Àwo̩n Ò̩nà Mé̩rin tí a fi lè tètè s̩e ìfìdíòdodo-múlè̩ àwòrán lórí è̩ro̩ ìbánisò̩rò̩

Láti o̩wó̩ Raymond Joseph | O̩jó̩ Ke̩rìnlélógún, Os̩ù Ògún, 2021

GIJN ti s̩e àfikún ató̩nà oní-sísè̩-n-tè̩lé wa lórí níní àrídájú lórí àwo̩n àwòrán láti mò̩ bóyá àwòràn tí e̩ ń rí lórí ayélujára jé̩ gidi.

Pè̩lú bí àwo̩n àwòrán ayédèrú s̩e ti pò̩ tó lórí ayélujára, ó dunnu nínú pé àwo̩n ohun èlò ò̩fé̩ tí kò sòrò ó lò wà – lára èyí tí a ti rí TinEye, Google Reverse Image Search, Photo Sherlock, àti Fake Image Detector — tí e̩ lè lò láti lo orísun àwòrán àti bóyá wo̩n s̩e àfo̩wó̩yí rè̩.

Pátákó Ìpolówó Kan, Orílè̩-èdè Mé̩rin, Ìfiráns̩é̩ Mé̩rin

Ò̩nà pò̩ si láti gbin ìròyìn èké ko̩já pípín àwòrán èké nìkan. Sís̩e àfo̩wó̩yí àwòrán tún jé̩ ò̩nà mìíràn láti s̩I àwo̩n ènìyàn ló̩kàn, ló̩pò̩ ìgbà, láti ti ète ìs̩èlú lé̩yìn. 

Fún àpe̩e̩re̩, nígbà tí Belgium’s Médecins Sans Frontieres s̩e àgbékalè̩ pátákó ìpolówó ní Liberia nígbàkan láàrin 2006 tàbí 2007, ète rè̩ ni láti so̩ fún àwo̩n tí wo̩n bá jàajàbó̩ nínú ìfipábánilòpò̩, ibi tí wo̩n ti lè gbe ìtó̩jú. Láìpé̩ yìí, àwòrán pátákó ìpolówó náà tí wo̩n ti yí tí ó sì bani lé̩rù tàn ká lórí àwo̩n ìtàkùn ìbánidó̩rè̩é̩, tí ó tó̩ka iró̩, gé̩gé̩ bí ó s̩e wà nínú AFP Fact Check yìí, pé àwo̩n ènìyàn aláwò̩ dúdú lè pa àwo̩n ènìyàn aláwò̩ funfun ní orílè̩-èdè South Africa, láì sí ìjìyà kankan – pè̩lú àtìlé̩yìn ìjo̩ba tí African National Congress ń darí. 

Ìgbà àkó̩kó̩ tí wo̩n máa yí àwòràn náà pádà kó̩ ni èyí. Snopes kó̩kó̩ ko̩ nipa pátákó yìí kan náà ní o̩dún 2016. Ní inú è̩yà tí ó bani lé̩rù yìí, olùfaragbá orí pátákó náà jé̩ obìnrin aláwò̩ funfun tí wo̩n ń s̩e àfihàn pé àwo̩n o̩kùnrin aláwò̩ dúdú ń fi ìyà je̩. Ìtumò̩ rè̩ nígbà yìí: E̩gbé̩ ìs̩èlú Green League ti Finland ń s̩e àtilé̩yìn ètò àwòs̩e ti ó gba àwo̩n àrè láàyè tí yóò sì fi àwo̩n obìnriin aláwò̩-funfun sílè̩ fún ìyà je̩ ló̩wó̩ àwo̩n àrè. Àwòrán pátákó tí wo̩n yí yìí kan náà ni àwo̩n e̩gbé̩ ti wo̩n kò fara mó̩ àrè pín ní Sweden, wo̩n tún yí olùfaragbá sí aláwò̩ funfun tí ó sì ní àwo̩n ò̩rò̩ tí ó fé̩ jo̩ ayédèrú pátákó ti ilè̩ Finland. 

