Àwọn òǹkà yẹn jẹ́ ohun ìkorò fún àwọn akẹgbẹ́ wa káàkiri àgbáyé. Gẹ́gẹ́ bí aṣojú àwọn oníṣẹ́-ìròyìn ìfẹ̀hónú hàn ṣe sọ, láti 1992, àwọn oníròyìn tí ó ju egbèje (1,400) lọ ní ó di pípa.
Àwọn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ó-dín-mẹ́wàá (890) lọ ni wọ́n pa pẹ̀lú àìbìkítà. Lónìí, àwọn oníròyìn tó ju ẹ̀rìnlé-lé-ní-àádọ́rin-ó-lé-nígba (274) ni ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní kárí-ayé, ọ̀pọ̀ fún ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ ìlànà-iṣẹ́ jíjábọ̀ ní ọ̀pọ̀ àgbáyé. Bẹ́ẹ̀ sì ni, ìṣòro yìí ń pò síi ni. Àwọn détà titun ṣàfihàn ìkọlù àti ìpànìyàn tí ó pọ̀jù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpànìyàn àwọn tó wà ní ipò gíga ti àwọn onìròyìn iwọ̀-oòrùn – bí Marie Colvin tàbí Daniel Pearl – rinlẹ̀ jákèjádò àgbáyé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpànìyàn t ó lágbára ni pípa àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ tó ń ṣe áayan ìròyìn tí agbègbè. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ìpànìyàn yìí tún kéré nínú ọ̀ràn yí. Lílù, ìjínigbé, ìgbéni-sẹ́wọ̀n, àti ìhalẹ̀ mọ́ àwọn oníṣẹ́-ìròyìn le jù lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ó sì tó gẹ́gẹ́ láti pa wọ́n lẹ́nu mọ́.
Ìhalẹ̀ mọ́ni máa ń wá láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi: ẹgbẹ́ olówò oògùn tàbí àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́tẹ̀; àwọn ìjọba aládàáṣe tàbí àwọn ọ̀tá ẹ̀yà; àwọn àṣìta ìbọn tàbí bọ́m̀bù oníjàgídíjàgan. Lóòtọ́ọ́, ó le jẹ́ bí gbígbòòrò ìhalẹ̀ mọ́ni ṣe yàtọ̀ sí ara ni ó jẹ́ kí “ ìwọn kan bá gbogbo mu” àtúnṣe ṣòro láti rí.
Ìdajì dọ́sìnì àwọn àjọ alámọ̀dájú ni ọwọ́ wọ́n dí hágáhágá nínú ìṣoro yìí, bí àwọn aṣojú àjọ tó ní ju ẹgbẹ́ kan lọ, nínú wọn ni Ìgbìmọ̀ gbogboogbò ti orílẹ̀-èdè Àgbáyé (United Nations) àti Àjọ fún Ààbò àti Àjùmọ̀ṣe ní Úròpù (Organization for Security and Cooperation in Europe).
Gẹ́gẹ́ bí ara àtẹ̀léra Global Investigative Journalism Network ti àwọn ojú-ewé ohun-àmúlò (Resources Pages), a ń tẹ ohun ìtọ́nisọ́nà láti má sì í ewu fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ tó ń ṣe áayan ìròyín. A bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìtọ́kasí sí oríṣìíríṣìí àwọn ohunìtọ́nisọ́nà tó ṣe kókó lóri àwọn àkọ́lé tówà nílẹ̀, òmìnira àwọn oníròyìn jákèjádò àgbáyé sì tẹ̀lé e àti ẹgbẹ́ àìléwu tí ó kan ara wọn, nínú àwọn àṣà kan, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìkọlù íwà-ipá lórí àwọn oníṣẹ́-ìròyìn.
ÀWỌN OHUN ÌTỌ́NISỌ́NÀ FÚN WÍWÀ LÁÌLÉWU ÀTI KÍKÓ ÌRÒYÌN JỌ LÓRÍ RÒGBÒDÌYÀN
Ohun Tí Ó Yẹ Kó O Ṣe Lásìkò Tí Àwọn Aláṣẹ Já Wọ Ilé Rẹ: Kókó àmọ̀ràn wa lónìí níṣe pẹ̀lú bí ó ṣe yẹ ká hùwà nígbà tí a bá ń ṣe ìwádìí. Ìrírí fihàn wí pé àwọn òṣìṣẹ́ máa ń ṣọ́ra ṣe díẹ̀-díẹ̀ nígbà tí wọ́n ba rí i wí pé àwọn ènìyàn mọ ẹ̀tọ́ wọn (2021).
Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Lásìkò Tí Wọ́n Tẹ̀lé Ìwọ Tàbí Orísun Ìròyìn Rẹ: Bí a ṣe lè mọ̀ àti bí a ṣe má a yanjú ìsọ́ tara láti ọwọ́ NICAR21 data journalism conference (2021).
Aṣojú Fún Ààbò Ti Ohun Èlò Ìléwu Oníròyìn: Apákan nínú mẹ́rin ohun èlò àìléwu tí CPJ tẹ̀ jáde ní 2018 pèsè àlàyé tó ṣe pàtàkì lórí tara fún oníròyìn àti yàrá-ìròyìn, ẹ̀rọ ayélujára pẹ̀lú ohun-àmúlò àti èlò aláìléwu ẹ̀kọ́-ìmọ̀ ọkàn. Español, Français, ,لعربية Русский, Somali, ارسی, Português, 中文, Türkçe, မြန်မာဘာသာ.
Ní àfikún, CPJ tẹ àwọn ìwé àìléwu jáde, bí i àwọn àfikún 2019 lórí Aìléwu tara: Ijábọ̀ ìròyìn aládàáṣe àti Àìléwu tara: Díndín ìfipá-báni- lòpọ̀ kù. Ẹ wo àwọn ìdìbò U.S. 2020 tí CPJ pẹ̀lú: Ohun èlò àìléwu oníròyìn.
OHUN ÌTỌ́NISỌ́NÀ ÀÌLÉWU FÚN ÀWỌN ONÍṢẸ́-ÌRÒYÌN: Ìwé-Ìléwọ́ Fún Àwọn Oníròyìn Tí Ó Wà Ní Agbègbè tó kún fún Téwu ní àlàyé tó ń lọ lọ́wọ́ ní 2017 láti ọwọ́ Reporters Without Borders àti UNESCO. Ó wà ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Faransé, Èdè Sípènì, àti Èdè Pọ́túgà.
A CULTURE OF SAFETY (ACOS) Ó jẹ́ àgbájọpọ̀ àjọ ìròyìn, ẹgbẹ́ oníròyìn ọ̀fẹ́, àti ẹgbẹ́ òmìnira àwọn oníròyìn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti fọnrere àìléwu àti ìgbáradì tí ó níṣe pẹ̀lú oníṣẹ́-ìròyìn. Àwọn ohun èlò wọn níṣe pẹ̀lú irinṣẹ́ ìgbéléwọ̀n ara-ẹni láìléwu (safety self-assessment tool), àwọn ìlànà aláìléwu (Safety principles), àwọn àkójọ àyẹ̀wò àìléwu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ(more). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò yìí wà ní Àrábìkì, Èdè Faransé, Hébérù, Pásíànì, Èdè Pọ́túgà, Rọ́ṣíànì, Èdè Sípènì, àti Èdè Tọ́kì.
Ìwé-ìléwọ́ Ààbò Fún Kíkó Ìròyìn Jọ Lórí Àwọn Tó ń Fẹ̀hónú Hàn, láti ọwọ́ Abraji(Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Bìràsílì ti iṣẹ́-ìròyìn Aṣèwádìí). Ẹ lè yẹ íwé-àfọwọ́ṣe ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì wò níbí, ní Èdè Pọ́túgà níbí, àti Èdè Sípènì. Wo àwọn ìpín lórí kíkó ìròyìn jọ lórí àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn lópòópónà níbí.
Ìwé-ìléwọ́ Àìléwu Fún Àwọn Oníṣẹ́-ìròyìn Obìnrin: Ojú-ìwé márùn-ún-dín-lọ́gọ́rùn-ún ohun ìtọ́nisọ́nà (95-page) yìí tí wọ́n ṣe ní 2017 nípaṣẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin jákèjádò àgbáyé ní rédíò àti amóhùnmáwòrán tí a ṣe fún àwọn oníṣẹ́-ìròyìn obìnrin, dá lórí àwọn agbègbè rògbòdìyàn àti jíjábọ̀ ogun, àti pẹ̀lú ìpín lórí ìgbéléwọ̀n ewu, ìyọnilẹ́nu lórí ìtàkùn, àti ìrìn-àjò àìléwu. Àrábíkìì
Kíkó Ìròyìn Jọ Lórí Àwọn Tó ń Ṣe Ìwọ́de Àti Mími Ìlú Lògbò-lògbò. Ohun ìtọ́nisọ́nà yìí láti ilé-ẹ̀kọ́ àìléwu ìròyìn jákèjádò Àgbáyé kó bí a ṣè lè ṣètò fún iṣẹ́-àyànṣe jọ, àwọn ohun èlò tó yẹ ká gbé, àti àwọn ohun tí ó yẹ kí á fojú sílẹ̀ fun.
