GIJN Nílẹ̀ Adúláwọ̀: Àǹfààní sí Àkọsílẹ̀ Gbogbogbò

Láàrín àwọn ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tó bọ́ sí gúúsù aṣálẹ̀ nílẹ̀-adúláwọ̀, àǹfààní sí àkọsílẹ̀ gbogbogbò kìí ṣe ohun tó rọrùn rárá títí dòní, bí-ó-tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àwọn òfin tó ṣe àtìlẹyìn fún bíbèrè àkọsílẹ̀ lọ́wọ́ oníròyìn tàbí fún òṣìṣẹ́ ìjọba láti ní àǹfààní sí àkọsílẹ̀ tó jẹ́ ti ìpínlẹ̀ náà.

Fún ìdí èyí, àwọn orílẹ̀-èdè kan ti wá ojútùú sí èyí nípa jíjẹ́ kí àńfààní sí àlàyé gbogbogbò rọrùn. Nísàlẹ̀, ni àwọn orísun-ìmọ̀ péréte tó dára jù lọ wà fún àwọn oníròyìn tó wà ní gúùsù aṣálẹ̀ nílẹ̀-Adúláwọ̀ tó ń wá ọ̀nà sí àlàyé gbogbogbò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin dè é.

Àjọ òmìnìra Àlàyé ilẹ̀-Adúláwọ̀: ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orísun-ìmọ̀ tó gbòòrò nílẹ̀-Adúláwọ̀ pẹ̀lú àwọn òfin díẹ̀ tó de àǹfààní sí àlàyé. Ó pèsè àlàyé lórí òfin “FOI” ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀.

“IFEX” ní àkójọpọ̀ ìsọníṣókí òfin “FOI” ilẹ́-Adúláwọ́ tó gbòòrò, pẹ̀lú àwọn ìṣòrò tó ń dojú kọ ìmúṣẹ rẹ̀.

Kẹ́ńyà: Ìkànnì Ìjábọ̀ Lórí ìṣejọba Rere ní Kenya.Org ṣe àpèjúwe àwọn òfin orílẹ̀-èdè àti abẹ́lé pẹ̀lú òfin fún àǹfààní sí àlàyé pẹ̀lú àtẹ̀jáde ìjábọ̀ lórí àwọn ìrírí oníròyìn. Àwòrán-ìgbà-lódé-gidi pẹ̀lú. Bákàn náà, wo ìwé-ìléwọ́ lórí òfin kenya ti ilé-ẹ̀kọ́ “Katiba” gbé jáde. 

“Liberia”: “”InfoLib” pèsè ọgbọ́n-inú orí-ìkànnì-àgbáyé fún ìmúdẹrùn ìbéèrè “FOI”. Bí-ó-tilẹ̀-jẹ-pé aládàání ni, a lè rí i lábẹ́ “Gbé ìgbésẹ̀” lóri ìkànnì àjọ àlàyé Liberia.

Mozambique: Guin do Direito a Informacao Para Jornalistas ìtọ́sọ́nà fún “FOI” fún àwọn oníròyìn ti “IREX” ṣe àgbéjáde.

Nàìjíríà: R2K Nigeria pèsè àlàyé tó fẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ nípa òfin “FOI” . Ilé-iṣẹ́ Ìgbóhun-tuntun-jáde lórí Àfàyọ pẹ̀lú Ìmọ́gaara ní Nàìjíríà ní ìkànnì “FOI” láti bèèrè ìbéèrè lóri ìkànnì-ayélujára Àjọ Àtúnṣe iṣẹ́ Gbogbogbò ní ìkànnì “FOI” pẹ̀lú. Àjọ tó ń rísí Ẹ̀tọ́ àti Ojúṣe iṣẹ́-Àkànṣe Ọrọ̀-ajé-àwùjọ Ṣàgbéjáde ìwé-ìtọ́sọ́nà kan ní Oṣù kẹrin (Ọdún 2013). Lílo ẹ̀tọ́ rẹ̀ fún àlàyé tó kójú ìjà sí ìwà-ìbàjẹ́ ní abala èto-ìlera ètò-ẹ̀kọ́.

Gúùsù ilẹ̀-Adúláwọ̀: Àjọ Ìgbaninímọ̀ràn lórí ìṣèjọba-Àwòrawa Tómọ́ gaara pèsè ìwé-ìforúkọsílẹ̀ láti bèèrè fún ìwé-àkọsílẹ̀ lábẹ́ òfin àǹfààní sí Àlàyé àti Ìpèsè ìrànwọ́. “Right2know” jẹ́ ẹgbẹ́ kan gbòógì tó ń rísí ìpè fún ìmọ́gaara. “OPAC” pèsè ìrànwọ́ lórí ẹ̀tọ fún àǹfààní àlàyé tó wà ní àrọ́wọ́tó lábẹ́ òfin Àǹfààní sí Àlàyé.

Ilé-ẹ̀kọ́ iṣẹ́-ìgbéròyìn-jáde ní Gúúsù ilẹ̀-Adúláwọ̀ náà ní ojú-ìwé kan tó ní ìkànnì àwọn òfin “FOI” tí ilẹ̀-Adúláwọ̀.

Ùgáándá: Bèèrè Lọ́wọ́ Gómìnà Ùgáńdà jẹ́ ìkànnì “FOI” fún ìbéèrè lòrí ìkànnì-ayélújára níbi tí àwọn aṣàmúlò ti lè bèèrè ìbéèrè tó jẹ mọ́ abala ìṣèjọba. Ìkànnì yìí tún máa ń pèsè ìdáhùn gbogbogbò fún àwọn ìbéèrè yìí.

Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àǹfààní sí àkọsílẹ̀ gbogbogbò, lọ sí orísun-ìmọ̀ lórí àwọn òfin òmìnira àlàyé lágbàáyé.