Ohun tí àwọn Oníròyìn nílò fún ìkóròyìn jọ tó dára lásìkò Àjàkálẹ̀ Ààrùn Tókárí-ayé COVID- 19 ti ṣe ìwúrí fún idàgbàsókè àkójọ olùgbówósílẹ̀ láti ṣe ìfúnni sí àwọn Oníròyìn.
Ń wá àwọn ohun èlò sì lóri kíkó ìròyìn jọ lórí COVID- 19? Jẹ́ kó dá ọ lójú láti tẹ Ìkànnì Ohun èlò GIJN.
Ní àfikún, Ìfúnni ti ìrànlọ́wọ́ sí àwọn Olùtẹ̀wéjáde ń jẹ́ kí ó rọ̀ wọ́n lọ́rùn lórí bí èèfún owó ṣe pọ̀ sí i lórí àwọn òwò kékèké.
GIJN ti ṣe ìṣọníṣókí oríṣìí méjèèjì nínú àǹfààní tó wà ní ìsàlẹ̀.
Ní àfikún, àwọn àǹfààní yòókù, tí kì í ṣe èyí tó ń fojú sí ilé-iṣẹ́ ìròyìn gangan, le wà nílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìjọba àti onírúurú àwọn Onínúure. Fún àpẹẹrẹ, wo Átíkù Yàrá-ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ Nieman ní orí ìgbanisílẹ̀ US, àti abẹ́rẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn láti ọ̀dọ Ìjọba Canada. Àwọn Aládàáni ní US náà le yẹ fún àwọn àǹfààní.
Àkókò Ìparí nínu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan jẹ́ àìpẹ́. Mọ̀ nípa àwọn ètò tí kò sí ní àkójọ níbí? Kọ síwa ní [email protected].
Ìjábọ̀ Àwọn Ìfúnni COVID- 19
Àwùjọ Agbègbè Orilẹ̀-èdè (Kárí-ayé)
Àwùjọ Agbègbè Orílẹ̀-èdè ṣe ìfilọ́lẹ̀ owó pàjáwìrì fún àwọn Oníròyìn kárí ayé, àwọn tí ó wù láti kó ìròyìn jọ lórí COVID- 19 láàárín agbègbè wọn.
Wọ́n gba ìbẹ̀wẹ̀ lórí bí ó bá ṣe kàn án sí.
Ìfúnni tí ó bẹ̀rẹ̀ láti $1,000 sí $8,000 ní wọ́n máa “fún ìgbáradì ìkóròyìn abẹ́lé jọ, ìdáhùn, àti ipa èyí lórí Àjàkálẹ̀ ààrùn tó kárí-ayé gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí í láti inú ẹ̀rí tí ìjábọ̀ iròyìn gbé kalẹ̀.”
Owó Àwùjọ Agbègbè Orílẹ̀-èdè “máa gbé ìtẹnumọ́ kan ní pàtó kalẹ̀ lórí jíjábọ̀ ìròyìn láti fún iye ènìyàn tí kò tó,” nífẹ̀ ẹ́ sí i ní “ti agbègbè, kódà ti èyí tó kọjá agbègbè pínpín àwọn awoṣe,” àti pé o fẹ́ rí àwọn ìtàn “ti àìṣedédé tí ààrùn COVID- 19 ti mú wá.” Rí ìfilọ̀ fún àlàyé tó kún si.
Àwọn Òǹkọ̀wé, àwọn olùyàwòrán, olùyafídíò, àwọn oníròyìn olóhùn, Ayàwòrán-máàpù, aláwòrán fíìmù, àti àgbà-ọ̀jẹ̀ ìwòran déétà le wáyé nínú ìgbòwòsìlẹ̀ yìí.
International Women’s Media Foundation (Kárí ayé)
Iṣẹ́ ìròyìn ti IWMF ìdẹ̀rùn owó ṣí sílẹ̀ sí àwọn oníròyìn obìnrin-tí-wọ́n-dámọ̀ tí wọ́n ti kojú ìnira owó tó lápẹrẹ, sọ iṣẹ́ nù, wọ́n ṣí wọn sílẹ̀ láìpẹ́ tàbí ẹni tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ kíákíá láti yàgò fún ìnira, àbájáde tí kò ṣe é dá padà. Owó yìí yóò pèsè ìfúnni kékeré tí ó tó $2,000 ní ìbéèrè kọ̀ọ̀kan. Àkíyèsi: Èrò tó ṣe pàtàkì ni wọ́n yóò fún ìṣẹ̀lẹ̀ ẹjọ́-sí-ẹjọ́ sí àwọn tí wọ́n nílò owó jù.
IWMF ti bá àwọn Onínúure Craig Newmark ṣiṣẹ́ pọ̀ láti dá Owó Pàjáwìrì Iṣẹ́-ìròyìn United States sílẹ̀. “Owó yìí yóò ran àwọn oníròyìn U.S. tó nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n le wọlé sí ibi iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì sí ìjọba tiwantiwa tó ń ṣiṣẹ́”. Ó wà ní U.S. oníròyìn tó tẹ̀dó láìnífiṣe jẹ́ńdà (Pẹ̀lú ìdánimọ-akọ).