Ìfẹ̀hónúhan Hong Kong: Ọ̀wọ́ Ìpàdé Àkanṣe-iṣẹ́ FCC Fún Àwọn Oníṣẹ́-ìròyìn: Àwọn sẹminá tí ó wáyé lórí ìtàkùn àgbáyé tí wọ́n ṣe ní ọdún 2019 láti ọwọ́ The Foreign Correspondent’s Club, Hong Kong. Àwọn ìfàwòránhàn kan wà níbẹ̀.
Ìlànà ìtọ́sọ́nà Mẹ́tà-lé-lógún (23) fún àwọn oníṣẹ́-ìròyìn láti kó ìròyìn jọ lórí ìfẹ̀hónúhàn láìséwu: Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Poynter ni ó ṣèto àwọn àbá yìí nígbà tí ìfẹ̀hónúhàn ṣẹlẹ̀ ni US ni 2020 nípa bí wọn ṣe pa George Floyd ní Minneapolis, Minn.
Ohun tí ó yẹ ní ṣiṣé tí wọ́n bá fí ọ ní tajú-tajú: Itósọ́nà ọdún 2019 yìí láti ìwé ìròyìn sáyẹ̀nsì ìlúmọ̀ọ́ká kó ìròyìn jọ lórí bì a ṣe lè dáàbò bo ara wa àti àwọn ìyókù.
Àwọn Ìtalólobó fún wíwà láìséwu nígbà tí a bá ń kó ìròyìn jọ níbi ìfẹ̀hónú ìwà-ipá: àkọsílẹ̀ kan ní ọdún 2017 láti ọwọ́ Jorge Luis Sierra, tí IJNet túmọ̀ sí Èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí ó sì tún tẹ̀ jáde. Rí ojúlówó rẹ̀ ní Periodistas en Riesgo níbi.
Ìtọ́sọ́nà fún àwọn Oníṣẹ́-ìròyìn tó ń kó Ìròyìn Ìfẹ̀hónú han jọ: Ìtọ́sọ́nà ọdún 2017 yìí láti ọwọ́ ẹgbẹ́ Muckrock ní US fọkànsí bí àwọn oníṣẹ́-ìròyìn US ṣe máa ń ṣàkóso àwọn ààbò ẹ̀rọ wọn àti ohun èlò fún jíjábọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń kó ìròyìn jọ lórí ìfẹ̀họ́núhàn.
Ìtalólobó Mẹ́tàlá (13) fún Ààbò: fún àwọn oníṣẹ́-ìròyìn tó ń kó ìròyìn jọ lórí ìkórira orí-ìtàkùn láti Harvard Kennedy School Shorenstein Center Journalist’s Resource.
Ìlànà aláìléwu COVID-19 ọdún 2020 yìí, tí ACOS Alliance ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀, ran àjọ ìròyìn lọ́wọ́ láti dáhùn sí àwọn ìdojúkọ tí àjàkálẹ̀ àrùn tó kárí-ayé mú wá fún wọn, pẹ̀lú ìfọkànsí lórí ìfiṣẹ́ṣe àìléwu ti oníṣẹ́-ìròyìn aládàáṣe. Àwọn irinṣẹ́ àti ìtalólobó rẹ̀ jẹ́ ohun tí a lè fi sí i jákèjádò sí ìkóròyìn jọ nígbà ìdààmú. Ó wà ní Ède Àrábíkìì, Èdè Faransé, àti Èdè Sípènì.
Ààbò + Àìléwu ní ọdún 2019 ṣe àtẹ̀jáde ìwé-ìléwọ́ àti àtẹ̀jáde àwọn àkójọ-àyẹ̀wò “tí ó kún fún àwọn ohun èlò tó dára jù tí a rí lórí ọ̀rọ̀ àìléwu àti ààbò tí ó dojú kọ àwọn tó ń ṣe fíìmù adálérí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi àti ibi tí ó yẹ kí á lọ láti rí àlàyé si àti/ tàbí ìdánilẹ́kọ̀ọ́.
