Láti o̩wó̩ Laura Dixon | April 5, 2021
Ní GIJN, a s̩e oríire láti s̩e alábàápàdé àwo̩n orís̩irís̩i ìwé àti ìròyìn lórí ipò is̩é̩-ìgbóhùnsáfé̩fé̩ aje̩mó̩ròyìn àti ìròyìn ò̩te̩lè̩múyé̩ tí ó mó̩yán lórí. Èyí ni méjìlá nínú àwo̩n àko̩sílè̩ tí wo̩n dùn-ún kà tí a s̩è̩s̩è̩ ri pé àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn ò̩te̩lè̩múyè̩ lè fé̩ mú kà ní 2021, pè̩lú ìwé-àròko̩ tí oníròyìn ò̩te̩lè̩múyé̩ ko̩ fún ìsinmi ránpé̩.
“The Mojo Handbook: Theory to Praxis,” láti o̩wó̩ Ivo Burum. Ató̩nà oní ojú-ewé ò̩ó̩dúrún lé ní àádó̩ta yìí jé̩ èyí tí Mojo Workin’ columnist Ivo Burum ti GIJN fúnra rè̩ ko̩ tí ó sì fúnni ní ìdánilé̩kò̩ó̩ ráńpé̩ lórí lílo àwo̩n ohun-èlò orí è̩ro̩ alágbèéká láti so̩ ìtàn olójú púpò̩. Pè̩lú àwo̩n ìmò̩ràn lórí sís̩e àkásílè̩ fídíò tó jo̩ ìwé aláko̩sílè̩ pè̩lú ohùn tó já gaara, sís̩e àtúns̩e lórí è̩ro̩ ìbánisò̩rò̩ e̩ni, àti ìtàn síso̩ lórí è̩ro̩ alágbèéká fún àkóónú tó ń dáni lára yá, tó sì ń fani mó̩ra.
“A Taste for Trouble,” Láti O̩wó̩ Aniruddha Bahal. Ní ogún o̩dún sé̩yìn, Bahal s̩e è̩dá a global storm by investigating match-fixing by some of India’s top cricketers. O kò lè mú is̩é̩ sís̩e àkóso ilé-is̩é̩ eré-ìdárayá tí ó gbo̩nńgbó̩ jù ní India té̩ḿbé̩lú, Bahal sì ní orúko̩ fúnra rè̩ gé̩gé̩ bí “the father of sting journalism in India”. Ìwé rè̩ tí ó jáde gbè̩yìn, “A Taste for Trouble,” jé̩ kíko̩sílè̩ ní àsìkò ìs̩émó̩lé, tí ó sì sò̩rò̩ nípa gbogbo nǹkan láti ìgbà kékeré rè̩ títí ìgbà tí ó fi dá ìbùdó is̩é̩ ìwádìí tirè̩ náà (GIJN member Cobrapost) sílè̩ nígbà tí ó jé̩ pé – gé̩gé̩ bí àko̩sílè̩ Hindustan Times – “síso̩ òdodo sí agbára kò sí nínú èrò àwo̩n ilé-is̩é̩ ìròyìn mó̩”.
“We Are Bellingcat,” láti o̩wó̩ Eliot Higgins. Nígbà tí ilé-is̩é̩ ìròyìn kékeré bá so̩ ara wo̩n di ò̩rò̩ ìgboro, e̩ ó mò̩ pé nǹkan ń s̩e̩lè̩. Nígbà tí àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn sì ti wo Bellingcat pè̩lú òye fún ìgbà díé̩, àwo̩n àgbéjáde wo̩n láìpé̩ yìí tí wo̩n fi è̩sùn kan FSB, e̩gbé̩ alamí Russia, FSB nípa fífún alátakò Alexey Navalny ní májèlé je̩, gba gbogbo ayé kan ní o̩dún yìí. Ìwé Olùdásílè̩ Eliot Higgins nípa e̩gbé̩ náà — “We Are Bellingcat” — kò lè wá ní àkókò tí ó dára jù bé̩è̩ lo̩. E̩ ka àyó̩ka GIJN níbí.
