Ìṣèdáṣe: Àwọ̀n Ìkànnì tí ó máa ń mówó wọlé fún àwọn òǹkọ̀wé 

Onírúurú ìkànnì tí ìdàgbàsókè ti débá ló wà tí ó ń ran àwọn òǹkọ̀wé lọ́wọ́la ti owó nípaṣè ìgbéjáde-ara-ẹni. Yàlá àwọn wọ̀nyí tọ̀nà fún ọ èyí yóò gbà ìwádìí.

Ní abala yìí, a kò ṣàkitiyan láti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbègbè tí ó ṣèrànwọ́ láti ṣẹ̀dá àwọn ìtàkùn-àgbáyé, àwọn lẹ́tà-onìròyìn àti àwọn búlọ̀ọ̀gì, tàbí bíbẹjú wo àwọn ìtàkùn mìíràn tí ó gba ìtajà àti ìfowórètò. Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbìnyànjú láti wọ àwọn ìkànnì ayélujára bi i “Telegram, Facebook, Reddit àti WhatsApp”.

Ìdàgbàsókè mímọ ìṣẹ̀dá àwọn àtẹ̀jàde àtẹ̀ránṣẹ́-ẹ̀rọ àdáwàni wọ́n ṣàpèjúwe nínú átíkù New York Times ní oṣù keje ọdún 2020, àti òmíràn ní Axios, àti ẹ̀kẹta nínú Medium láti ọwọ́ Media Consultant Mark Glaser.  

Ní abala mìíràn, a ṣàlàyé nipa ìfàmìhàn nípa àwọn ilé-iṣẹ́ orí-ìtàkùn tó làmìlaka bí i Apple News+ àti SmartNews, tí àwọn àwọn aládàáṣe kò ní àǹfààní sí. 

Fún àfikún Àlàyé lórí Ìfọ́nká, Ìgbéga, àti Ìṣedáṣe, wo Ìtọ́sọ́nà GIJN wa.

Ṣíṣefọ̀ǹká ètò pọ́díkààstì jẹ́ ìdojúkọ mìíràn. Àwọn àbá ni wọ́n ṣàfihan wọn nínu àtẹ̀ránṣẹ́, 22 Top Networks to Submit Your Podcast ní ọdún 2020, láti ọwọ́ Robert Katai tó jẹ́ àgbà-ọ̀jẹ̀ nínú ètò-ìtajà ní orílẹ̀-èdè US.

Àwọn èrò àgbéjáde tuntun ni ó peléke si. Èyí jẹ́ àyè tó ní àbùdá lóríṣìíríṣìí, torí náà ó gba ọgbọ́n láti ṣèwádìí lórí àwọn èrò rẹ. Ibì kan tí ó yẹ kí á máa ṣàbẹ̀wò sí ni “Blogging Guide” láti ọwọ́ Casey Botticello.

Àwọn Ìkànnì láti mú àwọn ìtàn rẹ lówó lorí

Medium

Ìkànnì yìí, bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2012, a sì gbọ́ wí pé ó ti ń ni àwọn àlejo ọgọ́fà mílíọ̀nù lóṣooṣù àti wí pé ó jẹ́ ibi tí “olúkùlùkù ti ń ní ìtàn láti fi sṣọwọ́ tí a sì fi èyí tí ó dára jù níbẹ̀ ṣọwọ́ sí ọ.”

“Nípa ṣíṣẹ̀da àkáùntì ọ́fẹ́, o le tẹ̀lẹ́ àwọn òǹkọ̀wé tó fẹ́ràn jù àti àwọn àgbéjáde, kópa nínú ìtàn wọn, tọ́jú wọn fún ọjọ́ iwájú, ṣàgbéjáde àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ tìrẹ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ,” gẹ́gẹ́ bí abala “Getting Started ti Medium”. “Ṣíṣe àgbéjáde lóri Medium jẹ́ ọ̀fẹ́ àti pé wọ́n le fọ́n àwọn ìtàn tí o bá ṣàgbéjáde ká sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ, àti pàápáá jù lọ àwọn òǹkàwé ogunlọ́gọ̀ mílíọ̀nù tí ó tẹ̀lé àwọn àkórí tó ṣe pàtàkì.”