Ìtalólobó Márùn-ún (5) láti ọwọ́ IPI fún àwọn oníṣẹ́-ìròyìn tí wọ́n ń ní ìrírí ìyọlẹ́nu: Àkọsílẹ̀ ọdún 2020 yìí wá láti ọwọ́ International Press Institute, tí ó sì ti tẹ àwọn ìlànà yàrá-ìròyìn jáde lórí bí a ṣe le ṣe àtìlẹyìn oníṣẹ́-ìròyìn tó ń dojú kọ ìyọlẹ́nu lórí ìtàkùn ayélujára. IPI tún ṣẹ̀dá àwọn ohun èlò mìíràn fún ìyọlẹ́nu lórí ìtàkùn ayélujára.
SOS Orí-ìtàkùn Ayèlujára àwọn ohun èlò fún àwọn oníṣẹ́-ìròyìn tí wọ́n ń ní ìdojúkọ ìyọlẹ́nu orí-ìtàkùn ayélujára, pẹ̀lú àkójọ àyẹ̀wò, ìtọ́sọ́nà àgbà-ọ̀jẹ̀ àti àwọn àtòjọ ohun èlò.
Ìwé-Ìléwọ́ Ìyọni-Lẹ́nu Lóri Ayélujára láti ọwọ́ PEN ní Amẹ́ríkà ní ọdún 2017 kún fún “ète tó múnádóko àti ohun èlò tí àwọn òǹkọ̀wé, àwọn onísẹ́-ìròyìn, àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wọn, àti àwọn olùgbàsíṣẹ́ wọn le lò láti fi ṣe ìlòdì sí ìkórira-ìtàkùn-ayélujára àti ìfìlọ̀kulọ̀ lórí ayélujára”.
Ìwé-ìléwọ́ Àìléwu tí àkúnkọ rẹ̀ jẹ́ “ìlànà ìtọ́nisọ́nà fún oníṣẹ́-ìròyìn ní ipò pàjáwìjì tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ju bó ti yẹ lọ” ní wọ́n dá ní ọdún 2017 láti ọwọ́ South East Europe Media Organiṣation. Ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn èdè agbègbè mọ́kànlá.
Ọlọ́pàá, Àwọn Olùfẹ̀hónú-hàn, Àti Ilé-Iṣẹ́ Tó Ń Gbé Ìròyìn Jáde. Ní pàtàkì ìmọ̀ràn tólófin láti ọwọ́ Aṣojú Ẹgbẹ́ Oníròyìn fún Òmìnira Oníròyìn ní US, mudójú-ìwọ̀n ní ọdún 2020.
Ẹgbẹ́ ìlànà ìtọ́nisọ́nà rédíò àti Amóhùnmáwòran Ẹ̀rọ Ayélujára: rògbòdìyàn ìlú. Àbá láti ọwọ́ Ẹgbẹ́ US dojúkọ àìléwu díẹ̀, ṣùgbọ́n ní pàtàkì níṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń jábọ̀ ìròyìn, fún àpẹẹrẹ, “má ṣe yan èrò rẹ fún ẹnikẹ́ni; o kò le mọ ohun tí ènìyàn rò, àyàfi ohun tí wọ́n bá sọ tàbi ṣe”.
Ìyọnilẹ́ni Orí-Ìtàkùn Ayélujára Àwọn Oníròyìn: Ìkọlù Àwọn Alágbára: àwọn oníròyìn aláìníàlà (RSF) ṣe àtẹ̀jáde nẹ́tíwọ̀kì kárí-ayé tirẹ̀ ti ìròyìn ní ọ́fìsì méjìlá láti ṣe ìrànwọ́ láti tan ìmọ́lẹ̀ sí aburú fún àwọn oníròyìn – àwọn ìhalẹ̀mọ́ni àti àwọn ẹ̀gbin lórí ìtàkùn ayèlujára ti àwùjọ tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti dẹ́rùbá wọ́n kí wọ́n le panumọ́. RSF ní ọdún 2018 tè síwájú pẹ̀lú ìṣedúró mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n fún àwọn ìjọba, Àwọn Àjọ jákèjádò àgbáyé gbogbo, pílátífọ̀mù orí-ìtàkùn, ilé-iṣẹ́ oníròyìn àti àwọn olùpolówó láti fèsì sí àwọn ìpolongo apanirun wọ̀nyí. (Ní Èdè Faransé) wo ìsọníṣókí GIJN.
Àgbà-Ọ̀jẹ̀ ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde àti ìkọlura tó ni nǹkan ogun, ìwé-ìléwọ́ ọdún 2017 láti ọwọ́ British Red Cross àti British Institute of International and Comparative Law (BIICL).
Jíjábọ̀ Ìròyìn Fún Àyípadà: Ìwé-Ìléwọ́ Fún Àwọn Oníròyìn Ìbílẹ̀ Ní Àwọn Àgbègbè Tí Wàhálà Wà tí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2009 láti ọwọ́ Àjọ fún Àláfíà àti Ogun tí ó ń jábọ̀ ìròyìn tí ò sí ní orí lórí Agbègbè Ogun Aláìléwu. Ó wà ní Gẹ̀ẹ́sì, Àrábíkì, Fáásì (Farsi), Rọ́ṣíànì (Russian), Kazakh,, Kyrgyz àti Tajik.
Àjọ Ogún James W. Foley ti àgbékalẹ̀ oníròyìn ti kòríkúlọ̀mù Àìléwu fún akẹ́kọ̀ọ́ tí kò tíì gboyè àti èyí tó ti gboyè ní àwọn ilé-ìwé. Pẹ̀lú àwọn ìgbéléwọ̀n tó léwu, ìfòrò wá orísun àwọn ọ̀tá lẹ́nu wò, dídá ààbò bo àwọn détà ẹ̀rọ ayélujára, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Bí A Ṣe Lòdì Sí, Dá Àti Àdírẹ́ẹ̀sì Ohun Ìbanilọ́kànjẹ́ Pẹ̀lú Ìrírí Wọn – Nígbà Tí Wọ́n Sàkóso Àwọn Ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́ni-wo Ìmọ Orísun ní Àárín Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn, átíkù ọdún 2018 láti ọwọ́ Hannah Ellis, olùrànlọ́wọ́ ìwádìí ní Berkman Klein Center for Internet & Society ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Harvard.
Fáìlì Aládàáṣe: Fún Aládàáṣe Ní Agbègbè Tí Ìkọlura Wà, Ìrànlọ́wọ́ Wà Níta, Átíkù aláràbarà ní ọdún 2017 láti ọwọ́ Dale Willman lórí Àwùjọ lórí àwọn oníròyìn àyíká ní orí-ìtàkùn ayélujára.
Iṣẹ́- Ìròyìn Àti Ìbàlọ́kànjẹ́ Tí Ó Jèèrè: Ìtónisọ́nà Fún Àwọn Oníròyìn, Àwọn Olóòtú Àti Àjọ Oníròyìn. Ìwé-ìléwọ́ ọdún 2017 yìí láti ọwọ́ Sam Dubberley àti Michele Grant jẹ́ lórí àwọn ìdojúkọ tí ìbàlọ́kànjẹ́ dúró fún àti ìpèsè iṣẹ́ ìtalólobó àti ìlànà ìtọ́nisọ́nà.
Àjọ ilé-iṣẹ́ àwọn obìnrin tó ń gbé ìròyìn jáde jákèjádò àgbáyé gbogbo ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ̀kọ́ sí àwọn oníròyìn obìnrin. Wo àtòjọ àwọn ohun èlò níbí.
Ìtọ́jú-ara fún Àwọn Oníròyìn, “iṣẹ́ ìtalólobó” ní Powerpoint tí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ní NICAR2019.
Ìtónisọ́na Oníròyìn tó wà láàyè ní ẹ̀kọ́ ìdánilárayá mẹ́sàn-án, pẹ̀lú bí a ṣe lè mú tajú-tajú dání. Gbé e jáde ní ọdún 2012 láti ọwọ́ SKeyes Center fún ile-iṣẹ́ ìròyìn àti Òmìnira Àsà ní Samir Kassir Foundation, ó wà ní Gẹ̀ẹ́sì àti Àrábíkìì.
Ìlànà Ìwádìí Pàjáwìrì, láti ọwọ́ Ivan Gounov, oníròyìn Aṣèwádìí fún ìwé-ìròyìn Russian Meduza. Àgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ GIJ21 ṣàlàyé ìgbéṣẹ̀ tí Meduza gbé nígbà tí wọ́n gbé Golunov.
Òkodoro-òtítọ́: Ìlànà Ìtọ́nisọ́nà fún Oníròyìn níṣe pẹ̀lú àwọn ìlànà ìtọ́nisọ́nà láti pèsè àwọn oníròyìn pẹ̀lú àwọn ìlànà ètò àti àwọn ìgbáradì ní ẹ̀kọ́. Bákan náà àròkọ láti ọwọ́ ògbólògbó oníròyìn, lọ́pọ̀lọpọ̀ circa 2009. Wo átíkù ọdún 2009: ìtalólobó márùn-ún láti dáàbò bo ara-ẹni kúró lọ́wọ́ ìhalẹ̀-mọ́ni àti ìyọnilẹ́nu.
