Àtúpalẹ̀ Dátà – SQL

Padà sí orí ìkànnì ojú ewé iwájú

SQL jẹ́ ohun èlò tí wọ́n máa ń lò nígbà gbogbo nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀

lú ibi tí aà ń fi àwọn irin

iṣẹ́ pamọ́ sí. Ní pàtàkì jù lọ, wọ́n máa ń lò fún ohun èlò dátà tó bá pọ̀ ní jàńtìrẹrẹ, tó lè bá Excel

ṣiṣẹ́ àti ṣe àkójọpọ̀ dátà lóríṣiríṣi fún àtúpalẹ̀ to yẹ. Onírúurú àìmọ́yé rẹ̀ ni wọ́n máa ń lò nínú

yàrá ìkóròyìn jọ tí kò sì yọ Postgresql àti DB Browser tí wọ́n ń lò fún SQLite sílẹ̀.

Díẹ̀ rèé lára àwọn ọ̀nà tí a lè fi bẹ̀rẹ̀.

Àgbékalẹ̀ àwọn ọ̀nà mẹ́ta lórí bí a ṣe lè lo QL ni wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ ní GIJC19 láti ọwọ́ Jodi Upton

tí ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Syracuse, akọ̀ròyìn kan tí iṣẹ́ rẹ̀

jọ mọ́

iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn, Crina Boros àti

Helena Bengsston tí ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n Sveriges Television ní ìlú Sweden. SQL (Apá kìn ín ní),

SQL (Apá kejì ), SQL (Apá kẹta).

Excel sí SQL Crosswalk (2017) láti ọwọ́ MaryJo Webster jẹ́ atọ́nà tó ṣe àpèjúwe ìbámu tó wà

láàárín Excel àti SQL fún àwọn akọ̀ròyìn tó fẹ́ ní ìmọ̀ si nípa SQL, tí wọ́n sì ti mọ́ díẹ̀ nípa Excel.

Àfihàn SQL fún Iṣẹ́ Ìròyìn tó jọ mọ́ Dátà (2014) jẹ́

lára ìwé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún kíláàsì Dan Nguyen

ní ìlú Stan Ford. Ó bojú wo àwọn ohun èlò pàtàkì bíi SQL, pẹ̀

lú àwòrán, iṣẹ́ àdáṣe, àti atọ́nà fún

ìgbésẹ̀ tó yẹ láti tẹ̀

lé fún àwọn ìbéèrè lórí SQL. Ó tún ṣe atọ́nà fún Ìgbáradì lórí àwọn àkọlé tó ní

kìmí dáadáa.

Ilé Ẹ̀kọ́ Khan ń pèsè Ìfihàn sí ìlànà ìkọ́ni fún SQL pẹ̀

lú fọ́nrán ìkọ́ni ọ̀fẹ́. Ó tún bojú wo àwọn

ohun àmúlò gbogbo, ẹ̀ka ò jẹ̀ka, àwọn àtúntò gbogbo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀

lọ.

Ohun èlò SQL (2018) láti ọwọ́ Anthony DeBarros jẹ́ ọ̀pákútẹ́

lẹ́ fún kókó ọ̀rọ̀ tó ṣe gbòógì láti lo

èdè fún àtúpalẹ̀ dátà, àwọn ohun nípa lílo ìkànnì PostgreSQL, èyí tó jẹ́ ọ̀nà àrà láti ṣe àkójọpọ̀

dátà. DeBarros jẹ ògbóǹtarìgì nínú iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ dátà. Lọ́wọ́ báyìí, ó jẹ́ Olóòtú ìròyìn tó jọ

mọ́ dátà pẹ̀

lú ìwé ìròyìn Wall Street, ní Washington, D.C. (Ó wà fún títà )

Udemy ń pèsè offers ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ìkànnì SQL lọ́fẹẹ̀ẹ́, lórí fọ́nrán, lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Padà sí orí ìkànnì ojú ewé iwájú