Àwo̩n Ohun-Èlò Gbòógì fún Ìbò US: Ató̩nà Orí-Ìrìn fún Àwo̩n Ónís̩é̩-Ìròyìn ní Iwájú

Kò buŕkú jù láti so̩ pé orílè̩-èdè Amé̩ríkà kò tí rí irú ìbò bí èyí rí. Ní o̩jó̩ ke̩ta, os̩ù Bélú, àwo̩n o̩mo̩ orílè̩-èdè Amé̩ríkà yóò dìbò yan ààre̩, àwo̩n as̩ojú ilé ìgbìmo̩ as̩òfin àgbà àti kékeré, àti ò̩gò̩ò̩rò̩ àwo̩n alága ìbílè̩ pè̩lú òs̩èlú ìpínlè̩. Ìbè̩rù pé ó s̩eés̩e kí wó̩n rán Adigun awòdìbò lo̩ sí àwo̩n ibùdó ìd̀ìbò láti lo̩ dé̩rù ba àwo̩n olùdìbò, tàbí kí wó̩n s̩e ìdíwó̩ fún ìdìbò aláfiráns̩é̩ wà, è̩sùn èrú ìbò àti ìdásí ilè̩ òkèèrè, àti owó tí ó níyè láti o̩wó̩ àwo̩n olùgbéowó sílè̩, ní gbangba àti ní abé̩lé. Ìròyìn tó ń páni láyà, dé̩rù bani, àti ìmò̩ràn aláìláǹfààní- gbogbo è̩ nínú àjàkálè̩ àrùn e̩lé̩è̩kanló̩dún. Agbéléwò̩n rè̩ gá, kìí s̩e ní Orílè̩-èdè Amé̩ríkà, s̩ùgbó̩ fún gbogbo ayé, jé̩ èyí tí ó pò̩.

Fún ohun tí ó kù nínú àkókò ìdìbò tí ó bùáyà yìí, GIJN ń mú gbogbo ojú tí wó̩n ní ní gbogbo àgbáyé mó̩lè̩ sí ara US. A ti s̩e àgbéyè̩wò ò̩pò̩ ohun-èlò, a sì ti s̩e àwo̩n ohun tí a máa ń s̩e fún àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn ní àgbáyé: s̩e às̩àyàn àwo̩n kókó ìtanijí àti ohun èlò tí a rò pé ó lè wúlò fún àwo̩n oníròyìn tí wo̩n ń lé iwájú

A ń s̩e àtè̩lé pè̩lú àfikún ojoojúmó̩ tí e̩ lè máa bá lo̩ ní orí ìtàkùn Twitter ní #gijnElectionWatchdog, àti ní èdè Sípéèni #gijnLupaElectoral. Ǹjé̩ e̩ ní àfikún? E̩ fí àté̩jís̩é̩ ímeèlì ráns̩é̩ sí wa ní [email protected].

Èyí ni àkójo̩pò̩ àwo̩n ohun-èlò wà tí ó dára jù fún o̩dún 2020

Ìtúsíwé̩wé̩, Ààtò àti àkàpò̩

Ètò ìs̩úná fún ipolongo

Owó-ìná fún ìpolówó 

Ìròyìn èké àti ìdánilójú

Bí a se ń s̩e àkásílè̩ ìbò

Ààbò ìbò

As̩àlàyé Ìbò

Àwo̩n ohun tí ó je̩ mó̩ òfín àti àrekérekè

Ò̩rò̩ síso̩, Àwo̩sílè̩, Àko̩sílè̩ lórí Twitter àti fídíò 

Awo̩n È̩tó̩ àti Òfin Ìdìbò

Èsì Ìdìbò

Ìtúsíwé̩wé̩, Ààtò àti àkàpò̩

GIJN’s ElectionWatchDog s̩e àkójo̩pò̩ àwo̩n ìtalólobó àti irins̩é̩ tí ó wúlò fú àwo̩n oníròyìn.

Èyí tí ó tuntun jù lo̩ nínú àkó̩kó̩ ko̩ ni ti US 2020 Dashboard: ìjìnlè̩ òye yàjóyàjó lóri àìso̩fúnni tí ó ń gba àfikún ojoojúmó̩.

Ò̩jò̩gbó̩n Michael McDonald ti University of Florida, to̩pa tí wo̩n sì s̩e ìtúpalè̩ àko̩sílè̩ àkó̩dì ìbò gbogbogbò o̩dún 2020. 