Ẹgbẹ́ Aláàbò Àti Àìléwu Oníṣẹ́-Ìròyìn
A Culture of Safety (ACOS)
Àkóso ìbátan yìí ni wọn gbékalẹ̀ ní ìparí ọdún 2015 láti ọwọ́ àwọn ilé-iṣẹ́ oníròyìn tó ṣe kókó àti àwọn àjọ oníṣẹ́-ìròyìn láti mú ìlọsíwájú bá àwọn ìgbéléwọ̀n aládàáṣe ìdábòbò kárí àgbáyé.
Átíkù kọkàn-dín-lógún:
Tẹ̀dó sí Lọ́ńdọ̀nù (London), Àwọn Alámòójútó Átíkù kọkàn-dín-lógún, àwọn ìwádìí, àwọn àtẹ̀jáde, ìfilọ́lẹ̀, àwọn ìpolongo, ṣètò ìgbéléwọ̀n, àwọn ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ti ọ̀rọ̀ sísọ níbikíbi tí wọ́n bá ti halẹ̀ mọ́ ọ. Iṣẹ́ rẹ̀ níṣe pẹ̀lú àwọn ìpolongo láti dá ààbò bo àwọn oníròyìn kúrò lọ́wọ́ ìhalẹ̀-mọ́ni lórí ẹ̀mí wọn, ẹbí wọn àti ìgbésí ayé ẹni.
Committee to Protect Journalists (CPJ): Tẹ̀dó sí New York. Dá a ní 1981 àti àwọn ìgbìmọ̀ olùdarí oníròyìn ló ṣe àmójútó rẹ̀, CPJ máa ń ṣẹ̀dá àwọn ìjábọ̀ ìròyìn orílẹ̀-èdè lọ́dọọdún, máa ń ṣàkóso àwọn iṣẹ́ jákèjádò àgbáyé gbogbo, ó sì máa ń bójútó atọ́ka òmìnira ìjìyà rẹ̀, láàárín àwọn àṣàyan-iṣẹ́ tó ń bíni nínu yòókù. Ètò ìrànlọ́wọ́ oníròyìn ti CPJ pèsè tòfin, toníṣègùn, àti olùrànlọ́wọ́ ìgbé-bòmíràn sí àwọn oníròyìn nínú ewu, pẹ̀lú ìrànwọ́ fún àwọn ẹbí eni tí wọ́n pa àti àwọn oníròyìn tó wà lẹ́wọ̀n.
Iṣẹ́ Àkọ́kọ́ṣe jẹ́ èyí tí kì í ṣe ojúṣàájú sí akẹgbẹ́ àjọ ìtàkùn-ayélujára ìròyìn àti olúkúlùkù tó pèsè iṣẹ́-ṣíṣe àti ìlànà ìtọ́nisọ́nà ẹ̀yà lóri bí a ṣe le rí, mọ̀dájú, ṣe àtẹ̀jáde kókó orísun láti ayélujára àwùjọ.
Global Journalist Security: dá a sílẹ̀ ní ọdún 2011, tẹ̀dó sí Washington ti ile-iṣẹ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tí ó máa ń fúnni ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ààbò àti ìmọ̀ràn fún àwọn òṣìṣẹ́ oníròyìn, àwọn oníròyìn ọmọ-ìlú, àwọn ajìjàgbara ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn, àti òṣìṣẹ́ NGO. Ẹgbẹ́ yìí tún máa ń kọ́ àwọn ọmọ ológun ààbo ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti lajú bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n máa ń kan ìjọba ara-ẹni pọ̀ “láti pàdé àwọn òmìnira àwọn oníròyìn jákèjádò àgbáyé gbogbo àti àwọn ìlànà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn” pẹ̀lú bí a ṣe lè bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ láìséwu.
Inter American Press Association(IAPA): tẹ̀dó sí Miami, FL. Dá a sílẹ̀ ní ìparí ọdún 1940; ní ìsinyìí ó ní ọmọ-ẹgbẹ́ àtẹ̀jáde egbèje ní Canada sí Chile. Ó ń ṣe àmójútó àti alágbàwí fún òmìnira oníròyìn káàkiri agbedeméji ayé; àwọn ètò tó ṣe pàtàkì níṣe pẹ̀lú ẹ̀ka èsì tó yára tí wọ́n gbékúrò nígbà wọ́n pa oníròyìn, ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dún ni àbọ̀ lórí òmìnira oníròyìn ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, àti àtẹ̀jáde ti “máàpù tó léwu” láti tọ́ àwọn oníròyìn tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu sọ́nà. IAPA náà ṣe tiwọn lọ́tọ̀ “iṣẹ́ àkànṣe òmìnira kúrò nínú ìyà” pẹ̀lú àlàyé tó kún lórí ìpànìyàn àwọn oníròyìn káàkiri ibi.