Torí náà, a ní àgbéjáde kan pè̩lú ìfiráns̩é̩ mé̩rin. S̩ùgbó̩n tí e̩ bá wo ko̩já àgbéjáde tí ó jé̩ òótò̩ gan, lo̩ sí ìpìlè̩, ó hàn pé gbogbo rè̩ ló ní nǹkan kan papò̩. O̩kùnrin kan náa ní ìpìlè̩, àwo̩n o̩kò̩ kan náà ní ìpìlè̩ àti òpó tí ó ń gbé okùn iná lapá ò̩tún pátákó náà hàn gedegbe nínú pátákó ò̩tò̩ò̩tò̩ mé̩rin. Báwo ni e̩ ó s̩e wá bè̩rè̩ sí wo èyí tí ó jé̩ gidi.

The images above — some disturbing — all come from the same photo of a billboard, originally erected as part of an anti-sexual abuse campaign in Liberia by Médecins Sans Frontieres. Clockwise from upper left: the original photo of the billboard in Liberia; altered image circulated on WhatsApp in sub-Saharan Africa; altered images with racist, anti-immigrant messages in Sweden and Finland. Images: Screenshots

Àwo̩n irins̩é̩ tí ó ń s̩e is̩é̩ takuntakun

Nígbà mìíràn, sís̩e àmò̩dájú àworán, fífíò tàbí àgbéjáde lórí ìtàkùn ìbánidó̩rè̩é̩ lè ro̩rùn bí wíwá nǹkan lórí ayélujára. Ó lè rí i gan pé àjo̩ afìdí-òdodo-múlè̩ tí ó s̩e é gbé̩kè̩lé ti s̩e is̩é̩ náà fún e̩.

Ète: Bè̩rè̩ nípa wíwá àwo̩n kókó ò̩rò̩ tí o fé̩ wò lótí Google kí o sì s̩e àfikún “fact-check”.

TinEye

TinEye, ohun èlò ìyípadà wíwá àwòrán máa ń báni wá àwo̩n ìgbà mìíràn ní orí ayélujára tí àwòrán kan náà tàbí èyí tí ó jé̩ é̩ jé̩ títè̩jáde.

Òhun ni irins̩é̩ tí mo fé̩ràn jù torí pé, ju gbogbo àwo̩n irins̩é̩ tí a fi ń wádìí ìbè̩rè̩, ó tún ní ò̩nà láti mo̩ “èyí tí ó ní àyípadà tí ó pò̩ jù”, “èyí tí ó ti pé̩ jù”, àti èyí tí ó tuntun jù nínú àwòrán. Lílo “èyí tí ó ní àyípadà jù”, pè̩lú wíwá àwo̩n èsì fún ojúlówó pátákó ìpolówó ilè̩ Liberia ye̩n gbé ò̩pò̩ èsì jáde, léyìí tí e̩ lè fi s̩e àkàwé èyí tí e̩ ń s̩e ìwádìí rè̩. 

“Tí ó ti pé̩ jù” máa ń sábàá jé kí a mo̩ ìgbà tí wo̩n kó̩kó̩ lo àworán. Tí àkó̩ló t̀abí ìlò mìíràn bá s̩aájú èyí tí o ń wò, ó túmò̩ sí pé nǹkan kan ń s̩e̩lè̩. 

Ó s̩e pàtàkì lát rántí pé TinEye, bí àwo̩n irins̩é̩ ìwá-nǹkan ìpìlè̩ mìíràn, kàn lè rí àwòrán tí wo̩n fi sí orí ayélujára ni. Tori náà, tí àwòrán bá jé̩ yíyà tí wo̩n fi so̩wó̩ sí, bí àpe̩e̩re̩, e̩gbé̩ orí Whatsapp nìkan, tí wo̩n kò fi sí orí ayélujára, e̩ ò lè rí i. 

