ÀÀBÒ Ẹ̀RỌ AYÉLUJÁRA

Wọ́n gba àwọn Oníròyìn ní ìyànjú gidigidi láti dá ààbò bo àwọn ìbánisọ̀rọ̀ wọn àti àwọn ìròyìn wọn láti dènà ìruga sókè ìhalẹ̀mọ́ni.

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ṣe àfihàn pé ọ̀pọ̀ àwọn oníròyìn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbàgbọ́ pé ewu náà jẹ́ òtítọ́, wọn kò gba àwọn ààbò tó jẹ́ ìpìlẹ̀

Àjọ Rory Peck gbé ìtọ́nisọ́nà ààbò ẹ̀rọ ayélujára síta pẹ̀lú èròńgbà sí àwọn Aládàáni, títẹnumọ́ ọ pé “gbígba kékeré, àwọn ìgbésẹ̀ tó rọrùn le ṣe ìyàtọ̀ tó lágbára.”

Láti ṣe ìrànwọ́ fún ìdàgbàsókè ààbò ẹ̀rọ ayélujára, GIJN ti wo ìtọ́nisọ́nà yìí sí àwọn ohun èlò lórí kókó ọ̀rọ̀.

“O kò le sọ wí pé ẹnikẹ́ni ní ààbò tó pé yégéyégé” Trevor Timm ló sọ bẹ́ẹ̀, olóòtú kejì ti Àjọ fún Òmìnira àwọn oníròyìn , níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti PDNPulse. “Ṣùgbọ́n àwọn ìgbésẹ̀ ìpìlẹ̀ kan wà tí ẹikẹ́ni le gbé tí ó ma jẹ́ kí wọ́n ní ààbò tí ó ju àádọ́rùn-ún tàbí márùn-ún –dín-lọ́gọ̀rún ojú-ìwọ̀n àwọn tó ń lo ìtàkùn ayárabíàṣá, èyí si lọ ọ̀nà tó jìn.”

A bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìsọníṣókí ìṣedúró láti ọwọ́ Robert Guerra, alámọ̀dájú ààbò ẹ̀rọ ayélujára ní èyí tó tẹ̀dó sí ilé-ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ọmọ-ìlú ní Canada, ẹní tí ó ṣe ìkìlọ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn oníròyìn pé wọn gbé àwọn ìgbésẹ̀ ìṣọ́ra tó jù.

“Tí o bá ti di mímọ̀ fún ìkóròyìn ti aṣèwádìí, àwọn ènìyàn le lo ohun èlò ẹ̀rọ ayélujára láti wá lẹ́yìn ìwọ àti déétà rẹ,” Guerra ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí o ti ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ  kọ́ àwọn òṣìṣẹ́ NGO àti àwọn oníròyìn bí wọn ṣe le máa ṣàkóso ìbáṣepọ̀ tó láàbò àti déétà orí ìtàkùn ayélujára. “Bẹ̀ẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà. Mọ àwọn ewu. Àwọn ohun tó rọrùn kan wà tí àwọn ènìyàn le ṣe.”

Guerra mú àbá wá, tí ó bẹ̀rẹ̀ láti ibí yìí:

Ímeèlì

 • Bí o bá rin ìrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí o mọ̀ fún ṣiṣẹ amí lórí ilé-iṣẹ́ ìròyìn, má ṣe gbáralé àwọn olùpèsè ímeèlì tí ó tẹ̀dó síbẹ̀.
 • Ní ilé, lo olùpèsè tí ó ní ààbò – o lè sọ bí ímeèlì rẹ bá ní ààbò nípa wíwo “https” ní ààyè àdírẹ̀sì. Gmail ní ààbò tí ó ba wá, nígbà tí a lè ṣe àtúnṣe sí ti Yahoo àti Facebook. Kí ló dé? Bí o bá lo nẹ́tíwọ̀kì aláìlowáyà ọ̀fẹ́, ẹnikẹ́ni le tẹ̀ ẹ́ ní kíákíá lórí  àtẹ agbáwòrán-tàn pẹ̀lú èto software ọ̀fẹ́ àti èyí tó rọrùn. Ìṣòro nìyẹn bí o bá ń bá apwọn orísun rẹ sọ̀rọ̀. Ó dàbí pé ọwọ́ rẹ kún tàbí o ń ṣiṣẹ́ ní ìta gbangba tí o ń bà wọn sọ̀rọ̀ pẹlú àṣírí orísun, Guerra ṣàlàyé, “ṣùgbọ́n ẹ̀yin méjèèjì lẹ ń pariwo.”
 • Má ṣe rò pé àwọn òṣìṣẹ́ rẹ ń dá ààbò bo àkáùǹtì rẹ. Bí àwọn tábìlì ìmọ̀-ẹ̀rọ lórí àwọn ìṣọ́ra tí ó gbà, kí o sì ro níní àkáùǹtì tìrẹ láti Google tàbí Yahoo èyí tí o ní ìṣàkóso lé lórí.

Ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé àti ìgbésẹ̀-méjì fún ìwọlé

Bí o bá ní Gmail, gbogb ènìyàn ló mọ orúkọ-ìmúlò rẹ. Olùgbọ̀nà-ẹ̀bùrú-wọlé kan nílò ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó hànde ju ni lílo ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé tó dínjú. Àwọn ìtọ́nisọ́nà wà lóri ṣíṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé tó lágbára tí wọ́n tò sí ìsàlẹ̀. Àti pé, fún ìbáraẹniṣepọ̀ tó ṣe kókó, Gmail, Twitter, àti Facebook ti ṣe àfikún – àṣàyàn – ipele ààbò – ìgbésẹ̀-méjì fún ìwọlé. Bí o bá ti jẹ́ kí ìgbéṣẹ̀-méjì náà ṣiṣẹ́, tẹ ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ sí i, àkáùntì fi àtẹ̀ránṣẹ́ sí ọ lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀, ti ó ń pèsè àwọn kóòdì ìfàṣẹṣí aláìlẹ́gbẹ́ tí o gbọ́dọ̀ tẹ̀ sí i láti ní àǹfààní sí àkàúǹtì.