Owó Ìrànwọ́ Àwọn Òǹkọ̀wé Pàjáwìrì (Kárí-ayé)
Owó-ìrànwọ́ wà fún àwọn tí kò le ṣiṣẹ́ nìkan nítorí wọ́n ń ṣàárẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí wọ́n ń ṣè tọ́jú ẹni tí ó rẹ̀, kì í ṣe àwọn tí isẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn, gẹ́gẹ́ bi Onígbọ̀wọ́ ṣe sọ, Ẹgbẹ́ Àwọn Oníròyìn America àti Òǹkọ̀wé. “Àwọn òǹkọ̀wé tí wọn bá bèèrè fún un kò nílò láti gbé inú United States ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ fi àwọn ìwé tàbí àwọn átíkù tí wọ́n kọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀.”
Iṣẹ́ Àkànṣe tó ń jábọ̀ ìròyìn Africa-China (Africa)
Iṣẹ́ Àkànṣe tó ń jábọ̀ ìròyìn Áfíríkà-China ní iṣẹ́-ìròyìn Wits ní South Africa pe àwọn Oníròyìn láti wa fi àwọn àbá wọn sílẹ̀ fún owó-ìrànwọ́ àwọn ìjábọ̀ tí ó tó $1,500 fún ìwádìí tó níṣe pẹ̀lú ààrùn COVID- 19. Àwọn iṣẹ́ àkànṣe yìí wá àwọn àbá ní ọjọ́ ọgbọ̀n, oṣù kẹrin fún ìwádìí “ìdáhùnsí ohun tí ó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́, agbára, àwọn àṣeyọrí/ìkùnnà, àwọn ohun àìtọ́, àwọn iṣẹ́ àti ìbáṣepọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀, àwọn agbègbè, àti àwọn Àjọ.”
Owó ìrànwọ́ fún iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí (US)
Owó fún iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí ń fún àwọn Oníròyìn Aṣèwádìí Aládàáni tó tẹ̀dó sí US ní owó-ìrànwọ́ pàjáwìrì tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ìtàn ààrùn kòrónà pé “fọ́ ilẹ̀ titun kí o sì tú àṣìrí àṣìṣe ní gbangba tàbí ní aládàáni.” Fún oṣù díẹ̀ tó ń bọ̀, owó náà ń fúnni ní owó ìrànwọ́ tó tó $10,000, lórí ohun tó ń lọ lójoojúmọ́, fún iṣẹ́-àkanṣe aṣèwádìí aládàáni tí ó ní igun US tí ó le tó níṣe pẹ̀lú àwọn ọmọm-ìlú Amẹ́ríkà, ìjọba, tàbí iṣẹ́. Gbogbo ìtàn gbọ́dọ̀ jẹ́ títẹ̀ jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìgbéjáde ilé-iṣẹ́ ìròyìn ní United States.
Ìsinmi Owó Àwọn Oníròyìn (US)
Wọ́n dá owó-ìrànwọ́ yìí sílẹ̀ láti ara ìpolongo ìfowósílẹ̀-èrò bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn oníròyìn ti ìpínlẹ̀ Washington. Owó-ìrànwọ́ ti lọ sí nǹkan bí 175 – pẹ̀lú àwọn oníròyìn ní ìpínlẹ̀ máàrún-dín-láàdọ́ta. Fọ́ọ̀mù ìbẹ̀wẹ̀.
Owó o ẹgbẹ́ àwọn Oǹkọ̀wé (US)
Fún “àwọn Oníròyìn, àwọn Lámèyítọ́, àwọn òǹkọ̀wé kúkurú, àti àwọn akéwì pẹ̀lú ara iṣẹ́ tó ńlá ní ìgbàkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìsọ̀yínká orílẹ̀-èdè tàbí tó gbòòrò.” Wo àwọn ìlànà ìtọ́nisọ́nà yòókù. Owó-ìrànwọ́ ẹgbẹ́ àwọn òǹkọ̀wé ran àwọn òǹkọ̀wé lọ́wọ́ ní United States, láfi ti àwọn ọmọ-ìlú ṣe, àti oǹkọ̀wé ti Amẹ́ríkà tí wọ́n ń gbé lókè òkun.
Amẹ́ríkà PEN (US)
Amẹ́ríkà Pen ti fẹ Owó Oǹkọ̀wé Pàjáwìrì lójú àti pé yóò pín àwọn owó-ìrànwọ́ tí ó tó $500 sí $1,000 tó níṣe pẹ̀lú ìbẹ̀wẹ̀ tí ó ń ṣàpèjúwe àìlágbára láti pàdé ìnáwó kíákíá nílò èsì láti ní ipa ti ìtànkálẹ̀ COVID- 19. “Láti yẹ ní yíyàn, Olùbẹ̀wẹ̀ gbọ́dọ̀ tẹ̀dó sí United States, jẹ́ alámọ̀dájú Oǹkọ̀wé, kí o sì lè ṣe àpèjúwe pé owó-ìrànwọ́ fẹ̀kan-sùnlọ máa ní ìtumọ̀ ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ sí àdírẹ̀sì ipò pàjáwìrì.”
