ÀÀBÒ. DÍDÁÀÀBÒ BO ARA ẸNI LÓRÍ Ẹ̀RỌ AYÉLUJÁRA FÚN ÀWỌN ONÍRÒYÌN: ÌFÁÀRÀ

Láti ọwọ́ Martin Shelton | ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ, ọdún 2016

Ṣọ́ ògiri rẹ. (Peter Levy)

Dídáààbò bo ara ẹni láìsọ ọkàn rẹ nù

Àtẹ àwọn ohun èlò òǹkọ̀wé wà níbí.

Dídáààbò bo ara ẹni lórí ẹ̀rọ ayélujára ti ń di ohun tí ó ṣe pàtàkì fún ohun èlò irinṣẹ́ oníròyìn. Kọjá ewu sí ayé gbogbo ẹ̀rọ ayèlujára – jíjá-wọ ayàwòrán-oníjígí láìgbà àṣẹ, ìrúfin ímeelì, dá olè mọ̀ – àwọn ènìyàn tó ń ṣiṣẹ́ ní yàrá-ìroyìn gan wà nínú ewu tó jù. Yàrá-ìròyìn jẹ́ ọ̀kan nínú ibi tí wọ́n fojú sọ tó tobi jù ní àgbáye fún onígbọ̀wọ́-ìpínlẹ̀ ìkọlù ẹ̀rọ-ayélujára, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìhalẹ̀mọ́ni tó ti di bárakú.

Ṣùgbọ́n ààbò kì í ṣe nípa títi gbogbo ibi pa. Ó le lérò pé ó lágbára bí gbogbo rẹ bá wà lábẹ́ ìhalẹ̀mọ́ni. Ó jẹ́ mímú kí rírí àǹfààní sí àwọn ìtalólobó ìròyìn tí ó ṣe pàtàkì kí ó ní ààbò dípò. Kò sí nǹkan bẹ́ẹ̀ “ààbò tó péye”. Dípò, ó ju kíkọ́ àwọn ohun ìdínà lópòópónà tó lóokun, àti jíjẹ́ kó nira láti ni àǹfààní sí àwọn déétà wa láìgba ààyè lọ́wọ́ wa.

Fún àfikún àlàyé, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà àsopọ̀ sí àwọn orísun tí yóò ranni lọ́wọ́,wo ojú-ewé ohun èlò ààbò ẹ̀rọ-ayélujára ti GIJN.

Dojúkọ Àwọn Ìhalẹ̀mọ́ni Kan Pàtó  

Ro àwọn ìtalólobó ìròyìn tí o fẹ́ dá ààbò bo, ẹni tí ó le fẹ́ ẹ, àwọn ọ̀nà tí àwọn ìtalólobó ìròyìn yìí fi le di àdéhùn, àti ohun tí o lè ṣe láti fi sọ sí àwọn àlafo ààbò. Alámọ̀já ààbò máa ń pe èyí ní Àwòṣe ìhalẹ̀mọ́ni.

Dípò tí a ó fi máa ronú nínú àṣamọ̀, ríronú nípa àwòṣe ìhalẹ̀mọ́ni le ṣe ìrànwọ́ fún àwọn oníròyìn láti dojúkọ àwọn ìṣòro kan pàtó àti àtúnṣe rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, pẹ̀lú àyọlò díẹ̀, ó ṣeé ṣe kí púpọ̀ nínú wa má jẹ́ ìfọjúsí-lára tààrà láti ọ̀dọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ onílẹ́tà-mẹ́ta. Dípò, púpọ̀ nínú wa lè kíyèsára nípa àwọn orísun wa nípa ìdánimọ̀ pẹ̀lú àsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtàn kan pàtó. Púpọ̀ nínú wa nílò láti ṣí àwọn ìwé tí kò níye láti inú ímeelì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ a nílò láti yẹra fún àwọn fáìlì ìríra tàbí ìtọ́kasí. Púpọ̀ nínú wa ń yàgò fún ìdojúkọ-gbangba ti ìjalé déétà adójútini.   

Ní Òye Ìṣe-lo-kóòdù

Lílo kóòdù jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ọ̀nà tó múná dóko tí ó nira fún àwọn yòókù láti ní àǹfààní sí déétà wa.

