Àwọn Ìtalólobó fún Kíkọ́ ìròyìn-jọ-kọ̀ḿpútà fún Ìwádìí
Láti ọwọ́ Miriam Forero Ariza | ọjọ́ kẹtàlá oṣù keje, ọdún 2021
Ní tòròtòrò ọdún yìí, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè ti Colombia tí ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn mì wọ́n lògbòlògbò, àwọn ìkojú olóogun, àti ẹ̀sùn àsìlò agbára àwọn ọlọ́pàá, àwọn oníròyìn tiraka láti máa mọ tẹ̀lé bó ṣe ń lọ.
Bí wàhálà náà ṣe ń pọ̀ si, onírúurú ilé-iṣẹ́ ìròyìn aládàáni àti àjọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní kó deeta ìròyìn wọn jọ láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìpànìyàn tó níṣe pẹ̀lú ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn, èyí tí onírúurú NGO tẹ̀lé ohun tó ju àádọ́rin lọ ní tòròtòrò oṣù keje. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tó níṣe pẹ̀lú àṣìlò agbára, ìwà-ipá, àti ìtìmọ́lé àwọn olùfẹ̀hónúhàn ìwọ́de.
Ọ̀kan irú déétà ìròyìn ni Rutas del Conflicto ṣe – àwọn ọ̀nà ìkọlura – àjọ ẹ̀rọ ilé-iṣẹ́ ìròyìn tí ó máa ń lo ọgbọ́n ìwádìí àti déétà iṣẹ́-ìròyìn láti kó ìròyìn àádọ́ta ọdún ìkọlura olóogun Colombia jọ. Ní tòròtòrò ọdún yìí, ẹgbẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ìròyìn ìwà-ipá jọ tó níṣe pẹ̀lú ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí àbá àtúnṣe owo-orí ṣùgbọ́n tí ó di ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn tó lòdì sí ìjọba lápapọ̀.
Àwọn oníròyìn káàkiri àgbáyé ń ṣe déétà ìròyìn ti wọn nígbà tí wọ́n bá dojúkọ àìní déétà iṣẹ́, tàbí ibi tí dééta tó wà kò ṣé gbẹ́kẹ̀lé.
Oníròyìn Oscar Parra ni ó darí wọn, ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn, akẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́-ìròyìn, olùgbéjáde, Ayàwòrán kọ́ déétà-ìròyìn láti ṣe ìforúkọsílẹ̀ ikú nígbà tí wọ́n ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn pé àwọn ìlú tó mì lògbòlògbò káàkiri orílẹ̀-èdè.
Gbígbà àti Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìròyìn láti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́, ìjábọ̀ ìròyìn, àwọn NGO, àti àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn ajẹ́rìí àti àwọn mọ̀lẹ́bí olùfaragbà, ẹgbẹ́ yìí ní àǹfààní láti dá déétà-ìròyìn tí wọ́n ti wádìí òkodoro lé lórí nípa ti ìwà-ipá. Èyí jẹ́ kí wọ́n wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti ṣàwárí ẹni tí olùfaragbà náà jẹ́, nígbà tí wọ́n ń ṣe àtúpalẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yíká ikú wọn àti títú àṣírí bí ìpànìyàn àwọn ọlọ́pàá ṣe wà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí Parra máa dá déétà-ìròyìn tí iṣẹ́-ìròyìn le lò. Ní pàtó, wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ Rutas del Conflicto ní ọdún 2012 nígbà tí wọ́n kó ìròyìn jọ lórí ìlànà ìyípadà ìdájọ́ èyí tí àwọn òṣìṣẹ́-afarapẹ́lógun ti tẹ́lẹ̀ fi ẹ̀rí sí lórí ipa wọn ní Ogun Colombia láti lòdì sí Armed Rebel Forces of Coloombia, FARC.
Parra ṣàkíyèsí pé àwọn ìgbọ́ lóòrèkóòrè ṣàfihàn ọ̀rínkínníwín àlàyé lórí àwọn jagunjagun ọ̀tá wọn tí wọ́n ti pa. “Nítorí bẹ́ẹ̀, mo rò pé yóò dára láti pín gbogbo ìròyìn sí déétà-ìròyìn láti gbìyànjú láti ṣẹ̀dá àwọn èlò máàpù àti aago-àkókò,” ó ní, fífikún ìtàn ẹnìkọ̀ọ̀kan tó níṣe pẹ̀lú fífarahàn nílé ẹjọ́ kùnà láti kọ́ àwòrán tó pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà tí máàpù lé è gbà.
