Àwọn Ìtalólobó àti Àwọn Ète: Ìdáṣe Lásìkò Àjàkálẹ̀-ààrùn COVID-19

Ìdáṣe gẹ́gẹ́ bí oníròyìn oníwàádìí jẹ́ ìpèníjà ní àkókò tó dára jù, ó sì tún ṣàfihàn àwọn ìṣòro nígbà àjàkálẹ̀-ààrùn kòrónà. Láti ṣísàkóso ewu ajẹmára sí pípàdánù iṣẹ́ láti ara ìdínkù ọrọ̀-ajé lágbàáyé, àwọn ìṣòro wọ̀nyìí jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ àti pé àwọn ìpèníjà ń yàtọ̀.

Fún Àfikún Ìfọ́nká, Ìgbéga, àti Ìdáṣe, wo Ìtọ́sọ́nà GIJN wa.

Níbí ni àwọn ìtalólobó díẹ̀ àti àwọn òye tí ó le ṣe ìrànwọ́.

Sẹ́mínà ti àgbáyé ti “GIJN” – Iṣẹ́-ìròyìn Oníwàádìí Àdáṣe Lásìkò Àkókò ti COVID – ni wọ́n ṣe ní ọjọ́ kẹsàn-án, ọdún 2020, gẹ́gẹ́ bí apákan ọ̀wọ́ ìṣè-wádìí àjàkálẹ̀-ààrùn ti GIJN. 

Àwọn Àlejò ni Safa Al Ahmad, Aládàáṣe olùṣe-fíìmù Adálérí-ìṣẹ̀lẹ̀-gidi; Cecilia Anesi, Olùdásílẹ̀ Iṣẹ́-Àkànṣe Oníjàábọ̀ Oníwàádìí ti ilẹ̀ Italy; Emmanuel Freudenthal àti Fisayo Soyombo, àwọn méjèèjì jẹ́ olùjábọ̀ oníwàádìí Aládàáṣe; àti To, Giles, olùdarí àgbà, “Current Affairs ní Britai’s ITV, àti olóòtú nígbà kan rí ti ètò BBC’s Panorama.

Àwọn Ohun-èèlò Ètò-Ìnáwó

  • Folio ní ojú-ewé ọ̀tọ̀ fún àwọn oníròyìn àdáṣe tí àjàkálẹ̀-ààrùn COVID-19 nípa, èyí tí ó pẹ̀lú àtẹ owó-ìrànwọ́ tó ń yí, ibi tí wọ́n ti le rí iṣẹ́, àti àwọn ohun-èèlò ọ̀fẹ́ fún àwọn oníròyìn.
  • GIJN ti ṣe ìsọníṣókí àwọn owó-ìrànwọ́ tí ó wà fún àwọn oníròyìn àti àwọn atẹ̀wétà káàkiri àgbáyé. Nígbà tí wọn kò ṣe pàtó sí àwọn aládàáṣe àwọn tí wọ́n bèèrè níbí pọ̀.
  • Owó-ìrànwọ́ Ìdáàbòbò Òmìnira Oníròyìn ṣèfilọ́lẹ̀ iye àwọn oníròyìn kan tó nípa láti ara ìtànkálẹ̀-ààrùn. Owó-ìrànwọ́ oṣù keje ṣí fún gbígbà ní ìparí oṣù kẹfà; máa wo orí-ìkànnì ìfilọ̀ owó-ìrànwọ́ ọjọ́-iwájú.
  • Àjọ Oníròyìn Gúúsù ilẹ̀ Asia ti ṣe àgbàjọ àtẹ fún owó-ìrànwọ́ ọ̀tọ̀ fún Aládàáṣe àti àwọn oníròyìn tí kò níṣẹ̀, pẹ̀lú orísun mìíràn láti rannilọ́wọ́ láti kojú àjàkálẹ̀-ààrùn tó kárí-ayé. Abala ọ̀tọ̀ wà pẹ̀lú àwọn àǹfààní ìwé-kíkọ fún àwọn aládàáṣe nìkan.
  • Ẹgbẹ́ Oníròyìn tòkè-òkun dá owó-ìrànwọ́ pàjáwìrì COVID-19 kalẹ̀ fún àwọn oníròyìn Aládàáṣe ní oṣù karùn-ún, ati ní ìparí oṣù kẹfà bẹ̀rẹ̀ bíbẹ̀bẹ̀ fún ìtọrẹ fún ipele mìíràn, nítorí bẹ́ẹ̀ máa sọ́ owó-ìrànwọ́ tó kàn.
  • Ìdarapọ̀ fún àwọn obìnrin ní Iṣẹ́-ìròyìn ṣẹ̀dá mápùù tí ó ṣàfihàn oníròyìn tí ó jábọ̀ lórí COVID-19. “Àwọn olóòtú, Yàrá-ìròyìn  ń wá àwọn Aládàáṣe tí wọn yóò gbà ní àgbègbèkágbègbè tí wọ́n ti le rí wọn lórí máàpù. Àwọn oníròyìn le tẹ̀lé àwọn obìnrin tó wà nílẹ̀ kí wọ́n sì tẹ̀lé iṣẹ́ wọn.”