Ìlokóòdù máa ń ṣe ìrànwọ́ fún dídáàbò bo àwọn àkóónú àwọn ìfiránṣẹ́ tí a pín láàárín rẹ àti iṣẹ́ orí-ìtàkùn. Rò ó pé o fi káàdì ìfiránṣẹ́ kélébé ránṣẹ́, tí o sì fi àtẹ̀ránṣẹ́ náà sílẹ̀ láti ṣe é kà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ kà á ní ọ̀nà ìrìnajò. Ayélujára máa ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà kan náà. Fún àpẹẹrẹ, tí o bá ń  gbìyànjú láti ṣí ẹ̀rọ ayárabíaṣà wi-fi, ẹnikẹ́ni lórí nẹ́tíwọ̀kì le rí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ tí kò láàbò ṣe ń ṣàn ní ọ̀nà tí àtẹ̀ránṣẹ́ ṣe é kà.

Kín ni kí á ṣe? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a ń ṣe iṣẹ́ tó ti di bárakú àti pé a lè má ní ìtanijí tó ga. Pàápàá ní àwọn ẹjọ́ báyìí, a máa ń fẹ́ dín ojú-ẹsẹ̀ déétà wa kù lọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣọ́ni. 

So ó pọ̀ sí ẹ̀rọ ayélujára

Láìléwu si

 • Paápàá jùlọ nígbà tí o bá wà ní orí nẹ́tíwọ̀kì wi-fi tó ṣí sílẹ̀, rò ó láti lo Nẹ́tíwọ̀kì aládàáni orí-ìtàkùn ayélujára (VPN) fún àsopọ̀ ìlòkóòdù èyí yóò jẹ́ kí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ó dúrò láti ọ̀nà jínjìn. Agbègbè to jìnnà náà le ka àwọn súnkẹrẹ-fàkẹrẹ rẹ tí kò lo kóòdù, ṣùgbọ́n yóò lo kóòdù ní agbègbè nẹ́tíwọ̀kì. Èyí le ṣe ìrànwọ́ fún dídáàbò bo súnkẹrẹ-fàkẹrẹ rẹ nígbà tí o bá ń ṣe àbẹ̀wò sí àwọn àpèjọ tàbí àwọn ibi-ìtajà. Kò sí àìpé kankan ní àwọn iṣẹ́ tí kò wọ́n tí ó le ṣe ìrànwọ́ fún dídá áábò bo súnkẹrẹ-fàkẹrẹ orí-ìtàkùn láti ìsamí nẹ́tíwọ̀kì agbègbè. O tún le ṣe àyẹ̀wò bóyá yàrá-ìròyìn yín ń lo Nẹ́tíwọ̀kì Aládàáni Orí-ìtàkùn Ayélujára(VPN) kí o lè ráyw` wọlé láti ara nẹ́tíwọ̀kì wọn.
 • Bí o bá ń ṣe ìwádìí kan lọ́wọ́, wọ́n le dá ọ mọ̀ déédé nípasẹ̀ súnkẹrẹ-fàkẹrẹ tí kò láàbò, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olùdámọ̀ tí kò mú ṣinṣin bí iàdírẹ̀sì IP rẹ. Rò ó láti lo ẹ̀rọ-ayárabíàṣá TOR láti lo kóòdù àti yẹ orúkọ tí yóò fa àìdánimọ̀ ní súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ẹ̀rọ-ayélujára. Pẹ̀lú TOR, súnkẹrẹ-fàkẹrẹ lílo ayélujára yóò farahàn láti àgbègbè tó jìnnà, èyí yóò sì ní kóòdù ní agbègbè ìpínlẹ̀ rẹ. Èyí le ṣe ìrànwọ́ nígbà tí o bá ń ṣe àwọn ìwádìí tó ṣe kókó. Àfi bí ó bá ṣe pàtàkì pátápátá, yàgò fún fífi àwọn italólobó ìròyìn ara rẹ tí wọ́n fi le dá ọọ mọ̀ sórí ẹ̀rọ ayélujára TOR.

Lo Ẹ̀rí Ìwọlé sí Orí Ẹ̀rọ-Ayélujára tó Lágbára

Ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé tó dára nìkan ni ohun tí ó da olùkọlù dúró láti ní àǹfààní sí wíwọ orí àkọọ́lẹ̀ rẹ.

 • Gbogbo ènìyàn mọ̀ wí pé o lo ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé kan náà ní gbogbo ibi. Jáwọ́ kúrò nínu lílo ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé kan náà ní gbogbo ibi.
 • Rò ó láti lo olùṣàkóso ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé. Olùṣàkóso ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé máa ń ranni lọ́wọ́ láti bójútó gbogbo ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé ẹni, ó tún le ṣe ìrànwọ́ láti dàrọ ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé tí kò létò. Ó tún jẹ́ ọ̀nà tó rọni lọ́rùn láti fi ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ sí i láìfọwọ́yi, fífi àkókò pamọ́ àti orí fífọ́ lásìkò tí o bá ń kún àwọn àyè inú fọ́ọ̀mù. Díẹ̀ nínú àwọn ohunèlò tó jẹ́ gbajúgbajà níṣe pẹ̀lú 1Password àti KeePassX (ọ̀fẹ́).
 • Lo ìgbésẹ̀-méjì ẹ̀rí ìwọlé sórí ẹ̀rọ-ayélujára. Ìgbésẹ̀-méjì ẹ̀rí ìwọlé sórí ẹ̀rọ-ayélujára máa ń ṣe àfikún ipele ààbò sórí ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ, bíbèèrè fún àlàyé kan si kí o tó le ní àǹfààní sí àkọọ́lẹ̀ rẹ. Ní ọ̀nà tó wọ́pọ̀, èyí ni nọ́ḿbà tí wọ́n máa ń fi ránsẹ́ sí orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ nípa SMS tàbí Ápùù orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ, bí i Google Authenticator. Àìmọye isẹ́ orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tó jẹ́ gbajúgbajà ní ó fàyè gba àfikún ìgbéṣẹ̀-méjì fún ẹ̀rí ìwọlé sórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá sí orí àkọọlẹ̀ rẹ, ó ń jẹ́ kó nira fún àwọn tí kò láṣẹ ẹnì-kẹta láti ní àǹfààní sí àkọọ́lẹ̀ rẹ.

Lo ìgbésẹ̀-méjì ẹ̀rí ìwọlé sórí ẹ̀rọ-ayélujára níbikíbi tí ó bá ti ṣe é ṣe, ṣùgbọ́n pàápàá jù lọ ímèèlì tó ṣe kókó, ó kéré tán, wọ́n le ráyè wọ inú àwọn àkọọ́lẹ̀ rẹ mìíràn lórí ìtàkùn nípa títún ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ tò, tó gbáralé ẹ̀rí ìwọlé sórí ẹ̀rọ-ayélujára ímèèlì. Àwọn tó ń lo ímèèlì le to ìgbésẹ̀-méjì ẹ̀rí-ìwọlé sorí ẹ̀rọ-ayélujára níbí.

Ṣọ́ra Fún Ẹgbẹ́ Kẹta

Dájúdájú, àsopọ̀ tó ní ààbò sí orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá le tú àṣírí ìbáraẹnisọ̀rọ wa bí òpin-àjò bá ní agbára láti pín àwọn ìṣe oníbàárà pẹ̀lú ẹgbẹ́ kẹta. Fún àpẹẹrẹ, àyàfi bí yàrá-ìròyìn yín bá gbàlejò olùpín ímeèlì ti wọn, àǹfààní pé yàrá-ìròyìn yín lo olùpèsè ímeèlì ohun-ìní tí ó le jẹ́ kí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yín má nì í kóòdù mọ́. Ọ̀pọ̀ àjọ ìròyìn ni ó máa ń ṣe é. Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí a bá bá àwọn orísun wa sọ̀rọ̀, a máa ń sábà fi àpẹẹrẹ nípa àwọn ohun tí a  sọ̀rọ̀ lé lórí sílẹ̀ ní ẹ̀dà déétà tó ń ṣàpèjúwe déétà mìíràn – àlàyé lóri ẹni tó ń sọ̀rọ̀ sí ta ni, ìgbà náà, àti bí ó ṣe pẹ́ tó. Àwọn èyí kò jẹ́ ìṣòro àròsọ àbá ìpìlẹ̀ fún àwọn àjọ ìròyìn. Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún 2013, Ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ tẹlifóònù ti ìfìwépè ìdájọ́ fún àkọsílẹ̀ ẹ̀rọ-ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí àwọn oníròyìn fún poṣù méjì ní ìtapọ̀ ilé-iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde. Nínú ọ̀rọ̀ mìíràn, a máa ń sábà fi ọkàn tọ́ déétà wa sí àwọn ilé-iṣẹ́  tí ó le má a (tinútinú tàbí àìmọ̀ọ́mọ̀) pín in pẹ̀lú ẹgbẹ́ kẹta.

Wà Ní Àìléwú Nígbà To Bá Ń Sọ̀rọ̀

Dídá ààbò bo ìbáraẹnisọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ tàbí àwọn orísun rẹ tí ń rọrùn.

 • Bí ìrònú bá bá ọ lórí àṣírí àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ rẹ SMS tàbí àwọn ìpè tí o gbà lórí ẹ̀rọ-ibanisọ̀rọ̀ rẹ, lo ìfihàn tó lágbára iOS tàbí Android láti fi kóòdù sí apwọn àtẹ̀ránsẹ́ rẹ. Rò ó láti bi àwọn orísun láti lò ó láti fi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ; ó rọrùn láti lo ìfihàn tó lágbára bí i ọ̀pọ̀ àtẹ̀ránṣẹ́ tí kò yí padà ní orí ápùù.
 • Ohun ìyàlẹ́nu ni pé gbajúgbajà ẹ̀rọ ayárabíàṣá WhatsApp iOS àti Android wá ń lo òpin-sí-ìparí kóòdù. Ẹ̀rọ ayárabíàṣá WhatsApp ń lo kóòdù tí ó farapẹ́ ìfihàn tó lágbára. Pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún ti mílíọ̀nù aṣàmúlò, ó ṣe é ṣe kí àwọn orísun rẹ ti máa lo ẹ̀rọ ayárabíàṣá WhatsApp tẹ́lẹ̀ rí, tí ó jẹ́ wí pé wà á kàn nílò láti fi ẹnìkọ̀ọ̀kan kún un ní orí ápùù ni. Ní i lọ́kàn pé, síbẹ̀síbẹ̀ pé ìfihàn tó lágbára àti ẹ̀rọ ayárabíàṣá WhatsApp kò fún àwọn tó ń ṣàmúlò rẹ̀ ní ìfipamọ́-orúkọ. (Ṣọ́ra: Àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn nípa àìlágbára ẹ̀rọ ayárabíàṣá WhatsApp ní ọdún 2019 mú ìmọ̀ràn yìí wá ní kíákíá láti ìgbìmọ̀ láti dáàbò bo àwọn oníròyìn.)
 • Àwọn ìwọ̀fún kan wà fún fífún ímeèlì rẹ ní kóòdù. Ní èyí tó ti pẹ́, èyí tó jẹ́ gbajúgbajà jù ni PGP, èyí tí ó máa ń ranni lọ́wọ́ láti fún àkóónú ímeèlì ní kóòdù. Nígbà tí o bá ń lo PGP, ilà kókó ọ̀rọ̀ àti àwọn ààyè àdírẹ̀sì ímeèlì kò ní ààbò. Ìmúṣẹ Orísun tó ṣí sílẹ̀ ti PGP ni à ń pè ní GnuPG, tí a tún le lò lórí Mac OS X, ẹ̀rọ ayárabíàṣá Windows, àti ẹ̀rọ ayárabíàṣá Linux. Ó fi ọ̀nà kan ní àríyànjiyàn nínu agbègbè ààbò nítorí pé ó jẹ́ àmúdijú tó ṣẹ̀tọ́, ó sì lè jẹ́ ìdúnàdúrà ńlá ti àkókò àti ìlàkàkà láti ṣètò. Ó sì tún le rọrùn láti ṣe àṣìṣe tí o lè fa kí ààbò aṣàmúlò fọ́. Ní ojú-ẹsẹ̀ yẹn, PGP fi kóòdù sí àkóónú, ju déétà tó ń ṣàlàyé déétà mìíran nínú àtẹ̀ránṣẹ́ lọ. Ní pàtàkì, kò dá ààbò bo ìdánimọ̀ àwọn olùkópa nínu ímeèlì. Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, PGP kò ṣe ìrànwọ́ láti dá ààbò bo ìforúkọpamọ́ àwọn orísun rẹ.

Ṣíṣètọ́jú ìforúkọpamọ́ bèèrè fún gbígbájúmọ́ déétà tó ń ṣàlàyé déétà mìíràn nípa àwọn ọ̀rọ̀ àjọsọ wa.

 • Bí o bá ń wá ààyè fún ìdánìkan wà nígbà tí ó bá ń bá ènìyàn sọ̀rọ̀, ro ẹ̀rọ ayárabíàṣá Ricochet láti sọ̀rọ̀ láìforúkọhàn lórí nẹ́tíwọ̀kì TOR. Ní ìdàkejì, Òjíṣẹ̀ TOR le jẹ́ irú iṣẹ́ tó fara pẹ́ ẹ. Òjíṣẹ́ TOR tún máa ń mú àwọn ìwọ̀fún fún ìgbàláàyè àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ tó ní kóòdù láti iṣẹ́ ohun-ìní bí i ẹ̀rọ ayárabíàṣá Google’s Hangouts messanger, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìwọ̀fún gédéńgbé. Èyí ní àwọn ohun èlò díẹ̀ tó rọrùn láti lò láti dá ààbò bo déètà tó ń ṣàlàyé déétà mìíràn àti àkóónú àtẹ̀ránṣẹ́ náà. Ó ṣeni láànú pé bí orísun rẹ bá kàn sí ọ nípasẹ̀ ìpè lórí fóònù déédé, àtẹ̀ránṣẹ́, tàbí ímèèlì, déétà tó ń ṣàlàyé déétà mìíràn tí wà tó ń tọpa rẹ. Jẹ́ kí àlàyé ìbánisọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ ògúnná (fún àpẹẹrẹ, lórí átíkù àti lójú-ewé àgbà-ọ̀jẹ̀) kí àwọn orísun rẹ mọ̀ pé o wa láyé láti ara ìtàkùn ìforúkọpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nílò.
 • Àwọn ohun èlò tó tayọ wà fún ríran àwọn orísun lọ́wọ́ láti so pọ̀ tàbí pín àwọn fáìlì pẹ̀lú àwọn oníròyìn aforúkọpamọ́, bí i ẹ̀rọ ayárabíàṣá SecureDrop, tí ó jẹ́ wí pé Àjọ Òmìnira ti àwọn Oníròyìn ni ó ṣètọ́jú rẹ̀. Dájúdájú, lílo ẹ̀rọ ayárabíàṣá SecureDrop bí ó ti yẹ bèèrè fún ìtọ́jú ju bí ó ti yẹ lọ ní apá àwọn orísun. Bí Intercept ṣe ṣàpèjúwe ní píráímà wọn tí tú àṣírí síta pẹ̀lú ẹ̀rọ ayárabíàṣá SecureDrop, àwọn ọ̀na pọ̀ tó wà láti ṣèṣì tú àsírí lóri déétà ara ẹni síta.   
 • Ó dá lé ipò rẹ, sísọ̀rọ̀ láti orí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ẹlòmíràn tàbí pípádé ara ẹni lójúkorojú le jẹ́ ọ̀nà tó rọrùn láti dín ìfẹsẹ̀tẹ̀ ẹ̀rọ ayélujára rẹ kùn. Èyí le jẹ́ àtúnṣe tó mú ọgbọ́n dání bí o bá ń ro “tó kéré jù” ìhalẹ̀mọ́ni ààbò.

Àṣírí Bárakú àti Ààbò 

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà tó rọrùn láti dá ààbò bo ara rẹ lórí ìtàkùn bèèrè ètò àsìkò-kan. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ààbò máa ń rí àǹfàání tó bèèrè fún ìbátan akitiyan kékeré.

 • Ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ ayélujára HTTP tí kò láàbò tún ní àwọn HTTPS tó láàbò ti ẹ̀yà orí-ìtàkùn wà. Gba HTTP Eẹerywhere fún Firefox tàbí Chrome láti ṣe ìgbésókè láìpariwo fún ìsopò nígbà tí o bá ń lo kiri ayélujára.
 • Ọ̀pọ̀ àwọn orí ìtàkùn ayélujára máa palọ́lọ́ ní ipa-ọ̀nà ibi to wà nípa lílo àwọn fáìlì tí wọ́n ń pè ní cookies, tí wọ́n máa ń fi pamọ́ sí orí-ìtàkun ayélujára rẹ bí o bá ṣe ń rékọjá àwọn ìtàkùn. Ní àpapọ̀, àwọn ẹ̀rọ ayélujára cookies le fún ọ ní àpapọ̀ tó gúnrégé tó ṣe déédé sí àwọn ibi tí ó máa ń wọlé sí lórí ìtàkùn ayélujára. O lè dínà àwọn ipasẹ̀ cookies ní ọ̀nà tó rọrùn nípa lílo àwọn tó ń já wọlé àṣírí fún Google Chrome or Firefox .
 • Bí o bá kàn ọ́ nípa àwọn fáìlì rẹ tí ó wà ní apá àwọn ẹgbẹ́ kẹta, rò ó láti lo “òdo ìmọ̀” iṣẹ́ kíláùdì

tí ó le gbàlejò déétà rẹ nígbà tí o bá ń fi àṣírí pamọ́ nítorí wọn kò ní kọ́kọ́rọ́ láti yọ kóòdù déétà rẹ. Fún àpẹẹrẹ, SpiderOak ṣe àtìlẹyìn fún fáìlì, ju bí Dropbox. Bẹ́ẹ̀ sì ni, iṣẹ́ òdo ìmọ̀ Crashplan le ṣe àtìlẹyìn ẹ̀rọ fún fífi déétà pamọ́ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kò rí àǹfààní sí àwọn ẹ̀rọ rẹ. Àlúyìpadà wà: pẹ̀lú púpọ̀ iṣẹ́ òdo ìmọ̀, o kò le gba àkáùtì rẹ padà ní kíákíá bí o bá gbàgbé ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ. Ó ṣe pàtàkì láti fi ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé rẹ pamọ́ sí ibi tí o ó ti rí àǹfààní sí i àti ibi tí ó ní ààbò.

 • Wo àwòfín sí URLs ní líǹkì kí o tó tẹ̀ wọ́n. Bí ohunkóhun bá wò yàtọ̀, lọ pẹ̀lú ọkàn rẹ; ó ṣe é se kí ó jẹ́ líǹkì tó jẹ́ ayédèrú tí wọ́n dàrọ bí òpin-àjò tó wù ọ́. Olùjáwọlé gbáralé àwọn àṣìṣe láti fi àwọn ayédèrú ímeèlì ránṣẹ́ lórí ìtàkùn ayélujára níbi ti a ti le tẹ àwọn orúkọ tí a ṣàmúlò tó bá òfin mu àti àwọn ọ̀rò-ìgbaniwọlé. Fún àpẹẹrẹ paypal.com paypal.server1314.com àti paypal.com ( pẹ̀lú 1 kan) le jọ ara wọn láìkíyèsí ara wọn. Àjọ Òmìnira ti Oníròyìn ṣe àgbéjáde ìtọ́nisọ́na tó péye pẹ̀lú àwọn àlàyé lórí bí wọ́n ṣe le gbèjà tó lòdì sí ayéderú ímeèlì.
 • Bí ara bá ń fun ọ́ lórí àwọn ìwé-àṣẹ tí o ti gbà (fún àpẹẹrẹ, lórí ímeèlì), dídánwò bí ó ti le rí, má ṣe fi lọ́lẹ̀ lórí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà rẹ. Lẹ́ẹ̀kan si, wo àwòfín kí o gbé fáìlì síta. Bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ bóyá ìfẹ̀lójú yìí mú ọpọlọ dání. Bí ẹni yẹn bá ń fi fáìlì tí a fẹ̀ lójú ránṣẹ́ fún ọ tí o máa reti láti jẹ́ .pdf tàbí .doc, nǹkankan le jẹ́ àṣìṣe. Àwọn fáìlì tó-ń-wò-bi-ìbófinmu le ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá malware. Ju kí o wá gbé ìwé-àṣẹ tó mú ìfunra dání lórí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà rẹ, rò ó láti lo Google Docs láti fi ṣí wọn. Bí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn pé Google ní àǹfààní sí fáìlì rẹ, èyí le jẹ́ ọ̀nà tó yá àti tó ní ipa láti wo àwọn ìwé-àṣẹ láìléwu.
 • Bẹ́ẹ̀, pa ẹ̀rọ rẹ mọ́, software, àti èyí tó lòdì sí ààrùn ìmúdojú-ìwọ̀n déédé. Rò ó láti ṣe ìmúdójú-ìwọ̀n tó kọni lóminú láìfọwọ́yí nígbàkúùgbà tó bá ṣe é ṣe. Àwọn Olùjáwọlé, Àwọn Olùwádìí àti àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò ń dá àwọn ihò titun mọ̀ nínú ẹ̀rọ ayárabíàṣá software, àti pé àwọn ihò nígbà mìíràn máa ń gbé e jáde pẹ̀lú àwọn òṣèré tó ń yan odì láti rí àǹfààní sí àwọn ẹ̀rọ. Ìmúdójú-ìwọ̀n le bíni nínú nígbà mìíràn, ṣùgbọ́n ó le rọrùn láti dí àwọn ihò yìí.

