Padà sí orí ìkànnì ojú ewé iwájú
Àwọn ìwé atọ́nà wọ̀nyí jẹ́ ohun èlò àkọ́kọ́ fún àwọn akọ̀ròyìn láti lò.
Wọ́n kéré lọwọ, lọ́nà tó ní àgbékalẹ̀ bíi .csv files. Microsoft Excel àti ojú òpó Google, jẹ́ àwọn
ohun èlò tí wọ́n máa ń lò jùlọ. Àwọn ohun èlò tí yóò ṣe ìrànwọ́
láti kiri ká lórí ìkànnì Excel àti ṣe
àlékú ìmọ̀ rẹ ló wà ní ìsàlẹ̀ yìí.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ ìròyìn tó jọ mọ́ Dátà: Excel fún àwọn Ìpẹ́ẹ́ẹ̀rẹ́
jẹ́ ètò Ìkọ́ni láti ọwọ́
akọ̀ròyìn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan MaryJo Webster tó ṣàlàyé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ló ìkànnì Excel àti ṣíṣe
àpèjúwe àwọn ohun èlò pẹ̀
lú àwòrán láti fi kín in lẹ́yìn.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí wá fún àwọn ti wọ́n ń lo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà orí tábìlì, sìbẹ̀ àwọn ohun èlò yìí wà
bákannáà fún àwọn tó ń lo kọ́ ǹpútà alágbèkáá.
Coursera àti edX náà pèsè ètò ìdáni lẹ́ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fọ́nrán lórí ìkànnì Excel fún oko òwò, àtúpalẹ̀
dátà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀
lọ. Kìí ṣe pé wọ́n fi orí àwọn wọ̀nyí sọrí iṣẹ́ ìròyìn ṣùgbọ́n ó lè kọ́ni nípa yíyí
nípa ìròyìn tó níí ṣe pẹ̀
lú dátà.
Wíwà Ìròyìn Lórí Ìwé àtẹ Spreadsheets (2016) láti ọwọ́ akọ̀ròyìn ọmọ ilẹ UK kan, Paul
Bradshaw ṣàlàyé pé ó jẹ́ ohun èlò fún àwọn oníròyìn alákọ̀bẹ́rẹ̀. Ó tún ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn nípa
wíwá ìròyìn láti inú àtẹ spreadsheet, tó tún jẹ́ alátìkẹyìn gidi fún àwọn akọ̀ròyìn. . (Ó wà fún títà).
GFCGlobal ń pèsè ètò ìdáni lẹ́ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́
lórí Excel pẹ̀
lú àwọn àkòrí bíi àtúntò, àwọn iṣẹ́ gbogbo,
yíyà sọ́tọ̀, tábìlì Pivot àti ìwé àwòrán. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí wá pẹ̀
lú ìdánwò kékeré.
Mr Excel jẹ ohun èlò láti dáhùn ìbéèrè lórí ìkànnì tó jọ mọ́ resource Excel. Bill Jelen ti ń ṣe
àkójọ rẹ̀
láti ọdún1998.
Atọ́nà fún Àwọn Akọ̀ròyìn lórí Excel (2016) ń pèsè àwọn àwòrán àti ìtọ́sọ́nà lórí lílo ìkànnì Excel
fún iṣẹ́ ìròyìn bíi tábìlì pivot àti àfọ̀mọ́ dátà. Ó tún ń ṣe atọ́nà fún àtẹ tí wọ́n ń lò fún Ìgbáradì.
Àtẹ fún Iṣẹ́ ìròyìn (2019) jẹ́ ọ̀nà tó yá kánkán fún àfihàn láti ọwọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa
iṣẹ́ ìròyìn nílẹ̀ Amẹ́ríkà Brant Houston lórí bí wọ́n ṣe ń lo ìkànnì Excel fún àtúpalẹ̀ dátà. Ó tún
ṣàlàyé díẹ̀
lára àwọn ohun èlò tí yóò jẹ́ kí ìkànnì Excel wúlò dáradára àti àpèjúwe bí wọ́n ṣe ń ṣe
ìṣirò ìpín tí wọ́n fi ń ṣe ìṣirò ní pẹrẹhu.
Padà sí orí ìkànnì ojú ewé iwájú