Cook Political Report jé̩ ikò̩ àwo̩n amòye alaígbáralé-e̩ni tí wo̩n máa s̩e àkásílè̩ ìdìbò US àti às̩à ìs̩èlú.  Ìtàkùn wo̩n máa ń fààyè sílè̩ fún àkóònù ò̩fé̩ àti ti alábàápín. 

FiveThirtyEight, tí a fi orúko̩ díè̩ nínú àwo̩n olùdìbò ní US Electoral College so̩rí, jé̩ èyí tí kò tò̩nà bí orúko̩ náà. S̩ùgbó̩n ikò̩ náà máa s̩e àkàpò̩ ìbò̩ tí ó mó̩yán lórí, ó sì jé̩ ìtàkùn tí e̩ lè lo̩ láti mo̩ àkójo̩pò̩ èsì ìbò. 

Electionland2020 ti ProPublica jé̩ àdàpò̩ is̩é̩-ìròyìn tí ó dá lórí ààyè ìbò dídì, ààbò orí ayélujára, ìròyìn èké, àti òtítò̩ ìbò nínú ìbò 2020.

The Associated Press (AP), ìfó̩wó̩so̩wó̩ ìròyì tí ó dá dúró ní oníròyìn ní gbogbo ibùdó, tí wo̩n sì máa ń s̩ètò àkásílè̩ ojoojúmó̩ fún ìdìbò.

Ètò ìs̩úná fún ipolongo

Center for Responsive Politics (CRP) jé̩ e̩gbé̩ ìwádìí aláìdásí tí ó máa ń to̩pa owó nínú ìs̩èlú US, pè̩lú ipa rè̩ lórí ìdìbò àti ìlànà gbogbogbò. Ìtàkùn ayélujára wo̩n, OpenSecrets, jé̩ ibi tí ènìyàn lè lo̩ fún òwó tí wo̩n dá fún ìpolongo ìjo̩ba àpapò̩, ò̩ro nípa àwo̩n ète àti ìtúpalè̩ yékéyéké.

Learning Center ti CRP s̩e àgbékalè̩ àwo̩n ohun tí ó kéré jù nípa ìsùná ìpolongo pè̩lú ìtalólobó, ohun-èlò àti àkókò; ibùdó yìí máa ń to̩pa ìpolongo ìjo̩ba àpapò̩ tó fi mó̩ ti ìjo̩ba ìbílè̩ elections; àti pé ilé-ìròyìn rè̩ máa ń s̩e àgbékalè̩ àlàyé lórí ìs̩èlú orílè̩-èdè.

National Institute on Money in Politics (NIMP) máa ń kun, kií wo̩n sì fó̩ ìs̩úná ìbò sí wé̩wé̩ pè̩lú àkàns̩e is̩é̩ wo̩n, Follow the Money.

FEC Itemizer ti ProPublica jé̩ kí ó ro̩rùn láti wádìí àwo̩n ètò ìs̩úná tí wó̩n ko̩ sílè̩ fún ìpolongo orí ayélujára láti ò̩dò̩ Federal Election Commission (FEC), tí ó fi mó̩ àko̩sílè̩ ojoojúmó̩, ìgbìmò̩ sí ìgbìmò̩, ìran, super PACs, àti àwo̩n mìíràn.

Àti pé orísun gbogbo àwo̩n ìmò̩ nípa ìsúná ìpolongo náà ni FEC. Òun ni e̩gbé̩ tí ó wà láti fi ló̩lè̩ kií wó̩n sì rí pé òfin ìsúná ìpolongo jé̩ títè̩lé.

Fún àlàyé lórí àwo̩n ìmò̩ lórí ètò ìsúná ìpolongo àti àwo̩n òfin US ni ìpiínlè̩, e̩ s̩e àyè̩wò sí National Conference of State Legislatures (NCSL) Disclosure and Reporting Requirements, àti àwo̩n ipa The Campaign Finance Institute sí official state agencies and disclosure reports.

Owó-ìná fún ìpolówó

Ǹjé̩ o fé̩ mò̩ nípa ìnàwó fún ìpolówó? CPR máa ń to̩pa ìye̩n náà. To̩pasè̩ iye tí wo̩n ń ná lórí Facebook and Google ní orí ayélujára, pè̩lú iye tí wo̩n ń ná lórí te̩lifísò̩n àti rédíò pè̩lú àwo̩n ató̩nà ìs̩èlú.

