọ́n ránṣẹ́ sí onírúurú ilé-iṣẹ́-ìtẹ̀wéjáde.” Àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ ní ìráàyè-sí láti tẹ àtẹ̀ránṣẹ́ sí àwọn ìrújú tó níṣe pẹ̀lú iṣẹ́ tàbí àwọn àǹfààní mìíràn àti tí ó ṣeé lò láti ró-ohùn àwọn òye ìtàn. HackPack ṣagbátẹrù ìgbélárugẹ àwọn sẹminá.

Fún Àfikún lóri Ìfọ́nká, Ìgbéga, àti Ìdáṣe, wo Ìtọ́sọ́nà GIJN wa

Paydesk, ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ oníròyìn àdáṣe àti  olùtajà ori-ìtàkùn ayélujára ló ṣẹ̀dá rẹ̀, ó jẹ́ orí-ìkànnì tí wọ́n ti máa ń ti ń forúkọ sílẹ̀ láti ṣe nǹkan láti sopọ̀ mọ́ àgbéjáde ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde pẹ̀lú àwọn oníròyìn àdáṣe káàkiri àgbáyé àti pé wọ́n sọ ìsanwó dẹ̀rọ̀.Wọ́n ti pè é ní “Uber” fún àwọn oníròyìn. Paydesk wà fún ríran àwọn ilé-iṣẹ́ agbéròyìnjáde lọ́wọ́ látilẹ̀; sí bẹ́ẹ̀, àwọn oníròyìn fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú Paydesk le gbé àwọn ìró-ohùn sí orí-ìtàkùn ayélujára fún àwọn olóòtú àti àwọn olùdarí láti wò. Àwọn Olùrajà Ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde fi Èdè Gẹ̀ẹ́sì sí ìtẹ̀wéjáde jákè-jádò ayé gbogbo àti olùgbóhùnsáfẹ́fẹ́, lọ́pọ̀ ìgbà ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti “British”.

Pitchwhiz gbèrò láti ran àwọn aládàáṣe lọ́wọ́ rí àwọn olóòtú ìfiṣẹ́ṣe àti àwọn olóòtú láti rí àwọn aládàáṣe. Ìforúkọsílẹ̀ ní orí-ìtàkùn ayélujára pẹ̀lú àwòrán orí (gẹ́gẹ́ bí olóòtú, aládàáṣe, tàbí méjèèjì) jẹ́ ọ̀fẹ́. O lè wá a láti ara ìtẹ̀-ọ̀rọ̀ àti fún “àwọn ìtàn tí wọ́n fúnni” tàbí “àwọn ìtàn tí wọ́n fẹ́”. Orí-ìkànnì ayélujára tún sọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ dẹ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn olùforúkọsílẹ̀.

101Reporters, tẹ̀dó sí Bengaluru, India, “àwọn orísun ojúlówó ìtàn láti olùjábọ̀ ìpìlẹ̀ṣẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè, lẹ́yìn ìgbà yẹn ṣolóòtú àti tà wọ́n sí ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde jákè-jádò àgbáyé àti lórílẹ̀-èdè, gẹ́gẹ́ bí orí-ìtàkùn ayélujára rẹ̀ ṣe sọ.

Aládàáṣe Alámọ̀dájú, Lẹ́tà-ìròyìn tó tẹ̀dó sí ilẹ̀ UK, ṣe àwọn ìpè kan pàtó fún àwọn ohun èèlò. Olùsanwó ( E90 lọ́dọọdún) gba òye olùsèso olóòtú Anna Codrea-Rado.

Solutions Journalism Talent Network so àwọn oníròyìn pọ̀ mọ́ àwọn olóòtú. Tí Teh Solutions Journalism Network ṣe. Àwọn Olùjábọ fi àwọn àlàyé sílẹ̀ sínú fọ́ọ̀mù, àti àwọn àlàyé wọn ni wọ́n gbé sórí ìtàkùn fún àwọn olóòtú láti kà.

Ibi tí ó yẹ láti Kọ́ Nípa Ìsanwó

Ọ̀pọ̀ àwọn ìkànnì pèsè àlàyé lórí irú ìtẹ̀wéjáde tó sanwó. Àkójọpọ̀-ìmọ̀ ni wọ́n máa ń sábà pèsè láìlórúkọ àti àpẹẹrẹ ìwọ̀n kéré, nítorí èyí àwọn ìwọ̀n ìṣọ́ra le fi gbani ní mọ̀ràn.

Aládàáṣe nípa ìṣakóónú ní àlàyé tó níṣe pẹ̀lú  ọ̀nà ìsanwó ní èyí tó ju ọgọ́rùn-ún àtẹ̀jáde àti ìtẹ̀wéjáde ẹ̀rọ ayélujára, bí wọ́n ṣe jábọ̀ láìlórúkọ láti ọwọ́ àwọn aládàáṣe mìíràn. Ọ̀pọ̀ àwọn atẹ̀wéjáde jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà pẹ̀lú agbéròyìnjáde jákè-jádò àgbáyé díẹ̀, pẹ̀lú Haaretz, BBC, àti Guarduan.

Ta ló sanwó fún àwọn Òǹkọ̀wé? Ó tún jẹ́ àtẹ ọ̀fẹ́, elérò mìíràn, tí ọ̀pọ̀ òǹkọ̀wé aláìlórúkọ ṣàbójútó rẹ̀. Ọ̀nà Ìsanwó, irúfẹ́ iṣẹ́ àyànṣe àti ìgùn, àti ìyára owó-sísan ni wọ́n pèsè fún ẹgbẹ̀rún olùtẹ̀wéjáde, pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Olùgbéròyìnjáde ti US.