Owó-ìrànwọ́ fún Iṣẹ́-ìròyìn: Àkókò ìparí ti kọjá, ìfilọ̀ padé
Kánjú-kánjú ti ọ̀pọ̀ agbátẹrù láti mú àkókò ìparí. Àwọn yòókù rẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú àwọn ìbẹ̀wẹ̀ tí wọ́n sì ti dúró láti máa gba àwọn ìbéèrè fún ìgbà díẹ̀. Àwọn ìfúnni ìsàlẹ̀ kò fẹsẹ̀ múlẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ilé-ẹ̀kọ́ le fara da wíwò.
Àwọn ìròyìn-kárí-ayé (Àgbáyé)
Nítorí àwọn ìbéèrè tó rẹ̀wẹ̀sì lórí Ìdáhùnsí owó tó yára kò ní wo yẹ ìbẹ̀wẹ̀ kankan wo títí di ìgbà tí wọ́n bá jẹ́ kí á mọ̀,”Àwọn-ìròyìn-kárí-ayé kọ èyí ní tòròtòrò oṣù kẹrin. “A dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí o ti gbà ìwé fún sísọ fún wa lórí àwọn iṣẹ́ tó yani lẹ́nu tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n máa kàn sí àwọn Olùbẹ̀wẹ̀ tó ṣe àṣeyọrí ní ó pẹ́jù ní ọjọ́ ẹtì ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹrin.”
Ìròyìn àwọnìròyìn-kárí-ayé gba àwọn ẹ̀mí ìdáhùnsí owó tó yára jẹ́ gbigba àwọn ìbẹ̀wẹ̀ láti ilé-iṣẹ́ ìròyìn, àwọn àjọ àti ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ń ṣiṣẹ́ láti pèsè èdè ìbílẹ̀ iṣẹ́-ìròyìn àti àwọn fọ́ọ̀mù mìíràn ti ìròyìn gbangba tó níṣe pẹ̀lú COVID/ àjàkálẹ̀ ààrùn tó káró-ayé kòrónà àti àwọn ipa rẹ̀. owó-ìrànwọ́ láti $500 sí $5,000 máa wà kún “ìdásílẹ̀, ìṣelọ́pọ̀ àti ìtànkálẹ̀ àwọn ìròyìn tó níṣe pẹ̀lú COVID/ àjàkálẹ̀ ààrùn tó káró-ayé kòrónà tí yóò fi àwọn ènìyàn pamọ́ láìléwu àti yóò ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ìpinu ara wọn, àwọn ẹbí wọn àti àwọn agbègbè: àwọn ìdàgbàsókè ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀nsì, àwọn àmì-àìsàn àti ìtọ́jú,àwọn àlàyé àti ìròyìn lórí ìlànà ìlera ní agbègbè ìbílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Ìfowósílẹ̀ tún lè lọ sí “ríra àwọn ohun ìpèsè tó pọn dandan láti tún ààbò yàrá-ìròyìn ṣe tàbí láti gba ìpàtẹ yàrá-ìròyìn ọ̀nà tó jìn láàyè àti ìkóròyìn jọ láti ọ̀nà tó jìn ti COVID/ ààrùn kórónà, pẹ̀lú ẹ̀ro-ìbáraẹnisọ̀rọ̀/káàdì orí-ìtàkùn àgbáyé fún àwọn òṣìṣẹ́, ẹ̀rọ-agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó pariwo, ohun-èlò fún ìgbohùnsílẹ̀ lórí ìtàkùn/ ọ̀nà tó jìn, ìrìnkèrindò fún àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n máa ń lo ohun ìrìnsẹ̀ ti gbogbogbò, owó ìtúnlé ṣe fún yàrá-ìròyìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wo gbogbo àríyànjiyàn níbí.
Ìfowósílẹ̀ Rory Peck lórí COVID- 19 (Àgbáyé)
Àwọn oníròyìn aládàáni tó jẹ́ alámọ̀dájú tí orísun ìrowó-wọlé wọn jẹ́ láti ọ̀dọ̀ iṣẹ́-ìròyìn tí àjàkálẹ̀ ààrùn tó kárí-ayé sì ṣe àkóbá fún iṣẹ́ wọn le ní ẹ̀tọ́ sí owó-ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ owó àágùn Rory Peck Rory Peck lórí COVID-19. Ní tòròtòrò oṣù kẹrin, Rory Peck sọ pé: “Nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì ìbéèrè, owó-ìrànwọ́ ti COVID-19 ti di títì pa fún ìgbà díẹ̀ sí àwọn olùbẹ̀wẹ̀ tó jẹ́ titun, bí a ṣe tẹ̀ síwájú sí àwọn tó ti gbà tẹ́lẹ̀. owó-ìrànwọ́ náà yóò di ṣìṣí láìpẹ́.”