Wíwọn Ipa Ètò-Owó  

Ìtẹ̀wésíta Tí Ó Ti Gé Ètò-Ìṣúná Àdáṣe lásìkò COVID

Àtẹ kan tí Gbọ̀ngàn Àkọ́jinlẹ̀ ti ìtẹ̀wétà bójútó tí ó ti gé ìṣúná ìdáṣe wọn. Pẹ̀lú ìṣebánidọ́rẹ̀ẹ́ “ìmúdójú-ìwọ̀n” lẹ́jà pẹ̀lú ìtàtẹ ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé.

Fihàn: Ìdààmú tó ń Kojú Iṣẹ-Ìròyìn lójú “COVID-19”

Mẹ́ta nínú Oníròyìn mẹ́rin ti kojú ìdènà iṣẹ́, ìdílọ́wọ́, tàbí ìjáyà nínú ìjàbọ̀ lórí COVID-19, gẹ́gẹ́ bí ìfojú-lọ́lẹ̀ tó ju oníròyìn ti-ìṣàájú èédégbèje lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè ẹẹ́tà-dín-lọ́gọ́rin láti ọwọ́ Àjọ Oníròyìn Jákè-jádò Àgbáyé ní oṣù Kẹrin.

Àkójọpọ̀-ìmọ̀ láti Ìfojúlọ́lẹ̀ IFJ. Rí ojúlówó níbí.

Báwo ni COVID-19 ṣe ń Nípa lórí Ìwọ̀n Àdáṣe, Ìdíyelé àti Ìṣàn Iṣẹ́-Àkànṣe?

Átíkù Forbes lórí gbogbo ipa àjàkálẹ̀-ààrùn-tó-kárí-ayé lórí oríṣìíríṣìí ìdáṣe, kì í ṣe lórí iṣẹ́-ìròyìn pàtó. Ó tú àdàpọ̀ ipa lórí ìwàláàyè iṣẹ́ àti owó-oṣù síta. O tún le rí ìjábọ̀ láti inú “Payoneer”. 

Bí Àwọn Aládàáṣe Ṣe Ń Ṣàkóso Àrà Ọ̀tọ̀ Àwọn Ìpèníjà ààrùn “COVID-19”

Èsì sí ìfojúlọ́lẹ̀ àwọn aládàáṣe jákè-jádò àgbáyé (Olùfẹ̀ẹ́lójú ju àwọn òǹkọ̀wé) láti ọwọ́ ProWriter. Tipátipá ni ìdàjì àwọn olùdásí – 46% – sọ pé àwọn pàdánù iṣẹ́ wọn látara ìwálẹ̀ ọrọ̀-ajé.

Prowriter rí ọ̀pọ̀ aládàáṣe tí ipa ìdààmú lórí owó-tó-ń-wọlé fún wọn kàn.

 Ìṣe-ṣẹ́-lórí-ẹ̀rọ-kọ̀m̀pútà

“United Kingdom’s Press Gazette” kọ ọ́ nípa ìrúga lórí nẹ́tíwọ̀kì orí-ìtàkùn fún àwọn aládàáṣe lásìkò àjàkálẹ̀-ààrùn-tó-kárí-ayé, pẹ̀lú àwọn àsopọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́ àti àwọn ohun-èèlò, nínú átíkù yìí láti ọwọ́ John Crowley.

Àjọ Iṣẹ́-ìròyìn bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹfà ọdún 2020 láti ọ̀dọ̀ Ìkànnì Iṣẹ́-ìròyìn Yúròòpù “ láti dúró gẹ́gẹ́ ibi ìpàdé níbi tí àwọn aládàáṣe ti máa péjọ tí wọn yóò ṣiṣẹ́ papọ̀ láti fún ìṣọ́ iṣẹ́-oníròyìn àdáṣe lágbègbè ilẹ̀ Yúròòpù lágbára.”  Ìforúkọsílẹ̀ jẹ́ ọ̀fẹ́. “Ní àkókò aláìláànídájú yìí, oníròyìn aládàáṣe nílò ìrànwọ́ nẹ́tíwọ̀kì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

Hostwriter, nẹ́tíwọ̀kì tó ṣe ranàwọn oníròyìn lọ́wọ́ láti jọ dòwòpọ̀ káàkiri ààlal, pẹ̀lú ìbánidọ̀rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ìkànnì Iṣẹ́-ìròyìn ti Yúròòpù, ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ “COVID-19 Collaboration Wire”  ní oṣù karùn-ún, èèlò tí ó ran àwọn olóòtú lọ́wọ́ láti rí àwọn oniròyìn káàkiri gbogbo àgbáyé.

