Bíbẹ̀rẹ̀ lórí ìwé
Padà sí orí ìkànnì ojú ewé iwájú
Русский | Türkçe
Iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ dátà máa ń ní àkọ̀rí. Ojú ewé GIJN máa ń ní àwọn ohun èlò lóòrè kóòrè.
Ní ibi ìpàdé Àpérò GIJN 19 to wáyé ní ìlú Hamburg, àwọn olùkópa ní àǹfààní sí àwọn àgbékalẹ̀ lóríṣiríṣi: Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ dátà láti ipele ìgbàlódé kọ̀ǹpútà kan sí òmíràn láti ọwọ́ Sarah Cohen, ti ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Arizona; Brant Houston, ti ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Illinois àti Jennifer LaFleur, tíí tí ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Amẹ́ríkà.
Bákannáà, ní GIJC19, Ọ̀jọ̀gbọ́n ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Columbia kan, ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìròyìn, Giannina Segini ṣàlàyé lọ́dún 2019 bí wọ́n ṣe gba Àmìn Ẹ̀yẹ lórí iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ dátà àti ọ̀nà tí wọ́n gbà fi ṣe àṣeyọrí ọ̀hún: Ọdún Àwọn Òkú, Ìlera àti Ìwà Ọ̀daràn.
Tí ẹ bá fẹ́ mọ̀ sí nípa iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ dátà, yẹ àwọn ìwé wọ̀nyí wò, èyí tó wá láti ọwọ́ àwọn ògbọ́ǹtarìgì lórí Ìròyìn tó jọ mọ́ dátà ní àgbáyé, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ọ̀fẹ́ ni lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Ìwé Àkọmọ̀mà lórí Ìròyìn tó jọ mọ́ Dátà
(Lẹ́yìn ọdún 2017) kún fún kìkì ohun èlò àti atọ́ka fún yàrá ìkóròyìn jọ tí wọ́n fẹ́ máa ṣe àmúlò ìròyìn tó jọ mọ́ dátà láti ọwọ́ Kuang Keng Kuek Ser fún àjọ Media Development Investment Fund (Ọ̀fẹ́ ni PDF rẹ̀).
Ìwé atọ́nà fún àwọn oníròyìn tó fẹ́ ní ìmọ̀ si nípa iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ Dátà (2016) láti ọwọ́ akọ̀ròyìn kan tó fi ìlú Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé, Jonathan Stray ṣe àgbékalẹ̀ ọgbọ́n àtinúdá tí a lè lò láti fi ronú nípa dátà: “Èyí kìí ṣe bí a ṣe lè lo dátà nìkan ṣùgbọ́n bí a ṣe lè ‘ṣùgbọ́n bí dátà ṣe lè ṣiṣẹ́.'”
Dátà fún Àwọn Akọ̀ròyìn: Ìwé atọ́ni sónà fún lílo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà láti fi kó ìròyìn jọ (Ìpín kárun, Ọdún 2018) láti ọwọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa iṣẹ́ ìròyìn kan tó fi ìlú Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé, Brant Houston. Ìwé náà kún fún ìgbésẹ̀ tó yẹ láti tẹ̀lé lọ́kan ò jọ̀kan láti yàn nà ná dátà pẹ̀lú àwọn èyí tí a yóò fi dára yá. (Ó wà fún títà).
Ìwé atọ́nà fún iṣẹ́ akọ̀ròyìn tó jọ mọ́ dátà Kejì (2019) Àtúntẹ̀ àti àmúlò láti inú ìwé atọ́nà fún iṣẹ́ akọ̀ròyìn (2012). Àwọn méjèèjì ló pèsè àwọn ohun èlò tó gíríkì.
Jonathan Gray àti Liliana Bounegru ti ẹ̀ka láàbù dátà gbo gbo gbọ̀ ló ṣe àtúntọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àfikún láti ọwọ́ àwọn oníròyìn tó jọ mọ́ dátà ní Úróòpù. Ó tún wà ní èdè Lárúbáwá (PDF), Azerbaijani, Chinese, Gẹ̀ẹ́sì (PDF), Faransé , Greek, Japanese, Russian, Spanish àti Ukrainian)
Akọ̀ròyìn tó jọ mọ́ Dátà (2017) pèsè àfihàn lórí iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ dátà láti ọwọ́ àwọn ògbọ́ǹtarìgì oníròyìn ilẹ̀ Canada méjì, Fred Vallance-Jones àti David Mckie, tí kò sì yọ ètò ìkọ́ni lórí ẹ̀rọ ayélujára sílẹ̀ (Ó wà fún títà).
Kíkọ́ ẹ̀kọ́ lórí Dátà: Ìtọ́ni Sọ́nà
(2015) láti ọwọ́ onímọ̀ nípa iṣẹ́ akọ̀ròyìn tó jọ mọ́ dátà, èyí tó fi ìlú Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé, Ọ̀jọ̀gbọ́n David Herzog pèsè ìgbésẹ̀ lọ́kan ò jọ̀kan lórí pàtàkì dátà fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Èyí kò yọ gbígbá dátà, ṣe àyẹ̀wò, ṣe àfọ̀mó, and ṣe Àtúpalẹ̀ àti fífi ojú inú wo ìwúlò dátà.”) Ó wà fún títà)
Òtítọ́ ṣọ̀wọ́n láti ọwọ́ Akọ̀ròyìn tẹ́lẹ̀ rí fún ìwé ìròyìn Guardian, Simon Rogers mú wá sí ìrántí àwọn ménigbàgbé ìròyìn lórí ẹ̀rọ ayélujára ìwé ìròyìn Guardian. Òpó ìwé ọ̀hún rèé láti ọwọ́ La Nacion ní èdè Spanish.
