Níní ìṣedúró nígbà tí o wà lórí àwọn iṣẹ́ àyànṣe eléwu le jẹ́ ìkówólé tó mú ọpọlọ dáni àti èyí tí kò wọ́n tó bí o ṣe bẹ̀rù. Rí àwọn atẹ̀wétà láti sanwó fún un bí ó bá ṣeé ṣe.
Ohun o ó ṣedúró fún?
- Àwọn Ìṣòro ìrìn àjò tó ga jù: pàdánù ìrìn-àjò ọkọ̀-òfúrufú, àwọn ìwé-àkọsílẹ̀ tó sọnù, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
- Àwọn ọ̀rọ̀ ètò ìlera: Àìsàn, Egbò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Ìkóròyìn-jọ COVID-19 kò sí níbẹ̀.)
- Ìyokúrò, ìyẹn tí ó bá ṣe kókó.
- Ìjínigbé.
- Ìsedúró Àìlókun.
- Ìdápadà sí ìlú abínibí àwọn tó kù ní ibi-ìṣe ikú.
- Ìpàdánù ti tàbí ìsọnù sí àwọn ohun-èèlò.
“The Rory Peck Trust”, ẹgbẹ́ ti ilẹ̀ US tí ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún àìléwu ti àwọn oníròyìn aládàáṣe, ti fi àwọn ìwé sílẹ̀ lórí àwọn irúfẹ́ ìkóròyìn-jọ àti àwọn ohun tí wọn yóò rò nígbà tí wọ́n bá ń kàn sí àwọn olùpèsè ìṣedúró. Wọ́n ṣàfihàn ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti bèèrè àti àwọn ìṣòro ipa-níní.
Rírí ìsedúró tó léwu tí wọ́n kọ sí inú àdéhùn ìgbaṣẹ́ rẹ jẹ́ ọ̀nà kan láti lọ. Àwọn wọ̀fún mẹ́ta ni wọ́n tò kalẹ̀ nínú àdéhùn àgbékalẹ̀ ti ACOS Alliance ṣe, ẹgbẹ́ ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbéròyìn-jáde kan tí ó gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ àìléwu ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbròyìn-jáde.
ACOS dábàá:
- Jíjẹ́ kí ilé-iṣẹ́ tọ́ àwọn aládàáṣe ní ètò ìrànlọ́wọ́ ìrìn-àjò tirẹ̀.
- Jíjẹ́ kí ilé-iṣẹ́ fún àwọn aládàáṣe ni owó-gbà-má-bìínú fún ìnáwó gbígba “ìníyelórí tó mú ọpọlọ dání” sí iṣẹ́ àkànṣe.
- Jíjẹ́ kí àwọn aládàáṣe gbé ìnáwó, pẹ̀lú ìnáwó tó níye lórí lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá ti yanjú gbogbo iye àdéhùn.
Àwọn Wọ̀fún láti ẹgbẹ mẹ́ta
Ọ̀pọ̀ ilé-iṣẹ́ ló wà káàkiri àgbáyé tí wọ́n ta ìṣedúró ìrìn-àjò, ṣùgbọ́n onírúurú àjọ ilé-iṣẹ́-tó-ń-gbéròyìn-jáde jákè-jádò àgbáyé ló ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn aṣèdúró aládàáni èyí tí ó pèsè àwọn ìlànà tí wọ́n gbékalẹ̀ láti jẹ́ àdáṣe àwọn oníròyìn.
Fún Ìfọ́nká sí i, ìgbéga, àti Ìdáṣe, wo Ìtọ́nisọ́nà GIJN wa.