Àwọn oníròyìn tí ò ní ààlà ní fídíò ìṣẹ́jú méjìlá lórí ṣíṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé tó ní ààbò.

Ìṣètò ìwọlé

Ṣẹ̀dá olùmúlò àkáùǹtì tó pọ̀ lóri ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà rẹ, pẹ̀lú ó kéré tán àkáùǹtì olùmúlò kan sí alámòójútó àkáùǹtì tó ba wá. Rí ri dájú pé àkáùǹtì kejì kò ní àǹfààní alámòójútó, nígbà náà lo ìyẹn láti wọlé fún iṣẹ́ òjọ́ ọ rẹ. Lẹ́yìn ìgbà náà, tí Èròjà Aṣèjàm̀bá bá gbìyànjú láti dúró sórí ẹ̀rọ láìfọwọ́yí i, ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà rẹ yóò sọ fún ọ pẹ̀lú àtẹ̀ránsẹ́ tó ń bèrè fún ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé alámòójútó.

Ẹ̀rọ Arárabíàṣá Èròjà Aṣèjàm̀bá

 • Ṣọ́ra fún àwọn àsomọ́ tó mú ìfunra dání, jẹ́ kí àwọn ètò rẹ mọ bí ó ṣe ń lọ, kí o sì gba ètò tó dára tó lòdì sí ààrùn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ètò tí o bá rà má a pèsè ààbò tó tóbi jù.
 • Wá fún àwọn ímeèlì láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ tàbí àwọn ènìyàn tí o lè mọ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń wò bí pé wọ́n yàtọ̀ – àwọn gírámà kékeré yí padà tàbí ìfàmìsí tó ṣàjèjì.
 • Olùmùlò Mac, yàgò fún ìpẹ̀tùn sí àwọn ìtumọ̀ òdì lórí ààbò.
 • Àwọn ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà tí kò bá ìgbà mu tí kò ní àbùlé ààbò le fi ọ́ sínú ewu tó lágbára.

Guerra ṣàpèjúwe àwọn ohun èlò kan pàtó tó wúlò níbí (èdè Gẹ̀ẹ́sí àti Spanish).

Nígbà Tí Nǹkan Bá Lọ Ni Ọ̀nà Tí Kò Tọ́

Pariwo bí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà rẹ bá bẹ̀rc` láti má a ṣe ṣégeṣège. Kàn sí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbẹ́ kòlérè tí wọn fi sọrí láti máa ṣàwári áti máa tọpa àwọn ìkọlù àti ìdánilẹ́kọ́ olùmúlò. Wọ́n níṣe pẹ̀lú:

 • Ìráyè sí wá ń ṣiṣẹ́ 24/7 ìlà-ìrànwọ́ ààbò ẹ̀rọ-ayélujára wà ní èdè mẹ́sàn-án: Èdè Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Spanish, Èdè Faransé, Èdè German, Èdè Portuguese, Èdè Russian, Èdè Tagalog, Èdè Àrábíkì, àti Èdè Italian. Wọ́n fèsì sí gbogbo ìbéèrè yìí láàrín wákàtí méjì.
 • Ìgbìmọ̀ sí Ààbo àwọn Oníròyìn, tí ó tẹ̀dó sí New York, ṣe alágbàwí lórí ipò àwọn oníròyìn ní gbogbo àgbáyé àti ohun ìbéèrè fún ìrànlọ́wọ́. 
 • Àwọn Oníroyìn tí kò láàlà, tẹ̀dó sí Paris, ṣe àgbàwí ohun tó fara jọ ti CPJ. Àwọn oníròyìn tí kò láàlà ṣe àwọn isẹ́ pàjáwìrì lórí ìrànwọ́ fún ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti tábìlì ìrànwọ́ ẹ̀rọ-ayélujára láti gba àwọn oníròyìn ní ìmọ̀ràn àti láti tì wọ́n lẹ́yìn ní kákàkiri àgbáyé lórí ààbò ẹ̀rọ-ayélujára. Àwọn Àlàyé lórí orí-ọ̀rọ̀ bí ìlokòòdù, ìforúkọpamọ́, ààbò àkáùntì àti ọ̀nà-ìmúṣe àgbà-ọ̀jẹ̀ láti ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀-òdì àti àwọn ìròyìn irọ́ ti wà ní helpdeck.rsf.org.
 • Ilé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ọmọ-ìlú ní ilé ìwé gíga ti Toronto, ṣe ìwádìí ààbò ìtàkùn ayélujára àti àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé-ìtalólobó

Kò sí àìpé ìtọ́nisọ́nà sí ààbò ẹ̀rọ ayélujára. Púpọ̀ ni ó dínjú, tí kò sì wúlò fún àwọn oníròyìn tí ó ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ìrànwọ́ wà níta, ó sì tọ́ fún yíyan ẹnìkan nínú ẹgbẹ́ ẹ yín, ní yàrá-ìròyìn yín, tàbí àwọn aṣiṣẹ́-kòlérè yín láti ṣíwájú láti rí àrídájú pé iṣẹ́ ẹ yín ní ààbò. Níbí I ni àwọn ohun èlò kan wà:

Bí Àwọn Oníròyìn Ṣe Lè Gbáradì Fún Ìhalẹ̀mọ́ni Orí Ìtàkùn Ayélujára, Ẹ̀bu Ìròyìn, átíkù kan ní ọdún 2021 láti ọwọ́ Howard Hardee sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn oníròyìn ṣe le ti wíwà lórí ìtàkùn ayélujára le kí ó tó di wí pé wọ́n fojú u sí I lára àti ohun tí yàrá-ìròyìn le ṣe láti ran àwọn òṣìṣẹ́ wọn lọ́wọ́.

Ohun-Èlò Fún Ààbò-Yàrá-Ẹ̀rọ-Ayélujára Ti GCA Fún Àwọn Oníròyìn, tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní ọdún 2020 láti Global Cyber Alliance, ọ̀fẹ́ ni, ohun-èlò tí wọn le ṣiṣẹ́ lórí rẹ ni pẹ̀lú èróńgbà láti ran àwọn oníròyìn lọ́wọ́, yàrá-ìròyìn kékeré àti àwọn ojú-laláńkàn-fi-ń-ṣọ́rí tí wọ́n fagbára kún ìfikọ́ra ààbò-ayélujára. 

Ewé-Ìwé Ìyànjẹ Fún Orísun Tó Ṣí Sílẹ̀ Ti Ìwọ̀fún Ààbò Ẹ̀rọ-Ayélujára tí wọ́n ṣe fún GIJN ní ọdún 2019 láti ọwọ́ Katarina Sabados, ẹni tí ó jẹ́ oníròyìn aládàáṣe àti olùwádìí pẹ̀lú ti èyí tó jẹ́ Ètò Iṣẹ́-àkànṣe Ìkóròyìnjọ ti Jẹgúdújẹrá àti Ẹ̀ṣẹ̀ (OCCRP).

Ìgbìmọ̀ láti dá ààbò bo àwọn oníròyìn, ohun-èlò ààbò ẹ̀rọ- ayélujára Español, Français, àti Русский

Ìtọ́nisọ́nà ti ọdún 2019 níṣe pẹ̀lú orí mẹ́fà:

Dá ààbò bo àkáùntì rẹ

Olè orí-ímeèlì

Ààbò ẹ̀rọ

Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó ní kóòdì

Dá ààbò bo ìlò ìtàkùn ẹ̀rọ ayárabíàṣá

Kíkọjá ààlà

Ìmọ̀ràn ààbò CPJ: Oníròyìn fojú sọ afòyemọ̀-ẹṣin ti ẹ̀rọ ayárabíàṣá Èròjà Alamí (2019)

Ìpàdé ẹ̀kọ́ ààbò àkókò ẹ̀rọ ayélujára ní New York kún fún ìtọ́nisọ́nà lórí bí o ṣe le ṣe àkọsílẹ̀ ara rẹ lórí ìtàkùn ayélujára àti Ààbò ìtàkùn ayárabíàṣá & ìwé-àyẹ̀wò ìdánikan wò. Ipa-ẹ̀kọ́ ìtọ́nisọ́nà fún àkọsilè náà wà fún àwọn olùṣètò ìpàdé-àkànṣe-iṣẹ́.

Àpapọ̀ Àwọn Oníròyìn Jákèjádò Àgbáyé Gbogbo ní oṣù kọkànlá ọdún 2019, ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilànà ìtọ́sọ́nà láti jà padà lápapọ̀ láti lòdì sí àwọn ìsọ̀rọ̀-òdì sí àwọn oníròyìn obìnrin lórí ìtàkùn ẹ̀rọ-ayélujára.

Ìyẹrawò Ààbò ẹ̀rọ-ayélujára láti yàgò fún jíjẹ́ ẹni tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, láti ọwọ́ Will Carless, ẹni tí ó jẹ́ akọ̀wé ìròyìn fún títú àṣírí tó bò ó. Ìgbékalẹ̀ GIJC19. 

Ààbò Ẹ̀rọ-Ayélujára Fún Àwọn Oníròyìn Bèèrè Fún Awọn Ohun-Èlò Tó Ṣé Ń Faradà Átíkù ọdún 2019 wá láti ọ̀dọ̀ Grégoire Pouget, Ààrẹ àti Olùdásílẹ̀ Nothing2Hide.

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ààbò Ẹ̀rọ-ayélujára fún àwọn Ajìjàgbara àti Àwọn oníròyìn láti Totem, ẹ̀kọ́ orí-ìtàkùn ayárabíàṣá fún àwọn oníròyìn, àwọn ajìjàgbara àti àwọn ajà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní àìléwu, agbègbè yàrá-ìkẹ́kọ̀ọ́. Totem pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ lórí ààbò ẹ̀rọ ayélujára ní Èdè Arabic, Èdè Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Faransé, Persian, àti Spanish.

Òṣùwọ̀n Fún Yàrá Ìròyìn Àti Àwọn Oniròyìn Láti Sọ̀rọ̀ Sí Ìhalẹ̀mọ́ni Orí Ìtàkun Àgbáyé Àkójọpọ̀ àwọn ohun èlò tí àwọn àjọ oníròyìn kárí-ayé gbogbo(IPI) lorí ètò ní ọdún 2019 kó jọ láti bo orí-ọ̀rọ̀ bí i ohun tó yẹ ní ṣíṣe nígbà tí oníròyìn bá gba ìhalẹ̀mọ́ni orí-ìtàkùn ayárabíàṣá àti bí yóò ṣe ṣẹ̀dá àṣà fún àìléwu nínú yàrá-ìròyìn.

Àwọn Oníròyìn tí kò ní Ààlà àlàyé lórí àwọn orí-ọ̀rọ̀ bí i ìlokóòdù, ìforúkọpamọ́, ààbò àkáùntì àti ìkonusí alámọ̀dájú tí ó níṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé àti àwọn ìròyìn ẹbu ti wà ní helpdesk.rsf.org.

Ààbò Ẹ̀rọ-ayélujára: Yọ gbogbo déètà tó bá jẹ́ ti ara re kúrò lórí ìtàkùn àgbáyé di títẹ̀ jáde ní ọdún 2019 láti ọwọ́ àwọn Ìgbìmọ̀ láti dá ààbò bo àwọn Oníròyìn.

Àwọn Ìtọ́sọ́nà Sí Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ààbò jẹ́ ipa-ẹ̀kọ́ tí àwọn OpenNews ṣàmójútó rẹ, ẹgbẹ́ tí ó ṣe ìrànwọ́ fún àwọn olùdàgbàsóke, olùgbélárugẹ, àti olùṣàgbéyẹ̀wò déétà láti bá àṣà mu àti àṣepọ̀ lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣẹ tóṣí sílẹ̀, àti BuzzFeed Open Lab, iṣẹ́-ọnà àti ètò àjọṣepọ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n-àmúṣe ní àwọn ìròyìnBuzzFeed.