Owó-Ìrànwọ́ Facebook Ìyẹ̀wò-Òótọ́-Ọ̀rọ̀
Facebook, tí ó ń bá Poynter’s International Fact-Checking Network (IFCN) ṣiṣẹ́ pọ̀, ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò owó-ìrànwọ́ mílíọ̀nù kan dọ́là láti ṣe ìrànwọ́ fún olùyẹ̀wò-òótò nínú iṣẹ́ wọn tó yí COVID-19 kà á. Àjọ Àyẹ̀wò-òótọ́ le ṣe àwárí àwọn ọ̀rínkínníwín àlàyé lóri ìtàkùn àgbáyé IFCN. Wọ́n gba lẹ́tà ìkópa láti ọjọ́ kejì-dín-lógún títí di ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹrin. Wo bí ó ṣe ń lọ lórí àwọn tí ó gba owó. Àjọ Àyẹ̀wò-òótọ́ mẹ́tàlá káàkiri àgbáyé ni wọ́n mú ni ìpele àkọ́kọ́ láti gba owó-ìrànwọ́ láti ran iṣẹ́-àkànṣe lọ́wọ́. Àwọn iṣẹ́-àkànṣe tí ó níṣe wá láti Italy, Spain, Bosnia & Herzegovina, Greece, Turkey, Montenegro, Lithuania, Brazil, Colombia, Mexico, India, Congo àti United States.
Ìdojúkọ owó-ìrànwọ́ COVID-19 láti ọ̀dọ̀ ìlànà Ìmọ̀-ọgbọ́n àmúṣe Aspen
Ilé-iṣẹ́ ìlànà Ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ Aspen, àjọ-aláìjèrè ti US, fi owó-ìrànwọ́ sílẹ̀ sí “onímọ̀-àmúṣe àwùjọ àti,” pẹ̀lú àwọn yàrá-ìròyìn àti ẹgbẹ́ tó gbájúmọ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn, ṣíṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sí ọ̀nà iwájú láti dín ipa COVID-19 kùn. (Àwọn tó gba owó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ US tàbí àwọn Olùgbé ibẹ̀). Ọjọ́-ìparí: Ọjọ́ ọgbọ̀n, oṣù kẹta.
Ilé-Ẹ̀kọ́ Brown Fún Àrà-Titun Ilé-Iṣẹ́ Tó Ń Gbé Ìròyìn Jáde
Ilé-iṣé náà fúnni ní owó-ìrànwọ́ kékeré tó “yára” láti ṣe ìranwọ́ fún àwọn oníròyìn,onímọ̀-ọgbọ́n ìmọ́ṣe, olùwádìí ètò-ìlera, onimọ̀-sáyẹ̀ǹsì déétà, onímọ̀-sáyẹ̀nsì àwùjọ, àti gbogbo tàbí àgbègbè kágbègbè tí ó níṣe pẹ̀lú kíkó ìròyìn jọ lórí àjàkálẹ̀ ààrùn náà.
Ẹgbé Àwọn Oníròyìn Gúsù Asia (US)
Ẹgbẹ́ àwọn Oníròyìn Gúsù Asia, Àjọ tó jẹ́ ọmọ America àti Canada tó lọ ẹgbẹ̀rún kan, ti ṣe filọ̀ ètò owó-ìrànwọ́ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó bá tọ́ sí iṣẹ́ ní United States. Owó-ìrànwọ́ méjì, tí ó tó $2,500 fún ẹnìkọ̀ọ̀kan, ni ó wà nílẹ̀ láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn iṣẹ́-àkànṣe aládàáni lorí ìtànkálẹ̀ àti ipa rẹ̀. ìtàn lè wa ní ọ̀nàkọnà. Ọjọ́-íparí jẹ́ ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹrin.
Fọ́tò Àwọn Obìnrin (Àgbáyé)
Fọ́tò àwọn obìnrin COVID-19 owó-ìrànwọ́ pàjáwìrì pèsè iye owó kékeré láti ran àwọn obìnrin tó dá fó lọ́wọ́ àti olùyà-fọ́tó tí kò níṣẹ́ méjì ní gbogbo àgbáyé tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ – kò sí òté ìjẹyọpọ̀-àbùdá kankan lórí ohun tí owó-ìrànwọ́ náà le ṣe: ìmójútó-ìlera, àwọn ọmọ, ìgbalé, ìnáwó alámọ̀dájú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn Olùys`-fọ́tò le bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ tó tó $500, bí ó tilẹ̀ jé wí pé ìdálẹ́kun jẹ́ bíbèèrè kí ọ̀pọ̀ ènìyàn le di rírànlọ́wọ́ bí ó bá ṣe é ṣe. Ọjọ́-ìparí ni ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin.