Àlàyé Aládàáṣe Asia tó ń pín ewé jẹ́ àtẹ orísun-elérò pẹ̀lú òsùwọ̀n fún bí olùtẹ̀wéjáde méjì-dín láàdọ́ta (dọ́sìnnì mẹ́rin) tí ṣàtẹ rẹ̀, pẹ̀lú àlàyé ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ olóòtú.

Study Hall jẹ́ àjọ ìfọmọ̀ẹgbẹ́-ṣe ìsanwó tó tẹ̀dó sí US fún àwọn aládàáṣe tó pèsè àkójọpọ̀-fáyẹ̀wò lórí òsùwọ̀n ìsanwó àti “listserv” láàárín àwọn ohun-èèlò mìíràn.

Àwọn Ohun-èèlò Journo, tí wọ́n dárúkọ lókè, ní àtẹ ìtẹ̀wéjáde tó gùn àti ohun tí wọ́n san.

Ẹgbẹ́ Oníròyìn Àdáṣe ti Àwọn Òṣìṣẹ́ Ilé-iṣẹ́ lágbàáyé ní “spreadsheet” lórí òsùwọ̀n, lọ́pọ̀ ìgbà fún ìtẹ̀wéjáde ti ilẹ̀ US.

Kókó pínpín àlàyé òsùwọ̀n ìsanwó ni wọ́n ṣàjọrò le ní Àtúnyẹ̀wò Átíkù Iṣẹ́-ìròyìn ti Colombia ti ọdún 2020 láti ọwọ́ Elizabeth King.

Élòó gan-an ni wọ́n ń san àwọn Òǹkọ̀wé Àdáṣe (Àti bí wọ́n ṣe lè fikún owo wọn), átíkù ọdún 2019 láti ọwọ́ Alexander Cordova, sọ̀rọ̀ sí òṣùwọ̀n ìsanwó àárín US.

Àwọn Ibi láti Rí Iṣẹ́ Ìwé-kíkọ Àdáṣe

Òǹkọ̀wé Àdáṣe ń pọ̀ sí láti rí àwọn ọ̀nà tó ní làákàyè láti ṣe é ní ètò ọrọ̀-ajé iṣẹ́.

Àti nígbà tí a kò gbọdọ̀ retí láti rí àwọn ìpolówó fún iṣẹ́-àkànṣe oníwàádìí, ọ̀pọ̀ oníròyìn oníwàádìí sọ pé àwọn iṣẹ́ aláìjẹ́-oníwàádìí ṣe pàtàkì láti ní àyè láti ṣè rànwọ́ fún ìwà ìbàjẹ́ jẹgúdújẹrá wọn.

Àtẹ tó wà nísàlẹ̀ (ní títò alábídí) jẹ́ ìṣápẹẹrẹ. Àwọn àbá fún àfikún káàbọ̀.

Fiverr jẹ́ ìkànnì ayélujára fún àwọn aládàáṣe àti ó ṣe ìgbélárugẹ fún àwọn ìsọ̀rí iṣẹ́ tó ju àádọ́tàá-lé-lúgba lọ, pẹ̀lú ìkọ̀wé àti ìwádìí.

FlexJobs bo ọ̀pọ̀ iṣẹ́-amọ̀dájú ṣùgbọ́n ó ní ìsọ̀rí tó níṣe pẹ̀lú ìkọ̀wé.

Aládàáṣe láti ọwọ́ Contently jẹ́ èyí tó wà fún àwọn òǹkọ̀wé àdáṣe ní pàtó àti láti wá láti sopọ̀ mọ́ àwọn òǹkọ̀wé tó ti forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn okòwò tó nílò ìmọ̀ọ́ṣe wọn.

FreelanceWriting.com bójútó àtẹ ojoojúmọ́ àwọn iṣẹ́ tó wà nílẹ̀

Guru ní ìsòrí fún kíkọ-ìwé àti ìṣè-túmọ̀-èdè.

Indeed lérí láti jẹ́ orí-ìtàkùn ayélujára fún iṣẹ́ àkọ́kọ́ lágbàáyé àti àwọn àtẹ ju ti iṣẹ́ àdáṣe lọ. Níbi yìí ni ìsọ̀rí fún “Òǹkọ̀wé Àdáṣe ìtàkùn-ayélujára.”

Upwork ní onírúurú ìsọ̀rí ìkọ̀wé, pẹ̀lú ìwádìí orí-ìtàkùn ayélujára àti iṣẹ́-ìròyìn àdáṣe, níbi tí wọ́n ti fúnni ní iṣẹ́.

World Fixer jẹ́ nẹ́tíwọ̀kì àgbáyé tó ń so ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde àkọ́kọ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ìwádìí àti iṣẹ́-ìròyìn àdáṣe níbi tí wọ́n ti fúnni ní àwọn iṣẹ́.

World Fixer jẹ́ nẹ́tíwọ̀kì àgbáyé tó ń so ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde àkọ́kọ́ pọ̀, ṣùgbọ́nn pẹ̀lú oníbàárà alájẹṣẹ́kù àti ti ìjọba, pẹ̀lú àwọn alámọ̀dájú abẹlé tí wọ́n le mú iṣẹ́ wọn dẹ̀rọ̀ jákè òkun. 

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *