ÀRÙN KÒRÓRÀ

Àwọn tó Lùgbàdì Àrùn Kòrónà tí kò Fara Hàn 

By Ilé iṣẹ́ tó ń rí sí iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn ti Howard | Ọgbọ́n Ọjọ́, Oṣù Ọ̀pẹ, Ọdún 2020

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ẹ̀ka tó ń rí sí iṣẹ́ ìwádìí lórí Ìròyìn ti ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Arizona ti ṣe àgbéyẹ̀wò bílíọ́ọ̀nù mẹ́rin dọ̀là tí wọ́n yọ láti inú owó tí Wọ́n là kalẹ̀ fún Àjàkálẹ̀ Àrùn Kòrónà, tí wọ́n fi ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí kò ní ilé lórí, láti fi ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn. 

Àkànṣe iṣẹ́ ọ̀hún lórí ẹ̀rọ ayélujára dá lé àtúpalẹ̀ ìròyìn, àwọn àwòrán àti bí wọ́n ṣe ṣe àlàyé lẹ́kùńrẹ̀rẹ́ lórí lílọ dátà fún àgbékalẹ̀ ìròyìn ọ̀hún.