Àlàyé lórí ìnàwó ìpolongo ìs̩èlú s̩e é rí rà ló̩dò̩ àwo̩n alágbàtà bí Kantar MediaAdvertising Analytics, tàbí Media Monitors. Advertising Analytics máa ń s̩e àgbéjáde àfikún àti ìgbà dé ìgbà ní orí ìtàkùn Twitter rè̩.

Ìnàwó fún ìpolówó tún wà ló̩fè̩é̩ láti inú Public Inspection Files ti Federal Communications Commission (FCC), àti campaign finance data ti FEC, s̩ùgbó̩n ní ò̩nà tí kò fé̩rè̩ jé̩ kí ó s̩eés̩e láti s̩e àgbéyè̩wò rè̩ lápapò̩. Láti rí ìnáwó ìpolówó nínú àko̩sílè̩ FEC, kàn lo̩ sí spending tab, kí o yan “disbursements”, kí o sì yò̩rò̩ rè̩ pè̩lú “advertising.”

Ní àfikùn pè̩lú wíwádìí owó tí wo̩n ná lórí ìpolówó orí ayélujára, ó tún s̩e pàtàkì láti ní àgbó̩yé báwo tàbí bóyá bí àwo̩n àko̩sílè̩ náà s̩e ń ní òdiwò̩n, àti àwo̩n ìlànà tí àwo̩n ìtàkùn bí Facebook, Google, Reddit, Snapchat,àti Twitter ní nílè̩. 

E̩ lè rí ìròyìn tó gbo̩n-n-gbó̩n lórí ìnáwó ìs̩èlú lórí àwo̩n ìtàkùn ìbánídórè̩é̩ ńlá láti o̩wó̩ Digital Politics ní Center for Information, Technology, and Public Life (CITAP). E̩ s̩e àyè̩wò sí Platform Advertising àti Political Ad Database Comparisons.

Election Integrity Partnership s̩e àtúngbéyè̩wò ìlànà nípa àwo̩n àsìko̩ tí ó je̩ mó̩ is̩èlú ti ìtàkùn ìbánidó̩rè̩é̩ mé̩rìnlá ò̩tò̩ò̩tò̩, pè̩lú ató̩nà sí òfin àti àtúpalè̩ ìwúlò wo̩n.

Wesleyan Media Project (WMP) tí kò ní ìbátan-ìs̩èlú kankan s̩e ìtúpalè̩ iye, ìnáwó, onígbò̩wó̩ àti àkóónú ìpolówó ìs̩èlú.

NYU Online Transparency Project sè̩s̩è̩ s̩e ìfiló̩lè̩ Ad Observatory, irins̩é̩ tí ó máa ń ní ìwúlò tí ó pò̩ jú èyí tí ilé-ìkàwé nípa ìpolówó ti Facebook lo̩. S̩e àyè̩wò rè̩ nípa ìlú, às̩à ìwá-nǹkan, àko̩sílè̩ ìrántí.

Political advertising library ti Google jé̩ ara ìròyìn àtinúríwá, tí ó sì máa ń gba àfikún ní ojoojúmó̩. Wo àwon FAQ lórí ìpolówó ìs̩èlú nípa ohun tí ó wà níbè̩. 

Ad Library Report ti Facebook s̩e wá ní ò̩pò̩lo̩pò̩ ò̩nà, lára èyí tí a tí rí owó níná olùdíja, olùpolówó, àti ibùdó.

Ìròyìn èké àti ìdánilójú

Politifact ti The Poynter Institute tètè s̩e ìfìdí-òdodo-múlè̩ tàbí s̩é̩ àwo̩n ìdánilójú tí àwo̩n olùdíje tàbí àwo̩n àtè̩jáde tí ó gbajúmò̩ lórí ìtàkùn ìbánidó̩rè̩é̩ bá ń s̩e.

FactCheck.org jé̩ àkàns̩e is̩é̩ Annenberg Public Policy Center ti University of Pennsylvania àti pé, bí Poynter, wó̩n máa ń s̩e àgbéyè̩wò àwo̩n àso̩yán tí ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò, ò̩rò̩ síso̩, àti àso̩yán nígbà ìdìbò US. 