Parra lo ìmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ẹ̀rọ – iṣẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ – ìfẹ́ rẹ̀ fún iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí láti kọ́ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àti yanjú owó-ìrànwọ́ fún ipele àkọ́kọ́ ti Rutas del Conflicto, èyí tí yóò lọ láti jáwé olúborí 2017 Data Journalism Award for best data Journalism website.
La Paz en el Terreno – tàbí Àláfíà lórí ilẹ̀ – jẹ́ iṣẹ́-àkànṣe àkójọ-ìmọ̀ tí ó ṣàgbéyẹ̀wò ìwà-ipá ní Colombia lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tọwọ́ bọ ìwé ìsọ̀kan àláfíà. Àwòrán: Courtesy of Rutas del Conflicto
Ẹgbẹ́ tí fìgbà kan tẹ̀lé ìgbésẹ̀ kan náà láti gba, ṣètò, àti ìgbésẹ̀ àkójọ-ìmọ̀ lórí bí àwọn olùfaragbà ìkọlura ṣe fi tipátipá pòórá ní àwọn odò tó kọjá orílẹ̀-èdè, àti ìbáṣepọ̀ láàárín ìwà-ipá ní Colombia àti àríyànjiyàn ìní ilẹ̀.
Àwọn Yàrá-ìròyìn káàkiri àgbáyé ń kọ́ Àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò ti wọn nígbà tí wọ́n kojú àìní àkójọ-ìmọ̀ fún iṣẹ́, tàbí ibi tí àkójọ-ìmọ̀ wà kò ṣe é gbáralé. Àwọn mìíràn ti dá wọn gẹ́gẹ́ bí jíjábọ̀ ìròyìn tàbí ohun èlò aṣèwádìínígbà tí ìṣẹ́lẹ̀ ń lọ lọ́wọ́, tàbí nígbà tí ó tọ́ láti ṣe àtúnyẹ̀wò onírúurú orísun ìròyìn.
“Pé o kò ní àkójọ-ìmọ̀ tí o nílò lọ́wọ́ kì í ṣe ìdí fún ọ láti má sọ ìtàn tí o gbàgbọ́ pé ó le wúlò fún àwùjọ,” Romina Colman ló sọ bẹ́ẹ̀, àgbà-ọ̀jẹ̀ iṣẹ́-ìròyìn àkójọ-ìmọ̀ Argẹtinia àti Olóòtú Àkójọ-ìmọ̀ Latin America ní Organized Crime and Corruption Reporting Project (OCCRP).
Nígbà tí àwọn onìròyìn aṣèwádìí le kojú ìròyìn ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà – Ìjábọ̀ ìròyìn PDF, àkọsílẹ̀ pépà tó ti di rádaràda, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àwọn oníròyìn àti àkíyèsí, àwọn fáìlì tí wọ́n ti fojúwò gààrà, àwọn ìwé-àṣẹ aláfọwọ́kọ, àwọn ìpamọ́ tó ti pẹ́ – pẹ̀lú alámọ̀dájú tó tọ́, wọ́n le yí gbogbo àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò ti ó ṣe é ní àǹfààní sí.
Mo kọ́ èyí ní ọdún 2019 sẹ́yìn, nígbà tí mo ṣiṣẹ́ lórí dídá àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ GIJN Consejo de Redacción (CdR). Colombia’s association of inẹestigatiẹe journalists. A fẹ́ ṣe àkójọ0ìmọ̀ fún àyẹ̀wò fún àwọn olùbádòwòpọ̀ oníròyìn tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìwádìí òṣìṣẹ́ àwùjọ àti jẹgúdújẹra. Nígbà yẹn, àwọn èlò fún gbígba déétà fún ìwé-àṣẹ kò wọ́pọ̀. Iṣẹ́-ìròyìn Àkójọ-ìmọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní Colombia, àti pé a lè rí ìròyìn tó lódìwọ̀n ní ọ̀nà kíkà ẹ̀rọ tí ó ṣì ṣe ń lò.
Nígbà tí àwọn oníròyìn aṣèwádìí le kojú ìròyìn ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà pẹ̀lú alámọ̀dájú tó tọ́, wọ́n le yí gbogbo àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò ti ó ṣe é ní àǹfààní sí.
A bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àdàkọ ẹgbẹ̀rún pépà ìwé-àkọsílẹ̀, púpọ̀ nínú wọn ló jẹ́ aláfọwọ́kọ, ní èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ àwùjọ ṣàfihàn ìfẹ́ ìkọlura àti ìpolongo ìfowósílẹ̀. A rí àkọsílẹ̀ tó lé ní mílíọ̀nù méjì lẹ́yìn ọdún díẹ̀, lẹ́yìn tí a ṣe àfikún àwọn déétà tó níṣe pẹ̀lú rẹ̀ láti orísun oṣìṣẹ́ tó ju ogún lọ. Èyí ló darí èlọ̀ sí ìtúsìrí ìwà-àìda olóṣèlú, bí i èyí lórí ìtúnfọ́nká ilẹ̀ aláìlóòtọ́, láti ọwọ́ ìwé-ìròyìn aṣèwádìí tó ṣáájú Semana.
Ní ọdún 2011, gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso àkójọ-ìmọ̀ àti àtúpalẹ̀tí ó rọ́wọ́ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà iṣẹ́-ìròyìn, Colombia dara pọ̀ mọ́ Open Government Partnersip, ìpilẹ̀sẹ̀ àgbáyé tí wọ́n bọwọ́ lù ní orílẹ̀-èdè méjì-dín-lọ́gọ́rin láti mú ìlọsíwájú bá àkóyawọ́. Ìyẹn fún èmi àti ẹgbẹ́ mí ní ààyè láti tẹ̀síwájú ìdásílẹ̀ àkójọpọ̀-ìmọ̀ fáyẹ̀wò láti sọ àwọn ìtàn tó yẹ. Ọ̀kan wo àsopọ̀ tó wà láàárín Ọ̀gá-àgbà aṣèṣirò ìbílẹ̀ – òṣìṣẹ́ àwùjọ tí wọ́n fún níṣẹ́ pẹ̀lú ṣíṣàbójútó iṣẹ́ àwọn adarí-ìlú àti àwọn gómìnà – àti gbogbo àwọn ènìyàn tó yẹ kí wọ́n mójútó. Òmíràn tí wọ́n ṣàtúpalẹ̀ ẹni tí ó fowó sílẹ̀ fún ìpolongo fún ààrẹ àti ìpàdé ní ọdún 2018 nípa ṣíṣe àwòtúnwò ìjábọ̀ àwọn olùdíjẹ pẹ̀lú àdéhùn àwùjọ, ìforúkọsílẹ̀ àwọn ilé-iṣẹ́, àti déétà adálérí ìtàn gidi ti àwọn òṣìṣẹ́ àwùjọ ìbílẹ̀.
Nígbà tí àwọn oníròyìn ti ń kọ́ àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò láti ọdún 1980, ní tòròtòrò ọdún ìmọ̀ ọgbọ́n àmúṣe fún gbígba déétà láti àwọn ojú-ewé ayélujára, yíyí PDF padà tàbí àwọn fáìlì tí wọ́n ti fojúwò gààrà sí ṣíṣe é sí ọ̀nà ìṣolóòtú, àti pípa déétà tí iye rẹ̀ pọ̀ papọ̀ ti ó ti wà ní ojútáyé àti pé wọ́n ti lè ní àǹfààní sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nọ́ḿbà àwọn oníròyìn tó ń dàgbà ti gba ìkọ́ni ní ohun tí wọ́n ń pè ní ìjábọ̀ ìròyìn ìrànlọ́wọ́ kọ̀ḿpútà – tí wọ́n mọ̀ sí iṣẹ́-ìròyìn àkójọ-ìmọ̀ báyìí – àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn oníròyìn àti olùgbéejáde tàbí ìforúkọsílẹ̀ kọ̀ḿpútà, déétà adálérí ìtàn gidi ti àwọn òṣìṣẹ́ àwùjọ ìbílẹ̀.
Nígbà tí àwọn oníròyìn ti ń kọ́ àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò láti ọdún 1980, ní tòròtòrò ọdún ìmọ̀ ọgbọ́n àmúṣe fún gbígba déétà láti àwọn ojú-ewé ayélujára, yíyí PDF padà tàbí àwọn fáìlì tí wọ́n ti fojúwò gààrà sí ṣíṣe é sí ọ̀nà ìṣolóòtú, àti pípa déétà tí iye rẹ̀ pọ̀ papọ̀ ti ó ti wà ní ojútáyé àti pé wọ́n ti lè ní àǹfààní sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nọ́ḿbà àwọn oníròyìn tó ń dàgbà ti gba ìkọ́ni ní ohun tí wọ́n ń pè ní ìjábọ̀ ìròyìn ìrànlọ́wọ́ kọ̀ḿpútà – tí wọ́n mọ̀ sí iṣẹ́-ìròyìn àkójọ-ìmọ̀ báyìí – àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn oníròyìn àti olùgbéejáde tàbí onímọ̀-ẹ̀rọ kọ̀ḿpútà ti peléke, ó jẹ́ kó rọrùn àti kí ó ṣe ń ṣe láti kọ́ àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò fún àwọn ìdí oníròyìn.