Bíbẹ̀rẹ̀ Ìròyìn tó jọ mọ́ Dátà jẹ́ ìwé atọ́nà tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 2018 láti ọwọ́ Lawrence Marzouk, tó jẹ́ Olóòtú ìwé ìròyìn tó jọ mọ́ iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn ti ìkànnì Balkan, ìlú Albania àti oníṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn, Crina Boros. Èròǹgbà ìwé yìí ni láti ṣe àfihàn ọgbọ́n àtinúdá tó wà nínú ìròyìn tó jọ mọ́ dátà àti àwọn ohun tó ṣe pàtàkì láti mọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn àkòrí tó ṣíwájú dá lori gbígbá dátà fún àwọn akọ̀ròyìn ìlú Albania ṣùgbọ́n àwọn tó kú ṣe atọ́nà fún àwọn ìpẹ́ẹ́ẹ̀rẹ́ oníròyìn.
Bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìròyìn tó jọ mọ́ dátà (2016) láti ọwọ́ akọ̀ròyìn kan tó fi ìlú UK ṣe ibùgbé, Claire Miller ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìlànà fún àwọn ìpẹ́ẹ́ẹ̀rẹ́ oníròyìn tó jọ mọ́ dátà, tí kò sì yọ àwọn dátà oníṣẹ́ ìwádìí, ṣíṣe àfọ̀mọ́ dátà àti láti wá ìròyìn tó jọ mọ́ dátà bákannáà. (Ó wà fún títà)
Bí ó ṣe lè ṣe ayédèrú pẹ̀lú ìṣirò láti ọwọ́ Darrel Huff èyí tó sọ ìtàn lórí bí a ṣe lè ṣe ayédèrú nọ́mbà, èyí tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní ọdún 1954, àwọn ẹ̀kọ́ tó rọ̀ mọ́ ṣí wà títí di òní yìí. (Ó wà fún títà)
John Allen Paulos, jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Temple, ó sì ti kọ onírúurú ìwé pẹ̀lú àìmọye ìwé àlàyé lórí lílọ nọ́mbà ní àwùjọ àti nínú ìròyìn. (Ó wà fún títà)
Manual de Periodismo de datos iberoamericano es un proyecto gratuito y abierto, escrito de forma voluntaria por decenas de periodistas, programadores y diseñadores de medios de comunicación y organizaciones de Latinoamérica, España y Portugal. Èyí jẹ́ àkànṣe iṣẹ́ ọ̀fẹ́ tó wà fún ogunlọ́gọ̀ àwọn akọ̀ròyìn, àwọn onímọ̀ nípa nọ́mbà, àwọn oníròyìn tí wọ́n ń lo ọgbọ́n orí lórí ìròyìn àti àwọn ilé iṣẹ́ Latin America, Spain àti Portugal.
Nọ́mbà Nínú Yàrá Ìkóròyìn jọ (2014) jẹ́ ìwé atọ́nà tó wà fún Kíkọ àti lilo nọ́mbà láti inú Àwọn Akọ̀ròyìn àti àwọn Olóoòótú ìròyìn tó jọ mọ́ iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn tó tẹ̀lé ará wọn. Oníròyìn kan tó fi ìlú Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé, Sarah Cohen ló kọ ìwé ọ̀hún. Ìwé atọ́nà yìí yóò wúlò fún ẹnikẹ́ni tó bá yan ìròyìn tó jọ mọ́ nọ́mbà láàyò. (Ó wà fún títà)
Ìròyìn tó ṣe Rẹ́gí: Ìlànà fún àwọn Oníròyìn lórí Ìgbé Ayé Àwùjọ (2002). Èyí jẹ́ koṣeemani fún àwọn oníròyìn tí iṣẹ́ Wọ́n jọ mọ́ dátà. Ọ̀kan lára àwọn ògbọ́ǹtarìgì nínú ìmọ̀ nípa dátà àti ohun tó ń lọ láwùjọ, Philip Meyer.
ló kọ ìwé ọ̀hún. Oníròyìn kan tó ti gbà Àmín Ẹ̀yẹ, tó fi ìlú Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé, tó tún jẹ́ akọ̀ròyìn àti Olóoòótú Ìròyìn lórí Ìròyìn tó jọ iṣẹ́ ìwádìí àti dátà, ní wọ́n fi ìwé náà sọrí rẹ̀. (Ó wà fún títà)
Padà sí
Ojú Ewé Iwájú
Nípa
Ìkànsíraeni
Kàlẹ́ńdà
Ìtọrẹ
Àwọn Oniígbọ̀wọ́ àti àwọn Alátìkẹyìn
Àwọn Ọmọ Ẹgbẹ́ Ilé Iṣẹ́ Gbogbo
Owó Ìrànwọ́ àti Ìdàpọ̀
Ìpàdé Àpérò Àgbáyé
Tẹ̀lé GIJN Jákèjádò Àgbáyé Gbogbo