Ìbádòwòpọ̀-ọ̀rẹ́ àti Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lórí iṣẹ́-àkànṣe aṣèwádìí jẹ́ gbajúgbajà síi lójojúmọ́.

Ṣíṣeṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú alábàáṣiṣẹ́ le ṣe àfikún àti ìrànlọ́wọ́ jíjábọ̀ ohun èlò àti ìgbéga ọ̀nà oǹkàwé. Le gba àwọn Ìmọ̀ọ́ṣe tó yàtọ̀, bí i ṣiṣe àtúpalẹ̀ déétà, ṣíṣẹ̀dá àwòrán rírí, tàbí gbígbáradì fún àwọn fọ́nrán ilé-iṣẹ́ tó pọ̀.

Ìdàgbàsókè lítíréṣọ̀ tó sàré wà lórí bí a ṣe lè ṣe ìwádìí aláfọwọ́sowọ́pọ̀ – bí a ṣe lè kọ́ òtítọ́, ṣẹ̀dá ìkànnì iṣẹ́, pín déétà, ṣàmójútó ìtẹ̀wéjáde, ṣadarí ọ̀rọ̀ ìran, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n díẹ̀ ni wọ́n ti kọ lórí ojú ọ̀nà-ìgbéyàwó àti bí wọ́n ṣe hun “ìgbéyàwó.”

Ní ohun èlò Ìtọ́nisọ́nà yìí, GIJN fojúsí àwọn àkórí tó níṣe pẹ̀lú:

 • Nígbà tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ jẹ́ èrò gidi?
 • Báwo ni a ṣe le rí Alábàárìn.
 • Báwo ni a ṣe le “kọnu si” Alábàárìn.
 • Ohun tí ó yẹ ká fi sí Àjọsọ.
 • Àwọn Ìṣubú ti a gbọ́dọ̀ máa wò lọ́nà.

Ní àfikún sí ìsọníṣókí ẹ̀kọ́ yìí tí a ti kọ́, ohun èlò yìí máa tọ́ ọ sọ́nà sí àwọn ohun èlò tó yẹ. Ọ̀pọ̀ èyí lọ sí igun tó ga jù, kì í ṣe lórí ọ̀rọ̀ ipele àkọ́kọ́ nìkan, ṣùgbọ́n lórí gbogbo àwọn ipele ti ìfọwọ́sowọ́pọ̀.

Fún Ìfọ́nká si, ìgbéga, àti Ìdáṣe, wo Ìtọ́nisọ́nà GIJN wa.

Nígbà tí àfojúsùn àkọ́kọ́ jẹ́ lórí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó pẹ̀lú àjọ ilé-iṣẹ́ ìròyìn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, a tún fọwọ́ kan àkójọpọ̀ àjọ ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti àjọ aláìṣe-tìjọba, tàbí àwọn NGO.

Bóyá Àkópọ̀ ìmọ̀ràn tó gbòòrò jù lórí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí Rachel Glickhouse ṣe fún ProPublica, ilé-agbára jíjábọ̀ ìròyìn aṣèwádìí ti US: Collaboratiẹe Data Journalism Guide. 

Nígbà tí Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ jẹ́ Èrò Gidi?

“Àwọn ìtàn kan wà tí ó kan tóbi jù fún ìgbéjáde ìròyìn kan láti kojú,” Bastian Obermayer kọ ọ́, ta ni, pẹ̀lú Frederik Obermaier, kó ipa tó jẹ́ kókó nínú breaking the Panama papers and Paradise Papers stories. Àwọn oníròyìn German pín àkójọ-ìmọ̀ tó lu síta pẹ̀lú Washington, àwọn ìtẹ̀dó-DC International Consortium for Investigative Journalists, èyí tí ó ti di orúkọ tó tóbi jù ní Iṣẹ́-ìròyìn Aláfọwọsowọ́pọ̀. Awakọ̀ kọkọ́rọ́ ti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti lọ láti lọ ṣàkóso àwọn ìròyìn tí ó kọjá ààlà.