Ìtalólobo Mẹ́rin Ààbò Ẹ̀rọ-Ayélujára Tí Gbogbo Oníròyìn Nílò Láti Mọ̀ níbi tí wọn kò ti kó ìròyin jọ ní Asia ní ọdún 2018 ibi àpéjọpọ̀ ní Seoul, Chris Walker, àgbà-ọ̀jẹ̀ nínú ààbò ẹ̀rọ-ayélujára láti ọ̀dọ̀ Àpapọ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n-àmúṣe, pín áwọn kókó ìtalólobó tí àwọn oníròyìn le ṣe lónìí láti dá ààbò bo ara wọn, àwọn orísun wọn àti àwọn ìtàn wọn.

Òsùwọ̀n Fún Àwọn Yàrá-Ìròyìn Àti Àwọn Oníròyìn Láti Sọ Sí Ìhalẹ̀mọ́ni Orí Ìtàkùn Ayélujára, àkójọpọ̀ ohun èlò tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2019 láti ilé-ẹ̀kọ́ oníròyìn kárí-ayé gbogbo, pẹ̀lú ìlànà kan láti ṣe àtìlẹyìn fún àwọn oníròyìn tí wọ́n fojú sọ.

Ìhalẹmọ́ni Orí-Ìtàkùn Ayélujára Láàyè Ìtọ́nisọ́nà, gbé e jáde láti ọwọ́ PEN America, pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ràn fún oríṣìíríṣìí àwọn olùgbọ́ – Àwọn Òǹkọ̀wé – Àwọn Ẹlẹ́rìí – Àti àwọn òṣìṣẹ́ – pẹ̀lú àwọn àbùdá tí kò wọ́pọ̀, bí i Ìlànà ìtọ́nisọ́nà fún sísọ̀rọ̀ ssí àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ ẹni. 

Ẹ̀rọ-ìbáraẹnissọ̀rọ̀ rẹ àti ìwọ: ìwé-ìléwọ́ láti tọ́jú  fóònù alágbèéká tí ayé òde-òní ìtọ́nisọ́nà ọdún 2019 láti ọ̀dọ̀ Àjọ Òmìnira Oníròyìn.

Àtúnṣe ti oṣù kẹjọ ọdún 2017 ti Ohun-èlò Ààbò Ẹ̀rọ-ayélujára Lọ́wọ́lọ́wọ́ tí wọ́n fà papọ̀ láti ọwọ́ Martin Shelon, ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ láti máa ṣe àkíyèsí pé “àní ọọlọ́rọ̀ jùlọ ohun-èlò ààbò ẹ̀rọ-ayélujára tètè di ti ayé-àtijọ́.” Shelton tún jẹ́ oǹkọ̀wé átíkù kan lórí ọ̀kan lára Àmọ̀ràn ìdáàbobò tó wọọ́pọ̀ jùlọ, nípa lílo ìfàṣẹsí ìgbésẹ̀-méjì. Ohun mìíràn lórí ìkóròyìn rẹ jọ ni bí àwọn oníròyìn ṣe le gbáradì fún àwọn ẹ̀rọ ayárabíàṣá software tó ń mú ìríra dání.

Átíkù Shelton ti ọdún 2016 Dídáàbò bo ara ẹni lórí ẹ̀rọ ayélujára: Ìfáàrà, àtúntẹ̀jáde láti ọwọ́ GIJN, ku àlàyé tó wúlò fún orí-ọ̀rọ̀.

Ìṣọ́ Dídáàbò bo Ara-ẹni láti Àjọ Ààlà Ìtanná láti pèsè àwọn ìròyìn tó pọ̀, pẹ̀lú ìgbésẹ̀-méje “Àtòpọ̀ Olùbẹ̀rẹ Àìléwú.” Lára àwọn Àbá:

 • Lílo ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé dáradára: Yan ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé tó le nípa lílo Èròjá dáàsì, yàgò fún àtúnlò ọrọ̀-ìgbaniwọlé, rò ó láti lo kòòdù orí ẹ̀rọ àìléwu tàbí alákòóso ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé, yàgò fún fífun àwọn ìdáhún tó rọrùn fún ìbèèrè ààbò, líló ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé ìgbésẹ̀-méjì ìfàṣẹsí. Bí o bá kọ ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ sínu ìwé pélébé tí ó wà nínú àpamọ́wọ́ rẹ, rí i dájú pé o ṣe àfikún àwọn ìṣesí tó gọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ tó jẹ́ òótọ́, àti pé má ṣe sààmì tó hàn kedere sí àkọọ́lẹ̀ rẹ. Má lo ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé kan náà fún àkọọ́lẹ̀ tó pọ̀. kí o sì má a yí ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ padà déédé.
 • Má ṣe ba ẹ̀rí jẹ́, ṣùgbọ́n o lè ṣètọ́jú ètò ìmúlò ìdádúró ní èyí tí o ó má yọ fáìlì rẹ déédé. Rí i dájú pé ètò-ìmúlò náà wà ní kíkọ àti títẹ̀lé láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. “Ó jẹ́ ìgbèjà rẹ tó dára ju tó lòdì sí ìfìwépé sílé ẹjọ́ – wọ kò le gbà á bí o kò bá ní i.”
 • Ìpìlẹ̀ fún ààbò déétà: Bèèrè ìwọllé fún àkọọ́lẹ̀ àti àwọn ìpamọ́-àtẹ agbáwòrán-tàn. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ le. Rí i dájú pé o ní ìgbẹkẹ̀lé nínú àwọn Alámòójútó ètò rẹ.
 • Ìlo-kóòdù Déétà: Àwọn Ìjọba le rí àwọn ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé – dééta tó láàbò. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ – déétà tó ní kóòdù máa ń ṣòro. SSD ṣàgbékalẹ̀ àwọn ìtọ́nisọ́nà ìpìlẹ̀ mìíràn sí bí ìlo-kóòdù ṣe ń ṣiṣẹ́.
 • Ààbò láti Èròjà aṣejàm̀bá: Lo ẹ̀rọ ayárabíàṣá software tó ń dènà àarùn, jẹ́ kí àwọn Àbùlé Ààbò rẹ mọ bí ó ṣee ń lọ àti pé kí o yàgò fún títẹ àwọn àsopọ̀ tó mú ìfunra dání àti àwọn fáìlì.