“Ẹgbẹ́ Slack” tí ó fúnni ní ìrànwọ́ fún àwọn oníròyìn Aládàáṣe lásìkò ìdààmú ààrùn-kòrónà tí Oníròyìn Aládàáṣe fún Àwùjọ dá sílẹ̀. ẹgbẹ́ tuntun tí wọ́n kójọ ni oṣù kẹta ọdún 2020 láti ọwọ́ Laura Oliver, Aládàáṣe ilẹ̀ UK, àti àwọn mìíràn ní ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ìkànnì Iṣẹ́-ìròyìn ti ará Yúròòpù.

Fún $4 lóṣù kan studyhall.xyz pèsè ìráàyè sí ọ̀wọ́-tó-gbòòrò olùtàtẹ̀ àti ìkópọ̀ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti àwọn olóòtú  tí ó ń wá ìró-ohùn ìdáṣe. Máa ń sábà dojúkọ US.

Àwọn Ìpèníjà Ara-ẹni àti Àwọn Ìdáhùn

Àwọn Ìtalólobó Márùn-ún fún Àwọn Oníròyìn Àdáṣe láti faradà pẹ̀lú Ìwọ́gilé Ààrùn Kòrónà

Àwọn ìtalólobo márùn-ún láti ọwọ́ ẹgbẹ́ tó wà ní Journalism.co.uk ni: Àwọn olóòtú ṣì nílò àwọn ìtàn, wá ìrànwọ́ àwọn nẹ́tíwọ̀kì, padà sí àwọn ètò-iyebíye tó sọnù, sàkóso àwọn ojúṣe rẹ, kí o sì ṣe ọ̀pọ̀ ipò.

Àwọn Kókó Àgbàsọ lórí Ipa COVID-19 lórí Ìdáṣe

Ìsọníṣókí iṣẹ́-sẹ́mínà-orí-ìtàkùn tí IJNet ṣe agbátẹrù rẹ lórí ipò Ìdáṣe. Ó ṣàfikún oníròyìn olómìnira àti olùṣe-fíìmù “Zoe Flood”, sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Melissa Noel, oníròyìn olómìnira onílé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde, àti Marc Perkins, Olòótú Aṣàkóso fún BBC Africa Eye.

Fífi Orúkọ Pamọ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Oníròyìn Àdáṣe lásìkò COVID-19

Átíkù kan ní FrayIntermedia láti ọwọ́ Ntombi Mkandhla sọ pé “ọ̀pọ̀ oníròyìn àdáṣe ni ó ń gbé ọ̀pọ̀ ìdààmú” àti ṣè gbani-níyànjú ipa rẹ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà.

Kíkojú pẹ̀lú Ipá Ààrùn Kòrónà

Pódíkààsìtì láti ọwọ́ oníròyìn Àdáṣe Lily Canter àti Emma Wilkinson sọ̀rọ̀ nípa Ìṣàn owó-tó-ń-wọlé, Ìṣe-ìyapa, àti ṣíṣe ọ̀pọ̀ àwọn ipò tí ó le jù lásìkò àjàkálẹ̀-ààrùn-tó-kárí-ayé.

Dènà Ààrùn-kòrónà kúrò ní pípa Àwọn Owó-tó-ń-wọlé fún Àdáṣe Rẹ

Carol Tice – ẹni tí ó ṣèdásí sí “Make a Living Writing” – fúnni ní Òye Mẹ́wàá fún Àwọn Aládàáṣe.

Ṣíṣeṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Oníròyìn Àdáṣe nísìnyìí le ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kò ṣeé ṣe

Aládàáṣe US Meena Thiruvengadem kọ èyí fún Ilé-ẹ̀kọ́ Poynter: “Gẹ́gẹ́ bí Aládàáṣe lásìkò àjàkálẹ̀-ààrùn-tó-kárí-ayé, mo ní ìmọ̀lára ìgbójúlé àti ààbò ju bí mo ṣe lérò lọ. Ṣùgbọ́n mo ti ní láti kọjú síbìkan.” Ó tún ṣe sẹminá orí-ìtàkùn ayélujára fún Ẹgbẹ́ Ìròyìn Denver.