International Federation of Journalists (IFJ): Tẹ̀dó sí Brussels. Ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀nà ìgbàlódé, ní 1952, IFJ júwè é ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ oníròyìn tó tóbi jù lágbàáyé. Ó ń ṣàmójútó ọ̀rọ̀ òmìnira oníròyìn àti alágbàwí fún àìléwu àwọn oníròyìn àti pé ó jẹ́ olùdásílẹ̀ Ilé-ẹ̀kọ́ àìléwu ìròyìn jákèjádò àgbáyé gbogbo.
International Freedom of Information Exchange (IFEX): Bẹ́ẹ̀, ipa tí ó fojú hàn jù ní àjọ tó tẹ̀dó sí Toronto ni bí i orírun àlàyé; ó ṣe ohun tí à pè ní “ètò àlàyé asòye tó ga jù lórí ìgbé-èrò kalẹ̀ láìbẹ̀rù lágbàáyé” pẹ̀lú lẹ́tà-ìròyìn ímeèlì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn átìkù tí wọ́n ń gbéyẹ̀wò déédé tí ó níṣe pẹ̀lú òmìnira oníròyìn, àti “ìtanijí ìṣe” láti ọ̀dọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ yíká gbogbo ayé. Ó ní jú àjọ Àádọ̀rún ọmọ ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè tó ju àádọ́ta lọ. Ní ọdún 2011, ó dá ọjọ́ kẹtà-lé-lógún Oṣù Kọkànlá gẹ́gẹ́ bí Ọjọ́ ìfopin sí ìjìyà òmìnira jákèjádò àgbàyé gbogbo.
International News Safety Institute (INSI): Tẹ̀dó sí Brussels. Wọ́n dá a ní ọdún 2003 nítorí ìpilẹ̀ṣẹ̀ láti ọwọ́ IFJ àti IPI, ó ṣe àpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi “àjọ oníròyìn ti ìdarapọ̀ ti aláìlẹ́gbẹ́, oníròyìn ṣàtìlẹyìn àwọn ẹgbẹ́ àti olúkúlùkù tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ oníròyìn aláìléwu tí ó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn àyíká tó léwu”. Ó máa ń ṣàkóso ìdánilẹ́kọ̀ọ́, máa ń ṣe àtẹ̀jáde ìtalolóbó aláìléwu àti ìwé-àfọwọ́ṣe, ó máa ń ṣe àmójútó àwọn oníròyìn tó fara gbọgbẹ́ ní onírúurú ọ̀nà, yálà ìkọlù látara ìwà-ipá tàbí àwọn ìjàm̀bá.
International Press Institute (IPI): Wọ́n dá a ní ọdún 1950, tẹ IPI dó sí Vienna, ó máa ń pe ara rẹ̀ “olóòtú ti ìtàkùn ayélujará káríayé, àwọn aláṣẹ oníròyìn àti aṣíwájú àwọn oníṣẹ́-ìròyìn.” Olùdásílẹ̀ INSI, máa ń mójútó òmìnira àwọn oníròyìn pẹ̀lú Àtúnyẹ̀wò Òmìnira Àwọn Oníròyìn Lágbàáyé lọ́dọọdún, ṣàkóso àwọn iṣẹ́ déédé sí àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti léwu, àti àmì ìkọlù lórí àwọn Oníròyìn.
Reporters Without Borders
(Reporters Sans Frontières, tàbí RSF): dá a sílẹ̀ ní ọdún 1985, ó sì tẹ̀dó sí Paris, RSF kó àwọn àlàyé lórí àwọn ìrúfin òmìnira àwọn Oníròyìn jọ àti pé ó ṣe onígbọ̀wọ́ iṣẹ́ jákèjádò àgbáyé gbogbo . Láàárìn àwọn iṣẹ-ṣíṣe, ó pèsè ìrànwọ́ owó sí àwọn Oníròyìn tàbí Àjọ ìròyìn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ gbe ara wọn níjà, àti sí ẹbí àwọn Oníròyìn tó wà lẹ́wọ̀n, àti kí ó le tún àìléwu àwọn Oníròyìn ṣe, pàápàá jùlọ ní ẹ̀kun ogun. Ó máa ń ta Àṣedúró àti pé ó máa ń yá wọn ní àwọn aṣọ ayẹta-ìbọn àti akoto láìgba owó kankan lọ́wọ́ àwọn Oníròyìn tó ń lọ ìrìnàjò sí àwọn agbègbè tó léwu.