Medium máa ń rí owó lórí ìfowórètò fún $5/ lóṣù tàbí $50/lọ́dún, o le dárapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ Medium láti rí àǹfààní tí kò lódìwọ̀n sí gbogbo àwọn ìtàn orí Medium àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn Olùfowórètò orí Medium le tẹ̀lé àwọn òǹkọ̀wé àti “àwọn àgbéjáde” tí wọ́n gba ìtọ́sọ́nà láti ọwọ́ àwọn Aṣẹ̀dá wọn. (Smedian máa ń tẹ̀lé bẹ́ẹ̀ ó máa ń fún àwọn àgbéjáde tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ní ipò.) bákan náà, Medium máa ń tọ́ àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ sọ́nà àti pé wọ́n máa ń mú ìdàgbàsókè bá wọn nípa “Àwọn Àkòrí”.

“Àwọn Aṣẹ̀dá” Àkóónú le gba owó fún iṣẹ́ wọn. Fún ìfáàrà Medium , bẹ̀rẹ̀ níhìn-ín. Wọ́n máa ń rí owó nípa Ètò Ìbádowòpọ̀ Medium. Níhìn-ín ni Àtẹ̀ránṣẹ́ búlọ̀ọ̀gì Alálàyé ti Meium. Àti èyí: Pàdé Medium “Àwọn Àtẹ̀gùn” ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olóòtú méjì ní Medium.

“Nígbà tí ètò ìbádòwòpọ̀ jẹ́ èèrè tó ga jù fún àwọn ènìyàn làti ṣàgbéjáde lórí Medium, kí àwọn aládàáṣe má ni lérò láti di olówó,” Aládàáṣe Tallie Gabriel ló kọ ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018, ní ṣíṣe àlàyé bí “àwọn àtẹ̀wọ́” ṣe di owó. Ó gbaniníyàjú: 

“Láti láṣẹ lórí iṣẹ́ ara ẹni, kí àwọn aládàáṣe ro ṣíṣe àmúlò Medium gẹ́gẹ́ bí ìkànnì sẹ́kọ́dìrì tí ó ń tọ́ àwọn òǹkọ̀wé sí orí-ìtàkùn ayélujára ara-ẹni. ṣàgbéjáde àtẹ̀ránṣẹ́ lórí búlọ̀ọ̀gì rẹ kí o ṣì ṣe ìtúngbéjáde rẹ̀ lòrí Medium láti rí àwọn àyẹ̀wò si, pẹ̀lú ẹnà tó ṣeé fọwọ́ bà sí ìkànnì àti léta-oníròyìn tí wọ́n so mọ́ ọ sí òpin rẹ̀”.

Ní osù kìíní ọdún 2020, Medium jábọ̀ pé ìwọ̀n méjì-láàdọ́rin nínú ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún àwọn òǹkọ̀wé tí wọn kọ ó kéré tán ìtàn kan fún àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ rí owó. Ó sọ pé ìwọn mẹ̀jọ nínu ọgọ́rùn-ún tó múra sí iṣẹ́ rí ju $100 lọ, pé $21,650.88 ni owó tí òǹkọ̀wé kan rí jù, àti pé $8,855.73 ni owó tí wọ́n rí jù lórí ìtàn kan  ṣoṣo.

Fún ìmọ̀ràn sí i lórí Àgbéjáde lórí Medium, ẹ wo:

Medium àti WordPress – bí a ṣe le yan ìkànnì tó tọ̀nà? Ọ̀rínkínníwín ìjíròrò àti àfiwé láti ọdún 2020 lórí búlọ̀ọ̀gì WinningWP.

Àgbéjáde mẹ́wàá tó dára jù lóri Medium láti kọ ìwé lé lórí ní ọdún 2020, ní èyí tí olùdásí dédé Medium tí a mọ̀ sí Tom Kuegler jíròrò lórí bí a ṣe le bẹ̀rẹ̀ àwọn “Àgbéjáde” nínú Medium.

Ǹjẹ́ mo lè pawó lórí Medium bí? Átíkù ọdún 2019 láti ọwọ́ Aládàáṣe J.J. Pryor tí ó ń dáhùn ní àgbágbè.

Bí a ṣe le rí owó lóri Medium – bí mo ṣe rí ju $1,000+ nìpa kíkọ ìwé lóri Medium, átíkù ọdún 2020 nínú “This Online World”.

Bí a ṣe le rówó lórí Medium: ìtọ́sọ́nà tó kún fún àwọn alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, átíkù ọdún 2020 láti ọwọ́ Shane Dayton nínú NichePursuits.

Ìtálolóbó méje fún ìdàgbàsókè Medium láti àwọn átíkù rẹ jẹ́ ìlúmọ̀ọ́kà, átíkù ọdún 2018 kan láti ọwọ́ Larry Kim nínú “The Wordstream Blog”, àti átíkù rẹ̀ ní ọdún 2019, 4 Super-Effectiẹe Content Syndication Strategies for Bloggers, tí ó ní àkóónú ìdí mẹ́wàá láti lo Medium.