Bí Àwọn Aládàáṣe Ṣe ń Ọ̀pọ̀ Àjàkálẹ̀-ààrùn-tó-kárí-ayé ní ilẹ̀ Asia

Ní Ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbé-ìròyìn-jáde Splice, Meghna Rao kọ nípa àwọn ìrírí oníròyìn ilẹ̀ Asia mẹ́rin.

Ìtónisọ́nà Aládàáṣe láti ṣàkóso Aláìdájú Iṣẹ́ lásìkò Ìdààmú Ààrùn-kòrónà 

Átíkù kan láti ọwọ́ Guilia Pines ní ìwé-ìròyìn Owó tí ó dojúkọ ìṣètò ìnáwó àti ṣíṣe àtúnṣe.

Fọ́tọ̀-àtẹ-agbáwòrán-tàn ti àrà láti ọwọ́ Jade Schulz fún Owó

Pẹ̀lú Iṣẹ́ tó ń gbẹ, Níbí ni bí àwọn Aládàáṣe ṣe le yí sí ibìkan pàtó láti ré kọjá Àjàkálẹ̀ Ààrùn Kòrónà tó Kárí Ayé

Àmọ̀ràn Ètò-ìnáwó àti Ìṣàtúnṣe láti ìwé-ìròyìn Fortune Òǹkọ̀wé-ìròyìn déédé Jennifer Mizgata.

Àwọn Aládàáṣe, Àkókò yìí ni láti Ṣèpinyà àwọn Orísun wa

Carolyn Crist kọ Àtẹ̀ránṣẹ́-onílà déédé fún àwọn Aládàáṣe lórí ìkànnì orí-ìtàkùn ayélujára Ẹgbẹ́ Ìtọ́jú Ìlera Oníròyìn (Association of Health Care Journalist’s website), pẹ̀lú àwọn ìtalólobó tó ṣe pàtó láti kó ìròyìn COVID-19 jọ.

Àwọn Ohun-èèlò fún àwọn Òǹkọ̀wé Aládàáṣe lásìkò Ààrùn kòrónà

Aládàáṣe ti ilẹ̀ South Africa Rebecca L. Oní-ìtàkùn-ayélujára ní àwọn ọ̀wọ́ Olùkọ́ni Kíkọ pódíkààsìtì lóri àwọn Ìpèníjà tó níṣe pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn tó kárí-ayé.

Lóri Àkọsílẹ̀ pẹ̀lú Elizabeth Yuko, oyè ìjìnlẹ̀ gíga (Ph.D).: Ilé-iṣẹ́ ìròyìn lákòókò “COVID-19”

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú òǹkọ̀wé Àdáṣe Dr Yuko, ẹni tí ó sọ pé òun pàdánu orísun ọ̀nà-tówó-ń-gbà-wọlé kan ṣoṣo tó ṣe kókó.

Ààrùn Kòrónà Àti Ìṣèdáṣe: Bí àwọn Alámọ̀dájú Ọlọ́gbọ́n-àtinúdá ṣe ń yípadà sí ojú-ọjọ́ COVID-19

 Ègé kan lórí Ìṣọ́ni láti ọwọ́ Rose de Fremery ní Skyword.

Láti Dúró tàbí Lọ? Àwọn Aládàáṣe Jákè-jádò Àgbáyé kojú àwọn Ìpèníjà Lásìkò Ìtànkálẹ̀ Àjàkálẹ̀-ààrùn tó kárí-ayé

Átíkù kan nípa àìdájú tó ń kojú àwọn oníròyìn àdáṣe tí ó ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn orílẹ̀-èdè abínibí wọn: bóyá kí wọ́n dúró sí ilé tuntun wọn tàbí kí wọ́n padà tí orílẹ̀-èdè abínibí wọn. Aládàáṣe Ilẹ̀ US Kristi Eaton ló kọ ọ́, tẹ̀ ẹ́ jáde ní IJNet.

Àwọn Oníròyìn Àdáṣe fi ẹ̀mí wọn wéwu àti Ìgbáyé láàárín Ìtànkálẹ̀ ààrùn COVID-19

Átíkù kan láti ọwọ́ Dr Courtney C. Radsch, olùdarí Alágbàwí tí Ìgbìmọ̀ láti dá ààbò bo àwọn Oníròyìn.

Toby McIntosh jẹ́ olùbánidámọ̀ràn àgbà fún Ìkànnì Ohun-èèlò ti GIJN. Ó tún wà pẹ̀lú Bloomberg BNA ní Washington fún ọdún mọ́kàndínlógójì. Ó jẹ́ olóòtú tẹ́lẹ̀ ní FreedomInfo.org (2010-2017), níbi tí o ti kọ lórí àwọn ìlànà FOI káàkiri àgbáyé. Búlọ̀ọ̀gì rẹ̀ jẹ́ eyeonglobaltransparency.net.