Substack (Àgbáyé)
Substack, ilé-iṣẹ́ US tí ó ran àwọn Òǹkọ̀wé lọ́wọ́ láti dá lẹ́tà-ìròyìn ímeèlì kalẹ̀, ti fi $100,000 kalẹ̀ fún owó-ìrànwọ́ fún àwọn òǹkọ́wé tó dá fó tí wọ́n ń ní ìrírí ìnira ọrọ̀-ajé nítorí ìtànkálẹ̀ ààrùn kòrónà. Owó-ìranwọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti $500 sí $5,000. Àwọn tó gba owó yóò gba ìmọ̀ran ẹ̀rọ láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ Substack tí ó gbájúmọ́ ìfikọ́ra tó dára jù àti àfojúsùn wọn láti ran ìdàgbàsókè àwọn àtẹ̀jáde lọ́wọ́. “Àwọn owó-ìrànwọ́ yìí wà fún kíakíá, ìsanwó èlé fún àwọn Òǹkọ̀wé, àti pé kò sí àlọ́mọ́ kan tó so mọ́ ọ.” Gbígba lẹ́tà-ìbẹ̀wẹ̀ láti ara ọjọ́ keje oṣù kẹrin. O lè kà si nípa ètò yìí kí ó sì gba iṣẹ́ níbí.
Owó Ohùn Aládàáni
Ó wà fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti Ẹgbẹ́ àwọn dáńfó ní rédíò (afẹ́fẹ́) láti pèsè àwọn ìtura pàjáwìrì. Àwọn ohun èlò ní ibi tó mọ. Àwọn ohun pàtàkì yìí ni wọn yóò fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tó jẹ́ Aládàáni Alámọ̀dájú ohun tí wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí Oníròyìn, Atọ́kùn, Olóòtú àti àwọn onímọ̀-èrọ. Parí ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin.
Ìkànnì Putilizer (àgbáyé)
Ìkànnì Putilizer lórí ìṣẹ̀lẹ̀ wàhálà ti bẹ̀rẹ̀ ìdojúkọ ìbádòwòpọ̀ ìròyìn Ààrùn Kòrónà, owó-ìrànwọ́ titun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ láti jẹ́ kí orí àwọn oníròyìn alárà títun wú àti ìdòwòpọ̀ yàrá-ìròyìn lórí kíkó ìròyìn jọ lórí ìtànkálẹ̀ ààrùn kòrónà lágbàáyé káàkiri ìpínlẹ̀ àti ààlà orílẹ̀-èdè. Àǹfààní yìí ṣí sílẹ̀ sí gbogbo Oníròyìn tó dáńfó àti yàrá-ìròyìn ní United States àti Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
Ní àfikún sí àkóónú ìbádòwòpọ̀ tó lágbára fún ìjábọ̀ ìròyìn àti àtẹ̀jáde, ó gbìyànjú àwọn àbá pé:
- Gbájúmọ́ elétò, lábẹ́ ẹ̀ ọ̀rọ̀ ìròyìn tí ó ń fàlà sí wàhálà ààrùn kòrónà.
- Lo déétà ti o gbà tàbí àti ọ̀nà ìmọ̀ tó pọ̀ sí ìròyìn lórí ààrùn kòrónà.
- Mú ìṣirò tó lágbára dání.
Ìkànnì Putilizer ń gba àwọn lẹ́tà-ìbẹ̀wẹ̀ fún ìdojúkọ ìbádòwòpọ̀ ìròyìn Ààrùn Kòrónà lórí iṣẹ́ òòjọ́ fún ìyókù ọdún.
Ìròyìn Gbogbogbò (Àgbáyé)
Àláyé ìròyìn-gbogbogbògba ẹ̀mí àwọn owó ìdáhùnsí tó yára là ń gba lẹ́tà-ìbẹ̀wẹ̀ láti ìbọ́ọ́ta ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde, àwọn Àjọ, àti Olúkúlùkù tí ó ń ṣiṣẹ́ láti pèsè iṣẹ́-ìròyìn èdè ìbílẹ̀ àti àwọn ẹ̀ka tí ìròyìn gbangba tó níṣe pẹ̀lú COVID/ìtànkálẹ̀ Ààrùn Kòrónà àti ipa rẹ̀. Owó-ìrànwọ́ láti $500 sí $5,000 ni yóò wà fún “ìdásílẹ̀, ìṣelọ́pọ̀ àti ìfọ́nká ìròyìn tó níṣe pẹ̀lú COVID/ Ààrùn Kòrónà tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó yẹ fún ara wọn, ẹbí wọn àti àwọn agbègbè; ìdàgbàsókè ìmọ̀-sáyẹ̀nsì, ààmì àìsàn àti ìtọ́jú, àwọn ìlànà ètò ìlera ìbílẹ̀, àti àwọn ìlànà, ìwúlò ìbílẹ̀ ojoojúmọ́ ní agbègbè àwọn ìròyìn àti ìtalólobó àlàyé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Ìròyìn gbogbogbò máa ṣe àfikún ìkówólé láti pèsè iṣẹ́ ìgbìmọ̀ràn sí àwọn oníròyìn tí wọ́n ń fúnni ní ìmọ̀ràn ọ̀fẹ́ àti ti àgbà-ọ̀jẹ̀ lórí kíkó ìròyìn jọ lórí ààrùn ní oríṣìíríṣìí èdè, pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì, Spanish, French, Arabic àti Russian. Wo gbogbo ẹ̀yà níbí.