Ohun ṣíṣe àti àìgbọdọ̀ṣe ti iṣàtẹ̀jáde lórí Medium.com láti ọwọ́ Manifest.com ní ọdún 2018.

Àwọn èsì ìdánwò-ráḿpẹ́: ìṣàtẹ̀jáde lóri Medium àti LinkedIn àti Búlọ̀ọ̀gì Tara-ẹni. Átíkù ọdún 2018 kan láti ọwọ́ Rish Tucker.

Substack

Substack wàhálà ìrọ̀rùn ti bíbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà oníròyìn ọ̀fẹ́ àti rírí owó. “kò sí ìbéèrè fún ìmọ̀ọ́ṣe ẹ̀rọ: kàn sopọ̀ mọ́ àkáùntì ilé-ìfowópamọ́ àti ṣàgbékalẹ̀ iye,” orí-ìkànnì ayélujára ló sọ bẹ́ẹ̀.

Substack gba ìdá mẹ́wàá nínú ìwọn ọgọ́rùn-ún ti ìsanwó fún ètò pẹ̀lú káàdì ìgbowó ti 2.9% pẹ̀lú sẹ́ẹ̀ntí ọgbọ̀n fún ìṣanwó kan. Àwọn Òǹkọ̀wé tí wọ́n yàn láti fi àkóónú wọn pa owó le lo Substack fún ọ̀fẹ́.

Ìkànnì náà sọ pé ogunlọ́gọ̀ mílíọ̀nù àwọn òǹkàwé tó jáfáfá ló wà káàkiri Substack àti àwọn olùfowórètò tó ju 250,000 lówà.

Láti Oṣù keje ní ọdún 2020, Substack ti ń sefilọ́lẹ̀ ètò ìrànwọ́ abófinmu nípa ṣíṣàmúlò àwọn agbẹjọ́rò ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbéròyìn-jáde láti pèsè ìmọ̀ràn ọ̀fẹ́ àti ìtọ́sọ́nà fún àwọn òǹkọ̀wé, gẹ́gẹ́ bí Ìgbésíkànnì Búlọ̀ọ̀gì Substack. Ó tún bẹ̀rẹ̀ ètò ìdàpọ̀-ọ̀rẹ́. Substack tún ran ìfowórètò Pọ́díkáàstì lọ́wọ́.

Ní oṣù kaàrún yìí lọ́dún 2020, átíkù Kí ló kàn fún àwọn Oníròyìn?, Olùṣẹ̀dá Substack Hamish Mckenzie kọ nípa kíkọ orí-ire ètò-ìsúná ti iṣẹ́-ìròyìn, ó sì sọ pé, “A ń gbìyànjú láti kọ́ ọrọ̀-ajé ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbéròyìn-jáde mìíràn tí ó fún àwọn oníròyìn ní òmìnira ara-ẹni.

Patreon

Tẹ̀dó sí San Francisco, Patreon bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2014 láti ṣẹ̀dá ìkànnì fún “ìbánirajà ní ayé ẹ̀rọ ayélujára”. “Àwọn Aṣẹ̀dá” Patreon lo ìlànà ìsanwó ìfówórètò. Ìfisọrí bíi àfikún àkóónú tàbí ìràáyè sí tó dá yàtọ̀ le wà.

Ní ìparí ọdún 2019, Patreon lo àwọn olùṣẹ̀dá tó ju 100,000 lọ, tí àwọn Pétírọ̀nù tó ju mílíọ̀nù mẹ́ta ran lọ́wọ́. Ó ń retí láti sanwó fún àwọn olùṣẹ̀dá ni bílíọ̀nù dọ́là kan ní ọdún 2019. Kọ́ si i nípa bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ níbí àti níbí.

Àwọn àtúngbéyẹ̀wò kan, sábà jẹ rere, ṣàyẹ̀wò èyí ní Writer’s Edit, Merchant Maverick, àti VentureBeat. Àwọn ìdènà àkóónú kán wà, ṣùgbọ́n kì í ṣe kí ìkan kóbá iṣẹ́-ìròyìn oníwàádìí tó kójú òṣùwọ̀n. Owó tí wọ́n rí máa ń yàtọ̀ dáadáa. Graphreon wádìí gbogbo àwọn tó ń rówó ní Patreon.

TinyLetter

TinyLetter jẹ́ “iṣẹ́ lẹ́tà-ìròyìn ara-ẹni tí wọ́n mú wà sí ọ nípaṣè àwọn ènìyàn tó wà lẹ́yìn Mailchimp”. Ó jẹ́ ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n lódìwọ̀n sí àwọn olùfowórètò ẹgbẹ̀rún márùn-ún.