Lágbàáyé, yàrá-ìròyìn ti dá àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò láti ṣe ìwádìí àwọn ìní tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn ní Italy, ikú ẹ̀rọ-ìléwọ́ àti ọlọ́pàá lo ipá ní United States, bẹ́ẹ̀ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìwádìí tó ré kọjá orílẹ̀-èdè. Ní àìpẹ́ yìí, ẹgbẹ́ ti àwọn oníròyìn láti orílẹ̀-èdè méjìlá kọ́ àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò pẹ̀lú ìròyìn tí wọn kò tí ì fi ìgbà kankan tò sí ètò rí, tó níṣe pẹ̀lú ẹjọ́ 2,460 ìwà-ipá láti lòdì sí àwọn olùgbèjà ẹ̀tọ́ àyíká ní Latin America. Ẹgbẹ́ yìí ṣe atẹ̀jáde ìjábọ̀ ìròyìn aṣèwádìí mẹ́rin-dín-lógójì lórí ìpàtẹ-déétà ní iṣẹ́-àkànṣe tó yàtọ̀ tí wọ́n pè ní Land of Resistance (Tierra de Resistentes).
Àwọn oníròyìn kan láti iṣẹ́-àkànṣe Tierra de Resistentes. Àwòrán: Screenshot
Ní òdì kejì ayé, OCCRP jáwé olúborí Àmì-ẹ̀yẹ Sigma ti ọdún 2020 fún ìwádìí Troika Laundromat, ní èyí tí àwọn ẹgbẹ́ lò ìmọ̀ ọgbọ́n àmúṣe gígé-igun láti gba déétà tí ó ju 1.3 milìọ̀nù ìdúnàádúràá lọ láti ẹgbẹ̀rún àkọsílẹ̀ ilé-ìfowópamọ́. Iṣẹ́ yìí tú àṣírí bí aṣèjọba-olówó Russia àti àwọn olóṣèlú ní ìkọ̀kọ̀ ṣe ìdókòwò ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù tí wọ́n jí kó ní òkè òkun, ìnákúnàá owó, àti kó owó-orí lọ.
Àwọn iṣẹ́-àkanṣe yìí wúlò fún níní déétà tí wọ́n ti kójọ tí kò tí ì di mímọ̀ láwùjọ tàbí wọn kò tí kó o jọ ní gbogbo ibi láti sọ ìtàn tó ní ipa biribiri, ṣùgbọ́n èyí tí kò má bá ṣe é ṣe láìsí àwọn àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò tí ó gba àwọn oníròyìn láàyè láti húìwọ̀n ìtàn náà.Ṣùgbọ́n àwọn oníròyìn aṣèwádìí le ṣẹ̀dá àwọn àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò lórí ìwọ̀n kékeré àti pé wọn yó sì tún ní ipa tó gbéwọ̀n. Nítorí bẹ́ẹ̀, èyí ni àwọn ìtọ́nisọ́nà ìgbésẹ̀-níìgbésẹ̀ sí bí o ṣe le kọnu sí kíkọ́ àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò fún ìwádìí.
- Gbá radì
- Ṣàwárí àwọn ìwé-àṣẹ nínú èyí tí o ti máa gba déétà. Wò ó bí ó bá lè mọ pátànù; àwọn fọ́nrán aláwìítúnwí máa fún ọ ní olobó lórí bí a ṣe lè hun àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò. Bí o bá ń bẹ̀rẹ̀ láti ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ tí o ó sì gba àkọsílẹ̀ láti àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti ìjábọ̀ ìròyìn ìbílẹ̀, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ tó jọ ọ́ tàbí ìtàn láti rí ilẹ̀ tó wọ́pọ̀. Ó le wúlò fún àwọn àgbà ọ̀jẹ́ ní ipele ìṣàwárí yìí.