Lótìító̩, ìwé ìròyìn o̩ló̩sò̩ò̩sè̩ láti ibi àkàns̩e is̩é̩ afi-ìdí-òdodo-múlè̩ àti as̩e-ìs̩irò ti is̩é̩ ìròyìn ti American Press Institute, tún s̩e ìwádìí àwo̩n ohun tí ó tó̩ fún àsìso̩

Graphika ni ikò̩ tí ó ń mójú tó òdodo ìbò àti mímo̩ iró̩; e̩ wo àwo̩n àtè̩jáde àko̩sílè̩ àti ìròyìn wo̩n níbí.

Infotheque2020 ti First Draft s̩e àgbékalè̩ ató̩nà ìbè̩rè̩ fún àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn nípa ìròyìn ìròyìn èké lórí ìdìbò US, wo̩n sì s̩e àgbékalè̩ Irins̩é̩ tí ó mo̩ níwò̩n àti àwo̩n èròjà Àrídájú yòókù fún àwo̩n yàrá ìròyìn. Tí ó tún ní ìtumò̩: Ató̩nà First Draft lórí sís̩e àkásílè̩ ìs̩è̩lè̩ orí ayélujára,ìs̩è̩lè̩, attribution.news, lára èyì tí a ti rí àyinje̩, jíjágbà àti ìròyìn èké.

Nípa ìfìdí-òdodo múlè̩ ní gbòógì, e̩ má gbàgbé ìwé Verification Handbook ti DataJournalism.comOnline Investigation Toolkit ti Bellingcat, àti Verification and Digital Investigations Resources láti o̩wó̩ Craig Silverman.

Bí a se ń s̩e àkásílè̩ ìbò

Nieman Reports àti Nieman Lab ń s̩e àtè̩jáde àwo̩n ìtàn tí wo̩n ń s̩e àgbéyè̩wò bí àwo̩n ilé-ìròyìn ní US s̩e ń s̩e àkásílè̩ ìdìbò US.

Fún ààbò àso̩n sò̩rò̩sò̩rò̩, e̩ lo̩ wo àwo̩n ohun èlò ti Committee to Protect Journalists (CPJ) láti s̩e àkásílè̩ ìbò US ní 2020 ní àlàáfíà.

Àko̩sílè̩ how to Responsibly Report on Hacks and Disinformation ti Stanford Cyber Policy Center pè̩lú ìròyìn tí ó pé àti Ìtó̩só̩nà mé̩wàá láti ròyìn lórí ìpolongo. 

Political communication scholars s̩e àgbékalè̩ àwo̩n ìs̩edúró wò̩nyìí sí àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn tí wo̩n ń s̩e àkásílè̩ ìdìbò US ní o̩dún 2020.

American Press Institute (API) s̩e àtìlé̩yì àwo̩n ètò ìdìbò tí ó tan àwo̩n adarí ilé-ìròyìn pò̩, s̩e ìfiló̩lè̩ àwo̩n ètò àkásílè̩ ìbò tí ó mó̩yán lórí, pèsè àwo̩n ató̩nà fún ìkásílè̩ ìròyìn èké tí ó je̩ mó̩ ìdìbò, tí wo̩n sì tún ń wo àwo̩n àtamó̩ e̩jó̩ fínífíní.

API’s Trusted Elections Network s̩e àgbékalè̩ kòs̩eémání “Guide to Covering Elections and Misinformation.” E̩ tún s̩e àyè̩wò sí àko̩sílè̩ onígun mé̩rin tí àko̩lé rè̩ jé̩ “Getting it Right: Strategies for truth-telling in a time of misinformation and polarization.”

Ò̩kan nínú àwo̩n òs̩ìs̩é̩ ìdìbò nígbà kan rí s̩e àgbékalè̩ Ète mé̩jo̩ fún sís̩e àkásílè̩ ìdìbò US. Ohun kan pa gbogbo wo̩n pò̩: kó̩ ara re̩ nípa ìlànà ìdìbò, mo̩ òfin, má agba ìròyìn àtìgbàdégbà.

ProPublica s̩e àgbéjáde ató̩nà ìròyìn síso̩ pélébé lórí ìbò aláfiráns̩é̩, tí ó kún fún àwo̩n ète àti ìpìlè̩ tí ó s̩e é s̩e àmúlò.

Poynter s̩e àgbékalè̩ ató̩nà ìròyìn síso̩ s̩aájú ìbò ní alé̩ o̩jó̩ ìdìbò tí ó jé̩ èèmò̩ jù yìí: Ìbéèrè mé̩rìnlá fún àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn láti dáhùn s̩aájú o̩jó̩ ìdìbò láti gbáradì fún ìdádúró nínú àfojúsùn. 