Journalists For Transperency (J4T) Ìpilẹ̀ṣẹ̀ (Àgbáyé)
Journalists for Transperency (J4T) Àkóyawọ̀ ń wò láti ran àwọn oníròyìn méjì lọwọ́ lágbàáyé tí wọn yóò ṣe ìtàn aṣèwádìí tó fojú sí ìtànkalẹ̀ ààrùn COVID-19 láti agbègbè, ọrọ̀-ajé, ọmọnìyàn àti àfojúsùn tó dọ́gba. Olùbẹ̀wẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni bí Áàrùn-dín-lógójì kí ó sì le sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa. International Anti-Corruption Conference (IACC) ni J4T ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ àti Transperency International àti pé German Corporation for International Cooperation(GIZ) ní ó gbòwó kalẹ̀. Ìsúnà jẹ́ $10,000. ọjọ́-ìparí ni ọjọ́ kẹjọ oṣù kaàrún.
Owó Ayàwòrán (Àgbáyé)
Owó Ayàwòrán ni ààtò èróńgbà ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀ láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn oníṣẹ́-ọwọ́ Ayàwòrán Aládàáni tí ń kojú àwọn ìṣòro owó nítorí COVID-19. Ààtò jẹ́ ìkànnì orí-ìtàkùn ayélujára tí wọ́n gbé kalẹ̀ fún àwọn ayàwòrán láti fi iṣẹ́ wọn hàn àti láti mú iṣẹ́ wọn tẹ̀síwájú. Ìrànlọ́wọ́ tó tó $500 fún ẹnìkọ̀kan ni wọ́n pèsè.
Owó-ìrànwọ́ kékeré Meeden (tí ó ń wo ọrọ̀-ajé)
Ní ìgbìyànjú láti ran ilé-iṣẹ́ ìròyìn tó dá wà lọ́wọ́, olùyẹ̀wò-kíákíá, àwọn oníròyìn ọmọ-ìlú, àwọn ajìjàgbara, àti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àti onítara ìmọ̀mọ́ńkọmọ́ńkà ẹ̀rọ nínú ìgbìyànjú wọn láti kó ìròyìn ìbújáde náà jọ, Ètò Àgbáyé Àyẹ̀wò Meeden ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ owó-ìrànwọ́ kékeré COVID-19, ní pàtó pẹ̀lú èróńgbà sí àwọn ẹgbẹ́ tó n ṣiṣẹ́ láàárín àkóónú tó ń wo ọrọ̀-ajé (Àríwá Áfíríkà/ Iwọ̀-oòrùn Asia, Áfíríkaà, Latin America, Agbègbè Asia-Pacific). Ẹnìkọ̀ọ̀kan le fisi tó $500, àwọn àjọ kó tó $2,000, àti iṣẹ́-àkànṣe olùbádòwòpọ̀ le gbà tó $2,500. Meeden jẹ́ ilé-iṣẹ́ aláìgbèrè ti US tí “ àgbékalẹ̀ àti ìdàgbàsókè èròjà aláìrídìmú orísun tó ṣí silẹ̀, tó ń ṣáájú mímójútó àwọn iṣẹ́-àkànṣe, gbé àwọn gbèǹdéke ìgbéléwọ̀n jáde, àti pé ó ṣàkóso àwọn ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún iṣẹ́-ìròyìn ẹ̀rọ̀ àgbáyé, ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìwádìí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìjẹ́rìísí ẹ̀rọ.”
Jíjábọ̀ ìjọba tiwantiwa (Europe)
Jíjábọ̀ ìjọba tiwantiwa ń pe àwọn àbá fún àwọn ìtàn lórí bí wàhálà COVID-19 ṣe ń tún òṣèlú àti àwùjọ mọ ní Ààrín gbùgbù, Ìlà-oòrùn, àti ilà-oòrùn Gúsù Europe. Àwọn Àbá tó yọrí sí rere yóò gba owó-ìrànwọ́ láàárín 500 àti 2,500 íúrò. Ìpè yìí ṣí sílẹ̀ fún àwọn aládàáni àti àwọn oníròyìn láti orílẹ̀-èdè mẹ́rin Visegrad ti Poland, Czech Republic, Slovakia, àti Hungary, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn orílẹ̀-èdè Balkan ti Romania, Moldova, Bulgaria, Serbia, Croatia, Bosnia àti Herzegovina, Montenegro, Kosovo, Albania, àríwá a Macedonia, àti Greece. Wọn yóò máa yẹ àwọn àbá yìí wò ní ojoojúmọ́ ní alaalẹ́, pẹ̀lú ìṣísílẹ̀ ìbẹ̀wè di ìgbà tí wọ́n bá jẹ́ ká mọ̀. Àyẹ̀wò àkọ́kọ́ máa wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kaàrún, ọdún 2020.