Stefanie Murray, Olùdarí ti Center for Cooperative Media ní Unifásítì Montclair ti Ìpínlẹ̀ ní New Jersey, sọ pé ìdí máàrún tó wọ́pọ̀ tí iṣẹ́-àkànṣe aláfọwọ́sowọ́pọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ni:

 • Ìnáwó tó tóbi, bí i ètò ìdìbò, tí ó ń bọ̀ tí ó ní ẹ̀ka tó pọ̀ láti kó ìròyìn rẹ̀ jọ dáadáa láti ọwọ́ yàrá-ìròyin kan.
 • Ìdààmú ń dìde, tàbí ó ti ṣẹlẹ̀, bí i nínú ipò ṣíṣọ ìròyìn.
 • Yàrá-ìròyìn ní èrò kan fún àkórí ilé-iṣẹ́ tí ó mọ́pọlọ dání káàkiri yàrá-ìròyìn pẹ̀lú oríṣìíríṣìí olùwòran àti àwọn alámọ̀dájú.
 • Yàrá-ìròyìn ń ní wàhálà tí ó ń ha ìtàn fúnra rẹ̀ àti ó ro mímú àwọn oníròyìn tó le ṣe ìrànwọ́ wá si.
 • Yàrá-ìròyìn ti gba àwọn ohun-èlò àti owó-ìrànwọ́ (láti ṣe iṣẹ́-àkànṣe aláfọwọ́sowọ́pọ̀).

Wọ́n ṣàgbàsọ rẹ̀ ní ìtọ́nisọ́nà ProPublica orí Ǹjẹ́ Iṣẹ́-àkànṣe yìí mú ọ̀pọlọ dání fún Ìfọwọ́sowọ́pọ̀?

“Murray ṣe ìṣedúró pé nígbà tó bá ń ro Alábàáṣepọ̀, o máa fẹ́ kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò irúfẹ́ ìrànlọ́wọ́ tí yàrá-ìròyìn rẹ nílò láti ọwọ́ Àwọn Olùbádòwòpọ̀ tòtótọ́. O lè fẹ́ wá alábàáṣepọ̀ láti fún ibi tí kò lágbára ní yàrá-ìròyìn tirẹ ní okun. Ṣé o nílò àwọn oníròyìn sí i? Ìrànwọ́ láti ṣe àwọn ìbéèrè àkọssílẹ̀? Ṣé o nílò ìráàyè sí alámọ̀dájú bí àtúpalẹ̀ déétà? Ìmọ̀ọ́ṣe èdè tàbí ìráàyè sí agbègbè tí o ní wàhálà láti dé? Àbí o rí Ìbáṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ète ìkómọ́ra olùwòran àti pé ó ń wa láti wá ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú orísun tó ní ìròyìn tó tóbi jù tí o rí?”

Center for Cooperatiẹe Media náà ti ṣe àtẹ̀jáde àwọn ìtọ́nisọ́nà lórí àkórí mẹ́ta ìbádòwòpọ̀:

 • Budget and finance for journalism Collaborations, láti ọwọ́ Shady Grove Oliver.
 • Building new partnerships for journalism collaborations, láti ọwọ́ Heather Bryant.
 • Collaborating with non-news partners, láti ọwọ́ Heather Bryant.

Bí wọ́n ṣe le rí Alábàáṣepọ̀

Glickhouse’s “ìmọ̀ràn àkọ́kọ́ fún ìbádòwòpọ̀ àwọn alákọ̀ọ́kọ́ wá láti ọ̀pọ̀ alámọ̀dájú ní ààyè yìí ni pé ó le so èso sí iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀.” Ní ìtọ́nisọ́nà ProPublica orí How to Find and Approach Potential Partners, ó ṣe àfikún, “o ti gbìn ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìbánisọ̀rọ̀ báyẹn, èyí tí ó ṣe pàtàkì gan láti jẹ́ kí ìbádòwòpọ̀ ṣiṣẹ́.”