Bí o s̩e lè fin TinEye wá nǹkan

  1. S̩í TinEye lórí as̩àwákiri orí è̩ro̩ ìbánisò̩rò̩ re̩. Lórí Chrome tàbí Firefox fún alágbèéká, te̩ àwo̩n àmì ìdánudúró mé̩ta tí ó wà lókè tàbí nísàlè̩ lápá ò̩tún ojú amóhùnmáwòrán re̩. Níbi àgbéwálè̩, te̩ “add to home screen”, s̩e àtúns̩e láti rí “TinEye”, kí o sì te̩ “add”. O ti ò̩nà kúkúrú sí TinEye lójú amóhùnmáwòrán re̩.

Mò̩ pé: O lè rí bí o s̩e lè fi ìkànni sí ojú è̩ro̩ alágbèéká iPhone tàbi iPad re̩ nípa lílo sàfárì níbí. Tí o bá ń lo chrome lórí è̩ro̩ alágbèéká Apple re̩, tè̩lé àwo̩n ìlànà yìí.

  1. S̩e àgbàkalè̩ àwòrán tí ó fé̩ fìdí rè̩ múlè̩ nípa̩ títe̩ ojú àwòrán náà mó̩lè̩ títí tí àgbéjáde àkójo̩ yóò fi yo̩. Te̩ ‘save’. O sì tún lè yà á láti ojú fóònù kí o sì fi í pamó̩ sí ibi àwo̩n àwòrán yòókú lórí è̩ro̩ alágbèéká re̩. Kàkà bé̩è̩, s̩e àdàko̩ ìtò̩nà ayélujára tí o fé̩ fi ìdí rè̩ múlè̩ nípa títe̩ àwòrán náà kí o sì s̩e àdàko̩ URL rè̩. Rántí, URL àwòrán náà ni, kìí s̩e ti gbogbo ìtàkùn tí ó ti je̩ yo̩. 
  2. TinEye lórí è̩ro̩ alágbèéká re̩. O ti ní às̩àyàn méjì báyìí. O lè mú “upload image”, kí o sì s̩e àwárí àwòrán tí o ti s̩e àgbàkalè̩ sí orí è̩ro̩ re̩, tàbí kí o se àko̩sílè̩ URL àwòrán náà tí o ti s̩e àdàko̩ sínú àká ìwá-nǹkan TinEye.
  3. Nígbà tí wíwá náà bá ti parí, te̩ àká “sort by” ní apá òsì ní òkè kí o sì mú ò̩kan lára àwo̩n às̩àyàn tí ó wà níbè̩ – tí ó ti pé̩ jù, tí wo̩n ti yí padà jù abbl. Mímú “tí wo̩n ti yí padà jù”, kí a fi pátákó òkè yìí s̩e àpe̩e̩re̩, wá àwo̩n ìgbà tí pátákó láti ilè̩ Liberia náà ti jé̩ yíyípadà láti bá orís̩irís̩I ètò mu. Wá wo àwo̩n àwòrán náà lo̩, kí o sì mú àwòrán tí o fé̩ wò.
  4. Gbé “your image” àti “image match”yè̩wò sí ara wo̩n láti wo bí wo̩n s̩e ti yí àwòrán náà padà.

Google Reverse Image Search

Ohun pàtàkì jù lo̩ tí ó ye̩ fún wíwò nígbà tí a bá ń lo irins̩é̩ yìí ni ìgbà tí àwòrán kó̩kó̩ jé̩ lílò, ibi tí wo̩n ti lò ó, orísun àwòrán náà, àti bóyá orísun náà s̩e é gbàgbó̩.