“You Don’t Belong Here: How Three Women Rewrote the Story of War,” láti o̩wó̩ Elizabeth Becker. Àwo̩n olùbánisò̩rò̩ òkèèrè lè gbé ìròyìn ojoojúmó̩ tàbí ìpapòdà agbára ní o̩jó̩ pípé̩, s̩ùgbó̩n wo̩n tún lè gbé iwájú gbé ìròyìn jáde láti yí ìtàn padà. Ìwé yìí, láti o̩wó̩ àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn Elizabeth Becker, s̩e àgbéyè̩wò àwo̩n olùbánisò̩rò̩ obìnrin tí wo̩n pinnu láti yí òdiwò̩n jíjé̩ olùbánisò̩rò̩ o̩kùntin padà nípa bíbó̩ sí iwájú nígbà rúkèrúdò Cambodia láwo̩n o̩dún 1970, tí wo̩n sì yí ìtàn US nípa rúkèrúdò náà padà, tí wo̩n sì s̩e ìránwó̩ fún ìgbédìde Pol Pot, Olórí as̩ekúpani Khmer Rouge.
“Unsafe for Scrutiny,” láti o̩wó̩ The Foreign Policy Center. A lè pè é ní ìròyìn tí ó nípo̩n, kàkà tí a ó fi pè é ní ìwé, aàtè̩jáde yìí lórí àwo̩n ìdojúko̩ àwo̩n onís̩é̩ iròyìn lórí ríròyìn ìwà ìbàjé̩ tí ó je̩ mó̩ ò̩rò̩-ìsúná àti ìwà ìbèjé̩ lè gba omijé lójú ènìyàn. Ìròyìn “Unsafe for Scrutiny” yìí— tí ó dá órí ìwádìí tí wo̩n s̩e àgbéjáde rè̩ ní ìparí o̩dún tí ó ko̩já – rí i pé ìdá mó̩kàléláàdó̩rin nínú ìdá o̩gó̩rùn-ún ló ti ni ìrírí ìdé̩rùbani tàbí ìyo̩nilé̩nu nígbà tí wo̩n ń s̩e ìwádìí lórí ìwà ìbàjé̩ tí ó je̩ mó̩ ètò ìsúná àti ìwà ìbàjé̩. Ò̩rò̩ àti àko̩sílè̩ ìdé̩rùbani, àti bíbanilórúko̩jé̩ lórí ayélújára jé̩ ìdáhùn tí ó pò̩ jù, tí ó sì wó̩ pò̩ jù láàrin àwo̩n oníròyìn ò̩te̩lè̩múyè̩ obìnrin jù àwo̩n o̩kùntin e̩gbé̩ wo̩. Èyí tí ó pò̩ jù wà ní ààrin gbùngbùn apá ilà oòrù, àti Àríwá Áfíríkà, níbi tí gbogbo àwo̩n olùbánisò̩rò̩ tí wo̩n wádìí so̩ pé àwo̩n ti gba ìbáwí lé̩nu is̩é̩, tí ìdá o̩gó̩rin àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn tí ó ń sis̩é̩ ní àwo̩n Orílè̩-èdè Soviet Union té̩lè̩té̩lè̩ náà sì tè̩lé e.