“Má retí olùbádòwòpọ̀ rẹ láti wá bá ọ,” gẹ́gẹ́ bí ìtalólobó àkọ́kọ́ nínú 10 Tips for Successful Collaboration among Journalists, átíkù GIJN tí àwọn olùbádòwòpọ̀ Guilherme Amado, Xin Feng, Titus Plattner, àti Mago Torres kọ ní ọdún 2018. Wọ́n fẹ̀ ẹ́ lójú:

“Má jẹ̀ ẹ́ kí èrò ìtàn gidi dọ́ta. Tí o bá ní ìròyìn tó níyelórí àti ìfiyèsí fún ìbádòwòpọ̀, dá alábàáṣepọ̀ mọ̀ kí o sì fi èso rẹ tó dára jù hàn wọ́n. Èyí gbọ́dọ̀ yára àti gbẹ̀fẹ́. Èyí le hàn bí kedere, ṣùgbọ́n a ri wí pé kíkàn síni ló jẹ́ ìgbésẹ̀ tó le jù fún àwọn oníròyìn bí i tiwa, tí ó máa ń sábà ṣiṣẹ́ bí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ aládàáṣe.”

Ìtalólobó kejì ni wọ́n pè ní “ Wá Alábàáṣepọ̀ rẹ tó dára jù.”

Alábàáṣepọ̀ rẹ tó dára jù kì í sábà ṣe ògbóntagìrì oníròyìn láti ìgbéjáde ilé-iṣẹ́ tó wà lókè. Ó lè jẹ́ ọ̀dọ́ oníròyìn láti yàrá-ìròyìn kékeré tàbí aládàáni onítara. Àwọn oníròyìn tó jẹ́ ọ̀dọ́ máa ń dára nígbà mìíràn ju olùbádòwòpọ̀ nítorí wọ́n máa ń sábà ní aapọn, ṣetán láti ṣiṣẹ́, látinúdá. Bí o bá ṣe ṣe pẹ̀lú orísun, ṣàwárí ìnífẹ̀ẹ̀sí rẹ tó wọ́pọ̀. Yẹ ìpìnlẹ̀ wọn wò àti àwọn ìwé wọn. Wá ẹni tí ìmọ̀ọ́ṣe rẹ̀ kò dà bí tìrẹ, ṣùgbọ́n tó báramu.

Fún wíwá alábàáṣepọ̀ titun, Glickhouse dábàá wíwádìí èyí tí àwọn oníròyìn àti ìgbéjáde ilé-iṣẹ́ ìròyìn ń ṣe iṣẹ́ gidi lórí rẹ̀ lórí kókó kan náà. Ó gbà wọ́n nímọ̀ràn àsopọ̀  ní ìpàgọ́ ilé-iṣẹ́.

Ó tún dábàá sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní Center for Cooperative Media fún ìmọ̀ràn, tàbí ṣíṣé àwòfín sí àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò ìbáṣiṣẹpọ̀ aṣèwádìí fún èrò. Ó tún mú èrò lórí ọ̀nà ìfikọ́ra wá láti rí àwọn alábàáṣepọ̀ tó dára jù, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé lórí àwọn ọ̀rẹ́ tó wọ́pọ̀, ímeèlì tútù, àti gbígbé fọ́nrán ìbọwọ́lu-wọlé sí i láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.

Yàtọ̀ sí àwọn alámọ̀dájú kókó-ọ̀rọ̀, àwọn ìmọ̀ọ́ṣe mìíràn náà ṣe pàtàkì, náà. Èyí níṣe pẹ̀lú ìrírí ṣíṣàmójútó ẹgbẹ́ iṣẹ́-ìròyìn, ìrírí ìṣàkóso iṣẹ́-àkànṣe, àti àwọn ìmọ̀ọ́ṣe iṣẹ́ àjùmọṣe tó dára.

