Afghanistan: Bí wọ́n ṣe lè ran àwọn oníròyìn lọ́wọ́ àti àwọn yòókù tó wà nínú Ewu.

Láti ọwọ́ Smaranda Tolosano | Ọjọ́ kejì-dín-lógún oṣù kẹjọ, ọdún 2021

Ìmúdójú-ìwọ̀n tó kẹ̀yìn: Ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹjọ

Ní akitiyan láti ran àwọn oníròyìn àti àwọn yòókù tó ń gbìyànjú láti kúrò ní Afghanistan lọ́wọ́, GIJN ti kó atọ́ka ohun èlò yìí papọ̀ fún Ìkókúrò Pàjáwìrì àti àwọn ìgbésẹ̀ ilé-ààbò. A lérò pé yóò wúlò fún àwọn àjọ tó ń gbìyànjú láti yọ àwọn oníròyìn kúrò ní Afghanistan, tàbí fún ẹnikẹ́ni tí ó mọ oníròyìn níbẹ̀ tó nílò ìrànlọ́wọ́.

Wọ́n gbọ́dọ̀ daari àwọn ìbéèrè sí àwọn ẹgbẹ́ tó wà nísàlẹ̀.

Ìròyìn láti gbà jọ àti dá ààbò bò 

 • Ìwé-ìrìnnà, káàdì Ìdánimọ̀ Lórílẹ̀-èdè àti déètì ọjọ́ tí wọ́n gbà á àti ọjọ́ tí àkókò rẹ̀ yóò parí.
 • Déètì àti Ibi tí wọ́n bi sí.
 • Ibi tí ó wà lọ́wọ́lọ́wọ́.
 • Àdírẹ̀ẹ̀sì Ímeèlì.
 • Nọ́ḿbà ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀, àti nọ́ḿbà ìsàmì, bí ó bá yàtọ̀.

Àwọn Ìgbésẹ̀ Àjọ àti Àyẹ̀wò Àwọn Ìbéèrè Ìkókúrò:

Ìgbìmọ̀ láti dá ààbò bo àwọn Oníròyìn

 • Gba ìròyìn, le fi àwọn ìbéèrè ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tó yẹ.
 • Ímeèlì: [email protected]
 • Nọ́ḿbà ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀: +1 (212) 300-9018 àti +1 (212) 300-9017

Kó àwọn akẹgbẹ́ wa kúrò

 • Gba àwọn orúkọ àwọn oníròyìn tó ń bèrè fún ìkókúrò àti ṣètò pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba.
 • Ààtò Google fún àwọn Afghan lásán (wọn yóò fi atọ́ka náà ránṣẹ́ sí Ìjọba US fún ìsọdá-ìtọ́kasí).
 • Kan sí fún àwọn pàjáwìrì: [email protected]

Ìròyìn Ọ̀fẹ́ Aláìlódìwọ̀n 

 • Àwọn ìtura akitiyan jákè-jádò àgbáyé àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn oníròyìn tó wà nílẹ̀.
 • Kàn sí [email protected] àti +31 20 8000 400

International Federation of Journalists

 • Ríranni lọ́wọ́ láti gba ìwé-ìrìnnà, ìṣípòpadà aláàbò sí pápá ọkọ̀-òfúrufú ní Afghanistan, ṣíṣègbésẹ̀ lẹ́tà-ìgbaṣẹ́
 • Kàn sí [email protected]

International Media Support

 • Ìsádi àti àwọn ohun èlò sí àwọn oníròyìn Afghan àti ẹbí wọn, ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ aláàbò fún oníròyìn Afghan.
 • Kàn sí [email protected] àti tel: +45 8832 7000, +45 8832 7000

International Women’s Media Foundation

 • Ìtura àwọn ìlàkàkà ní Afghanistan láti dá ààbò bo àwọn òṣìṣẹ́ obìnrin ní ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti àwọn olùgbẹ́kẹ̀lé.
 • Kàn sí: [email protected] àti (+1) 202-496-1992 

Reporters Without Borders (RSF)

 • Pèsè ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀ fún àwọn oníròyìn
 • Fún àwọn NGOs àti ìgbéjáde ilé-iṣẹ́ ìròyìn: [email protected] àti +33 1 4483 6056
 • Fún àwọn oníròyìn kọ̀ọ̀kan nínú ewu: [email protected] àti +33 1 4483 8466

Ìdarapọ̀ Fún Àwọn Obìnrin nínú Iṣẹ́-ìròyìn

 • Ríranni-lọ́wọ́ lórí ìkókúrò àti Ìṣíbùgbé fún àwọn Oníròyìn.
 • Kàn sí [email protected]

Púpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí ní ọmọ ẹgbẹ́ Journalist in Distress, nẹ́tíwọ̀kì tó gbẹ̀fẹ́ ti àjọ jákè-jádò méjì-lé-lógún tó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tààrà sí àwọn oníròyìn.

Ní i lọ́kàn agbára àwọn s`jọ yìí jẹ́ olódìwọ̀n. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ni wọ́n ń péjọ àti ìṣàkóso ìròyìn láti pèsè òṣìṣẹ́ ìjọba tí ó lè pèsè ọkọ̀ òfúrufú, iṣẹ́-pépà, àti ópin ìrìnàjò fún ìkókúrò.

Àfikún Àwọn Ìgbésẹ̀

Bi àwọn oníròyìn bí wọ́n bá:

 • Jẹ́ ti àjọ ti jákè-jádò àgbáyé kankan (ó níṣe-pẹ̀lú-iṣẹ́-ìròyìn tàbí kò ní);
 • Ní ìdè sí orílẹ̀-èdè òkè-òkun (ìdàpọ̀, àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́, ohunkóhun tí wọ́n ṣe ṣẹ́yìn tó le jẹ́rìí àsopọ̀ kan);
 • Ní ará ilé kan ní òkè-òkun (òbí, àbúrò, àfẹ́sọ́nà, ọmọ).

Kàn sí ọ̀kan nínú èyí tó wà lókè, kí o sì béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ìwádìí ìlànà amòfin fún ibi ààbò tàbí ìtúngbépapọ̀ àti ìkókúrò ní orílẹ̀-èdè tí oníròyìn yẹn ní ìdè sí.

Ọ̀na Olófin fún Àwọn tó wà pẹ̀lú Ìdè sí:

Canada

United Kingdom

 • ARAP (Afghan Relocation and Assistance Policy) ṣe ìmúdójúìwọ̀n gbẹ̀yìn ní oṣù kẹfà ṣùgbọ́n láti pèsè ọ̀nà kan fún àwọn Afghan tí ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba UK láti gba ìwé-ìrìnnà dí UK.
 • Fún àwọn Afghan mìíràn nínú ewu (àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe ti British), pẹ̀lú àwọn oníròyìn, ọ́fìsì ilé British pèsè nọ́mbà ìbánisọ̀rọ̀ kíákíá ní +44(0)2475 389980. Jọ̀wọ́ ní àwọn àlàyé wọ̀nyìí nígbà tí o bá ń pè: Orúkọ kíkún gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe tò ó sí orí ìwé-ìrìnnà tàbí ID (Tazkira), ọjọ́ ìbí. Fi àlàyé kan náà kun fún àwọn agbẹ́kẹ̀lé rẹ (àwọn ebí rẹ pẹ̀lú àfẹsọ́nà, àwọn ọmọ).
 • A ó ṣe àfikún àtúntò nígbà tí Afghan citizens’ resettlement scheme bá jáde.

United States

 • Ẹ̀ka U.S ti Refugee Processing Center guidelines ní ìpínlẹ̀ fún Ìtọ́kasí P-2 (fún àwọn Afghan tó ṣiṣẹ́ fún ilé-iṣẹ́ ìròyìn U.S. tàbí àwọn NGO) àti ètò Special Immigrant Visa (SIV) fún àwọn Afghan ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, Dart àti Pashto.
 • Special Immigrant Visas (SIV) fún àwọn Afghan tó ṣiṣẹ́ fún/ pẹ̀lú ìjọba US.
 • Ìsọdọ̀kan Ẹbí bí ọmọ ẹbí rẹ bá jẹ́ Asásàláà/Olùwáààbò ní US TÀBÍ bí ọmọ ẹbí rẹ bá jẹ́ ọmọ ìlú US.
 • Ọ̀rọ-ẹnu Ire-ọmọnìyàn: Ẹnìkọ̀ọ̀kan níta US le ní àǹfààní àti bèèrè fún ọ̀rọ̀-ẹnu lórí ire-ọmọnìyàn kíákíá tàbí àwọn ìdí àǹfààní àwùjọ tó ṣe kókó.

Ìròyìn nípa gbogbo orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n tún ṣe ìsọníṣókí lórí atọ́ka yìí láti ọwọ́ Afghan Disapora for Equality and Progress. 

Atọ́ka orí-ìtàkùn titun méjì fúnni ni amọ̀ràn ìtìmọ́lé lóri gbígba ibi ààbò sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Europe àti Asia.

 • ExitSOS pèsè àlàyé ìmúdójúìwọ̀n nọ́ḿbà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fún lẹ́tà ìbẹ̀wẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé.
 • Iwé-àṣẹ Google yìí pèsè àwọn atọ́ka ìkókúrò titun, oníròyìn Afghan àti àwọn aláfarahẹ́ le fọwọ́si í pẹ̀lú àwọn ọ̀rínkínníwín àlàyé ìgbésẹ̀ ibi ààbò U.S. àti àwọn ìwé-ìwọ̀lú tó ṣe éṣe.