Eva Galperin ti Àjọ Ààlà Ìtanná káàkiri U.S. Ilé-iṣẹ́ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Gbangba pèsè ewé-ìwé ìtalólobo yìí ti ìfikọ́ra tó dára jù. Díẹ̀ nínú kókó tó ṣe pàtàkì ni :

 • Ẹ̀rọ ayárabíàṣá Skype kò ní ààbò tó bí a ṣe wò ó. Àwọn ìjọba le tọpa ìrìn rẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, rò ó láti lo Google Hangouts.
 • Àtẹ̀ránṣẹ́ kò ní ààbò àti pé kò lo kóòdù.

Ìfiránṣẹ́ Ìtọ́nisọ́nà ti Ààbò Ẹ̀rọ Ayélujára, láti ìwé-ìròyìn tí wọ́n fi ránsẹ́.

Myanmar: Ìtọ́nisọ́nà Ààbò Ẹ̀rọ Ayélujára fún Àwọn Oníròyìn: Ohun èlò tó rọrùn láti rí àǹfààní sí (2017) láti ran àwọn oníròyìn lọ́wọ́ láti dá ààbò bo àwọn ìbáraẹnisọ̀rọọ̀ wọn àti ẹ̀rọ ayélujára wọn láti lòdì sí jíjáwọ́-òpó ayélujára láìgbàṣẹ, Ìṣọ́ni àti ẹ̀dá ìhalẹ̀mọ́ni ẹ̀rọ ayélujára yòókù. Àwọn ilé-iṣẹ́ fún Òfin àti Ìjọba Tiwa-n-tiwa (CLD) pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Àtìlẹ́yìn Ilé-iṣẹ́ tó gbé ìròyìn jáde Kárí-ayé gbogbo (IMS), FOJO Ilé-ẹ̀kọ́ ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde àti Ìgbìmọ̀ Oníròyìn Myanmar (MPC) Ìtọ́nisọ́nà Ààbò Ẹ̀rọ Ayélujára [Èdè Gẹ̀ẹ́sì] Ìtọ́nisọ́nà Ààbò Ẹ̀rọ Ayélujára [Burmese]

 Steve Doig, Ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ilé-ìwé Gíga Ìpínlẹ̀ Arizona ní U.S. pèsè àwọn ìtalólobó wọ̀nyí nínú ìgbékalẹ̀ rẹ.

Spycraft: Pípa àwọn Orísun Aláàdi rẹ mọ́ (Powerpoint): 

 • Wá orí-ìtàkùn ayélujára pẹ̀lú IXQuick, èyí tí kò ní àdírẹ̀sì IP rẹ lọ́wọ́ tàbí ẹgbẹ́ ìwádìí. 
 • Dínbọ́n fún ẹni tó ń pè ọ́ pẹ̀lú SpoofCard. Èyí ṣiṣẹ fún ìpè kárí-ayé gbogbo.
 • Má ra kò-ládèéhùn ẹ̀rọ0ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kanakn pẹ̀lú owó.
 • Lo kóòdù sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ rẹ
 • Ìdánìkanwa tó d´ra lágbára àti ile-iṣẹ́ tó ní gbèǹdéke.
 • Spam Mimic ´òdù àwọn àtẹ̀rámṣé rẹ ní èyí tó jọ Ímeèlì Spam.
 •  Palẹ̀ mọ́ fáìlì tí wọ́n ti parẹ̀ fún dídára nípa lílo Webreoot Window Washer.
 • Nígbà tí o bá ń gba àwọn ìwé tí ó ti hànde láti ọ̀dọ̀ àwọn orísun ìjọba, ṣọ́ra fún àwọn ààmì-olómi tí a kò le fojú rí.

Àpapọ̀ Ìmọ̀ Ọgbọ́n-ìmọ́ṣe ti tẹ Ààbò-nínú-Àpóti jáde, wọ́n sì mu dójú-ìwọ̀n fún àwọn Ajà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àwọn Oníròyìn. Ó níṣe pẹ̀lú Bí-ìwé-pélébé tí ó ń bo agbègbè mọ́kànlá, Ọwọ́-lórí Ìtọ́nisọ́nà tó dojúkọ àwọn Freeware kan ní pàtó tàbí àwọn orísun tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀ ohun-èlò software àti ẹ̀ka Ààbò ẹ̀rọ-alágbèéká.

-English https://securityinaboọ.org/en/about,

– Russian https://securityinaboọ.org/ru/

– Arabic https://securityinaboọ.org/ar/

– Bahasa 

Indonesia https://securityinaboọ.org/id/

Àtẹ-àyẹ̀wò Ìṣọ́ Dídáàbò Ara-ẹni láti ìwọnú-ara tí ó ń ṣàpèjúwe ìpìlẹ̀, ààrín àti àwọn ìgbésẹ̀ àtiṣíwájú láti gbé.

Micah Lee ti ìwọnú-ara kọ́ ìwé Ìṣọ́ Dídáàbò bo ar-ẹni kúrò ní ìṣàkóso Trump, tí ó ń ṣe ìkìlọ̀ pé ìfẹ̀lójú kíákíá ti àwọn Aláṣẹ tó lágbára ní United States túmọ̀ si, “Àwọn tó ń gbáradì fún ìjà tó gùn níwájú gbọ́dọ̀ dá ààbò bo ara wọn, bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá tilẹ̀ dọ́gbọ́n díjú.”

Àwọn Oníròyìn Nínú Wàhálà: Dídáàbò Bo Ayé Ẹ̀rọ Ayélujára Rẹ tí wọ́n pèsè sílẹ̀ láti ọwọ́ Àwọn Oníròyìn Canada fún òmìniraa àti sọ̀rọ̀. Wọ́n ṣe é ní Èdè Faransé àti Èdè Arabic.