Ko-fi

Ko-fi ran àwọn olùṣẹ̀dá lọ́wọ́ nípaṣẹ̀ oríṣìíríṣìí ìrànlọ́wọ́ owó tán gbà, tí ó hàn gedegbe pé “ra kọ́ọ̀pù kọfí kan fún mi”. Ko-fi kì í ṣáye owó kankan léni. Ìsanwó lọ sínú àkáùǹtì “Paypal tàbí Stripe”. Fún dọ́là mẹ́fà lóṣù, ipele “Wúrà” fúnni ní àwọn àbùdá mìíràn, bí i èrò ìfòwórètò.

Ìtẹ̀jáde Kindle Direct 

Ìtẹ̀jáde Kindle Direct máa ń ṣiṣẹ́ kíákíá, ìtẹ̀jáde ọ̀fẹ́ fún àwọn ìwé-ẹ̀rọ àti èpo-ẹ̀yìn-ìwé. Ó gba àwọn òǹkọ̀wé láyè láti rí ẹ̀tọ́ wọn gbà pada àti kí wọ́n rí ẹ̀tọ́-ọba. Títẹ̀jáde wà ní ìbéèrè-fún àti ìfọ́nká látara Amazon. Wo ojú-ìwé “Getting Started” yìí. Sí bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ láti wò wáà. Àtúngbéyẹ̀wò ọdún 2019 yìí láti ọwọ́ Doris Booth nínú Àwọn Òǹkọ̀wé àti Àwọn Òǹkàwé fọwọ́tọ́ ọ̀pọ̀, pẹ̀lú àwọn òdìwọ̀n lóri àwọn èrò ìṣọdituntun àti àwọn kókó tó dára lójú ti èrò aládé. Tún wo átíkù ọdún 2020 yìí ní ìṣàtẹ̀jáde Ìmọ̀ràn nìkan nípa Ètò Ìmúni ti KDP, ní èyí tí o ní owó-ìrànwọ́ sí ọ̀pọ̀ ẹ̀tọ́ sí Amazon. Ọ̀pọ̀ ìfèsì-sí ló wà àti èyí tí ó ní ọ̀rínkínníwín àlàyé lórí bí wọ́n ṣe ṣé níbẹ̀, pẹ̀lú.

Àwọn Èrò Mìíràn

Gbígbé e sí ibòmìíràn le fẹ ìrọ́wọ́sí rẹ lójú àti kí ó sì mú àwọn òǹkàwé titun. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ìkànnì bí i Authory, BuzzFeed Community, LinkedIn, àti Muckrack tí ó le ṣèrànwọ́ pínpín iṣẹ́ rẹ ká.

Ṣùgbọ́n èyí kò pé, àti pé ọ̀pọ̀ àwọn èwu ìṣòwò ló wà, pẹ̀lúpẹ̀lú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ díẹ̀ sí orí ìkànnì ìtẹ̀jáde tìrẹ. Ẹ̀rọ Gúgù wá le mú àwọn òǹkàwé láti lo ìkànnì ààmì-kóòdù ju tìrẹ lọ. Sí bẹ́ẹ̀, àwọn àgbà-ọ̀jẹ̀ gbani nímọ̀ràn pé ìfaragbá yìí le dínkù.

Fún ìjíròrò ọ̀rọ̀ yìí, ka “Do’s and Don’ts of Re-publishing Content on Medium or LinkedIn”, átíkù kan láti ọwọ́ Carolyn Edgecomb ti Impact. Edgecomb pẹ̀lú àwọn àbá, bí i bí o ṣe lè pẹ̀lú kóòdù ti kékeré láti sọ fún Gúgù láti fún un ní gbogbo ògo fún ọ àti láti má to àwọn átíkù lórí ìtàkùn àgbáyé ti ìta.

Tún wo:

  • Medium Article Canonical Links láti ọwọ́ Casey Botticello
  • What Is Content Syndication & How Does It Impact SEO? Láti ọwọ́ Maddy Osman ní Partfinder SEO

Káàkiri Àgbáyé

Ọ̀pọ̀ àwọn ìkànnì ló tún wà káàkiri àgbáyé tí o le ṣàgbékalẹ̀ àwọn àǹfààní. Ran GIJN lọ́wọ́ láti ṣètò àtẹ àwọn ohun-èèlò ìtẹ̀jáde-ara-ẹni láti fífi àwọn ìtalólobó ránṣẹ́ sí wa níbi.