“Ọ̀rọ̀ ìbáṣepọ̀,” Stefanie Murray kọ ọ́ ní ọdún 2018 ní átíkù Center for Cooperatiẹe Media, Ń ro Iṣẹ̀-àkànṣe Ìjábọ̀ ìròyìn alábàáṣepọ̀? Níbí ni àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́jọ láti iṣẹ́-àkànṣe mẹ́fà. Ó fẹ̀ ẹ́ lójú:

“Mú àwọn Alábàáṣepọ̀ bí ọ̀rẹ́ rẹ,  bí o bá lè ṣe é – ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́ lámèyítọ́. Àti pé lílè sọ̀rọ̀ láìtijú, rẹ́rìn nígbà mìíràn, kí o sì gbádùn iṣẹ́ máa mú ìgbẹ̀yìn iṣẹ́ dára. ‘Mo lérò pé ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ tó ṣe kókó ní iyì ìbáṣepọ̀ iṣẹ́ tó lágbára láàárín àwọn àjọ alábàáṣepọ̀,’ Laura Lee, olóòtú ti Education NC, sọ fún wa.”  

Àwọn adarí fún ìbádòwòpọ̀ “lo oríṣìíríṣìí ìlànà fún ìgbaniwọlé, ìbáraẹnoisọ̀rọ̀ pẹ̀lú, ìṣàkóso, àti bíbójútó ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú iṣẹ́ wọn,” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ẹjọ́ lórí iṣẹ́-ìròyìn ìbádòwòpọ̀ ìbílẹ̀, láti ọwọ́ Joy Jenkins àti Lucas Graves ti Reuters Institute for the Study of Journalism ní Oxford (2019).

Nóòtì kan tó dùn lórí yíyan alábàáṣepọ̀ wáyé ní Global Investigative Journalism Conference ti 2019 ní Hamburg. Nígbà mìíràn, wọ́n mú àwọn alábàáṣepọ̀ “láàárín ọ̀nà láti ara ìwádìí, gẹ́gẹ́ bí ìnílò ìjábọ̀ bá ń rú sókè.” Àtẹ̀ránṣẹ́ yìí wá láti ọwọ́ Axel Gordh Humlesjo, olùjábọ̀ pẹ̀lú Olùgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Sweden’s SVT, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàpèjúwe ní átíkù GIJN láti ọwọ́ Rowan Philp. Humlesjo sọ síwájú si:

Ohun tó tóbi jù tí mo kọ́ lórí ìbádòwòpọ̀ ni: ta ni o nílò láti ṣe àṣeyọrí; ta ni o kò nílò? Nígbà tí o bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ohun tó ṣe pàtàkì bá lu síta láti United Nations àti àwọn orísun ní Congo tí wọ́n lè pa ní ìṣẹ́jú tó wù wọ́n, ó ṣe pàtàkì pé a ni alábàáṣepọ̀ tí a lè wò lójú tí a sì lè gbẹ́kẹ̀lé. A fìwé pe Ìwé-ìròyìn Ìlànà Àjòjì ní àárín iṣẹ́-àkànṣe nítorí wọ́n ṣàkíyèsí pé a nílò ẹnìkan tó wà nílẹ̀ ní New York pẹ̀lú nọ́ḿbà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ UN tó dára, àti ẹni tí ó lè ṣe igun yẹn sílẹ̀.”

Ìtọ́nisọ́nà mìíràn láti Bureau of Investigative Journalismní UK, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọ́fíìsì ìbílẹ̀ láti gba àwọn ọmọ ìlú tó lọ́wọ́ níbẹ̀ níyànjú, rán wa létí pé ìbádòwòpọ̀ le ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn yàtọ̀ sí àwọn oníròyìn:

“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, Ìbádòwòpọ̀ jẹ́ ìdíje tuntun. Ní orí ìkànnì ayélujára wa, oníkóòdù ran àwọn oníròyìn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀; àwọn olùdárà kọ́ àwọn àmúṣàwòrán fún yàrá-ìròyìn; àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ ti àwùjọ pèsè ìròyìn; àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ mú àwọn nọ́ḿbà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wá wájú àti ìmọ̀ ará inú-ilé; àwọn oníròyìn pín ohun èlò, àyọlò àti àwọn ìwádìí.”