Owó Ìtura Àwọn Aládàáni (US)
Owó Ìtura Àwọn Aládàáni máa pèsè ìrànwọ́ owó tí ó tó $1,000 fún àwọn Aládàáni tí ó ń ṣàdédé kojú ìnira nítorí ìtànkálẹ̀ COVID-19, yálà nítorí àìsàn, iṣẹ́ tó bọ́, tàbí ojúṣe àbójútó. Wo ìlànà ìtọ́nisọ́nà tó yéni. Ìgbésẹ̀ ìbẹ̀wẹ̀ ti di ṣíṣí.
Owó-yíyá-kékeré fún Àwọn Oníròyìn (US)
Ẹgbẹ́ kékeré ti Oníròyìn US, tí wọ́n máa ń sábà wá láti ProPublica, gbé owó tó ju $60,000 dìde láti ara àwọn ìlérí láti ọ̀dọ̀ àwọn Oníròyìn àti ètò láti rí ó kéré tán ọgọ́fà owó-yíyá sí àpàpọ rẹ̀ yóò jẹ́ $500 fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tó jẹ́ alámọ̀dájú Oníròyìn tí wọ́n ti lé kúrò níbi iṣẹ́, tí wọ́n fún ní ìwé gbélé fún ìgbà díẹ̀, tàbí tí wọ́n ti gé owó rẹ̀ kúrú tí ó sì nílò ìrànlọ́wọ́ ní kíákíá.
Iṣẹ́-àkànṣe Ìjábọ̀ Ìnira Ọrọ̀-ajé (US)
EHRP ní owó ìtura COVID-19 fún àwọn oníròyìn tó dáńfó tí ó nílò ìrànlọ́wọ́. Àwọn Oníròyìn le gba ìwé ìbẹ̀wẹ̀ fún jíjábọ̀ owó-ìrànwọ́ lórí ààrùn kòrónà àti ìjìyà owó ní US; tàbí fún ìtura owó tí wọ́n bá ti ní ipa lórí pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn nítorí àjàkálẹ̀ ààrùn tó kárí-ayé.
Ìdámọ̀ràn ilé-iṣẹ́ ìròyìn Àyípadà Ojú-ọjọ́ (Àgbáyé)
Climatetracker.org fúnni ní ìdámọ̀ràn sí àwọn oníròyìn mẹ́fà tó kéré tó ń tara láti gbé ìtàn ojú-ọjọ́ síta àti kí wọ́n le kẹ́kọ̀ọ́ nínu ìgbésẹ̀ náà. Láàárín oṣù kẹjọ àti oṣù kọkànlá ọdún 2021, ẹgbẹ́ tó pínyà máa kó ìròyìn lórí wàhálà ojú-ọjọ́ jọ láti ìwájú, gbígbé àwọn iròyìn alárà-ọ̀tọ̀ jáde fún Ìṣọ́ Ojú-ọjọ́. Ọjọ́-ìparí ni ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹjọ, ọdún 2021.
Ìrànwọ́ fún Àwọn Àjọ Ìròyìn
Google (Àgbáyé)
Owó Ìtura Iṣẹ́-ìròyìn Pàjáwìrì Lágbàáyé ti wà ní dídásílẹ̀ láti ran àwọn àjọ ìròyìn kékeré àti èyí tí kò kéré tí ó ń gbé àwọn ojúlówó ìròyìn jáde fún àwọn agbègbè ìbílẹ̀. Fèrèsé ìbẹ̀wẹ̀ má a tì ní ọjọ́ kọkàn-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ní 11:59 p.m, ṣùgbọ́n wọn ó ṣètò lẹ́tà ìbẹ̀wẹ̀ ní “ìgbà gbogbo” nítorí bẹ́ẹ̀, a ṣè ìgbìyàǹjú ìjọ̀wọ̀ “ní kété bí ó ti ṣe é ṣe.” Olùbẹ̀wẹ̀ tó yẹ ní yíyàn gbọ́dọ̀ ní ìwáláyé ẹ̀rọ àti pé kí ó ti wà nínú isẹ́ yìí fún ó kéré tán oṣù méjìlá. Àwọn Òfin tó níṣe pẹ̀lú ìtọ́ka ti “Àwọn ẹ̀kọ́ nípa ilé-ayé tó yéni.”
Facebook (Àgbáyé)
Facebook kéde ìkówólẹ̀ mílíọ̀nù $100 láti ṣe ìrànwọ́ fún ilé-iṣẹ́ ìròyìn – $25 mílíọ̀nù ní ìfowólẹ̀ pàjáwìrì owó-ìrànwọ́ fún àwọn ìròyìn ìbílẹ̀ láti ara Iṣẹ́-àkànṣe Iṣẹ́-ìròyìn Facebook, àti $75 mílíọ̀nù ní àfikún ìtajà tí wọ́n náà láti gbé owó sorí àwọn àjọ ìròyìn káàkiri àgbáyé.