Ààbò ìbò

Àkàns̩e is̩é̩ Brennan Center for Justice lórí Ààbò Ìbò s̩e àlàkalè̩ àwo̩n kùdìè̩kudie̩ nínú ètò ìdìbò US, pè̩lú àwo̩n ojútùú tí ó bá a mu àti ìlànà ìbánisò̩rò̩ fún àwo̩n amòyè nípa ìdìbò. Wo̩n tún ní àlàkalè̩ àwo̩n ìlànà tí kí àwo̩n òsìs̩é ìbò máa gbé láti rí ààbò ìbò dájú. Fi s̩e òdiwò̩n ìmúrasílè̩ àwo̩n òsìs̩é̩ ìbílè̩ re̩. 

Ààbò fún ohun èlò idìbò ti Cybersecurity and Infrastructure Security Agency (CISA), 

Ìròyìn àti è̩kó̩ Election Security Preparedness ti U.S. Election Commission’s (EAC).

Ààbò fún ìbò ti National Conference of State Legislators (NCSL): Ètò ìlú policies.

Ètò alátè̩lé pàtàkì ti National Public Radio lórí ìmúrasílè̩ fún ìbò jé̩ ò̩nà tí ó dára láti máa mò̩ nípa ohun tí ó sè̩s̩è̩ ń s̩e̩lè̩.

Voting Machine Verifier ti Verified Voting s̩e àkójo̩ àwo̩n è̩ro̩ irins̩é̩ ìdìbò wá sí ìpínlè̩ àti agbègbè dé agbègbè, láti 2006 – 2020. Àkòjó̩ ìrins̩é̩ ìdìbò wo̩n so̩ nípa  àwo̩n irúfé̩ irins̩é̩ ìdìbò.

New York Times s̩e àkójo̩pò̩ àwo̩n onímò̩ ààbò láti jíròrò lórí è̩rù méjè tí ó ga jù tí wo̩n ní nípa o̩jo̩ ìdìbò, pè̩lú ohun tí a lè s̩e sí i.

As̩àlàyé Ìbò

Àwo̩n ohun èlò ti onís̩é̩-ìròyìn s̩e àgbékalè̩ asàlàyé yìí: The Electoral College: How America picks its president.

The Massachusetts Institute of Technology’s Election Data + Science Lab (MEDSL)  jé̩ ibi tí ó lòòrìn fún àwo̩n as̩àlàyé ìbò (ò̩nà ìdìbò, ààyè sí ìdìbò, sís̩àkóso ìlànà ìbò dídì); Election Datasets and Tools; àti Election Experts.

FiveThirtyEight s̩e àyè̩wò àyípadà tí ó wà nínú máàpù ìdìbò láti ìgbà (lábé̩ ètò ìdìbò US, olùdíje kan lè borí ìbò tí ó gbajúmò̩, síbè̩ ki ó sì kùnà nínú ìbò náà. 

Ní inú ìfò̩rò̩wérò tí ó máa ń gba àfikún gbogbo ìgbà láti o̩wó̩ The New York Times, ìpìnlè̩ kò̩ò̩kan ní wo̩n ń lo òsùwo̩n Cook Political Report wo̩n ló̩wó̩ló̩wó̩ fún, léyìí tí ó s̩e òdiwò̩n àwo̩n bí ó s̩e s̩eése kí ò̩kankan nínú àwo̩n olùdíje méjèèjì jáwé olúborí.

Washington Post s̩e àyè̩wò àwo̩n ohun tí ó s̩eés̩e kí ó se̩lè̩ sií jíjáde dìbò àti ìlànà àfis̩àpe̩re̩ ìdìbò láti mo̩ bí ó s̩eés̩e láti rí fún Trump tàbi Biden nínú ìbò náà, tí ó sì tún pè̩lú àwo̩n àkójo̩ orísun àlàyé ní ìparí àko̩sílè̩ náà.

Àwo̩n ohun tí ó je̩ mó̩ òfín àti àrekérekè

Ìròyìn Brennan Center for Justice lórí Digital Disinformation and Vote Suppression  s̩e àlàkalè̩ tí ìbò US dojú ko̩ ní 2020. Ibùdó náà s̩e àlàkalè̩ àwo̩n ètè tí ó s̩eés̩e láti lò látí fi dé̩rù bà tàbí pa olùdìbò lé̩nu mó̩, àti àwo̩n è̩tàn burúkú tí ó ye̩ kí á máa mójú tó.