- Ki scope déétà tí o ó gbà. Ìgbà wo ni o ó kó jọ? Àwọn ẹjọ́ wo ni wọn yóò fi kún un, àti èyí tí o ó yọ kúrò? (Èyí bèèrè fún òsùwọ̀n tí kò sókùnkùn àti èyí tó jẹ́ pàtó). Ǹjẹ́ gbèdéke yóò wà fún iye àkọsílẹ̀ tí o ṣe ìgbésẹ̀ rẹ̀? ohun èlò fún iṣẹ́-àkanṣe rẹ – àkókò, owó-ìrànwọ́, ìmọ̀ ọgbọ́n àmúṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. – máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
- Ṣe atọ́ka àwọn ìbéèrè tí o fẹ́ dáhùn nígbà ìwádìí. Èyí yóò ṣe ìtọ́nisọ́nà ìbuyìkún àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò.
- Gba iṣẹ́-àjùmọ̀ṣe ní yànjú, pàápàá jùlọ ní ipele ti tẹ́lẹ̀. Àwọn ìjíròrò láàárín àwọn akẹgbẹ́ máa ń mú ipele àkọ́kọ́ yìí rọrùn àti iṣẹ́ rẹ lágbára. Ní tòótọ́, báyìí ni iṣẹ́-àkanṣe Tierra de Resistent ṣe bẹ̀rẹ̀: àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò àti ìwádìí ni wọ́n wò nígbà tí wọ́n ń ṣe ìpàdé àkanṣe-iṣẹ́ iṣẹ́-ìròyìn aṣèwádìí.
- Àrà àti Ìdàgbàsókè Àkójọ-ìmọ̀ fún àyẹ̀wò
- Bẹ̀rẹ̀ nípa kíki ohun tí àkọsílẹ̀ kọ̀ọ̀kan (ìlà ìbú) máa jẹ́: àwọn ẹjọ́, àwọn ènìyàn, àwọn ibi, àwọn ọjà, àwọn ayẹyẹ, àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìdúnàádúràá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
- Nígbà náà, ṣe àtòjọ àwọn èròjà tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àkọsílẹ̀ kọ̀ọ̀kan: èyí yóò jẹ́ iṣẹ́ rẹ (ìlà òòró). Fún àpẹẹrẹ, tí ìlà ìbú kọ̀ọ̀kan bá jẹ́ ẹnìkan, nígbà náà iṣẹ́ le jẹ́ orúkọ, nọ́ḿbà ìdánimọ̀, ọjọ́-orí, ibi, iṣẹ́-àmọ̀dájú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
- Ki kọ́kọ́rọ́ fún àkọsílẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Nọ́ḿbà ìdánimọ̀ jẹ́ èrò tó dára (nígbà tí ó wà) ju orúkọ lọ. Ó tún le fi kóòdù si nípa síso abala méjì tàbí mẹ́ta pọ̀ láti jẹ́ kí àkọsílẹ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Kọ́kọ́rọ́ yìí yóò ṣe pàtàkì tí o bá nílò láti ṣe àtúnyẹ̀wò láàárín ààtò-àkójọ-ìmọ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
- Yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìdánimọ̀, pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ fún àwọn àlàyé – máa ń sábà jẹ́ ìpínrọ̀ kúkurú tí ó máa wúlò fún ìsọ̀tàn – àti àwọn mìíràn fún ìpín-sí-sọ̀rí, bí i àwọn tí wọ́n máa ń tọ́kasí àwọn àbùdá tó wọ́pọ̀ àti èyí tó dá ìsọ̀rí sílẹ̀. Fún iṣẹ́ ìsọ̀rí wọ̀nyí, ó wúlò fún ìrònú lórí ìtàn tí yóò jáde láti inú ìkọ̀ọ̀kan wọn. Fún àpẹẹrẹ, ó le ṣe àfikún ìlàòòró fún “eré” láti ṣàtúpalẹ̀ bóyá apẹẹrẹ ìẹ̀mẹ̀yà pẹ̀lú ààtò-àkòjọ-ìmọ̀ kan ní pàtó.
- Ìsọ̀kan jẹ́ pàtàkì jùlọ. Nítorí bẹ́ẹ̀, lo ìṣètò àfọwọ́sí láti rí i dájú pé àwọn nọ́ḿbà jẹ́ títẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i nọ́ḿbà, ọjọ́ wà ní ọ̀nà-kíkà tó péye, àti pé wọ́n sípẹ́lì àwọn ìsọ̀rí ní ọ̀nà kan náà nígbà gbogbo. Bí ó ti ṣe é ṣe tó, jẹ́ kí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ jẹ́ àṣàyàn púpọ̀ dípò àwọn ìbéèrè tó ṣí sí ìparí.