“The ACOS Alliance” ṣàgbékalẹ̀ ìráàyè sí ìṣedúró ìrìn-àjò àti ìsedúró tí àwọn àjọ le rà láti dá ààbò bo àwọn aládàáṣe tó wà lókè òkun, àti méjèèjì tí wọ́n fúnni ní ilẹ̀ UK ní ilé-iṣẹ́ ìṣedúró InsuranceforJournalists.com pẹ̀lú ìdíkùn “7.5%” fún àwọn àjọ tí ó sanwó sí Àwọn Ìlànà Àìléwu Àwọn Oníròyìn Alàdàáṣe ti ACOS. ( wo àtẹ atọ́ka àwọn ohun-èèlò níbí.) Wọ́n dá a kalẹ̀ ní ọdún 2015, ACOS jẹ́ ìdàpọ̀ ti àjọ ìròyìn, ẹgbẹ́ oníròyìn aládàáṣe, àti àwọn ẹgbẹ́ òmìnira ilé-iṣẹ́ ìròyìn.
Ìlànà ìrìn-àjò yìí ṣí sílẹ̀ fún gbogbo oníròyìn tó ń rín ìrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè tówù lágbàáyé, pẹ̀lú ìkòríta ìkọlura. Ìkóròyìn-jọ wà láàárín ọ̀sẹ̀ tí ó sì níṣe pẹ̀lú: ikú ìjàm̀bá àti ìṣe-àìnípa, àìsàn àti kókó ìnàwó ilé-ìwòsàn ìjàm̀bá sí $250 tàbí E250 tí ó ṣe ń yọkúró ní ìlérí kọ̀ọ̀kan, àti pàjáwìrì ìwòsàn. Wo ojú-ìwé yìí fún ọ̀rínkínníwín àlàyé.
Ètò Ìyọkúrò mìíràn máa ń mú Aṣèrànwọ́-oníròyìn abẹ́lé dúró, olùgbéjáde abẹ́lé, olùtúmọ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ilè-iṣẹ́ ìròyìn yòókù tó wà nílẹ̀. ìlànà yìí bo ẹnìkọ̀ọ̀kan kúrò ní ìjónílùú níbikíbi lágbàáyé., pẹ̀lúpẹ̀lú nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè tíwọ́n ń gbé. Ìṣedúró ìkóròyìnjọ jẹ́ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú :ìkú nípa ìjàm̀bá, kókó ìnàwó ìwòsàn ìjàm̀bá sí ìṣe-díkùn sí $250, àti ìjàm̀bá pàjáwìrì ìyọkúrò ìwòsàn láti ibi ìṣẹ̀lẹ̀ sí ipele ìtọ́jú tó tọ́. Wo Ìṣedúró fún Ilé-iṣẹ́-ìròyìn Abẹ́lé.
Reporters Without Borders (RSF) pèsè ìṣedúró ìlera àti ìpadà-sí-orílẹ̀-èdè fún àwọn oníròyìn àti àwọn olùjábọ̀ tí wọ́n ń rin ìrìn-àjò lórí iṣẹ́-àyànṣe sí orílẹ̀-kórí-lẹ̀èdè, pẹ̀lú orígbó ogun, pẹ̀lú àwọn ìrètí kan. Ìjẹ́-ọmọ-ẹgbẹ́ RSF jẹ́ dandan.
Ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú “Escapade Travel Insurance”, RSF pèsè ohun tí wọ́n pè ní “Ètò tó ṣe Pàtàkì.” Wo ètò àpèjúwe níbi. Lábẹ́ ètò tó ṣe Pàtàkì, àwọn oníròyìn le kó ìròyìn jọ ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní orílẹ̀-èdè rẹ tàbí àwọn agbègbè tí ewu rẹ ga bí i orílẹ̀-èdè Afghanistan, Crimea, Iraq, Somalia, Sudan, South Sudan, Syria, West Bank/ Gaza, àti Yemen. Ìkóròyìn-jọ fún iṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè yìí, síbẹ̀ síbẹ̀, ó wà nílẹ̀ látara “Ètò tí wọ́n fẹ̀ lójú.” Ó ṣeni láàánú pé, “Àwọn Olùjábọ̀ tó tẹ̀dó sí ilẹ̀ US, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Bùràsílì tó ń gbé ní Bùràsílì, àti ọmọ ilẹ̀ kánádá ní Kánádà kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ètò ìṣedúró wọ̀nyí.”