Lé̩tà ìròyìn NCSL, The Canvass, s̩e àgbéyè̩wò àwo̩n e̩jó̩ tí ó ń lo̩ ló̩wó̩ tí ó je̩ mó̩ ìbò 2020. Ó s̩e àfàyo̩ kókó gbòógì mé̩rin: ìbò onílé̩tà-pó̩ńbélé, yíye̩ fún àti bíbèèrè fún ìdìbò aláìsíníbè̩, ohun ìlò fún e̩lé̩rìí, àti bí ìdìbò s̩e je̩yo̩.

Healthy Elections Project láti Stanford-MIT, s̩e è̩dá election litigation tracker, ibùdó ìkó-àlàyé-sí tí ó máa ń to̩ ipa àwo̩n ò̩rò̩-ìbò tí ó bá je̩ mó̩ COVID. Brennan Center s̩e àfikún sí ato̩-ipa Voting Rights Litigation 2020 wo̩n ní o̩jó̩ kejìlélógún os̩ù O̩wé̩wè̩, o̩dún 2020.

Know the rules: the William & Mary Law School and the National Center for State Courts s̩e è̩dá eBenchbook kan, ibùdó àlàyé tí ó s̩e é wá lórí ayélujára lórí àwo̩n nó̩ḿbà ìbò ìpínlè̩ àti àwo̩n ohun mìíràn tí ó je̩ mó̩ òfin ìdìbò.

Georgetown Law’s Institute for Constitutional Advocacy and Protection (ICAP) s̩e è̩dá àádó̩ta State Fact Sheets tí ó ń s̩àlàyé àwo̩n òfin lórí àwo̩n e̩gbé̩ ajìjiàgbara aládàáni tí kò gba às̩e̩.

Àjo̩ aláìgbójúlé-èrè Campaign Legal Center máa ń sis̩é̩ lórí ìpolongo ìsúná, è̩tó̩ ìdìbò, àtúnpińn ìletò àti ìhùwàsí ìjo̩ba.

Àjo̩ àwo̩n akò̩rò̩yìn ajìjàgbara fún òmìnira àwo̩n akò̩ròyìn ti s̩e è̩dá ató̩nà òfin láti ran àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn ló̩wó̩ láti ní àgbó̩yé è̩tó̩ wo̩n ní ibùdó ìdìbò, àti nígbà tí wó̩n bá ń s̩e àkásílè̩ ìbò. 

Àwo̩n Ò̩rò̩, Àko̩sílè̩, àko̩sílè̩ orí ìtàkù Twitter àti Fidio

Àwo̩n àkápamó̩ fídíò Campaign and election àti Campaign 2020 jé̩ kókó ò̩rò̩ tí a lè wá, tí ó sì wà ní orí C-SPAN, ìtàkún ayélujára gbogbogbò.

Talk2020 láti ò̩dò̩ The Wall Street Journal àti Factiva Dow Jones,  jé̩ àkójo̩pò̩ àwo̩n àsàyàn àko̩sílè̩ tí a lè wá nípa ìfilénà tàbí kí á kàn wá a. 

Internet Archive máa s̩e ìfilò̩ ibùdó àko̩sílè̩ ò̩fé̩ fún  àwo̩n ìròyìn orín amóhùnmáwòrán àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩. Ò̩rò̩ náà jé̩ àfàyo̩ àko̩sílè̩ tí a s̩e ló̩jò̩, tori náà e̩ ye fídíò náà wò fún ìfìdí-òdodo-múlè̩.

Tún wo Vote Smart, tí ó máa ń to̩ ipa ipo olùdíje, àko̩sílè̩ ìdìbò àti ò̩rò̩ e̩nu gbogbo ìlú.

Ààre Trump ń lo Twitter gé̩gé̩ bí ò̩nà ìbánisò̩rò̩ gbòógì, torí náà nígbà tí àwo̩n ò̩nà ìbánisò̩rò̩ mìíràn bí Compilation of Presidential Documents jé̩ àkó̩sílè̩ ti ìjo̩ba, e̩ wo Trump Twitter Archive àti àwo̩n deleted tweets ti Factbase fún ò̩pò̩ sí i láti o̩wó̩ Trump.