Ní o̩dún díè̩ sé̩yìn, àwòrán e̩ranko ajeegunje̩ran kan tí ó so mó̩ è̩yìn e̩ye̩ onígi tí ó ń fò gba gbogbo orí ìtàkùn ìbánidó̩rè̩é̩ kan, tí àwo̩n ènìyàn sì ń s̩e àwòrán è̩fe̩ tiwo̩n lára àwòrán náà. Kò jo̩ èyí tí ó lè jé̩ òótó̩, ó ní gbogbo ató̩ka àwòrán ayédèrú. S̩ùgbó̩n lílo Google Reverse Image Search láti fi ìdí rè̩ múlè̩ fi hàn pé òdodo ni tí ó sì jé̩ ara àwo̩n àwòrán alátè̩lé o̩mo̩dé ayàwòrán. Lára àwo̩n ohun tí ó fi àwòrán náà múlè̩ ni ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò BBC pè̩lú ayàwòrán náà gan, tí ó s̩e àlàyé pé òun ni òhun ya àwòrán mériìrí náà.

Ète: Ò̩nà ìwánǹkan kan náà, nípa lílo irins̩é̩ “most changed” ní  TinEye yóò s̩is̩é̩ dáadáa fún èyí.

Bí a s̩e lè lo Google Reverse Image Search

  1. Fi https://images.google.com kún ojú alágbèéká re̩ nípa lílo irú ìlànà  “add to home screen”, fún TinEye tí ó wà lókè yìí.
  2. S̩e àgbàkalè̩ àwòrán tí àwòrán tí o fé̩ lò tàbí kí o s̩e àdàko̩ ató̩ka ìtàkùn ayélujára àwòrán náà. Lé̩è̩kan si, ó gbo̩dò̩ jé̩ àtóka àwòrán náà gangan. 
  3. Tí o kò bá tíì s̩e àgbàkalè̩ ìlànà kúkúrú sí ojú alágbèéká re̩, s̩í https://images.google.com lórí búráósà è̩ro̩ re̩.  
  4. S̩í búráósà, kí o sìyan “Request Desktop Site” nínú àwo̩n àgbéjáde às̩àyàn. Ní Google Chrome, a lè rí às̩àyàn náà nípa títe̩ àmì ìdánudúró mé̩ta tí ó wà ní àpá ò̩tún lókè, t̀abí apá ò̩tún nísàlè̩ fún Firefox. Ni Safari, ìsàlè̩ láàrin ni ó wà.
  5. Nísìnyìí, te̩ àmì ayàwòrán níbi ìwá-nǹkan.
  6. O ti wá ní àwo̩ às̩àyàn díè̩ báyií: s̩e àdàko̩ URL àwòrán náà sí igun ìwá nǹkan, tàbí kí o te̩ “upload an image” láti s̩e àgbàjáde àwòrán láti orí è̩ro̩ ìbánisò̩rò̩ re̩.
  7. Irins̩é̩ yìí ti s̩e ò̩pò̩ is̩é̩, nísìnyìí ye̩ àwo̩n èsì wò láti mo̩ ibi àti ìgbà tí wo̩n ti lo àwòrán náà té̩lè̩ pè̩lú ò̩na tí wo̩n ti gbà lò ó. Ti o bá lo̩ sé̩yìn dáadáa, wà á rí ìgbà  tí wo̩n kó̩kó̩ lò ó àti e̩ni tí ó ni í. 

Ète: Tí o bá ń lo Google Chrome gé̩gé̩ bí awánǹkan gbogbo ìgbà lórí è̩ro̩ alágbèéká re̩, te̩ àwòrán kan mó̩lè̩ lórí ìkànnì kan, àgbéjáde àwo̩n às̩àyàn yóò sì yo̩. Mú “search Google for this image”. 

Photo Sherlock

Mo kanlè̩ fé̩ràn Ohun-èlò Photo Sherlock torí pé, yàtò̩ sí pé ó jé̩ ò̩fé̩, ó máa ń gba ènìyàn láyè láti s̩e ìwádìí ìpìlè̩ àwòrán pè̩lú irinsé̩ ìwá-nǹkan mé̩ta: Google, Yandex, ati Bing. Ó tún ní às̩àyàn láti wá e̩ni tí ó fi àwòrán sínú ìwé-ìròyìn. Lákò̩ó̩kó̩, e̩ s̩e àgbàkalè̩ rè̩ sórí è̩ro̩ alágbèéká re̩, fún  tàbí iPhone