Fi Kóòdù Sí Ẹ̀rọ Rẹ. 

Bí ẹnikẹ́ni bá jí ẹ̀rọ rẹ tí kò ní ààbò, ó rọrùn láti ní àǹfààní sí fáìlì rẹ tàbí jí hard drive rẹ. Pẹ̀lú oríire, ó tún rọrùn fún àwọn oníròyìn láti fi kóòdù sí àwọn ẹ̀rọ wọn. Bí o bá ni ẹ̀rọ ayárabíàṣá iPhone tí ó sì ní kóòdù ọ̀rọ̀-ìgbaniwọlé, àǹfààní gidi wà pé ẹ̀ro ìbánisọ̀rọ̀ rẹ ti ní kóòdù tẹ̀lẹ́. O tún le kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi kóòdù sí ẹ̀rọ ayárabíàṣá Android níbi. Bí o bá lo Mac OS X, o lè lo kóòdù sí àwọn ẹ̀rọ rẹ nípa nílo FileVault. Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí o bá jẹ́ ẹni tó ń ṣàmúlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá Windows, àwọn ẹ̀yà kan má agbà ọ́ láàyè láti lo kóòdù sí ẹ̀rọ rẹ pẹ̀lú BitLocker. 

Ní ìparí, ṣe àwọn nǹkan tí o mọ̀ wí pé ó yẹ kí o ṣe. Mo ti ṣe àbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn yàrá-ìròyìn níbi tí àwọn oníròyìn kò ti ti àwọn èbúté wọn nígbà tí wọ́n rìn kúrò ní ìdí kọ̀m̀pútà wọn. (lórí Windows, ti èbúté rẹ pẹ̀lú Windows+L. Lórí Mac, lo àwọn igun tó gbóná láti ti èbúté rẹ ní kíákíá.) yàgò fún fífi àwọn kọ́kọ́rọ́ USB àìmọ̀ sí àwọn ẹ̀rọ rẹ, tàbí ìfilọ́lẹ̀ àwọn fáìlì láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí o kò mọ̀. wọ́n le kún fún àwọn software apanilára.

Bẹ̀rẹ̀ Ní Ìrọrùn Bẹ̀rẹ̀ Nísinyìí

Kò sí àtúnṣe “ìwọ̀n kan bá gbogbo mu” sí ẹ̀rọ ayélujára ààbò, ṣùgbọ́n óyẹ kí èyí ranni lọ́wọ́ láti bẹ̀ẹ̀rẹ̀. kọ́ si bí wọ́n ṣe ń dá ààbò bo ara ẹni nípa ṣíṣe ìwádìí lórí ààbò ohun èlò. Àwọn ìwà ààbò tó rọrùn yìí le ṣe ìrànwọ́ láti jẹ́ kí yàrá-ìròyìn jẹ́ agbègbè tí ó ní ààbò. Èyí ni nípa fífi inú tán an àti àìléwu àwọn orísun, àti pé díndín ìfìfẹ́  láti tú àṣírí déétà yàrá-ìròyìn kù sí àwọn Olùfiran. Ní pàtàkì, èyií ni nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìròyìn tó múnádóko nípa níní òye ìkànnì ní èyí tó mú kí àlàyé rẹ ṣàn, àti bí o ṣe le ṣàkóso rẹ̀ dáradára.

Ìtàn yìí jẹ́ àkọ́ṣe lórí ìtàkùn ti orísun tí wọ́n ṣe àtúntẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lu gbígba ààyè. 

Martin Shelton jẹ́ ẹlẹgbẹ́ e Knight-Mozilla OpenNews ní ọdún 2016 tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú isẹ́ àkànṣe Coral ní New York Times. Martin ṣètọ́jú iṣẹ́ àkànṣeTinfoil, agbègbè fún kíkọ́ nípa iṣẹ́ ìròyìn àti ààbò ìròyìn. Ó ti fìgbà kan rí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìwádìí Àṣírí Google’s àti ẹgbẹ́ aṣàpẹẹrẹ àti ìwádìí Pew, àti ẹ̀rọ ayárabíàṣá Twitter gẹ́gẹ́ bi akọ́sẹ́.