Àjọ àwọn oníròyìn Jákè-jádò Àgbáyé ní ìfọwọsowọ́pọ̀ pẹ̀lu ilé-iṣẹ́ ìṣedúró ti UK “Battleface” láti fún àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ rẹ́ ní ìṣedúró ìkóròyìnjọ ìrìn-àjò pẹ̀lú ìnáwó pàjáwìrì ìwòsàn àti ìyọkúrò. Àwọn wọ̀fún tún wà látin mú àwọn ohun-èèlò dúró. Wo ojú-ìwé “Battlefield” yìí fún ọ̀rínkínníwín àlàyé
Ìnáwó
Níwọ̀n ìgbà tí ìye ti jẹ́ ìdènà tó jù, ẹ jẹ́ kí á wá sí i lóri iye – ní gidi gidi.
A ṣàyẹ̀wò oríṣìíríṣìí ìfúnni mẹ́ta, tí kò kọbi ara sí àwọn ìlànà tó ṣe pàtó, èyí tí ó hàn gbangba pé wọn kò le ṣèdúró rẹ̀ fún ìnájá tó kójú òsùwọ̀n.
Fún ọ̀sẹ̀ kan ní orílẹ̀-èdè tí ewu rẹ̀ ga, iye rẹ le jẹ́ láti $80 sí $105. Ìnáwò máa ń kéré ní àwọn ibi tí kò séwu fún ọ̀sẹ̀ kan ní orílẹ̀-èdè tí ewu rẹ kèrè, fojúsọ $18 sí $32.
Ìnáwó láti insuranceJournalism.com ni wọ́n gbékalẹ̀ lóri ìmúdójú-ìwọ̀n òǹyà tó gbẹ̀yìn ní ọdún 2016 ní èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè pín sí ipele márùn-ún, láti “igun” sí ewu “kékeré”. Fún orílẹ̀-èdè ní ipele tó ga, bí i Libya, ìlànà ọ̀sẹ̀ kan ná wọn ní $80.Ìnáwó ní orílẹ̀-èdè eléwu-kékeré jẹ́ $24.
Ètò ìpìnlẹ̀ Àwọn Olùjábọ̀ Aláìláàlà ná wọn ní $18.48 lọ́sẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí gbèdéke kan tí wọ́n pèsè fún ètò tó níṣe pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó ga. Òṣìṣẹ́ kan pẹ̀lú ìṣedúró ilé-iṣẹ́ sọ pé ìfiwéra ìnàwó fún Syria máa jẹ́ “nǹkan bí $55.82 ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ọ̀sẹ̀ kan,” èyí tí ó ń lọ bí $390 lọ́sẹ̀ kan.
Ìlànà “Battleface” fún Syria máa tó ìnáwó $105 lọ́sẹ̀ kan. Ìnáwó yẹn yóò jẹ́ $32 fún orílẹ̀-èdè eléwu-kékeré.
Rántí ìkìlọ̀ ńlá: ìfiwéra ìnáwó gidi le ṣini lọ́nà. Ṣàyẹ̀wò fún àwọn ìkóròyìn-jọ kan pàtó.
Àwọn Wọ̀fún Mìíràn
Bí wọ́n ṣe fi ìka tọ́ ọ lókè, ọ̀pọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ fúnni ní ìṣedúró ìrìn-àjò; díẹ̀ nínú wọn lóni ohun tí ó ṣètò kalẹ̀ fún àwọn oníròyìn lọ́kàn. Àtẹ atọ́ka kékeré ti olùpèsè “tí wọ́n mọ́ láti jẹ́ ìṣejọra sí ohun-ìní àwọn aládàáṣe,” ni Rory Peck Trust gbé sórí `tàkùn ayélujára.
Tún wo:
- Yonder ti ṣàgbékalẹ̀ àtúnṣe fún àwọn oníròyìn.
- Bellwood Prestbury ní ojú-ìwé lóri ìṣedúró fún àwọn oníròyìn.