Ààbò orí ìtàkùn Ayélujára fún Àwọn Oníròyìn: Àwọn ohun-èlò àti Ìtalólobó fún Dídáàbò bo Àwọn Ìbàraẹnisọ̀rọ̀ rẹ. Ìwé àkọsílẹ̀ (ní French) láti ọwọ́  aàwọn Olùkópa nínú kọ́ọ̀sì Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Àjọ Oníròyìn Europe (EFJ) ṣe agbátẹrù rẹ̀ àti Ilé-ẹ̀kọ́ Ìsọ̀kan Ìtajà Europe (ETUI) dẹ̀rọ̀ lati ọwọ́ Àgbà-ọ̀jẹ̀ nínú Ààbò Ẹ̀rọ-ayélujára, Dmitiri Vitaliev.

Àtẹ̀ránsẹ́ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀: Ọ̀pọ̀ àwọn Àgbà-ọ̀jẹ́ ló ṣe ìṣedúró nìpa lílo Ìṣàmìsí tàbí WhasApp. Wo Átíkù lórí Ìsàmìsí láti ọ̀dọ̀ Journalism.co.uk. Èènì, Átíkù Àfọwọ́yà Àkọ́kọ́ lórí lílo WhatsApp fún kíkó ìròyìn jọ. Àwọn Mozilla pèsè ilé-iṣẹ́ pínpín fáìlì tó jẹ́ ọ̀nà ńlá láti gba àwọn fáìlì láti ọwọ́ àwọn ènìyàn tí kò ní ìtura pẹ̀lú tàbí ní ipò láti fi kóòdù sí fáìlì fún ra wọn tàbí rán wọn nípaṣẹ̀, fún àpẹẹrẹ. Ìsàmìsí.

Privacidade Para àwọn Oníròyìn (ibi Àṣírí fún àwọn Oníròyìn) jẹ́ oríṣìí-ẹ̀dà Brazillian ti Ojú-ìlà Australian tí Oníròyìn Raphael Hernande ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Ó níṣe pẹ̀lú àwọn ìtọ́nisọ́nà àti àwọn ohun èlò bí i ọ̀kan lórí “ìtúpalẹ̀ ìhalẹ̀mọ́ni.” Ìtalólobó rẹ̀ márùn-ún tó jẹ́ ìpìlẹ̀ ni wọ́n ṣe ìsọníṣókí rẹ̀ sínú átíkù yìí lóri Knight Center Journalism ní búlọ̀ọ̀gì America (Spanish) (Portuguese):

 • Ìlokóòdù ti HD àti Ibi ìpamọ́ ọlọ́jọ́-pípẹ́ kékeré – ìlokóòdù máa ń fi ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé sí orí hard drive àti ẹ̀rọ USB, èyí tí ó máa ń dá ààbò bo àwọn orísun àti fáìlì ti ara ẹni bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ohun èlò sọnù tàbí wọ́n jí i.
 • Ìgbésẹ̀-méjì Ìfaṣẹsí – lò fún àwọn ìráàyè sí ilé-ìfowópamọ́ lórí ìtàkùn ayélujára, ó le ṣe àtúntò rẹ nínú ímeèlì àti nẹ́tíwọ̀kì orí-ìtàkùn. Ìwọlé ti di ṣíṣe pẹ̀lú nǹkan tí o mọ̀ (ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ) àti nǹkan tí o ní (kóòdù tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ, fún àpẹẹrẹ). Èyí máa ń yàgò fún àwọn ìṣòro bí o bá tilẹ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀-ìgbaniwolé tó gbògùn.
 • Ìsàmìsí – Ìbẹ̀wẹ̀ wà fún àtẹ̀ránṣẹ́ kóòdù ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. bí wọ́n bá yí ẹ̀rọ iléwọ́ ìbánisọ̀rọ padà, kò sí ẹni tí ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ le yé.
 • Sync.com – Ẹ̀rọ ìkó-nǹkan sí lórí ìtàkùn ayélujára lọ́fẹ̀ẹ́. Ó ń lo ìlànà òdo-ìmọ̀, èyí tí ó túmọ̀ sí pé o fi ìròyìn pamọ́ ṣùgbọ́n kò mọ ohun tí ó kó pamọ́. Gẹ́gẹ́ bí òfin, orí ìtàkùn tí a máá ń sábà fojúwò gààrà àwọn fáìlì àti darí àwọn ìròyìn sí àwọn aláṣẹ. Sync ní kóòdù, ó sì tún ní ààbò tó jù, ó rọrùn láti lò.
 • PGP – àgékúrú Pretty Good Priẹacy. Ó jẹ́ ọ̀nà kan láti fi kóòdù sí ímeèlì. Bí ẹ̀yà àyà, ṣùgbọ́n pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ méjì: ọ̀kan láti tì àti èkejì láti ṣí. O fún wọn ní kọ́kọ́rọọ́ tó ń ti àyà kí àwọn ènìyàn le fi fáìlì ranṣẹ́ àti Àtẹ̀ránsẹ́. Ṣùgbọ́n ìwọ nìkan lo ní kọ́kọ́rọ́ láti ṣí àkóónú.

Ibi Àṣírí fún Àwọn Oníròyìn jẹ́ ojú ìkànnì ní Australia tí CryptoAustralia ṣe alákòóso rẹ̀. Órí-ọ̀rọ̀ titun ni wọọ́n ṣo ní Búlọ̀ọ̀gì, bí i Fífi àwọn Fáìlì ní orí ìtàkùn níkọ̀kọ̀, Yíyan ẹ̀rọ Àwárí Aláàbò àti fi kóòdù sí ẹ̀rọ USB rẹ lórí Windows.

Bí O Ṣe Le Fòpin Sí Ìtọpa Ibi Tí O Wà Átíkù New York Times ti oṣù kejìlá ọdún 2018 láti ọwọ́ Jennifer Valentino-DeVries àti Olóorin Natasha. Wọ́n ṣe ìṣedúró yíyí ibùdó padà, ṣíṣe àkíyèsí pé ìròyìn wọn wáyé ní paàtàkì sí United States. 