Bí a s̩e ń lo Photo Sherlock 

Tí o bá ti s̩í Photo Sherlock, wàá rí às̩àyàn láti:

  1. Ya àwòrá – ti àlè̩mó̩lé tàbí àwòrán nínú ìwé-ìròyìn – nípa títe̩ àmì ayàwòrán. 
  2. Fi àwòrán so̩wó̩ nípa títe̩ onígun mé̩rin funfun pè̩lú onígun mé̩ta dúdú méjì. Eléyìí máa gbé orís̩irís̩i às̩àyàn wá, lára èyí tí a ti rí “gallery,” [Google] “Drive,” àti “files”, léyìí tí yóò fún wa láàyè sí orís̩irís̩i ibi tí wo̩n fi àwòrán pamó̩ sí. Wá àwòrán tí o fé̩ yè̩ wò kí o sì tè̩ é̩. 
  3. Irins̩é̩ yìí yóò wá wá orís̩i irú àwòrán yìí tí ó wà ní orí ayélujára, yóò sì fí Google s̩e ìbè̩rè̩. Tí o bá fé̩ lo irins̩é̩ ìwá-nǹkan mìíràn tí wíwá náàbá ti parí, te̩ onígun mé̩rin kékeré tí ó ní o̩fà ní ìsàlè̩ alákò̩ó̩kó̩. Wà á rí às̩àyàn láti lo Bing tàbí Yandex, irins̩é̩ ìwánǹkan tí ó ní agbára tí ó sì ko̩jú mó̩ Russia àti apá Ìwò-Oòrùn Yúróòpù. 
  4. Nísìnyìí, s̩e àwárí àwo̩n tí ó jo̩ ó̩ kí o sì wo̩ bi wo̩n s̩e kó̩kó̩ lo àwòrán náà, o̩jó̩ tí wo̩n kó̩kó̩ lò ó àti ibi tí wo̩n ti kó̩kó̩ lò ó. 

Fake Image Detector

Irins̩é̩ yìí máa ń gba ibi méjì sis̩é̩ láti wo ibi tí àwòrán ti wá àti òdodo rè̩. Àkó̩kó̩ ni èyí tí àwo̩n olús̩è̩dá máa ń pè ní “error level analysis” — ohun tí ó máa ń s̩e ní pàtó ni láti wo ìdínkù àwòrán láti mò̩ bóyá wo̩n ti yí i. È̩kejì ni “behind the scenes” tí ó má ń wà tí o bá ti ya àwòrán.

Ète: Orí è̩ro̩ alágbèéká Android nìkan ni irins̩é̩ yìí ti máa ń sis̩é̩ s̩ùgbó̩n Veracity jé̩ irins̩é̩ tó dára fún àwo̩n tí wo̩n ń lo iPhone. Ó wà ló̩fè̩é̩ ní orí Apple app store, kò sì léwu láti lò.

Bí a s̩e ń lo Fake Image Detector

Láti bè̩rè̩ sí lo irins̩é̩ yìí, s̩e àgbàkalè̩ irins̩é̩ Fake Image Detector láti app store Chrome tàbí Firefox. S̩í irins̩é̩ náà, kí o sì mú ò̩kan lára àwo̩n àsàyàn wò̩nyìí:

  1. Yan láti gálé̩rì; eléyìí yóò fún e̩ láàyè sí ibi tí àwòrán máa ń wà ní ìpamó̩ lórí alágbèéká re̩ láti s̩e ìwádìí ìpìlè̩ fún àwòrán. 
  2. Mú lára àwo̩n àwòrán tí kò tíì pé̩; mú àwòrán ìwé ìlèwó̩, tàbí àwòrán inú ìwé ìròyìn.
  3. Wa rí èsì tí ó so̩ pé “Digitally Altered”, “Not from Camera”, “50-50 Chance”, tàbí “Like a Real Camera Image”. Mò̩ pé èyí kàn jé̩ àfihàn pé nǹkan ń s̩e̩lè̩ àti pé o ní láti s̩e sùúrù. 
  4. Nísàlè̩ ìdáhùn kò̩ò̩kan, wa rí metadata nípa àwòrán re̩. Ohun tí ó wúlò jù láti wa, tí wo̩n kò bá tíì yo̩ ni o̩jó̩ àti ìgbà ti ògidì, tí yóò so̩ ìgbà tí ó jé̩ yíyà.