Síwájú sí Sàlẹ̀ Òpópónà

Yíyan Alábàáṣepọ̀ jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀.

Ìmọ̀ràn nípa ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ fún ṣíṣètò ìbádòwòpọ̀ ní àwọn ìbáramu kan sí ìgbésẹ̀ yíyàn. Ègbè tó wọ́pọ̀ jù ni ìnílò láti dá ìgbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀. Níbi yìí ni àwọn ohun èlò tó yẹ kan:

 • Tún orí àwọn Ìbáṣiṣẹ́pọ̀ tí wọ́n ń dá sílẹ̀ yẹ̀wò àti àwọn Adéhùn, MOUs àti àwọn Ìbámu Àìgbẹ̀fẹ́ ní ìtọ́nisọ́nà ProPublica.
 • Ka àwọn ìtalólobó 3-10 láti átìkù tí wọ́n sọ lókè, 10 Tips for Successful Collaboration among Journalists. 
 • Ka ríro Iṣẹ́-àkànṣe Jíjábọ̀ Ibádòwòpọ̀? Níbí ni ẹ̀kọ́ mẹ́jọ láti iṣẹ́-àkanṣe mẹ́fà láti ọwọ́ Stefanie Murray. 

Àwọn ohun èlò láti ṣàwárí mìíràn, pẹ̀lú àfikún lórí ẹ̀kọ́ láti iṣẹ́ àtẹ̀yìnwá, àpẹẹrẹ ìbádówòpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.:

 • “Iṣẹ́-àjùmọṣe Agbàáyé: The Rise of Collaboration in Investigative Journalism, ìwé 2018 (ẹ̀rọ ayélujára) tí Richard Sambrook ṣe olóòtú rẹ̀ àti àtẹ̀jáde láti ọwọ́ Reuters Institute for the Study of Journalism. Orí karùn-ún, tí Olùdarí ètò Anne Koch ti GIJN, bo Bí Àwọn Oníròyìn, àwọn NGO ṣe lè – & gbọdọ̀ – fọwọ́sowọ́pọ̀.
 • “Iṣẹ́-Ìròyìn Ìbádòwòpọ̀ Ìsọdá-Ààlà: Ìtọ́nisọ́nà Ìgbésẹ̀- ní-ìgbésẹ̀,” ìwé 2019 láti ọwọ́ Brigitte Alfter.
 • The Center for Cooperatiẹe Media tó tẹ̀dó sí Ilé-ẹ̀kọ́ Gíga Ifáfitì Ìpínlẹ̀ Montclair ti Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti Ilé-iṣẹ́ Ìròyìn ní onírúurú ohun èlò lórí ìtàkùn ayélujára rẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú: Àkójọpọ̀ àwọn ìtọ́nisọ́nà, ewé Ìtalólobó, àti Ìfikọ́ra tó dára jù fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti Àkójọpọ̀-fáyẹ̀wò Iṣẹ́-ìròyìn Ìbádòwòpọ̀.
 • Ìwé-iṣẹ́ Iṣẹ́-ìròyìn Ìbádòwòpọ̀ láti ọwọ́ Iṣẹ́-àkànṣe Facet.
 • Ìbádòwòpọ̀ àti Ìṣẹ̀dá Iṣẹ́-ìròyìn tó wọ́pọ̀ titun, ìjábọ̀ tó jinlẹ̀ láti ọwọ́ Carlos Martinez de la Serna, akẹgbẹ́ ní Tow Center for Digital Journalism àti oníròyìn àti olùwádìí tí ó tẹ̀dó sí ìlú New York.
 • Iṣẹ́-àkànṣe Ìbádòwòpọ̀ Pegasus ṣe àfikún àwọn ewu fún ìjẹgúdújẹra àwọn olùjábọ̀.