Àti pé, dájúdájú, pọ́díkáàsìtì. Pọ́díkáàsìtì onítàn: Ààbò Ẹ̀rọ Ayélujára – Bí Àwọn Oníròyìn àti Àwọn Ajìjàgbara ṣe le di dídáàbò bò lórí ẹ̀rọ ayélujára. Agbàlejò àti Oníròyìn Della Kilroy ní wọ́n dàpọ̀ láti ọ̀dọ̀ Oníròyìn Onítàn Jenny Hauser àti Eoghan Sweeney, pẹ̀lú àwọn Àlejò Pàtàkì àgbà-ọ̀jẹ̀ ààbò, Andrew Anderson, Olóòtú Àgbà pẹ̀lú àwọn Olùgbèjà tí iwájú, àti Holly Kilroy, Olùdásílẹ̀ Ààbò Àkọ́kọ́.

 Kaveh Waddel ní Atlantic sọ̀rọ̀ lórí bí Àwọn Oníròyìn ṣe le dá ààbò bo àra wọn nígbà Àbójútó ìjọba Trump? Láàárín àwọn nǹkan tó kù, ó dábà á pé lílo alákóso Èròjà Aláìrídìmú ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé láti pilẹ̀sẹ̀ ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé tó le.

“Gbogbo oṣù kìíní, mo máa ń ṣe ìrugasókè ẹ̀rọ ayélujára…,”kọ Julia Angwin ti ProPublica bí ó ṣe àfihàn àbá mẹ́sàn-án rẹ̀. “ Ní ọdún yìí, Iṣẹ́ lérò ní pàtàkì kíákíá bí a ṣe dojúkọ ayé ní aláìròtẹ́lẹ̀ ìhalẹ̀mọ́ni sí ààbò ẹ̀rọ ayélujara lọ.

Ìgbésẹ̀ mọ́kànlá ni Aimee O’Driscoll fún Comparitech gbà wọ́n ní ìyànjú. “Ìgbéléwọ̀n èyí láti lílo ọpọlọ pípé láti gba àwọn Onímọ̀-ẹ̀rọ tó bá ìgbà mu jù, kí o sì fi àwọn ọgbọ́n bí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ oníkóòdù àti yíyàgò fún orí-ìkànnì tó jẹ́ gbajúgbajà. Nígbà tí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà yìí le dà bí àfikún iṣẹ́, nígbà tí o bá jàn án pọ̀, wọ́n le dín ewu ìròyìn kùn láti má jẹ́ kí àwọn ojú tó ń ṣọ́ni rí i.”

Ṣíṣe àkọsílẹ̀ pé “ayé ẹ̀rọ ayélujára ń dẹ́rùbà ni,” David Trilling dá ìtalólobó ewé-ìwé kalẹ̀ “fún àwọn oníròyìn fún ipele ìtura-ẹ̀rọ ayélujára gbogbo bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn líǹkì sí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wúlò.” Journalist’s Resourse ti Harvard’s Shorenstein Center lórí Òṣèlú Ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde àti ìlànà gbangba. Àkójọ àwọn líǹkì lóri ààbò ẹ̀rọ ayélujára ní ó jẹ́ pípèsè láti ọwọ́ DW Akademie, Àjọ Germany fun ìdàgbàsókè ilé-iṣẹ́ ìròyìn kárí-ayé gbogbo.

Wíwò Àkọ́kọ́ sí Ààbò Ẹ̀rọ Ayélujára – ìwé-pélébé orísun-tó-ṣí-silẹ̀ – láti ràn ọ́ lọ́eọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sí mímú ààbò ẹ̀rọ ayélujára dára sí I lórí ìtàkùn àgbáyé, àti ìmúdójú-ìwọ̀n lórí ìtàkùn àgbáyé ní Github.

Átíkù tí ó ń  fi ìtalolobó márùn-ún sílẹ̀ ni àwọn Ugandan Hub ṣe fún Ilé-iṣẹ́ Ìròyìn Aṣèwádìí, èyí tí ó kọ́ àwọn Oníròyìn lórí ààbò ẹ̀rọ syélujára pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ DW Akademie.

Ìlòdì sí ẹbu-ímeèlì àti Ìmọ́tótó Ímeèlì ní Àjọ Òmìnira àwọn Oníròyìn sọ̀rọ̀ lé.

Ìtalólobó ìdènà mẹ́jọ láti dáàbò bò ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní wọ́n ṣe àpèjúwe ní ọ̀nà àlayé-ẹ̀yà-àwòrán láti ọwọ́ Àjọ Òmìnira àwọn Oníròyìn. Ohun tí ó tún pani lẹ́rìn-ín ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Harlo Holmes, Olóòtú Yàrá-ìròyìn Ààbò Ẹ̀rọ Ayélujára ní Àjọ Òmìnira Àwọn Oníròyìn, tí ó sọ pé “ Ojoojúmọ́ ni abọ́ àwọn àkekèé titun.”

Ohun èlò àjọgba òògùn fún iṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára “ṣe ìfúnni ìpatẹ ti àfijá-ara ohun èlò fún àwọn ajà fún ẹ̀tọ́ ọmọmnìyàn, àwọn olùkọ-nǹkaǹ-sórí-ìtàkùn, Àwọn Àjìjàgbara àti àwọn Oníròyìn tí wọ́n ń dojúkọ àwọn ìkọlù fúnra wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni pípèsè àwọn ìtọ́nisọ́nà fún ẹ̀rọ ayélujára fún àwọn olùdáhùnsí àkọ́kọ́ láti ran àwọn tó wà ní abẹ́ ìhalẹ̀mọ́ní.” Àwọn Alábàáṣepọ̀ Olùgbèjà Ẹ̀rọ Ayélujára àti àwọn NGO tó ju méjìlá lọ ni ó pèsè rẹ̀.