Àko̩sílè̩ àwo̩n olùdìbò

Ìpolongo, ilé-is̩é̩ ìròyìn, àti àwo̩ mìíràn máa ń lo àwo̩n àko̩sílè̩ olùdìbò bí tí èyí tí ó gbòòrò láti L2 Political láti wá, kí wó̩n sì fojú sun àwo̩n ènìyàn nípa lílo ibùdó. Ó sì tún wà ló̩dò̩ àwo̩n alágbàtà bí LexisNexis; iye je̩ mó̩ ò̩pò̩lo̩pò̩ nǹkan. 

Àko̩sílè̩ àwo̩n olùdìbò̩ jé̩ àko̩sílè̩ gbogbogbo tí àráàlú kankan lè rí;  wádìí ohun tí ìpínlè̩ kò̩ò̩kan jé̩ kó wà nílè̩, sí ta ni, níbí, láti ò̩dò̩ NCSL.

Kàn sí àwo̩n alákosò ìbò ti ìbílè̩ tàbí ti ìpínlè̩ fún àwo̩n àlàyé gbòógì lórí ìforúko̩sílè̩ olùdìbò, àti àwo̩n ibùdó ìdìbò, àwo̩n òdiwò̩n ìdìbò, òfin ìdìbò, àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩. 

Election 2020 láti ò̩dò̩ The Pew Research Center s̩e àlàyé kíkú lórí Changing Racial and Ethnic Composition of the U.S. Electorate.

Àwo̩n È̩tó̩ àti Òfin Ìdìbò

Àgbéjáde ilé ni a lè fi ìdìbò àpapò̩ US wé. Ojús̩e láti s̩àkós̩o ètò ìdìbò jé̩ ti ìpínlè̩ àti àgbègbè kò̩ò̩kan, ìpínlè̩ méjì kìí sí s̩e é bákan náà. 

National Conference of State Legislatures (NCSL) s̩e àgbéjáde ìpa ìròyìn tí ó ń fi ìgbà gbogbo yí padà nípa ohun tí ènìyàn nílò fún ìdánimò̩ olùdìbò, ibùdó ìdìbò, o̩jó̩ tí àwo̩n ìwé ìdìbò aláìwá máa jé̩ fífí ráns̩é̩, o̩jó̩ tí ìbò kíkà lè bè̩rè̩, àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩. Wó̩n tún máa ń mójú tó orísun ìmò̩ ti State Elections Legislation.

Da ìye̩n pò̩ mó̩ àtòjo̩ àwo̩n ohun èlò láti National Association of State Election Directors  (NASED) àti ìtàkùn ayélujára Can I Vote ti National Association of Secretaries of State (NASS), e̩ ó sì ní ohun tí e̩ nílò láti ní àgbó̩yé nípa àwo̩n ìlànà tí ó jo̩ mó̩ ètò ìdìbò US, ìlànà àti ìmò̩ è̩ro̩.

NASS máa ń s̩e àfikùn gbogbo ìgbà sí ìwádìí nípa ìsàkóso fún ìbò lórí àwo̩n o̩jó̩ ìdìbò aláìsínílé, sís̩e ìpolongo àkókò, òfin ìpínlè̩ lórí ìdìbò àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩.

U.S. Election Commission ní ohun-èlò fún àwo̩n olùdìbò àti àwo̩n olùdarí ìbò àti ò̩pò̩ àwo̩n ìròyìn tó je̩ mó̩ ìdìbò, è̩kó̩ àti ìmò̩.

Ìwé ìtó̩nisó̩nà àwo̩n Associated Press’s (AP) nípa ìtè̩síwájú lórí òfin ìdìbò  fún ìpínlè̩ kò̩ò̩kan, pè̩lú òǹkà àwo̩n olùdìbò aláisínílé tí wó̩n fi ráns̩é̩ fún ìpínlè̩ kò̩ò̩kan tí wó̩n sì dá padà.

Ìtàkùn ayélujára tí àwo̩n ACLU, Let People Vote jé̩ kí ó ro̩rùn láti rí o̩jó̩ ìforúko̩sílè̩ fún ìdìbò, àlàyé àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩ fúnb orílè̩-èdè kò̩ò̩kan site makes it easy to find voting registration dates, details and more for each state.

US Vote Foundation s̩e àlàkalè̩ àwo̩n ètò fún ìbéèrè fún ìdìbò aláìsíníbè̩ àti ìforúko̩sílè̩ fún àwo̩n ará US ní ilé àti òkè òkun.