“Classroom 15: How the Hoover FBI Censored the Dreams of Innocent Oregon Fourth Graders,” láti o̩wó̩ Peter Laufer and students. Sís̩e àyè̩wò àko̩sílè̩ 21 Best New Journalism Books to Read in 2021 yìí láti o̩wó̩ BookAuthority, A rí díè̩ nínú àwo̩n àko̩lé tí ó fani mó̩ra fún àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn ò̩te̩lè̩múyé̩. Àkó̩kó̩ ni “Classroom 15: How the Hoover FBI Censored the Dreams of Innocent Oregon Fourth Graders”, ìwé láti o̩wó̩ Peter Laufer tí ó dá lórí ìwádìí àwo̩n aké̩kò̩ó̩ ní University of Oregon, tí wo̩n gbórìyìn fún lé̩gbè̩é̩ kan. Ìwé náà s̩e àyè̩wò bí McCarthyism tí ó ní oró s̩e kó bá àwo̩n o̩mo̩ o̩dún mé̩sàn-án àti mé̩wàá tí wo̩n ń wá ò̩ré̩ ìbákò̩wé, tí wo̩n kò gbà láàyè láti ko̩ ìwé sí àwo̩n ake̩gbé̩ wo̩ ní Soviet Union torí è̩rù “Communist propaganda”. Nígbà tí ìtàn náà jáde nígbà tí àwo̩n FBI ń s̩̩e ìwádìí, olùkó Geography kíláàsì náà gba ìbáwí púpò̩ láti o̩wó̩ àwo̩n ará ìlú tí wo̩n kò dé̩kun.
“Dark Mirror: Edward Snowden and the American Surveillance State,” láti o̩wó̩ Barton Gellman. Láti inú àkójo̩pò̩ BookAuthority fún 2021 náà ni ìwé yìí láti o̩wó̩ e̩ni tí ó ti gba è̩bùn Pulitzer ní è̩è̩me̩ta, Barton Gellman. Ní o̩dún 2013, Edward Snowden fún onís̩é̩-ìròyìn náà, pè̩lú Laura Poitras àti Glenn Greenwald, ní àwo̩n àko̩sílè̩ kan tí ó s̩e àlàyé kíkú nípa ààyè tí ìjo̩ba ilè̩ Amé̩ríkà ní sí ìbánisò̩rò̩ àwo̩n ará ìlú. As̩àyè̩wò kan pe ìwé yìí, tí yóò jáde ní Os̩ù Èbìbí ní, “the definitive master narrative of Edward Snowden and the modern surveillance state”.
“She Said: Breaking the Sexual Harassment Story that Helped Ignite a Movement,” láti o̩wó̩ Jodi Kantor and Megan Twohey. Ìwé yìí láti o̩wó̩ àwo̩n olùborí ìdíje Pulitzer Jodi Kantor àti Megan Twohey jé̩ ìs̩irò is̩é̩-ìwádìí wo̩n nínú Harvey Weinstein fún The New York Times, àti bí wo̩n s̩e lo ìfò̩rò̩wanilé̩nuwò pè̩lú àwo̩n òs̩èré, àwo̩n òsìs̩é̩ té̩lè̩, àti àwo̩n orísun mìíràn láti s̩e ìwádìí è̩sùn ìdójú ìjà ko̩ ènìyàn lórí ò̩rò̩ ìbálòpò̩ àti ìfipábánilò. Weistein wo̩ àtìmó̩lé ní 2020, os̩ù díè̩ lé̩yìn tí ìwé náà jé̩ gbígbéjáde. Aláríwísí New York Post náà, Carlos Lozada pe àtè̩jáde náà ní “an instant classic of investigative journalism … ‘All the President’s Men’ for the Me Too era.”
“The Data Journalism Handbook: Towards a Critical Data Practice,” àtúns̩e láti o̩wó̩ Liliana Bounegru àti Jonathan Gray. Àgbéjáde yìí kó orí méjì tó jé̩ ti àwo̩n ènìyàn GIJN sínú: own: Eunice Au àti Pinar Dağ, tí àwo̩n méjèèjì kò̩wé ní sísè̩-n-tè̩lé, nipa lílo #ddj ìpè lórí Twitter ati lórí títo̩pa ikú àwo̩n òsìs̩é̩ ní Turkey.
“The Golden Thread: The Cold War and the Mysterious Death of Dag Hammarskjöld,” láti o̩wó̩ Ravi Somaiya. Ikú akò̩wé àgbà fún United Nations Secretary General Dag Hammarskjöld ní o̩dún 1961 — e̩ni tí wo̩n bá lókùú nínú igbó lé̩yìn tí o̩kò̩ òfúrufú rè̩ jábó̩ ní ibi tí ó jé̩ Northern Rhodesia nígbà náà – jé̩ ò̩kan lára àwo̩n ìpànìyàn tí ó rúnni lójú jù ní àkokò Ogun odì. O̩kùnrin náà ti fi ìgbà kan pe ààre̩ US John F Kennedy ní “Òs̩èlú ńlá ti ìgbà wa”, wà ní is̩é̩ àpínfúnni fún who àlàáfíà nígbà náà. E̩ni tí ó ti fi ìgbà kan jé̩ òǹkò̩wé New York Times Ravi Somaiya s̩e àkójo̩pò̩ àwo̩n è̩rí àti ìjé̩rìí tuntun láti s̩e àyè̩wò ohun tí ó pè ní “ò̩kan lára àwo̩n àdìítú Ò̩rúndú Ogún”.
“Plata como cancha,” láti o̩wó̩ Christopher Acosta. Láti Peru ni ìwé Èdè Spanish “Plata como cancha” (tí a lè ro̩ra túmò̩ sí “owó tó pò̩”) tí ó so̩ ìtàn ìgbésí-ayé, ìtàn ìs̩èlú, àti is̩é̩ sís̩e olùdíje fún ipò ààre̩ César Acuña Peralta ti wá. Ìtumò̩ ìwé náà – “Às̩írí, àìbìkítà, ìs̩èlú àti ìgbé-ayé is̩é̩ César Acuña” — lè s̩e àlàyé ìdí tí kò tí fi gbogbo ara jé̩ ìté̩wó̩gbà gbogbo ayé, tí ó sì ń fa àròyé aje̩mófin, àti ìbéèrè oé kí wo̩n kó o kúrò ní o̩jà. Àwo̩n ìbéèrè náà ti jé̩ títè̩mó̩lè̩ láti o̩wó̩ IPYS tó jé̩ olùgbanisís̩e Acosta té̩lè̩, Institute for Press and Society tí ó wà ní ilè̩ Lima, tí ó so̩ pé irú ìbéèrè bé̩è̩ “te̩ òmìnira ìsò̩rò̩ mó̩lè̩ gidi”
“Investigative Journalism,” láti o̩wó̩ Hugo de Burgh and Paul Lashmar. Ìwé-ìléwó̩ yìí láti o̩wó̩ àwo̩n onís̩é̩ akadá tí wo̩n ń ko̩ àwo̩n ènìyàn ní Uniiversity of Westminister àti City University ni UK, jé̩ àmúlò ìwádìí fún àwo̩n oníròyìn fún ò̩pò̩ o̩dún. Àgbéjáde e̩lé̩è̩ke̩ta jé̩ títè̩jáde ní Os̩ùn E̩ré̩nà, 2021, tí ó sì s̩e àlàkalè̩ “ayé tuntun fún is̩é̩ ìwádìí”, tí ó dá lé orí ipa ìmò̩ è̩ro̩ àti ayélujára. Ó dá lórí ìwádìí sínú ìwà ìbàjé̩ EU, ìparun àgbègbè Malaysia, àti is̩é̩ ìwádìí ní China, Poland, Turkey, àti ibòmìíràn. Sheila S colonel, olùdarí Stabile Center for Investigative Journalism ní Columbia university s̩e àkíyèsí pé ìwé náà “to̩pa àgbéjáde àwo̩n ohun èlò àti ìlànà tuntun láti pe agbára lé̩jó̩, tí ó sì tún s̩e àpéjúwe àwo̩n àwòkó̩s̩e tuntun tí ó ń jáde fún ìbàdápò̩ káàkiri àti ààbò”.