Ipele Àkọ́kọ́ lórí ìfowósílẹ̀, fún yàrá-ìròyìn US àti Canada, bọ́ sí owó-ìrànwọ́ Àádọ́ta láti ara Ètò owó-ìrànwọ́ Nẹ́tíwọ̀kì Agbègbè COVID-19. Ipele kejì ṣe agbátẹrù yàrá-ìròyìn ìbílẹ̀ erinwó. Tí ó wà ní méjì-dín-láàdọ́ta ìpínlẹ̀ ní US, Washington D.C., Puerto Rico, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbèríko àti agbègbè ní Canada, àwọn Atẹ̀wétà yóò gba owó-ìrànwọ́ $5,000 láti bo àwọn ìnáwó tí wọn kò retí tí ó níṣe pẹ̀lú ìjábọ̀ lórí wàhálá ní agbègbè wọn. Facebook kéde ọjọ́ keje oṣù kẹrin pé lẹ́tà ìbẹ̀wẹ̀ fún Ètò Owó-ìrànwọ́ Ìtura Ìròyìn Agbègbe pé yóò parí ní ọjọ́ kẹrìn-lé-lógún oṣù kẹrin, ní 11-59 p.m. ET. Iye owó-ìrànwọ́ máa bẹ̀rẹ̀ láti $25,000-$100,000.
Lápapọ̀ fún- àti àjọ ìròyìn ìbílẹ̀ aláìjèrè yóò di rírò wò fún owó-ìrànwọ́. Wọn yóò yẹ lẹ́tà ìbẹ̀wẹ̀ nípa àwọn ìgbìmọ̀ tí wọ́n ti mú tí wọ́n ṣo di aṣojú láti Institute for nonprofit news (INN), The Lenfest Institute for Journalism, Local Independent Online News Publishers (LION), Local Media Association (LMA), Local Media Consortium (LMC), National Association of Broadcasters (NAB), àti Facebook.
Facebook dábàá pé àwọn tí ó bá nífẹ̀ẹ́ láti wọ orí Lẹ́tà-ìròyìn Iṣẹ́-àkànṣe Iṣẹ́-ìròyìn Facebook.
Lọ́tọ̀, Facebook gbé Ètò Iṣẹ́ owó-ìrànwọ́ kékeré kan kalẹ̀ pẹ̀lú mílíọ̀nù $100 ní owó-ìrànwọ́ àti àfikún owó-orí-báǹkì tó tó fún àwọniṣẹ́ gidi kékèké ní orílẹ̀-èdè ọgbọ̀n níbi tó ti ń ṣiṣẹ́.
Owó-ìrànwọ́ COVID-19 fún Iṣẹ́-Ìròyìn Àwọn Europe (Europe)
Ìkànnì Iṣẹ́-ìròyìn àwọn ara Europe àti Iṣẹ́-àkànṣe Iṣẹ́-ìròyìn Facebook ṣe ìfilọ́lẹ̀ owó mílíọ̀nù $3 láti ran àwọn ẹgbẹ̀rún agbègbè lọ́wọ́, ìbílẹ̀ àti àwọn àjọ ìròyìn ìgbèríko aráa Europe. Ìbẹ̀wẹ̀ sí ní ọjọ́ kẹrìn-dín-lógún oṣù kẹrin fún owó-ìrànwọ́ tó bẹ̀rẹ̀ láàárín E5,000 àti E50,000. Owó-ìrànwọ́ COVID-19 fún Iṣẹ́-Ìròyìn Àwọn Europe yóò pèsè ìfúnni lówó tó ṣe pàtàkì sí àwọn àjọ ìròyìn àti àwọn oníròyìn láti ran àwọn agbègbè tó kópa lọ́wọ́, sọ̀rọ̀ sí àwọn ìní iṣẹ́ tó lágbára, àti sọ ìkóròyìn jọ lórí àjàkálẹ̀ ààrùn tó kárí-ayé dẹ̀rùn. Wọ́n bẹ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí i láti ṣe ìforúkọsílẹ̀ ìnífẹ̀ẹ́sí wọn nípa wíwọlé sí orí àtẹ méèlì wa fún ìmúdójú-ìwọ̀n.
Ọmọ-ìlú (Europe)
Àwọn ọmọ-ìlú ní èròǹgbà láti dá ẹgbẹ́-ìrànwọ́ tó lágbára ti dáńfó sílẹ̀, Àjọ Iṣẹ́-ìròyìn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìtagbangba tí ó gbèjà ìjọba tiwantiwa ní Europe nípa kíkó ìròyìn pàtàkì ìtàn àwùjọ jọ. Lẹ́tà-ìbẹ̀wẹ̀ tí wọ́n gbà láti àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyìí:
- Albania, Austria, Belgium, Bosnia, Bulgaria, Croatia, Cyprus, Czech Republic, Denmark, Estonia, Finland, France, Germany, Greece, Hungary, Iceland, Ireland, Italy, Kosovo, Latvia, Lithuania, Liechtenstein, Luxembourg, North Macedonia, Malta, Montenegro, Netherlands, Norway, Poland, Portugal, Romania, Serbia, Slovakia, Slovenia, Spain, Sweden, Switzerland, and United Kingdom.
Ọjọ́-ìparí Ọjọ́ Ọgbọ̀n oṣù kẹfà.
Ìmúdójú-ìwọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2021.