- Pẹ̀lú iṣẹ́ láti dá ẹni tí ó gbé ìròyìn kọ̀ọ̀kan wọlé mọ̀ àti kín ni ojúlówó orísun jẹ́ (so pọ̀ mọ́ ọ, pẹ̀lú). Èyí yóò wúlò lẹ́yìnwá bí o bá nílò láti yẹ déétà kankan wò.
- Gbìyànjú láti má lọ jù lórí iye iṣẹ́. Ṣẹ̀dá àwọn èyí tí ó yẹ nìkan fún ìwádìí, bẹ́ẹ̀ náà fún àtúpalẹ̀ déétà, àti àwọn èyí tí ẹgbẹ́ rẹ máa ní àǹfààní láti kún.
- Àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò rẹ le nílò ju tábìlì kan lọ, èyí gbáralé lórí bí àkòrí rẹ bá ṣe díjú sí àti ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn èròjà tó níṣe.
- Rí i dájú pé àrà àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò jẹ́ olùmúlò-ọ̀rẹ́ fún gbogbo ẹni tó níṣe pẹ̀lú iṣẹ́-àkànṣe, ibi yòówù tí ipele ìmọ̀ ọgbọ́n àmúṣe. “Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èlò tí wọ́n kọ́ pàápàá jùlọ fún àwọn oníròyìn àti pẹ̀lú àwọn oníròyìn,” Paul Radu ló sọ bẹ́ẹ̀, Olùdásílẹ̀ àti Àgbà àrà tuntun ní OCCRP.
- Jẹ́ kí àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wo jẹ́ ìsékálé: àrà rẹ le jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ iṣẹ́-àkànṣe ọjọ́-iwájú tó tóbi jù, bóyá láti ọwọ́ rẹ àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tàbí ẹlòmíràn.
- Àyẹ̀wò, Àyẹ̀wò, Àyẹ̀wò
- Ṣe ìdánrawò ti àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò. Fi àwọn àkọsílẹ̀ láti rí i bóyá ó ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà tí ó retí rẹ̀ láti ṣe àti láti ráàyè bóyá ó máa wùlò fún ìtàn tí ó lérò láti ṣiṣẹ́ lé. Ọ̀nà tó dára kan láti fojú bí iṣẹ-àkànṣe náà ṣe le gùn tó: wọ̀n ọ́n kí o sì ṣe ìṣìrò àkókò àròpín tí ó gbà láti ṣe àfikún àkọsílẹ̀ titun, àyẹ̀wò ìwé-owó, nígbà náà jẹ́rìísí àlàyé náà.
- Ṣe àtòjọ “bí ó bá” láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn ìdíwọ́ tó ṣe eṣe tàbí àwọn awòmáwòrán àṣiṣe àti kí o sì dá bí o ó ṣe gbà wọ́n káàkiri wọn.
- Ṣàgbéyẹ̀wò ìgbẹ́kẹ̀lé àti Àìtàsé(rá) ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì. Bí o bá ní onírúurú orísun tó ń sọ oríṣìíríṣìí nǹkan – èyí tí ó wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwòrán tàbí déétì – o lè fẹ́ gbé ìròyìn sí àlàyé ìlà òòró níbi tí o ti lè ṣàpèjúwe àìgbà dípò aláìnídìí tí ó ń yan ẹni tí ó ń sọ òótọ́.
- Fílìì Àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò
- Fi ohun tí o kọ́ ní ìgbésẹ̀ ìdánrawò si láti fún ọwọ́ lóri ìkọ́ni sí àwọn oníròyìn tí yóò gbà, gbé wọlé, àti ṣàtúpalẹ̀ ìròyìn ní àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò. Rí i dájú pé gbogbo ènìyàn ni àtinúdá yìí yé àti ìsọ̀rí ọ̀nà kan náà.
- Ṣàmúlò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìpamọ́ èlò, kí ìráàyè sí má bá gbáralé ẹnìkan ṣoṣo.
- Pín déétà tó ń lo ìsọ̀rí tí o kì ní ipele àrà kí àwọn òfin le hàn lórí àwọn tó gba kín ni ìròyìn àti bí wọ́n ṣe le yàgò fún àdàkọ.