“In the Company of Killers,” láti o̩wó̩ Bryan Christy. Kín ni àwo̩n onís̩é̩-ìròyìn máa ń kà fún afé̩? Ìwé ìtàn ò̩te̩lè̩múyé̩ tí onís̩é-ìròyìn ò̩te̩lè̩múyé̩ ko̩ ńkó̩? Ìwé yìí láti ò̩wó̩ by Bryan Christy, e̩ni tí ó ti fi ìgbà kan rí jé̩ olórí ago̩n àkàns̩e ìwádìí fún National Geographic, tí is̩é̩ ìwádìí rè̩ sì jé̩ kí o̩wó̩ òfin te̩ Anson Wong, e̩ni tí wo̩n ń dà pè ní “the Pablo Escobar of wildlife trafficking”. Ìwé náà dá lórí è̩dá-ìtàn mériìrí Tom Klay. Is̩é̩ Klay? Ó jé̩ oníròyìn ò̩te̩lè̩múyé̩ tí ó je̩ mó̩ e̩ranko igbó fún gbajúgbajà ìwé-ìròyìn.
Àwo̩n ohun tí ó tún wà fún kíkà
Data Journalism Books: The GIJN Collection
Writing a Nonfiction Book? Here’s Advice from a Pulitzer Prize Bestselling Author
Journalists and True Crime: The Best Narrative Nonfiction Crime Books by Reporters
Laura Dixon jé̩ as̩àtúnko̩ oníbàátan àti onís̩é̩-ìròyìn adás̩é̩s̩e. Ó ti ròyìn láti Columbia, US àti Mexico, awo̩n is̩é̩ rè̩ ti jé̩ títè̩jáde pè̩lú The Times, The Washington Post àti The Atlantic pè̩lú àwo̩n yòókù. Ó ti gba àjo̩s̩epò̩ aje̩mó̩ is̩é̩-ìròyìn láti IWMF àti The Pulitzer Center, tí ó tì tún jé àra Transparency International’s Young Journalists Program.
TÍ Ó KÀN FÚN KÍKÀ
GIJN Bookshelf: 7 Investigative Titles to Read in 2022
Àfikún àpótí-ìwé GIJN tí ó tuntun jù yìí pè̩lú àwo̩n èrò láti ò̩dò̩ àwo̩n as̩àtúnko̩ wa káàkiri àgbáyé. Tí ó sì ní àwo̩n àkòrí lórí sís̩í àwo̩n ìwà ìbàjé̩ tí ó je̩ mó̩ COVID-19, títo̩pa pípa àkò̩ròyìn kan, àti fífi ojú-ìtàn wo àkó̩kó̩ oníròyìn ò̩te̩lè̩múyé̩ obìnrin, pè̩lú wíwádìí àdìítù o̩kò̩-òfúrufú ńlá tí ó ya gbogbo ayé lé̩nu.
Investigating Russia Around the World: A GIJN Instant Toolkit
GIJN ti s̩e àkójo̩pò̩ irúfé̩ àká ohun-èlò kan láti ran àwon onís̩é̩-ìròyìn ló̩wó̩ láti wádìí owó Russia, ìdásí àwo̩n òs̩èlú, àti ìròyìn èké ní ìlú tiwo̩n. Láti ibi àwo̩n o̩kò̩ òfúrufú aládàánìkàn-s̩e-ìjo̩ba sí àwo̩n amójútó owó kò-tó, e̩ ó rí ìtàkùn tí ó lé ni o̩gbò̩n ní ibí.
Freedom of Expression: Asia Pacific Round-Up
Ìró̩ké̩ké̩ mó̩ àwo̩n àjo̩ aláìgbára-lé-ìjo̩ba àti àwo̩n e̩gbé̩ ajàjàgbara o̩mo̩nìyàn ti rú ga sókè ní ò̩pò̩ ìlú káàkiri ilè̩ Ás̩íà àti Pásífíìkì, lára èyí tí a ti rí gbígbé àwo̩n ajìjàgbara tí wo̩n ta ko ìbò fún e̩gbé̩ ìs̩èlú kan ní ilè̩ Thailand àti àwo̩n alátìlé̩yìn West Papua Freedom movement ní Pásífíìkì.