Ètè fún sís̩e ìfimúlè̩ àwòrán

Pè̩lú àwo̩n è̩kó̩ tí o ti ní gé̩gé̩ bí oníròyìn, àwo̩n ìbéèrè tí ó ye̩ nígbà tí o bá rí àwòrán tí ó lè jé̩ tàbí kí ó má jé̩ ògidì:

  1. Ǹjé̩ ògidì àwòrán náà ni o ń wò?
  2. Ìgbà wo ni wo̩n kó̩kó̩ lò ó àti pé o̩jó̩ wo ni ó s̩aájú èyí tí o ń wò dájú?
  3. Ibo ni ojú-ìlò rè̩ àkó̩kó̩? Fi só̩kàn pé àwo̩n àwòran tí ó jé̩ ògidì láì ní àbùlà máa ń jé̩ lílò kúrò ní ojú-ìlò pè̩lú ète láti s̩i àwo̩n ènìyàn ló̩kàn. 
  4. Ǹjé̩ o mo̩ e̩ni tó ya àwòrán náà? Mímo̩ e̩ni tí ó yà á túmò̩ sí pé o lè pè wó̩n kí o sì béèrè àwo̩n ohun mìíràn àti ìlò.
  5. Ǹjé̩ o mo̩ ibi tí wo̩n ti ya àwòrán náà? Kín ni àwo̩n ènìyàn ń wò̩? Ǹjé̩ as̩o̩ wo̩n bá ìmúra ibi tí wo̩n so̩ pé àwòrán náà ti jé̩ yíyà mu?
  6. Wá àwo̩n àmì ojú pópó àti àwo̩n ìpolówó mìíràn, àko̩lé ilé-ìtajà àti pátákó ìpolówó, nó̩ḿbà o̩kò̩ àti ohunkóhun tí ó bá lè ràn ó̩ ló̩wó̩ láti mo̩ ibi tí wo̩n ti ya àwòrán náà.
  7. Báwo ni ojú-o̩jó̩ s̩e rí nínú àwòrán náà? Tí o bá mo̩ o̩jó̩ tí wo̩n ya àwòrán kan, lo WolframAlpha láti wádìí bí ojú-o̩jó̩ s̩e rí ní o̩jó̩ náà láti mò̩ bóyá ó bá tinú àwòrán mu. 
  8. Wo bí ìmò̩lé̩ s̩e rí nínú àwòrán náà. S̩e àwo̩n ohun tí wo̩n súmó̩ ara wo̩n mó̩lè̩ bákan náà àbí ò̩ka jo̩ pé ó tàn tàbí dúdú? Tí ó bá rí bé̩è̩, ó fé̩rè̩é̩ ní láti jé̩ pé wo̩n ti fi kún-un tàbí kí wo̩n yí i.
  9. S̩e àwo̩n ènìyàn , nǹkan tàbí ènìyàn inú àwòrán  ní igun tí kò dán tó?tí ó bá rí bé̩è̩, ó lè jé̩ ató̩ka pé wo̩n ti yí i. 
  10. Wádìí òjìji. Pàápàá. Pè̩lú àwo̩n àwòrán tí wo̩n bá yí pè̩lú àìfarabalè̩ tí wo̩n fi nǹkan kún, wo̩n kìí sábà ní òjìji torí wo̩n s̩òro láti s̩e.
  11. Wá àwo̩n ìwò̩n àti ìrísí àwòrán tí kò bá gbèdeke mu. Ó máa ń sábà tó̩ka sí pé wo̩n ti s̩e àtúns̩e sí àwòrán náà láti yo̩ ohun tí ó s̩e pàtàkì.
  12. Nínú ìs̩è̩dá, oris̩irís̩i òye àti àwò̩ ló wà. Tí ò̩pò̩ ibi nínú àwòrán bá papò̩ ní àwò̩, ó lè jé̩ ìtó̩ka pé wo̩n ti lo irins̩é̩ ìyì-àwòrán láti s̩e è̩dà, fi kún tàbí yo̩ nǹkan.
  13. Tí o bá ń wá àwòrán tí ó mó̩lè̩ pè̩lú jú ènìyàn kan nínu rè̩, wo inú ojú wo̩n láti mò̩ bóyá òye tí ó hàn bára mu.