Ìwé-ìwọ̀lú sí Àwọn Orílẹ̀-èdè Alábàágbé

 • Pakistan ń ṣe bí ìwé-ìwọ̀lú yóò ṣe rọ̀rùn fún àwọn oníròyìn Afghan àti àwọn ẹbí wọn. Ẹ lè kàn sí Olùdámọ̀ràn Ìròyìn gẹ́gẹ́ bí Aṣojú Mansoor Ahmed Khan ṣe sọ.


Fún Ìrànlọ́wọ́ Owó

Oríṣìí owó-ìrànwọ́ ló wà láti pèsè oníròyìn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ pàjáwìrì. Journalists in Distress Fund ni àwọn Oníròyìn Canada fún Ìsọ̀rọ̀sí àìnídè, èyí tó “pèsè ìrànlọ́wọ́ ire-ọmọnìyàn sí àwọn oníròyìn káàkiri àgbáyé tí ìgbé àti àláfíà ni wọ́n halẹ̀ mọ́ nítorí iṣẹ́ wọn.” Ìròyìn Ọ̀fẹ́ Aláìlódìwọ̀n ń ṣe Reporters Respond emergency fund. Fún àfikún, wo ìtọ́nisọ́nà GIJN Emergency Aid for Journalists.

 Àwọn Ìgbésẹ̀ Ààbò Ẹ̀rọ

 • Ààmì máa ń ríi dájú pé ààbò péye, àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ oníkòòdù, bẹ́ẹ̀ náà ni Briar App.
 • Ráàyè sí i lónìí pèsè àwọn ìgbésẹ̀ ọ̀rínkínníwín fún ààbò ẹ̀rọ ní Dari àti Gẹ̀ẹ́sì.
 • Umbrella App pèsè ẹ̀kọ́ ìtọ́sọ́nà-ara-ẹni àti ìtọ́ka-àyẹ̀wò fún ìgbésẹ̀ tó rọrùn, àfikọ́ra. Lórí iOS, Android, Amazon, àti F-Droid.
 • Bí o ṣe le pa ẹ̀kọ́-ìtàn Ẹ̀rọ rẹ rẹ́ jẹ́ ìtọ́nisọ́nà kúkurú lórí pípa ìfẹsẹ̀tẹ̀ ẹrọ rẹ rẹ́.

Fún Àwọn Ìdí Aláàbò, Má ṣe:

 • Pín àwọn ìròyìn ara rẹ sórí ilé-isẹ́ ìròyìn àwùjọ. Bí ó bá ṣe é ṣe, lo ápùù àtẹ̀ránsẹ́ oníkòòdù bíi Alámì.
 • Pín ìròyìn tó lágbára lórí Ibi-ìpamọ́ Google tàbí orí-ìkànnì tí wọ́n le pìn nǹkan sí kíákíá mìíràn.
 • Fi ìròyìn ara-ẹni ránṣẹ́ láìri dájú pé o ní nọ́ḿbà ìkànsí ẹni tó ṣe é fọkàn tọ́.
 • Ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ pàtó ibi ti oníròyìn wà/ olùwá-ibi ààbò.

Tún Ro… 

Àwọn ìdè àti nọ́ḿbà ìkànsí ní àwọn orílẹ̀-èdè Alábàágbé (Pakistan, Tajikistan, Kazakhstan, Uzbekistan), àti àwọn ẹbí, àwọn agbanisísẹ́ tẹ́lẹ̀, tàbí àwọn olùgbówósílẹ̀ lókè-òkun. Àjọ Afghan lókè-òkun le rí àtúnṣe bí i àwọn ótiṣeéṣe fún ibi ààbò – tí ó máa ń sábà bèèrè fún onígbọ̀wọ́ láti àjọ tàbí àwọn ènìyàn ní orílẹ̀-èdè ibi ààbò. Ní ìparí, àwọn àsopọ̀ ara-ẹni le ṣe ìrànwọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀nà gbẹ̀fẹ́ sí ààbò.

Rí ìròyìnkíròyìn tí kò tọ́ tàbí tí àkókò rẹ̀ ti kọjá? Kọ ọ́ níbí. 

Àwòrán Smaranda Tolosano, GIJN

Smaranda Tolosano ṣàkóso ìtúmọ̀-èdè àti ìbádòwòpọ̀ fún GIJN. Ó jábọ̀ fún Thomson Reuters Foundation ní Morocco, tó ń kó ìròyìn jọ lórí ìlò Èròjà Ìsọ́ni ti ìjọba láti fojúsun ìṣèjọba tó yàtọ̀ àti gbígbé Ìfàrahàn tí Aṣègbèfábo lórí ilé-iṣẹ́ ìròyìn àwùjọ.