- Bí o bá nílò láti yọ déétà kúrò ní orí-ìtàkùn ayélujára tàbí kúrò ní ìwé-àṣẹ àtẹ̀ránṣẹ́, fọkànsí akitiyan rẹ lórí ìwádìí rẹ tí o yẹ jù, àti kín ni yóò pinnu ìdojúkọ àwọn ìtàn rẹ. Nínú iṣẹ́-àkànṣe Troika, fún àpẹẹrẹ, ìpinnu ìdí ìdúnàdúrà jẹ́ kọ́kọ́rọ́.
- Tí iye déétà tí o ní bá tóbi jù láti ṣe e múlò, gbèrò láti gba alámọ̀dájú láti ìta tàbi ilé-iṣẹ́ láti ṣe àdàkọ ìwé-àṣẹ sí àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò tẹ́lẹ̀ tí wọ́n dárà pẹ̀lú yàrá-ìròyìn rẹ.
- Àyẹ̀wò-iwé-ajé àti Àyẹ̀wò-kíákíá
- Kíkọ́ àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ kan ṣoṣo ìwádìí. Kí o tó ṣàtúpalẹ̀ déétà àti ìkádìí ìyàwòrán, o nílò láti jẹ́rìísi pé ojúlówó orísun ni, bóyá ìyẹn níṣe pẹ̀lú ìwé-àṣẹ tàbí ẹ̀dá tó jẹ́ kókó ìtàn náà. “A gbé déétà wa jáde sí àwọn agbègbè níbi ti ìpakúpa ti ṣẹ̀lẹ̀ kí àwọn tórí yọ le ṣe àtúnṣe sí àwọn àṣiṣe tí ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ènìyàn tó kù ti ń sọ fún ọdún,” Parra ṣàlàyé, lórí ọ̀kan lára iṣẹ́-àkànṣe ní Rutas del Conflicto.
- Pinnu irúfẹ́ àyẹ̀wò ìwé-owó tí o máa ṣe, èyí tí yóò yàtọ̀ gbáralé ìlànà iṣẹ́-àkànṣe. O lè wo gbogbo àkọsílẹ̀ kọ̀ọ̀kan nípa títún ìtọ́kasí-yẹ̀wò pẹ̀lú ojùlówó ìwé-àṣẹ tàbí lè ṣe àyẹ̀wò-ìrànrán tó yípo, ṣùgbọ́n wọ́n gbọ́dọ̀ kó iye àkọsílẹ̀ tó ṣe pàtàkì ní àkojọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò. Ní èyíkèyí ìran, ẹni tí ó ń àtúnyẹ̀wọ̀ déétà kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó gbé e wọ̀ ọ́.
- Kín ni kí o wá nínú ìwé-owó? Àṣìṣe ìtẹ̀wé, àwọn nọ́ḿbà, àwọn déètì, àwọn ẹ̀dà, àti àkọsílẹ̀ tí kò mú òsùwọ̀n ṣẹ.
- Èrò méjì fún àtúnwò nọ́ḿbà: jẹ́ kí ètò àkópọ̀ lápapọ̀ láìfọwọ́yí àti kí o ṣe àfiwé wọn sí àwọn tó wà nínú ojúlówó ìwé-àṣẹ, kí o sì yanjú déétà láti rí ní olùtayọ (àwọn àwòrán tí ó tóbi jù tàbí kéré jù àti tí ó lè ṣàṣìṣe).
- Àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò kò tí ì ní ṣetán fún lílò àfi tí ó bá ti lọ nípaṣẹ̀: Àyẹ̀wò-kíákíá, ayẹ̀wò ìwé-owó, ìkojú orísun tara ẹni, àti àtúnwò tó bófin mu.
Máàpù ialálàyé kọlù àwọn olùgbèjà àyíká ní Gúsù àti Àárín-gbùgbù America, láti ẹgbẹ́ níTierra de Resistentes. Àwòrán: Screenshot
Èròjà Aláìrídìmú
Gẹ́gẹ́ bí oníròyìn, o kò nílò láti di Olùgbééjáde ètò láti ṣiṣẹ́ lórí iṣẹ́-àkànṣe Àkójọ-ìmọ̀ Fáyẹ̀wò. Dípò, mú ẹnìkan pẹ̀lú àmọ̀dájú ní ẹgbẹ́ rẹ kí ẹ sì ṣiṣẹ́ ní àbáṣepọ̀. Àtòjọ èlò lè ṣe ìrànlọ́wọ́:
- Ápùù fún ṣíṣẹ̀dá fọ́ọ̀mù ayélujára tí yóò ran àwọn oníròyìn lọ́wọ́ tí ó kún ní àkójọ-ìmọ̀: Fọ́ọ̀mù Google, Node.js, Django, tàbí Flask.