Ìbéèrè tí ó gbo̩ngbó̩n fún gbogbo wa, yálà a ń s̩e àgbéyè̩wò àwòrán náà gé̩gé̩ bí oníròyìn tàbí aráàlú lásán, ni: s̩é o mo̩ èrè o̩kàn e̩ni tó ya àwòrán náà? S̩é àwòrán náà bà ó̩ nínú jé̩, mú inú bí e̩ tàbí mú ìmò̩lara líle kan jáde láti ò̩dò̩ re̩. Àwo̩n àwòrán tí wo̩n ti yí tàbí s̩ì lò máa ń sábà jé̩ láti fi ìmò̩lara àwo̩n ènìyàn s̩eré.

Gbogbo è̩, gbògbò è̩? Tí kò bá dá o̩ lójú, má pín in. O le jé̩ ara ojútùú sí “ìròyìn èké”, tàbí láti jé̩ ara ìs̩òro.

Ohun Èlò

Àwo̩n wò̩nyìí ni irins̩é̩ àwòrán wíwá tí e̩ lè yè̩ wò:

  • FirstDraftNews, lára èyí tí a ti rí fídíò nípa ìyípo àwòrán àti ohun-èlò tí ó s̩e s̩e àgbàkalè̩ fún sís̩e àrídájú awòrán. 
  • Google’s Fact Check Explorer jé̩ kókó ò̩rò̩ láti wá àrídájú nípa ènìyàn tàbí àkòrí.
  • Fullfact lórí mímo̩ àwòrán tó n s̩i ènìyàn lónà tàbí tí wo̩n ti yí po.
  • How-To, Ató̩nà Geek lórí mímo̩ nípa àwòrán . 
  • Àkótán GIJN lórí ìfìdí-òdodo-múlè̩ àti àrídájú tún ní àwo̩n ohun èlò tí ó gbo̩n-n-gbó̩n fún àrídájú fídíò àti àwòrán.

Additional Reading

Ató̩nà tí ó gbòòrò si lórí wíwádìí àkóónú fídíò

Àpótí ohun-èlò GIJN: wíwádìí orúko̩ àti ìtàkùn, àrídájú fídíò, ìtàkùn ìwá-nǹkan tí ó kún fó̩fó̩

ìbéèrè-oun-ìdáhùn ojoojúmó̩ tí ó máa ń kó̩ àwo̩n onís̩é̩ ìròyìn láti wádìí ibùdó àwòrán

Ò̩nà mé̩ta láti s̩e àrídájú àwòrán lórí fóònù

Raymond Joseph jé̩ onís̩é̩-ìròyiìn adás̩é̩s̩e àti olùkó̩ is̩é̩-ìròyìn. Ó wà lára àwo̩n tí ó gba àmì-è̩ye̩ Nat Nakasa Community Journalism Award fún is̩é̩-ìròyìn onígboyà. Ó máa ń kó̩ àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn nípa ìfìdí-òdodo-múlè̩ àwo̩n àkóónú orí ayélujára àti ìtàkùn ìbánidó̩rè̩é̩, ó sì tún jé̩ olùgbéyè̩wò fún Poynter-hosted International Fact-Checking Network.