Orísun náà fúnni ni Ààbò fún Àwọn Oníròyìn, Àpá kìn-ín-ní: Àwọn Ìpìlẹ̀ láti ọwọ́ Jonathan Stray. Ìgbàwọlé kejì, Ààbò fún Àwọn Oníròyìn, Apá Kejì: Àwòṣe Ìhalẹ̀mọ́ni

Dídáàbò àwọn Orísun nígbà tí wọ́n bá ń fi àwọn ìwé tó ṣe kókó sílẹ̀ láti ọwọ́ Ted Han àti Quinn Norton tí wọ́n ṣe àtúnkọ, “pa déétà-nínú-déétà rẹ́, yẹ àwọn ìròyìn wò dáadáa, wá àwòrán kékeré & jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ààbò Ẹ̀rọ ayélujára Fún Àwọn Aládàáni, láti ọwọ́ Rory Peck Trust, tí ó bo oríṣìí àwọn orí-ọ̀rọ̀ ti Ààbò ẹ̀rọ ayélujára.

Àjọṣepọ̀ Àwọn Oníròyìn Aṣèwádìì Káàkiri Àgbàyé ní ààmì agbára lórí Ohun èlò fún àwọn Oníròyìn Aṣèwádìí.

Àpótí-ohunèlò Àwọn Oníròyìn láti Àwùjọ fún líǹkì Àwọn Alámọ̀dájú Oníròyìn sí ọ̀pọ̀ ọrọ̀.

Ààbò nínú Àpótí fún un ní oríṣìí àwọn fídíò ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn ọ̀nà tó rọrùn láti ṣètọ́jú ìsọníṣókí àlàyé ara ẹni lórí ìtàkùn ayélujára tí kò pariwo. Ó wà ní French, Spanish, Italian, Portuguese, Russian, Arabic, Armenian, Croatian, Ukrainian, Serbian, Albanian, Bosnian. 

Àwọn ìgbìmọ̀ láti dá ààbò bo àwọn oníròyìn gba àwọn aláàbò-orí-ìtàkùn ní ìyànjú gẹ́gẹ́ bí ara Ìtọ́nisọ́nà Ààbò Iṣẹ́ ìròyìn. Ààbò Ìmọ̀ Ọgbọ́n Ìmúṣe ni Orí kẹta.

 Àwílé lórí àmọ̀ràn CPJ ti kíkọjá ààlà ni Robert Graham ti Ààbò Errata sọ.

Àwọn Oníròyìn Aláìlálà ti ṣe àtẹ̀jáde Ohun Èlò Ìwàláàyè Lórí Ìtàkùn Ayélujára, ó wà ní èdè márùn-ún.

Àwọn Ohun èlò Àkọ́kọ́ Ẹ̀rọ ayélujára jẹ́ ìtọ́nisọ́nà tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ọ̀dọ̀ ilé-iṣẹ́ ìròyìn tó jú méjìlá tó níṣe pẹ̀lú NGO, pẹ̀lú ooníròyìn ọ̀fẹ́ àìlópin, ilé òmìnira, Àwọn ohùn Àgbáyé, àti Àwọn Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.

Ìkànnì tí ó tẹ̀dó sí London fún iṣẹ́ ìròyìn Aṣèwádìí ní ojú ewé ọgọ́rin ìwé ìléwọ́, ìròyìn ààbò fún àwọn oníròyìn, ìtalólobó tó kún àti àwọn ìlànà.

Ààbọ̀ UNESCO Kíkọ́ Ẹ̀rọ Ayélujára Aláìléwu Fún Iṣẹ́ Ìròyìn, ìlapa-èrò méjìlá ìhalẹ̀mọ́ni ẹ̀rọ ayélujára pàtó “pẹ̀lú arúfin tàbí ìsọ́ ẹ̀rọ ayélujára onípọ́nna, ìtọpa agbègbè, àti software àti ìgbéjáde hardware láìsí ìmọ̀ àwọn tí wọ́n fojúsí lára”. Ó pèsè àwọn ìtalólobó lórí bí a ṣe le fi déétà pamọ́ àti ara rẹ láìléwu. Ó tún wà ní: Español.

Facebook ní àwọn ìtalólobó ààbò fún àwọn Oníròyìn ní èdè ogún.

Ìtọ́nisọ́nà fún àwọn ohun èlò ara ẹni 2019 ìtọ́nisọ́nà yìí ní ìkójọ tó gbòòrò tí ìbẹ̀wẹ̀ tata-ẹni ọ̀fẹ́, ohun èlò àti iṣẹ́ tí  àwọn aṣámúlò le ṣe kárí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀rọ. Marcus P.Zillman ló kó o jọ fún LLRX (Law and Technology Resourses for Legal Professionals).

 Ìtọ́nisọ́nà Motherboard kò gbọdọ̀ di jíjá-wọlé láìgbàṣẹ Èyí ni Motherboard tó jẹ́ ìtọ́nisọ́nà tó gbòòrò sí ààbò ẹ̀rọ-ayélujára. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó bo ààbò alágbèékà.

Ìtọ́nisọ́nà DIY sí Aṣègbèfábo Ààbo-orí-ìtàkùn láti ọwọ́ Noah Kelley ẹni tó ṣàwárí ìṣègbèfábo-orí-ìtàkùn láti ara Àjọ ajìjàgbara HACK*BLOSSOM.

Ààbò-orí-ìtàkùn fún àwọn Oníròyìn àti ilé-iṣẹ́ ìròyìn, àwọn ohun èlò láti ọwọ́ Stephen Cobb ti Ilé-iṣẹ́ Ààbò ESET. Orí-ìtàkùn Àgbáyé àti àwọn ohun èlò tí wọ́n tò kalẹ̀. 

Dáàbò bo àwọn ìlànà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fún àwọn oníròyìn, tí wọ́n kọ ní ọdún 2017 láti ọwọ́ Gabor Szathmari tí ó kó fífagilé déétà nínú déétà láti inú ìwé àṣẹ jọ, àtẹ̀ránṣẹ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àti pínpín fáìlì, àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó ní ààbò. Ìfikọ́ra tó dára jù fún ṣìsàkóso ìwádìí tó léwu àti dídá ààbò bo ara rẹ kúrò ní ìyọlẹ́nu orí-ìtàkùn, tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Data & society ní Ọdún 2016tí wọ́n ṣe fún àwọn Olùwádìí acadá, ṣùgbọ́n tí ó kún fún àmọ̀ràn gidi àti àtòjọ àwọn ohun èlò mìíràn.