World Association of Newspapers and News Publishers (WAN-IFRA): dá a sílẹ̀ ní ọdún 1948, tẹ̀dó sí Paris, WAN rọ́pò iṣẹ́ àtẹ̀jáde tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì-dín-lógún lórí kọ́tínẹ̀tì márùn-ún. Ní àfikún láti pèsè ìrànwọ́ àti àlayé lórí ohun tí ó ṣe kókó lórí ọ̀rọ̀ ilé-iṣẹ́, WAN ní ìdojúkọ tí ó ṣe pàtàkì lórí òmìnira oníròyìn, mimójútó ìkọlù lórí Oníròyìn, àti ṣíṣàkóso ìpolongo ọlọ́jọ́-pípẹ́ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti fojú sọ pẹ̀lú èróńgbà láti dá ìmọ̀ àwùjọ ẹ̀dá lórí ọ̀rọ̀ òmìnira oníròyìn tó ń kani láyà.”
Free Press Unlimited: Ìdàgbàsókè Ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde ti Dutch, NGO ní èsì àwọn oníròyìn (Reporters Respond), olùnáwó pàjáwìrì jákèjádò àgbáyé gbogbo pèsè ìrànlọ́wọ́ tààrà fún àwọn oníròyìn àti ilé-iṣẹ́ tó ń gbé gbè ìròyìn jáde, fún wọn ní ààyè láti wọ iṣẹ́ ní bí ó yára ṣe e ṣése tó nígbà tí wọ́n bá dojúkọ ìdíwọ́ agbègbè. Ẹgbẹ́ yìí lérò láti fèsì sí àwọn ìbéèrè láàárin wákàtí mẹ́rìn-lé-lógún.
Ní àfikún, nípasẹ̀ ìnáwó ààbò olófin fún àwọn oníròyìn, Ìgbéròyìnjáde aláìlópin lọ́fẹ̀ẹ́ pèsè ìrànwọ́ lórí owó fún àwọn Oníròyìn tí wọ́n ń dojúkọ inúnibíni tàbí ìgbésẹ́wọ̀n, tàbí wọn kò ní àǹfààní láti san owó olófin.
Rory Peck Trust: tẹ̀dó sí London, Rory Peck Trust pèsè ìrànlọ́wọ́ ṣíṣe àti ìrànwọ́ fún Àwọn Akóròyìnjọ Aládàáṣiṣẹ́ àti ẹbí wọn lágbàáyé, láti gbé àwòrán-orí(pírófáìlì) wọn sókè, láti gbé àláfíà àti àìléwu wọn ga, àti láti ran ẹ̀tọ́ wọn lọ́wọ́ láti ròyìn láìsi ìbèrù. Ìwé ètò pẹ̀lú ètò olùrànlọ́wọ́ aládàáṣe, ohun èlò aládàáṣe, àti Àwọn Ẹ̀bùn-ẹ̀yẹ Rory Peck.
RISC: Reporters Instructed in Saving Colleagues jẹ́ ẹgbẹ́ tó tẹ̀dó sí US tí ó máa ń fúnni ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àìléwu ní ọ̀fẹ́ fún àwọn Oníròyìn tí ó ṣiṣẹ́ ní agbègbè rògbòdìyàn àti àwọn tó wà lọ́nà jínjìn káàkiri àgbáye. Ó pèsè ìlànà ààbò ọjọ́ méjì tí ó dojúkọ ìlòdìsí ìdààmú, tí kọ́ọ̀sì ọlọ́jọ́ mẹ́rin tó gbòòrò lórí ajọgbá ògùn fún gbogbo iṣẹ́. Ìlànà ètò yìí wà fún àwọn tó ní ìrírí, tó ń ṣiṣẹ́, alàdàáṣe àti àwọn oníròyìn tagbègbè. Àwọn Ipò máa ń yípada (Sao Paolo àti Sarejavo ní ọdún 2018) àti pé wọ̀n le ṣàkóso rẹ̀, èyí lórí ẹni tí ó bá fisí i.
Mu dójú ìwọ̀n ní Oṣù Kẹfà, ọdún 2021.