- Ìfipamọ́ Àkójọ-ìmọ̀: MongoDB Atlas tàbí Google’s Firebase.
- Fún híhun àti ìgbésẹ̀ déétà: python (èyí tí ó le sopọ̀ mọ́ ìwọ̀fún ìpamọ́ tí a mẹ́nubà lókè), PostgreSQL, ELK stack, àti Olùṣefíìmù.
- Fún yíyọ dééta àti ìyípadà PDF: Wondershare Pdf Converter Pro, Olùyípadà ìpìlẹ̀ ìwé-àṣẹ Google, iLovePDF, Smallpdf, Tabula, Import.io.
- Dájúdájú, o le gba déétà nígbà gbogbo láti ètò àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò àti kí o sì ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ pẹ̀lú Excel tàbí Google Spreadsheets. Bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kan lára wọ̀fún tó dára fún iṣẹ́-àkànṣe kékeré.
Àwọn Ìsedúró àti Àwọn Ìtalólobó Gbẹ̀yìn
- Ààbò jẹ́ kókó ìṣòro ní irúfẹ́ àwọọn iṣẹ́-àkànṣe yìí, fún ìdí èyí lo ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó ní kóòdù, ṣíṣe ègbè àwọn ẹ̀dà déétà, àti kí o ro àìléwu ara rẹ̀.
- Kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo Excel, ṣùgbọ́n kí o tún jùmọ̀ṣe pẹ̀lú onímọ̀-sáyẹ̀ǹsì déétà àti olùgbéjáde.
- Ṣọ́ra fún àwọn irínṣẹ tí o lè jẹ́ kí iṣẹ́ náà rọrùn: àwọn èlò fún àfàyọ, fọ́ọ̀mù orí-ìtàkùn láti kún àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò, olùyípadà PDF, ìfojúwòká pẹ̀lú OCR (Optical character recognition), àti ìgbéṣẹ̀ àtẹ̀ránṣẹ́ tó pọ̀. Ní OCCRP, wọ́n dá, ìkànnì tí ó máa fẹ́rẹ̀ ṣe gbogbo iṣẹ́; ó ran ni lọ́wọ́ pẹ̀lú ìráàyèsí tó rọrùn, ìwádìí, ìyílẹ́tàpadà, àti lílọ kiri àyélujára ti ìwọ̀n ńlá àkọsílẹ̀ ìwé-àṣẹ ọ̀nà-kíkà tó pọ̀.
- Níwọ̀n ìgbà tí ìpilẹ̀sẹ̀ máa ń sábà bèèrè fún ẹgbẹ́ ńlá, pinnu ẹni tí yóò jẹ́ adarí iṣẹ́-àkànṣe, àti ro àwọn ìṣedúró fún àjùmọṣe aṣèwádìí.
- Jẹ́ kí ọgbọ́n-ìkọ́ni àti orísun hàn kedere fún àwọn olùwòran rẹ, rò ó pé àwọn ìlànà ààbò àti àìléwu gbà á. Fi àpẹẹrẹ ìwé-aṣẹ ojúlówó hàn láti èyí tí o ṣẹ̀dá àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò láti kọ́ ìgbélékè.
- Tẹ àlàyé àwọn nọ́ḿbà ìbánisọ̀rọ̀ rẹ jáde lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìwádìí kí àwọn òǹkàwé le mọ ìbèèrè tàbí tí wọ́n bá rí àṣìṣe nínú àkójọ-ìmọ̀ fáyẹ̀wò.
Àfikún Ohun èlò
Bí àwọn oníròyìn ṣe wá Déétà tó sọnù láti yí àsọgbà padà tàbí aláìnílé
Bí o ṣe lè dá ẹgbẹ́ iṣẹ́-ìròyìn Déétà sílẹ̀
Bí o ṣe lè lo iṣẹ́-ìròyìn Déétà láti fi kó ìròyìn ogun àti Ìkọluraa jọ
(banner)
Miriam Forero Ariza jẹ́ aládàáni aṣèwádìí àti oníròyìn àkójọ-ìmọ̀ tí wọ́n ti tẹ iṣẹ́ rẹ jáde láti ọwọ́ Igbá-kejì, Colombiacheck, àti El Espectador. Ó ní ju ìrírí ogún ọdún lọ nínú ìwádìí àjùmọ̀ṣe, ìtúpalẹ̀ àkójọ-ìmọ̀, àti ìwòran. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé Iberoamerican Data Journalism Handbook.