Àti pé, National Vote at Home Institute ń sis̩é̩ pè̩lú àwo̩n òsìs̩é̩ ìbò àti àwo̩n e̩gbé̩ ajìjàgbara láti jé̩ kí ìbò dídì nípa lé̩tà fó̩nkálè̩ ní gbogbo ìpínlè̩.

Èsì Ìdìbó

The Associated Press (AP) s̩e àte̩ àwo̩n èsì ìbò ò̩pò̩ nínú àwo̩n ìpínlè̩ US àti tí abé̩lé fún e̩gbé̩ fún ìbò orílè̩-èdè, ìbò gbogbogbò àti àpérò. Báyìí ni wó̩n se s̩e é

AP tún s̩e àlàyé bí àjàkálè̩ àrùn s̩e ń kópa nínú ìdìbò o̩dún yìí àtí bí wó̩n s̩e ń so̩ e̩ni tó jáwé olúborí. 

Ní àwo̩n o̩jó̩ tàbí gan ò̩sò̩ tí ó bá tè̩lé ìdìbò, e̩ máa tè̩lé àwo̩n ìròyìn yàjóyàjó nípa wo̩n ní orí ìtàkùn Twitter: #APracecall.

Pè̩lú ìrèti ò̩pò̩ ìdìbò aláìsíníbè̩ nínú ìdìbo 2020, ó s̩ees̩é kí ìdádúrò wà nínú ìròyìn ìbò. E̩ kà sí i nínú Fair Elections During a Crisis láti University of California, Irvine School of Law, àti àwo̩n ìmò̩ràn láti rí ìté̩wó̩gbà.

Èsì Congressional Research Service yìí, The Electoral College: A 2020 Presidential Election Timeline, s̩e àlàyé ipa titi di O̩jó̩ ke̩ta Os̩ù Bélú, ati gbogbo àkókò ìparí, òfin àti ìs̩è̩lè̩ tí ó s̩eés̩e lé̩yìn tí ìbò bá ti jé̩ dídì, tó fi mó̩ àwo̩n ìtaláyà láti tún ìbò dì.

Ohun tí ó lè s̩e̩lè̩ lé̩yìn o̩jó̩ ìdìbò̩ tí àrìyànjiyàn bá wà lórí èsì ń jé̩ gbígbéyè̩wò pè̩lú ojù òfin àti ìs̩èlú.

NCSL s̩e àkójo̩pò̩ àwo̩n òfìn tí ìpínlè̩ kò̩ò̩kan ní fún compiled the rules each state has for àtúnkà dandan, nígbà tí èsì ìbò bá súnmó̩.

Àlàyé kíkún wá láti ò̩dò̩ Edward B. Foley, Ò̩jò̩gbo̩n ìmò̩-òfín ní fáfitì ní Ìpínlè̩ Ohio: Preparing for a Disputed Presidential Election: An Exercise in Election Risk Assessment and Management.”

Òjò̩gbó̩ láti Harvard Law School, Cass R. Sunstein s̩e àlàkalè̩ àwo̩n ipa tí ìwé-òfin US, ilé-è̩kó̩ ìmò̩ ìbò, àpérò àti igbákejì ààre̩ ń s̩e nígbà tí ìbò bá súnmò̩ tí àwo̩n ènìyàn sì ń jiyàn nípa e̩ni tí ó jáwé olúborí: “Post-Election Chaos: A Primer.”

Ò̩jò̩gbó̩n nínú Ìmò̩ Òfin Richard Hasen so̩ nìpa ìwé rè̩, Election Meltdown: Dirty Tricks, Distrust and the Threat to American Democracy nínú ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò fún os̩ù Se̩e̩re̩, O̩dún 2020 pè̩lú Terry Gross láti NPR.

Ìlànà yìí jé̩ kíkójo̩ láti o̩wó̩ olùdari GIJN Resource Center, Lynn Dombek, pè̩lú ìrànwó̩ Toby McIntosh àti àwo̩n òsìs̩é̩ GIJN. Lynn ti lo o̩gbò̩n o̩dún tó ń sis̩é̩ pè̩lú, tí ó sì tún ń darí àwo̩n ikò̩ olùwádìí ní olórí è̩ka ti orílè̩-èdè fún NBC News, ABC News, Time Inc., àti the Associated Press, níbi tí ó ti jé̩ olùdarí ìwádìí wo̩n fún o̩dún mé̩wàá.