Dátà fún iṣẹ́ ìròyìn: Àkójọpọ̀ GIJN

Ìwòye Dátà

Padà sí orí ìkànnì ojú ewé iwájú

Türkçe

Nígbà tí o bá ti ṣe àtúpalẹ̀ rẹ, o lè fẹ́ ya àwọn àwòrán, ìwé àwòrán àpẹẹrẹ ilẹ̀, tàbí máàpù láti ṣe

àpèjúwe àbájáde rẹ. Èyí ni díẹ̀

lára àwọn ohun èlò tí yóò ṣe ìrànwọ́ fún ẹ lórí bí ó ṣe lè àfihàn

dátà rẹ, tí yóò sì dùn ún wò; yóò sì fa àwọn tó fẹ́ẹ́ ṣe àmúlò wọn mọ́ra.

Ìkànnì Chartable jẹ́ ìkànnì Ìròyìn tó fi ìlú Germany ṣe ibùgbé, èyí ilé iṣẹ́ kan tó ń rí àwọn ohun

èlò ìwòye dátà, Datawrapper dá sílẹ̀. Ó ní onírúurú ohun èlò bíi Atọ́nà fún lílo àwọ̀ alárànbarà

nínú ìwòye dátà láti ọwọ́ Lisa Charlotte Rost.

Atọ́nà Chartmaker jẹ́ àwòrán tó ní onírúurú ìwòye dátà nínú, pẹ̀

lú ìtọ́kásí àwọn àpẹẹrẹ Kóòdù

ní ọ̀kẹ̀ àìmọ́yé èdè àti ohun èlò ìwòye.

Data Viz Done Right jẹ́ ìkànnì tó ń yàǹàná àpẹẹrẹ dátà nínú àwọn àtẹ̀

jáde jákèjádò àgbáyé

gbogbo.

Ìwé àwòrán ìwòye dátà kún fún àwọn àwòrán pẹ̀

lú àlàyé, àpẹẹrẹ lílo wọn, àti ìtọ́kásí àwọn

ohun èlò tó lè ṣe ìlọ́po wọn. Kò kún rẹ́rẹ́ bíi ìwé àkópọ̀ Chartmaker.

Ìwòye Dátà: Ìwé Àfihàn (2018) láti ọwọ́ Kieran Healy. Ìwé yìí jẹ́ àkójọpọ̀ ìwé òye fún àgbékalẹ̀

ìwòye dátà tó kánjú òṣùwọ̀n àti Ìgbáradì fún ìwòye dátà nínú R. Healy jẹ́ gbajúgbajà alámọ̀ṣepọ̀

ọmọ ilẹ̀ Ireland tó jẹ́ olùkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Duke. Ìwé yìí wá fún títà lójú òpó Amazon, tàbí kí o

wo àbábọ̀ rẹ̀

lọ́fẹẹ̀ẹ́

lórí ẹ̀rọ ayélujára níbí.

Kókó Dátà fún Ojú Ìwòye (2019) láti ọwọ́ Claus O. Wilke bojú wo Ìpilẹ̀ ìwòye dátà nínú R, pẹ̀

àkíyèsí pàtàkì sí àwọn ohun tó lè ṣe àkóbá fún àwọn àwòrán. Wilke jẹ́ ògbọ́ǹtarìgì ní ẹ̀ka

iṣẹ́dálè (biology) ní ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Texas ní Austin. Ìwé ọ̀hún wá fún títà, bẹ́ẹ̀

ló tún wà lọ́fẹẹ̀ẹ́ lórí

ẹ̀rọ ayélujára.

Ìbáṣepọ́ Ìwòye Dátà fún Ẹ̀rọ Ayélujára, Àtúnṣe Kejì (2017), láti ọwọ́ Scott Murray, who is

atọ́nà fún àkójọpọ̀ àwòrán àti máàpù nípa lílo ohun èlò àwòrán ìgbàlódé D3. Murray jẹ́

igbá-kejì

Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì San Francisco ṣùgbọ́n ní báyìí, ó wà pẹ̀

lú ilé iṣẹ́ ìròyìn O’Reilly. (Ó wà

fún títà)

Peter Aldhous, jẹ́ akọ̀ròyìn lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, tó fi ìlú Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé fún ìwé ìròyìn Buzzfeed

News, ní ẹ̀rọ ayélujára pẹ̀

lú ìwé Àmọ̀ràn ní ṣókí àti ètò ẹ̀kọ́ (pẹ̀

lú ìkànnì àkójọpọ̀ GitHub) tó kún

fún ìwòye dátà, Ìpilẹ̀ṣẹ̀ R, ìjìnlẹ̀ Kóòdù àti àtúpalẹ̀ dátà.